ORÍ 16
Jésù Ní Ìtara Fún Ìjọsìn Tòótọ́
JÉSÙ FỌ TẸ́ŃPÌLÌ MỌ́
Lẹ́yìn ayẹyẹ ìgbéyàwó tó wáyé ní Kánà, Jésù rìnrìn àjò lọ sí Kápánáúmù. Ìyá rẹ̀ àtàwọn àbúrò rẹ̀, ìyẹn Jémíìsì, Jósẹ́fù, Símónì àti Júdásì náà wà pẹ̀lú rẹ̀.
Àmọ́ kí ló dé tí Jésù fi ń lọ sí Kápánáúmù? Ohun kan ni pé ìlú yìí tóbi ó sì tún gbajúmọ̀ ju ìlú Násárẹ́tì àti Kánà lọ. Yàtọ̀ síyẹn, Kápánáúmù àtàwọn agbègbè tó wà nítòsí rẹ̀ ni ọ̀pọ̀ lára àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọmọ ẹ̀yìn Jésù ń gbé. Torí náà, àǹfààní nìyẹn jẹ́ fún Jésù láti dá wọn lẹ́kọ̀ọ́ ní àdúgbò wọn.
Onírúurú iṣẹ́ ìyanu ni Jésù ṣe ní gbogbo àsìkò tó fi wà nílùú Kápánáúmù. Ọ̀pọ̀ àwọn aráàlú náà àtàwọn tó ń gbé láwọn agbègbè tó wà nítòsí ibẹ̀ gbọ́ ìròyìn àwọn nǹkan tó ṣe. Àmọ́ Jésù àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ gbọ́dọ̀ tètè bọ́ sọ́nà Jerúsálẹ́mù kí wọ́n lè lọ ṣe Ìrékọjá ti ọdún 30 S.K. torí pé Júù ni wọ́n, wọn ò sì fi ìjọsìn Ọlọ́run ṣeré.
Nígbà tí wọ́n dé tẹ́ńpìlì ní Jerúsálẹ́mù, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù rí ohun kan nípa Jésù tó ṣeé ṣe kí wọ́n má tíì rí rí, nǹkan náà sì wú wọn lórí gan-an.
Òfin Ọlọ́run sọ pé kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa fi ẹran rúbọ ní tẹ́ńpìlì, àwọn tó bá sì rìnrìn àjò wá láti ìlú míì máa nílò oúnjẹ lásìkò tí wọ́n fi máa wà ní Jerúsálẹ́mù. Torí náà, Òfin sọ pé àwọn tó bá wá láti ọ̀nà jíjìn lè mú owó dání kí wọ́n lè ra “màlúù, àgùntàn, ewúrẹ́” àtàwọn nǹkan míì tí wọ́n máa nílò lásìkò yẹn. (Diutarónómì 14:24-26) Látàrí èyí, àwọn oníṣòwò tó wà ní Jerúsálẹ́mù máa ń ta ẹran tàbí ẹyẹ nínú àgbàlá ńlá tẹ́ńpìlì. Ọ̀wọ́n gógó làwọn kan lára wọn sì ń ta ọjà wọn kí wọ́n lè rẹ́ àwọn èèyàn jẹ.
Nígbà tí Jésù rí àwọn tó ń tajà nínú tẹ́ńpìlì, inú bí i, ló bá da owó àwọn tó ń pààrọ̀ owó nù, ó dojú tábìlì wọn dé, ó sì lé àwọn ọkùnrin náà jáde. Ó wá sọ pé: “Ẹ kó àwọn nǹkan yìí kúrò níbí! Ẹ yéé sọ ilé Baba mi di ilé ìtajà!”—Jòhánù 2:16.
Nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù rí ohun tó ṣe yìí, wọ́n rántí àsọtẹ́lẹ̀ kan nípa Ọmọ Ọlọ́run, tó sọ pé: “Ìtara ilé rẹ máa gbà mí lọ́kàn.” Ṣùgbọ́n àwọn Júù bi Jésù pé: “Àmì wo lo máa fi hàn wá, torí o ti ń ṣe àwọn nǹkan yìí?” Jésù dá wọn lóhùn pé: “Ẹ wó tẹ́ńpìlì yìí lulẹ̀, màá sì fi ọjọ́ mẹ́ta kọ́ ọ.”—Jòhánù 2:17-19; Sáàmù 69:9.
Tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù ni àwọn Júù rò pé Jésù ń sọ, torí náà, wọ́n bi í pé: “Ọdún mẹ́rìndínláàádọ́ta (46) ni wọ́n fi kọ́ tẹ́ńpìlì yìí, ṣé ọjọ́ mẹ́ta lo máa wá fi kọ́ ọ?” (Jòhánù 2:20) Àmọ́, ara ẹ̀ ni Jésù pè ní tẹ́ńpìlì. Lẹ́yìn ọdún mẹ́ta, àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ rántí àwọn ọ̀rọ̀ yìí nígbà tó jíǹde.