Ẹ̀KỌ́ 87
Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa
Ọdọọdún làwọn Júù máa ń ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù Nísàn. Ìdí tí wọ́n fi ń ṣe é ni pé kí wọ́n lè máa rántí bí Jèhófà ṣe gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọmọ Íjíbítì tó ń fi wọ́n ṣẹrú àti bó ṣe mú wọn wá sí Ilẹ̀ Ìlérí. Lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni, Jésù àtàwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá nínú yàrá òkè kan ní Jerúsálẹ́mù. Nígbà tí wọ́n jẹun tán, Jésù sọ pé: ‘Ọ̀kan lára yín máa dà mí.’ Ẹnu ya àwọn àpọ́sítélì, wọ́n sì bi Jésù pé: ‘Ta ni ẹni náà?’ Jésù sọ pé: ‘Ẹni tí mo bá fún ní búrẹ́dì ni ẹni náà.’ Ó wá fún Júdásì Ìsìkáríọ́tù ní búrẹ́dì. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Júdásì dìde, ó sì jáde kúrò nínú yàrá náà.
Lẹ́yìn náà, Jésù gbàdúrà, ó pín búrẹ́dì mélòó kan sí wẹ́wẹ́, ó sì fún àwọn àpọ́sítélì tó kù. Ó sọ fún wọn pé: ‘Ẹ jẹ búrẹ́dì yìí. Ó dúró fún ara mi tí màá fi rúbọ nítorí yín.’ Lẹ́yìn ìyẹn, ó gbàdúrà sórí wáìnì, ó sì gbé e fáwọn àpọ́sítélì ẹ̀. Ó wá sọ pé: ‘Ẹ mu wáìnì yìí. Ó dúró fún ẹ̀jẹ̀ mi tí màá fi rúbọ kí Ọlọ́run lè dárí ẹ̀ṣẹ̀ jì. Mo ṣèlérí fún yín pé ẹ máa jọba pẹ̀lú mi ní ọ̀run. Ẹ máa ṣe èyí ní ọdọọdún láti fi rántí mi.’ Lónìí, àwa ọmọlẹ́yìn Jésù ṣì máa ń pàdé pọ̀ láti ṣe ìrántí ikú ẹ̀ lọ́dọọdún. Ìpàdé yìí la wá mọ̀ sí Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa.
Lẹ́yìn oúnjẹ náà, àwọn àpọ́sítélì tó kù bẹ̀rẹ̀ sí í bára wọn jiyàn nípa ẹni tó máa jẹ́ ọ̀gá láàárín wọn. Jésù wá sọ fún wọn pé: ‘Ẹni tó máa jẹ́ ọ̀gá láàárín yín lẹni tó rí ara ẹ̀ bí ẹni tó kéré jù láàárín yín.’
Jésù tún sọ fún wọn pé: ‘Ọ̀rẹ́ mi ni yín. Gbogbo ohun tí Bàbá mi fẹ́ kí n sọ fún yín ni mò ń sọ fún yín. Láìpẹ́, mo máa pa dà sọ́dọ̀ Bàbá mi ní ọ̀run. Ẹ̀yín ṣì máa wà láyé, àmọ́ àwọn èèyàn máa mọ̀ pé ọmọlẹ́yìn mi ni yín tí wọ́n bá rí bẹ́ ẹ ṣe nífẹ̀ẹ́ ara yín. Torí náà, ẹ gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ ara yín bí èmi náà ṣe nífẹ̀ẹ́ yín.’
Lẹ́yìn gbogbo ohun tí Jésù ṣe yìí, ó gbàdúrà sí Jèhófà pé kó dáàbò bo àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun. Ó ní kí Jèhófà ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè jọ máa ṣiṣẹ́ pọ̀ ní àlàáfíà. Ó tún gbàdúrà pé kí orúkọ Jèhófà di mímọ́. Lẹ́yìn ìyẹn, Jésù àtàwọn àpọ́sítélì ẹ̀ kọrin ìyìn sí Jèhófà, wọ́n sì jáde lọ. Àsìkò ti wá tó báyìí táwọn èèyàn máa mú Jésù.
“Má bẹ̀rù, agbo kékeré, torí Baba yín ti fọwọ́ sí i láti fún yín ní Ìjọba náà.”—Lúùkù 12:32