Ẹ̀KỌ́ 50
Jèhófà Gbèjà Jèhóṣáfátì
Jèhóṣáfátì ọba Júdà wó gbogbo pẹpẹ táwọn èèyàn ti ń bọ òrìṣà Báálì nílẹ̀ náà. Ó fẹ́ káwọn èèyàn mọ òfin Jèhófà, torí náà ó rán àwọn ìjòyè àtàwọn ọmọ Léfì pé kí wọ́n máa kọ́ gbogbo èèyàn Júdà ní òfin Jèhófà.
Torí pé Jèhófà wà pẹ̀lú àwọn èèyàn ilẹ̀ Júdà, ẹ̀rù ń ba àwọn ọ̀tá láti wá gbéjà kò wọ́n. Kódà, ńṣe ni wọ́n máa ń kó ẹ̀bùn wá fún Ọba Jèhóṣáfátì. Àmọ́, àwọn ọmọ Móábù àtàwọn ọmọ Ámónì àtàwọn kan láti agbègbè Séírì wá bá àwọn èèyàn Júdà jagun. Jèhóṣáfátì mọ̀ pé Jèhófà nìkan ló lè ran àwọn lọ́wọ́. Ó wá pe gbogbo àwọn ọkùnrin àti obìnrin àtàwọn ọmọ kékeré pé kí wọ́n wá sí Jerúsálẹ́mù. Òun náà wá dúró síwájú wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbàdúrà, ó sọ pé: ‘Jèhófà, láìjẹ́ pé o ràn wá lọ́wọ́, a ò lè borí àwọn èèyàn yìí. Jọ̀ọ́ sọ ohun tá a máa ṣe fún wa.’
Jèhófà wá dáhùn àdúrà wọn, ó ní: ‘Ẹ má fòyà. Màá ràn yín lọ́wọ́. Ẹ dúró sáyè yín, ẹ dúró jẹ́ẹ́ kẹ́ ẹ sì rí bí màá ṣe gbà yín là.’ Báwo ni Jèhófà ṣe gbà wọ́n là?
Láàárọ̀ ọjọ́ kejì, Jèhóṣáfátì yan àwọn akọrin, ó sì sọ fún wọn pé kí wọ́n máa kọrin lọ níwájú àwọn ọmọ ogun. Báwọn ọmọ ogun ṣe ń yan tẹ̀ lé wọn nìyẹn títí wọ́n fi dé ojú ogun níbì kan tí wọ́n ń pè ní Tékóà.
Ńṣe lohùn àwọn akọrin ń dún lákọlákọ bí wọ́n ṣe ń fayọ̀ yin Jèhófà, Jèhófà sì gbèjà àwọn èèyàn ẹ̀. Ó da àárín àwọn ọmọ ogun Ámónì àti Móábù rú débi pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í bára wọn jà, wọ́n sì pa ara wọn tán pátápátá. Àmọ́ Jèhófà dáàbò bo àwọn èèyàn Júdà, àwọn ọmọ ogun wọn àtàwọn àlùfáà. Gbogbo àwọn ìlú tó wà lágbègbè wọn ló gbọ́ nípa ohun tí Jèhófà ṣe, èyí jẹ́ kó dá wọn lójú pé Jèhófà ló ń gbèjà àwọn èèyàn ẹ̀. Báwo ni Jèhófà ṣe ń gba àwọn èèyàn ẹ̀ là? Oríṣiríṣi nǹkan ló máa ń ṣe. Àmọ́ Jèhófà ò nílò ìrànlọ́wọ́ ẹnikẹ́ni láti dáàbò bo àwọn èèyàn ẹ̀.
“Kò ní sídìí fún yín láti ja ogun yìí. Ẹ dúró sáyè yín, ẹ dúró jẹ́ẹ́, kí ẹ sì rí ìgbàlà Jèhófà lórí yín.”—2 Kíróníkà 20:17