Ẹ̀KỌ́ 76
Jésù Lé Àwọn Tó Ń Tajà Nínú Tẹ́ńpìlì
Ní ọdún 30 Sànmánì Kristẹni, Jésù lọ sí Jerúsálẹ́mù. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló wá sílùú yẹn láti wá ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá. Ara nǹkan tí wọ́n máa ń ṣe nígbà àjọyọ̀ yìí ni pé wọ́n máa ń fi ẹran rúbọ nínú tẹ́ńpìlì. Àwọn kan máa ń mú ẹran tí wọ́n fẹ́ fi rúbọ wá látilé, àwọn míì sì máa ń rà á ní Jerúsálẹ́mù.
Nígbà tí Jésù lọ sí tẹ́ńpìlì, ó rí àwọn tó ń ta màlúù, àgùntàn àti àdàbà níbẹ̀. Ńṣe làwọn èèyàn yẹn ń ṣòwò nínú ilé Jèhófà. Ẹ ò rí i pé wọn ò bọ̀wọ̀ fún Jèhófà rárá! Kí ni Jésù wá ṣe? Ó fi okùn ṣe ẹgba, ó sì fi lé àwọn àgùntàn àti màlúù náà jáde kúrò nínú tẹ́ńpìlì. Ó da tábìlì àwọn tó ń ṣẹ́ owó nù, owó wọn sì dà sílẹ̀. Jésù wá sọ fáwọn tó ń ta ẹyẹ àdàbà níbẹ̀ pé: ‘Ẹ kó nǹkan yìí kúrò níbí! Ẹ má sọ ilé Bàbá mi di ọjà!’
Ẹnu ya àwọn èèyàn sí ohun tí Jésù ṣe yìí. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ wá rántí àsọtẹ́lẹ̀ kan tó wà nínú Ìwé Mímọ́ nípa Mèsáyà pé: ‘Ìtara fún ilé Jèhófà máa gbà mí lọ́kàn.’
Nígbà tó di ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, Jésù tún lé àwọn tó ń tajà kúrò nínú tẹ́ńpìlì. Ìdí sì ni pé Jésù ò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni sọ ilé Bàbá ẹ̀ di ibi ìtajà.
“Ẹ ò lè jẹ́ ẹrú Ọlọ́run àti Ọrọ̀.”—Lúùkù 16:13