ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 7/1 ojú ìwé 30-31
  • Ìbẹ̀wò Kan Tó Lérè Púpọ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbẹ̀wò Kan Tó Lérè Púpọ̀
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìròyìn Tó Fani Lọ́kàn Mọ́ra
  • Àwọn Ìbéèrè Apinnilẹ́mìí, Àwọn Ìdáhùn Títẹ́nilọ́rùn
  • Ẹ̀kọ́ Tí A Rí Kọ́
  • Nígbà Tí Ìwà Ọ̀làwọ́ Bá Pọ̀ Gidigidi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Sólómọ́nì Fọgbọ́n Ṣàkóso
    Kí Ló Wà Nínú Bíbélì?
  • Ọbabìnrin Ṣébà Mọyì Kéèyàn Jẹ́ Ọlọ́gbọ́n
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2023
  • Máa Yin Jèhófà Nítorí Ọgbọ́n Rẹ̀
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2022
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 7/1 ojú ìwé 30-31

Wọ́n Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà

Ìbẹ̀wò Kan Tó Lérè Púpọ̀

ÌRÌN àjò láti Ṣébà sí Jerúsálẹ́mù ti ní láti jẹ́ kó rẹ ọbabìnrin náà tẹnutẹnu. Ẹni tó jẹ́ pé ìgbésí ayé oníyọ̀tọ̀mì ló ń gbé. Tó wá ń rin ìrìn àjò elégbèjìlá [2,400] kìlómítà báyìí lórí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, tó sì jẹ́ pé aṣálẹ̀ tó gbóná gan-an ló pọ̀ jù nínú àwọn ọ̀nà tí yóò gbà kọjá. Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí àwọn kan fojú díwọ̀n, ìrìn àjò náà ti ní láti gbà á tó nǹkan bí ọjọ́ márùndínlọ́gọ́rin, bẹ́ẹ̀ àlọ nìkan nìyẹn o!a

Èé ṣe tí ọbabìnrin ọlọ́rọ̀ yìí fi ilé rẹ̀ onídẹ̀rùn ní Ṣébà sílẹ̀ tó sì rin irú ìrìn àjò tí ń tán ni lókun bẹ́ẹ̀?

Ìròyìn Tó Fani Lọ́kàn Mọ́ra

Ọbabìnrin Ṣébà wá sí Jerúsálẹ́mù lẹ́yìn tó “ń gbọ́ ìròyìn nípa Sólómọ́nì ní ìsopọ̀ pẹ̀lú orúkọ Jèhófà.” (1 Ọba 10:1) A kò sọ ohun tí ọbabìnrin náà gbọ́ ní pàtó. Àmọ́, a mọ̀ pé Jèhófà fi ọgbọ́n gígalọ́lá, ọrọ̀, àti ọlá jíǹkí Sólómọ́nì. (2 Kíróníkà 1:11, 12) Báwo ni ọbabìnrin náà ṣe wá mọ̀ nípa èyí? Níwọ̀n bí Ṣébà ti jẹ́ ibùdó ìṣòwò, ó lè jẹ́ ẹnu àwọn oníṣòwò tó ń wá sí orílẹ̀-èdè rẹ̀ ló ti gbọ́ nípa òkìkí Sólómọ́nì. Ó ṣeé ṣe kí àwọn kan lára wọn ti dé Ófírì, níbi tí Sólómọ́nì ní òwò tó jọjú sí.—1 Ọba 9:26-28.

Ohun yòówù tí ìbáà jẹ́, ọbabìnrin náà dé Jerúsálẹ́mù “pẹ̀lú ẹgbẹ́ ọbabìnrin wíwúnilórí gan-an, àwọn ràkúnmí tí ó ru òróró básámù àti wúrà púpọ̀ gan-an àti àwọn òkúta iyebíye.” (1 Ọba 10:2a) Àwọn kan sọ pé àwọn ẹ̀ṣọ́ tó dìhámọ́ra wà lára “ẹgbẹ́ abánirìn wíwúnilórí gan-an” náà. Èyí kò lè fa họ́wùhọ́wù, táa bá fojú inú wò ó pé ọbabìnrin náà jẹ́ ẹni ńlá kan tó ń kó àwọn ohun iyebíye olóbìítíbitì owó lọ sí ìrìn àjò.b

Àmọ́ ṣá o, ṣàkíyèsí pé ọbabìnrin náà gbọ́ òkìkí Sólómọ́nì “ní ìsopọ̀ pẹ̀lú orúkọ Jèhófà.” Ó túmọ̀ sí pé kì í ṣe ọ̀ràn òwò ló bá wá. Ó hàn kedere pé, ohun tó gbé ọbabìnrin náà wá gan-an ni àtigbọ́ ọgbọ́n Sólómọ́nì—bóyá kó tiẹ̀ kọ́ nǹkankan nípa Ọlọ́run rẹ̀, Jèhófà, pàápàá. Ìgbà tó kúkú jẹ́ pé àtọmọdọ́mọ Ṣémù àti Hámù tí wọ́n jẹ́ olùjọsìn Jèhófà ni ọbabìnrin náà, ó ti lè máa hára gàgà láti mọ̀ nípa ìsìn àwọn baba ńlá rẹ̀.

Àwọn Ìbéèrè Apinnilẹ́mìí, Àwọn Ìdáhùn Títẹ́nilọ́rùn

Bí ọbabìnrin náà ṣe dé ọ̀dọ̀ Sólómọ́nì, ó bẹ̀rẹ̀ sí í fi “àwọn ìbéèrè apinnilẹ́mìí” dán an wò. (1 Ọba 10:1) A lè túmọ̀ ọ̀rọ̀ Hébérù táa lò níhìn-ín sí “àlọ́.” Àmọ́, èyí kò túmọ̀ sí pé ọbabìnrin náà kàn ń bá Sólómọ́nì tàkúrọ̀sọ lásán. Ó dùn mọ́ni pé ní Sáàmù 49:4, a lo ọ̀rọ̀ Hébérù kan náà fún àwọn ìbéèrè pàtàkì nípa ẹ̀ṣẹ̀, ikú, àti ìràpadà. Ó ṣeé ṣe nígbà náà kí ọbabìnrin Ṣébà máa bá Sólómọ́nì jíròrò àwọn ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ tó ń fi bí ọgbọ́n rẹ̀ ṣe pọ̀ tó hàn. Bíbélì sọ pé ó “sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a sọ ohun gbogbo tí ó wà ní góńgó ọkàn-àyà rẹ̀.” Sólómọ́nì, ẹ̀wẹ̀, “ń bá a lọ láti sọ gbogbo ọ̀ràn obìnrin náà fún un. Kò sí ọ̀ràn kankan tí ó fara sin fún ọba, tí kò sọ fún obìnrin náà.”—1 Ọba 10:2b, 3.

Ọgbọ́n Sólómọ́nì àti aásìkí ìjọba rẹ̀ wú ọbabìnrin Ṣébà lórí gan-an ni débi pé “kò wá sí ẹ̀mí kankan mọ́ nínú rẹ̀.” (1 Ọba 10:4, 5) Àwọn kan túmọ̀ gbólóhùn ọ̀rọ̀ yìí sí pé ọbabìnrin náà “sé èémí.” Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan tilẹ̀ sọ pé ó dákú! Èyí ó wù kó jẹ́, ẹnu ṣáà ya ọbabìnrin náà sí ohun tó rí àti èyí tó gbọ́. Ó pe àwọn ìránṣẹ́ Sólómọ́nì ní aláyọ̀ nítorí àǹfààní tí wọ́n ní láti gbọ́ ọgbọ́n ọba yìí, ó sì fi ìbùkún fún Jèhófà fún gbígbé tó gbé Sólómọ́nì sórí ìtẹ́. Lẹ́yìn náà ó wá fún ọba ní ẹ̀bùn olówó iyebíye, àpapọ̀ iye owó wúrà nìkan ń lọ sí nǹkan bí ogójì mílíọ̀nù dọ́là táa ba fi bí nǹkan ṣe rí lónìí ṣírò rẹ̀. Sólómọ́nì náà fún ọbabìnrin náà lẹ́bùn, ó fún un ní “gbogbo ohun tí ó jẹ́ inú dídùn rẹ̀, èyí tí òun béèrè.”c—1 Ọba 10:6-13.

Ẹ̀kọ́ Tí A Rí Kọ́

Jésù lo ọbabìnrin Ṣébà gẹ́gẹ́ bí kókó ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n kan fún àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisí. Ó sọ fún wọn pé: “A óò gbé ọbabìnrin gúúsù dìde ní ìdájọ́ pẹ̀lú ìran yìí, yóò sì dá a lẹ́bi; nítorí pé ó wá láti àwọn òpin ilẹ̀ ayé láti gbọ́ ọgbọ́n Sólómọ́nì, ṣùgbọ́n, wò ó! ohun kan tí ó ju Sólómọ́nì lọ wà níhìn-ín.” (Mátíù 12:42) Dájúdájú, ọbabìnrin Ṣébà fi ìmọrírì ńlá hàn fún ọgbọ́n tí Ọlọ́run fún ọba náà. Bí òun bá rin ìrìn àjò egbèjìlá [2,400] kìlómítà láti fetí sí Sólómọ́nì, láìsí àní-àní, ó yẹ kí àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisí fetí sílẹ̀ dáadáa sí Jésù tó wà lọ́dọ̀ wọn gan-an.

Àwa lónìí pẹ̀lú lè fi ìmọrírì jíjinlẹ̀ hàn sí Sólómọ́nì Títóbi jù náà, Jésù Kristi. Lọ́nà wo? Ọ̀nà kan ni nípa pípa àṣẹ rẹ̀ mọ́, ìyẹn ni láti “máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn.” (Mátíù 28:19) Ọ̀nà mìíràn ni kí a gbé àpẹẹrẹ Jésù àti ẹ̀mí ìrònú rẹ̀ yẹ̀ wò kí a sì máa ṣàfarawé wọn.—Fílípì 2:5; Hébérù 12:2, 3.

Lóòótọ́, títẹ̀lé àpẹẹrẹ Sólómọ́nì Títóbi jù yóò gba pé ká sapá gidigidi. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èrè la óò rí gbà. Láìṣe àní-àní, Jèhófà ṣèlérí fún àwọn ènìyàn rẹ̀ pé bí wọ́n bá fi ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ hàn, òun óò ‘ṣí ibodè ibú omi ọ̀run fún wọn, òun ó sì tú ìbùkún dà sórí wọn ní ti tòótọ́ títí kì yóò fi sí àìní mọ́.’—Málákì 3:10.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ọ̀pọ̀ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ló gbà gbọ́ pé gúúsù ìwọ̀ oòrùn Arébíà, táa wá ń pè ní Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti Yemen lónìí, ni Ṣébà wà nígbàanì.

b Gẹ́gẹ́ bí ohun tí Strabo, ọmọ ilẹ̀ Gíríìkì ìgbàanì tó mọ̀ nípa ilẹ̀, sọ, àwọn ara Ṣébà lówó bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀. Ó sọ pé wọ́n máa ń fi wúrà dára sára àwọn nǹkan ọ̀ṣọ́ ilé wọn, àti àwọn ohun èlò wọn, kódà wọ́n fi ń bo ara ògiri, ilẹ̀kùn, àti àwọn òrùlé ilé wọn pàápàá.

c Àwọn kan gbà pé ohun tí gbólóhùn yìí ń sọ ni pé ọbabìnrin náà ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú Sólómọ́nì. Àwọn ìtàn àtẹnudẹ́nu tilẹ̀ sọ pé wọ́n bí ọmọkùnrin kan. Àmọ́, kò sí ẹ̀rí tó ti èyíkéyìí nínú rẹ̀ lẹ́yìn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́