Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 1
Ohun tó bẹ̀rẹ̀ Bíbélì ni ìtàn bí Jèhófà ṣe dá gbogbo nǹkan, ó jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan tó rẹwà tí Jèhófà dá lọ́run àti láyé. Tó o bá jẹ́ òbí, jẹ́ kí ọmọ ẹ rí oríṣiríṣi nǹkan tí Ọlọ́run dá. Jẹ́ kó rí i pé Ọlọ́run fún wa ní ọgbọ́n tó ju ti àwọn ẹranko lọ. Bí àpẹẹrẹ, àwa lè sọ̀rọ̀, a lè ronú, a lè fàwọn nǹkan tó wà láyé dá oríṣiríṣi àrà, a lè kọrin, a tún lè gbàdúrà. Bákan náà, jẹ́ kó mọrírì agbára àti ọgbọ́n tí Jèhófà ní, kó o sì jẹ́ kó rí i pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ gbogbo nǹkan tó dá títí kan gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.