Ẹ̀KỌ́ 37
Jèhófà Bá Sámúẹ́lì Sọ̀rọ̀
Élì tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà ní àwọn ọmọkùnrin méjì tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ àlùfáà nínú àgọ́ ìjọsìn. Hófínì àti Fíníhásì lorúkọ wọn. Wọn ò pa òfin Jèhófà mọ́ rárá, wọ́n sì ń hùwà tí kò dáa sáwọn èèyàn. Táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá mú ẹbọ wá fún Jèhófà, Hófínì àti Fíníhásì máa mú èyí tó dáa jù lára ẹran tí wọ́n fẹ́ fi rúbọ. Élì gbọ́ nípa ohun táwọn ọmọ ẹ̀ ń ṣe, àmọ́ kò ṣe nǹkan kan sí i. Ṣé Jèhófà máa gbà kírú ìwà yìí máa bá a nìṣó?
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Sámúẹ́lì kéré sí Hófínì àti Fíníhásì, kò hùwà búburú ní tiẹ̀. Inú Jèhófà sì ń dùn sí Sámúẹ́lì. Lálẹ́ ọjọ́ kan, nígbà tí Sámúẹ́lì ń sùn, ó gbọ́ ohùn kan tó pe orúkọ ẹ̀. Ó sáré dìde lọ bá Élì, ó sì sọ pé: ‘Èmi nìyí!’ Àmọ́ Élì sọ pé: ‘Mi ò pè ẹ́. Pa dà lọ sùn.’ Ni Sámúẹ́lì bá pa dà lọ sùn. Ó tún gbọ́ ohùn náà lẹ́ẹ̀kejì. Nígbà tí Sámúẹ́lì gbọ́ ohùn náà lẹ́ẹ̀kẹta, Élì wá rí i pé Jèhófà ló ń pe Sámúẹ́lì. Ni Élì bá sọ fún un pé tó bá tún gbọ́ ohùn náà, kó sọ pé: ‘Jèhófà, sọ̀rọ̀. Ìránṣẹ́ rẹ ń gbọ́.’
Sámúẹ́lì wá pa dà lọ sùn. Lẹ́yìn náà, ó gbọ́ tí ohùn náà sọ pé: ‘Sámúẹ́lì! Sámúẹ́lì!’ Ó wá dáhùn pé: ‘Sọ̀rọ̀, nítorí ìránṣẹ́ rẹ ń gbọ́.’ Jèhófà sọ fún un pé: ‘Sọ fún Élì pé, màá fìyà jẹ òun àti ìdílé rẹ̀. Ó mọ̀ pé àwọn ọmọ òun ń hùwà tí kò dáa nínú àgọ́ ìjọsìn, àmọ́ kò ṣe nǹkan kan sí i.’ Nígbà tílẹ̀ mọ́, Sámúẹ́lì ṣílẹ̀kùn àgọ́ ìjọsìn bó ti máa ń ṣe. Ẹ̀rù ń bà á láti jíṣẹ́ tí Jèhófà rán an sí Élì àlùfáà àgbà. Àmọ́, Élì ránṣẹ́ sí i, ó sì béèrè lọ́wọ́ ẹ̀ pé: ‘Ọmọ mi, kí ni Jèhófà sọ fún ẹ? Sọ gbogbo ẹ̀ fún mi.’ Ni Sámúẹ́lì bá jíṣẹ́ fún Élì.
Bí Sámúẹ́lì ṣe ń dàgbà, Jèhófà ò fi í sílẹ̀. Gbogbo ilẹ̀ náà làwọn èèyàn ti mọ̀ pé Jèhófà ti yan Sámúẹ́lì láti jẹ́ àlùfáà àti adájọ́.
“Nítorí náà, rántí Ẹlẹ́dàá rẹ Atóbilọ́lá nígbà ọ̀dọ́ rẹ.”—Oníwàásù 12:1