ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • my ìtàn 89
  • Jésù Fọ Tẹ́ńpìlì Mọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jésù Fọ Tẹ́ńpìlì Mọ́
  • Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Jésù Lé Àwọn Tó Ń Tajà Nínú Tẹ́ńpìlì
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Itara fun Ijọsin Jehofa
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Jésù Ní Ìtara Fún Ìjọsìn Tòótọ́
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • Àwọn Ẹranko
    Jí!—2015
Àwọn Míì
Ìwé Ìtàn Bíbélì
my ìtàn 89
Jésù lé àwọn tó ń pààrọ̀ owó kúrò ní tẹ́ńpìlì, ó sì dojú tábìlì wọn dé

ÌTÀN 89

Jésù Fọ Tẹ́ńpìlì Mọ́

INÚ ń bí Jésù gidigidi níbí, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí inú fi ń bí i tó bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé àwọn èèyàn tó wà nínú tẹ́ńpìlì Ọlọ́run ní Jerúsálẹ́mù wọ̀nyí ya olójú kòkòrò púpọ̀. Wọ́n fẹ́ máa kó owó púpọ̀ jọ láti ọwọ́ àwọn èèyàn tó wá sínú tẹ́ńpìlì láti sin Ọlọ́run.

Ṣé o rí àwọn akọ màlúù kéékèèké àti àgùntàn àti ẹyẹlé wọ̀nyẹn? Ohun táwọn èèyàn wọ̀nyí ń tà nínú tẹ́ńpìlì níbí yìí gan-an nìwọ̀nyẹn. Ǹjẹ́ o mọ ìdí rẹ̀? Ìdí ni pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nílò àwọn ẹran àti ẹyẹ láti rúbọ sí Ọlọ́run.

Òfin Ọlọ́run sọ pé tí ọmọ Ísírẹ́lì kan bá ṣe ohun tí kò tọ́, kó rú ẹbọ sí Ọlọ́run. Àwọn ìgbà míì sì tún wà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbọ́dọ̀ ṣe ìrúbọ. Ṣùgbọ́n ibo ni ọmọ Ísírẹ́lì tó bá fẹ́ rúbọ á ti rí àwọn ẹyẹ àti ẹran tó máa fi rúbọ sí Ọlọ́run?

Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kan máa ń sin ẹyẹ àti ẹran. Nítorí náà wọ́n lè mú nínú wọn kí wọ́n fi rúbọ. Àmọ́, ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ni kì í sin ẹran tàbí ẹyẹ kankan. Àwọn míì sì ń gbé ní ibi tó jìnnà gan-an sí Jerúsálẹ́mù tí wọn ò fi ní lè mú ọ̀kan lára àwọn ẹran wọn wá sínú tẹ́ńpìlì. Nítorí náà, àwọn èèyàn á wá sínú tẹ́ńpìlì níbí láti ra ẹran tàbí ẹyẹ tí wọ́n máa nílò. Ṣùgbọ́n iye táwọn èèyàn wọ̀nyí ń ta ohun tí wọ́n ń tà ti wọ́n jù. Wọ́n ń rẹ́ àwọn èèyàn jẹ. Yàtọ̀ sí ìyẹn, kò yẹ kí wọ́n máa tajà nínú tẹ́ńpìlì Ọlọ́run gan-an.

Ohun tó bí Jésù nínú rèé. Nítorí náà, ó yí tábìlì àwọn ọkùnrin yẹn àti owó tó wà lórí rẹ̀ dà nù, àwọn ẹyọ owó tó wà níbẹ̀ sì fọ́n ká. Ó tún fi okùn tẹ́ẹ́rẹ́ ṣe pàṣán, ó sì lé gbogbo àwọn ẹran wọn jáde kúrò nínú tẹ́ńpìlì. Ó pàṣẹ fún àwọn ọkùnrin tó ń ta ẹyẹlé náà pé: ‘Ẹ kó wọn jáde kúrò níhìn-ín! Ẹ yéé sọ ilé bàbá mi di ibi tẹ́ ẹ ti ń kó owó púpọ̀ jọ.’

Díẹ̀ lára àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù yìí. Ohun tí Jésù ṣe yà wọ́n lẹ́nu. Ìgbà yẹn ni wọ́n wá rántí ibi tí Bíbélì ti sọ nípa Ọmọ Ọlọ́run pé: ‘Ìfẹ́ tó ní sí ilé Ọlọ́run á máa jó nínú rẹ̀ bí iná.’

Nígbà tí Jésù wà ní Jerúsálẹ́mù níbí fún Ìrékọjá, ó ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu. Lẹ́yìn náà, Jésù kúrò ní Jùdíà, ó sì bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò padà sí Gálílì. Ṣùgbọ́n ní ọ̀nà àjò rẹ̀, ó gba àgbègbè Samáríà kọjá. Jẹ́ ká wo ohun tó ṣẹlẹ̀ níbẹ̀.

Jòhánù 2:13-25; 4:3, 4.

Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́