Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 9
Apá yìí máa jẹ́ ká mọ àwọn ọ̀dọ́, àwọn wòlíì àtàwọn ọba tí wọ́n nígbàgbọ́ tó lágbára nínú Jèhófà. Nílẹ̀ Síríà, ọmọbìnrin kékeré kan tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì nígbàgbọ́ pé wòlíì Jèhófà máa wo Náámánì sàn. Wòlíì Èlíṣà nígbàgbọ́ pé Jèhófà máa gba òun lọ́wọ́ àwọn ọmọ ogun ọ̀tá. Jèhóádà àlùfáà àgbà fẹ̀mí ara ẹ̀ wewu kó lè dáàbò bo Jèhóáṣì lọ́wọ́ Ataláyà ìyá ẹ̀ àgbà tó fẹ́ pa á. Ẹ̀rù ò ba Ọba Hẹsikáyà nígbà táwọn ará Ásíríà ń halẹ̀ mọ́ ọn torí ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ó sì mọ̀ pé ó máa gba àwọn là. Ọba Jòsáyà fòpin sí ìbọ̀rìṣà, ó tún tẹ́ńpìlì ṣe, ó sì mú káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa jọ́sìn Jèhófà pa dà.