Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 7
Apá yìí dá lórí ìtàn Ọba Sọ́ọ̀lù àti Ọba Dáfídì. Ìtàn náà sì gba nǹkan bí ọgọ́rin (80) ọdún. Onírẹ̀lẹ̀ ni Sọ́ọ̀lù níbẹ̀rẹ̀, ó sì bẹ̀rù Ọlọ́run, àmọ́ nígbà tó yá, ó yíwà pa dà, kò sì tẹ̀ lé òfin Jèhófà mọ́. Torí náà, Jèhófà kọ̀ ọ́ sílẹ̀, Jèhófà sì sọ fún Sámúẹ́lì pé kó yan Dáfídì gẹ́gẹ́ bí ọba tó máa jẹ lẹ́yìn Sọ́ọ̀lù. Sọ́ọ̀lù bẹ̀rẹ̀ sí í jowú Dáfídì, ó sì wá ọ̀nà láti pa á, àmọ́ Dáfídì ò gbẹ̀san. Jónátánì tó jẹ́ ọmọ Sọ́ọ̀lù mọ̀ pé Dáfídì ni Jèhófà fẹ́ kó jọba, torí náà ó dúró ti Dáfídì. Nígbà tó yá, Dáfídì dá ẹ̀ṣẹ̀ tó lágbára, àmọ́ ó gba ìbáwí Jèhófà. Tó o bá jẹ́ òbí, jẹ́ kọ́mọ ẹ rí ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká jẹ́ adúróṣinṣin, ká sì máa ṣègbọràn sí Jèhófà àtàwọn tó ń ṣàbójútó nínú ètò ẹ̀.