Ẹ̀KỌ́ 77
Obìnrin Kan Wá Pọn Omi Nínú Kànga
Lẹ́yìn tí àjọyọ̀ Ìrékọjá parí, Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ ń rìnrìn àjò pa dà sílùú Gálílì, àmọ́ ìlú Samáríà ni wọ́n gbà kọjá. Nígbà tí wọ́n détòsí ìlú Síkárì, Jésù sinmi nídìí kànga kan tí wọ́n ń pè ní kànga Jékọ́bù, àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ sì lọ ra oúnjẹ wá.
Kò pẹ́ sígbà yẹn, obìnrin kan wá pọn omi. Jésù sọ fún un pé: ‘Fún mi lómi mu.’ Obìnrin náà sọ pé: ‘Kí ló dé tó ò ń bá mi sọ̀rọ̀? Ọmọ ìlú Samáríà ni mí. Àwọn Júù kì í sì í bá àwa ọmọ ìlú Samáríà sọ̀rọ̀.’ Jésù wá sọ fún un pé: ‘Ká ní o mọ̀ mí ni, ìwọ lo máa béèrè omi lọ́wọ́ mi, màá sì fún ẹ lómi ìyè.’ Obìnrin náà wá sọ pé: ‘Ọ̀rọ̀ ẹ ò yé mi o, torí kò sí korobá kankan lọ́wọ́ ẹ.’ Jésù sọ fún un pé: ‘Ẹnikẹ́ni tó bá mu omi tí mo sọ yìí, òùngbẹ ò ní gbẹ ẹ́ mọ́ láé.’ Obìnrin náà wá sọ fún un pé: “Ọ̀gá, fún mi ní omi yìí.”
Jésù sọ fún un pé: ‘Lọ pe ọkọ ẹ wá.’ Obìnrin náà dáhùn pé: ‘Mi ò ní ọkọ.’ Jésù sọ fún un pé: ‘Òótọ́ lo sọ. O ti ní ọkọ márùn-ún rí, ọkùnrin tó o sì ń fẹ́ báyìí kì í ṣe ọkọ ẹ.’ Obìnrin náà wá sọ fún un pé: ‘Mo ti rí i pé wòlíì ni ẹ́. Àwọn èèyàn wa gbà pé a lè jọ́sìn lórí òkè ńlá yìí, ṣùgbọ́n ẹ̀yin Júù sọ pé Jerúsálẹ́mù nìkan ló yẹ ká ti máa jọ́sìn. Mo mọ̀ pé tí Mèsáyà bá dé, ó máa kọ́ wa bó ṣe yẹ ká máa jọ́sìn.’ Jésù wá sọ ohun kan tí kò tíì sọ fún ẹnikẹ́ni rí, ó ní: ‘Èmi ni Mèsáyà náà.’
Bí obìnrin yẹn ṣe sáré lọ sínú ìlú nìyẹn, ó sì lọ sọ fún àwọn ará Samáríà pé: ‘Ó dà bíi pé mo ti rí Mèsáyà o, torí pé gbogbo ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí mi ló mọ̀. Ẹ wá lọ wò ó!’ Bí gbogbo wọn ṣe tẹ̀ lé e pa dà sídìí kànga nìyẹn, wọ́n sì tẹ́tí sóhun tí Jésù kọ́ wọn.
Àwọn ará Samáríà yẹn ní kí Jésù wá sílùú àwọn. Torí náà, Jésù lo ọjọ́ méjì pẹ̀lú wọn, ó ń kọ́ wọn, àwọn èèyàn náà sì gba ohun tó sọ gbọ́. Wọ́n wá ń sọ fún obìnrin náà pé: ‘Lẹ́yìn tá a ti gbọ́ ohun tí ọkùnrin yìí ń sọ, a ti wá mọ̀ pé, òun ló máa gba aráyé là lóòótọ́.’
“‘Máa bọ̀!’ kí ẹnikẹ́ni tí òùngbẹ ń gbẹ sì máa bọ̀; kí ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́, gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.”—Ìfihàn 22:17