Ọ̀rọ̀ Ìṣáájú fún Apá 12
Jésù kọ́ àwọn èèyàn nípa Ìjọba Ọlọ́run. Ó tún kọ́ wọn pé kí wọ́n máa gbàdúrà pé kí orúkọ Ọlọ́run di mímọ́, kí Ìjọba Ọlọ́run dé, kí ìfẹ́ Ọlọ́run sì ṣẹ láyé. Tó o bá jẹ́ òbí, ṣàlàyé ohun tí àdúrà yẹn túmọ̀ sí fún ọmọ rẹ. Jésù ò jẹ́ kí Sátánì sọ òun di aláìṣòótọ́ sí Ọlọ́run. Nígbà tó yá, Jésù yan àwọn àpọ́sítélì ẹ̀, àwọn ni wọ́n sì kọ́kọ́ di ọmọ Ìjọba Ọlọ́run. Kíyè sí bí Jésù ṣe nítara fún ìjọsìn tòótọ́. Torí pé Jésù fẹ́ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, ó mú àwọn aláìsàn lára dá, ó fún àwọn tébi ń pa lóúnjẹ, ó tiẹ̀ tún jí òkú dìde. Àwọn ohun tí Jésù ṣe yìí jẹ́ ká mọ àwọn ohun tí Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe fún gbogbo èèyàn.