Ẹ̀KỌ́ 44
Wọ́n Kọ́ Tẹ́ńpìlì fún Jèhófà
Lẹ́yìn tí Sólómọ́nì di ọba Ísírẹ́lì, Jèhófà béèrè lọ́wọ́ ẹ̀ pé: ‘Kí lo fẹ́ kí n fún ẹ?’ Sólómọ́nì sọ pé: ‘Ọmọdé ni mí, torí náà mi ò gbọ́n. Jọ̀ọ́, fún mi ní ọgbọ́n tí màá lè fi bójú tó àwọn èèyàn ẹ.’ Jèhófà dáhùn pé: ‘Torí pé ọgbọ́n lo béèrè, màá sọ ẹ́ dẹni tó gbọ́n jù láyé. Màá sì jẹ́ kó o lówó gan-an. Tó o bá ṣe ohun tí mo fẹ́, wàá pẹ́ láyé.’
Sólómọ́nì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ tẹ́ńpìlì, ó lo àwọn nǹkan tó dáa gan-an láti fi kọ́ tẹ́ńpìlì náà, irú bíi wúrà, fàdákà, igi àti òkúta. Àìmọye èèyàn lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló pawọ́ pọ̀ kọ́ tẹ́ńpìlì náà. Ọdún méje (7) ni wọ́n fi kọ́ ọ, lẹ́yìn náà wọ́n yà á sí mímọ́ fún Jèhófà. Pẹpẹ tí wọ́n kọ́ sínú ẹ̀ ni wọ́n ti máa ń rúbọ. Sólómọ́nì kúnlẹ̀ síwájú pẹpẹ náà, ó sì gbàdúrà pé: ‘Jèhófà, tẹ́ńpìlì yìí tóbi lóòótọ́, ó sì rẹwà, àmọ́ kò lè gbà ọ́. Mo bẹ̀ ọ́, máa gbọ́ àdúrà wa, kínú ẹ sì dùn sí ìjọsìn wa.’ Ṣé inú Jèhófà dùn sí tẹ́ńpìlì yẹn, ṣé ó sì gbọ́ àdúrà Sólómọ́nì? Bẹ́ẹ̀ ni. Torí pé kò pẹ́ tí Sólómọ́nì gba àdúrà náà tán ni iná wá láti ọ̀run, ó sì jó gbogbo ẹbọ tí wọ́n kó sórí pẹpẹ. Ìyẹn fi hàn pé inú Jèhófà dùn sí tẹ́ńpìlì náà. Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn, inú wọn dùn gan-an.
Ibi gbogbo làwọn èèyàn ti ń gbọ́ pé Ọba Sólómọ́nì gbọ́n gan-an, kì í ṣe nílẹ̀ Ísírẹ́lì nìkan. Torí náà, àwọn èèyàn máa ń gbé ìṣòro wọn wá sọ́dọ̀ ẹ̀ pé kó bá wọn yanjú ẹ̀. Ọbabìnrin ilẹ̀ Ṣébà tiẹ̀ béèrè àwọn ìbéèrè tó ta kókó lọ́wọ́ Sólómọ́nì. Ṣùgbọ́n nígbà tó rí bí Sólómọ́nì ṣe dáhùn àwọn ìbéèrè ẹ̀, ó sọ pé: ‘Mi ò kọ́kọ́ gba ohun táwọn èèyàn sọ nípa ẹ gbọ́, àmọ́ èmi fúnra mi ti wá rí i pé ọgbọ́n ẹ kọjá ohun táwọn èèyàn sọ. Jèhófà Ọlọ́run tó ò ń sìn ti bù kún ẹ gan-an.’ Lásìkò yẹn, nǹkan ń lọ dáadáa nílẹ̀ Ísírẹ́lì, inú àwọn èèyàn sì ń dùn. Àmọ́, nǹkan máa tó yí pa dà.
“Ẹ wò ó! ohun kan tó ju Sólómọ́nì lọ wà níbí.”—Mátíù 12:42