Ẹ̀KỌ́ 53
Jèhóádà Nígboyà
Jésíbẹ́lì ní ọmọbìnrin kan tórúkọ ẹ̀ ń jẹ́ Ataláyà, òun náà sì burú bíi Jésíbẹ́lì ìyá ẹ̀. Ataláyà ni ìyàwó ọba Júdà. Nígbà tọ́kọ ẹ̀ kú, ọmọ ẹ̀ di ọba. Àmọ́ nígbà tí ọmọ ẹ̀ kú, Ataláyà sọ ara ẹ̀ di ọba Júdà. Lẹ́yìn náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wá bó ṣe máa pa ìdílé ọba run, ó ń rán àwọn kan kí wọ́n máa pa gbogbo àwọn tó mọ̀ pé wọ́n lè di ọba, kódà ó pa àwọn ọmọ ọmọ ẹ̀. Gbogbo èèyàn wá ń bẹ̀rù ẹ̀.
Nígbà tí Àlùfáà Àgbà tó ń jẹ́ Jèhóádà àtìyàwó ẹ̀ tó ń jẹ́ Jèhóṣébà rí ìwà burúkú tí Ataláyà ń hù yìí. Wọ́n tètè gbé ọ̀kan lára àwọn ọmọ ọmọ Ataláyà tó ń jẹ́ Jèhóáṣì pa mọ́ kí wọ́n má bàa rí i pa. Ohun tí wọ́n ṣe yìí léwu gan-an, síbẹ̀ wọ́n tọ́ ọmọ náà dàgbà nínú tẹ́ńpìlì.
Nígbà tí Jèhóáṣì pé ọmọ ọdún méje, Jèhóádà pe gbogbo ìjòyè àtàwọn ọmọ Léfì, ó wá sọ fún wọn pé: ‘Ẹ máa ṣọ́ gbogbo ẹnu ọ̀nà tẹ́ńpìlì, ẹ ò sì gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ẹnikẹ́ni wọlé.’ Lẹ́yìn náà ni Jèhóádà wá fi Jèhóáṣì jẹ ọba Júdà, ó sì gbé adé lé e lórí. Gbogbo èèyàn ilẹ̀ Júdà sì bẹ̀rẹ̀ sí í kí ọba, wọ́n ń pariwo pé: ‘Kábíyèsí o, kádé pẹ́ lórí o!’
Ataláyà gbọ́ ariwo náà, ó sì sáré lọ sínú tẹ́ńpìlì. Nígbà tó rí i pé wọ́n ti yan ọba tuntun, ó kígbe pé: ‘Áà, ọ̀tẹ̀ rèé o, ọ̀tẹ̀!’ Ni àwọn ìjòyè bá yí ayaba burúkú yìí ká, wọ́n mú un jáde, wọ́n sì pa á. Àmọ́ báwo ni wọ́n ṣe máa fòpin sí àwọn ìwà burúkú tó ti mú kó gbilẹ̀?
Jèhóádà ran àwọn èèyàn náà lọ́wọ́, ó ní kí wọ́n bá Jèhófà ṣàdéhùn, kí wọ́n sì ṣèlérí fún un pé òun nìkan làwọn á máa jọ́sìn. Jèhóádà tún ní kí wọ́n lọ wó gbogbo ilé òrìṣà Báálì, kí wọ́n sì fọ́ àwọn ère wọn sí wẹ́wẹ́. Ó wá yan àwọn àlùfáà àtàwọn ọmọ Léfì pé kí wọ́n tún tẹ́ńpìlì ṣe káwọn èèyàn lè pa dà máa jọ́sìn Ọlọ́run níbẹ̀. Ó tún yan àwọn kan pé kí wọ́n máa ṣọ́ ẹnu ọ̀nà tẹ́ńpìlì náà kí ẹnikẹ́ni tí kò mọ́ má bàa wọlé. Lẹ́yìn gbogbo èyí, Jèhóádà àtàwọn ìjòyè wá mú Jèhóáṣì lọ sí ààfin, wọ́n sì gbé e sórí ìtẹ́ ọba. Inú àwọn èèyàn Júdà dùn gan-an pé àwọn ti bọ́ lọ́wọ́ Ataláyà àti òrìṣà Báálì, ní báyìí, àwọn á lè máa jọ́sìn Jèhófà. Ó dájú pé bí Jèhóádà ṣe jẹ́ onígboyà ló ran àwọn èèyàn náà lọ́wọ́?
“Ẹ má bẹ̀rù àwọn tó ń pa ara àmọ́ tí wọn ò lè pa ọkàn; kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ bẹ̀rù ẹni tó lè pa ọkàn àti ara run nínú Gẹ̀hẹ́nà.”—Mátíù 10:28