ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w09 2/1 ojú ìwé 16-17
  • Nípa Àwọn Àdúrà Tí Ọlọ́run Ń Gbọ́

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Nípa Àwọn Àdúrà Tí Ọlọ́run Ń Gbọ́
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé gbogbo àdúrà ló dùn mọ́ Ọlọ́run nínú?
  • Kí ló yẹ ká máa gbàdúrà fún?
  • Ṣó yẹ ká máa gbàdúrà fáwọn ẹlòmíì?
  • Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbàdúrà láìdabọ̀?
  • Àǹfààní Pàtàkì Ni Àdúrà Jẹ́
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
  • Sísún Mọ́ Ọlọrun Nínú Àdúrà
    Kí Ni Ọlọ́run Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?
  • Máa Gbàdúrà Kó O Lè Túbọ̀ Sún Mọ́ Ọlọ́run
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Sún Mọ́ Ọlọ́run Nípasẹ̀ Àdúrà
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
w09 2/1 ojú ìwé 16-17

Ohun Tá a Kọ́ Lọ́dọ̀ Jésù

Nípa Àwọn Àdúrà Tí Ọlọ́run Ń Gbọ́

Ibi táwọn èèyàn ò ti ní dí Jésù lọ́wọ́ ló ti sábà máa ń gbàdúrà, ohun tó sì rọ àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ láti máa ṣe náà nìyẹn. Bíbélì sọ pé: “Wàyí o, ní àkókò tí ó wà ní ibì kan tí ó ń gbàdúrà, nígbà tí ó ṣíwọ́, ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ wí fún un pé: ‘Olúwa, kọ́ wa bí a ṣe ń gbàdúrà‘ . . . Ó wí fún wọn pé: ‘Nígbàkigbà tí ẹ bá ń gbàdúrà, ẹ wí pé, “Baba, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.”’” (Lúùkù 5:16; 11:1, 2) Jésù tipa báyìí jẹ́ ká mọ̀ pé Bàbá òun, ìyẹn Jèhófà, nìkan la gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà sí. Òun nìkan ni Ẹlẹ́dàá wa àti “Olùgbọ́ àdúrà.”—Sáàmù 65:2.

Ṣé gbogbo àdúrà ló dùn mọ́ Ọlọ́run nínú?

Àwọn àdúrà àkọ́sórí táwọn kan máa ń sọ lásọtúnsọ kì í dùn mọ́ Ọlọ́run nínú. Jésù sọ pé: “Nígbà tí ìwọ bá ń gbàdúrà, má ṣe sọ ohun kan náà ní àsọtúnsọ.” (Mátíù 6:7) A gbọ́dọ̀ máa bá Bàbá wa ọ̀run sọ̀rọ̀ látọkàn wá. Nígbà kan, Jésù jẹ́ kó yé àwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ pé Ọlọ́run máa gbọ́ àdúrà ẹlẹ́ṣẹ̀ tó ṣe tán láti ronú pìwà dà tọkàntọkàn ju àdúrà onígbèéraga tó gbé àwọn àṣà ìsìn karí. (Lúùkù 18:10-14) Torí náà, tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run gbọ́ àdúrà wa, a ní láti máa fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ wá bá a ṣe lè máa fàwọn ohun tó sọ fún wa ṣèwà hù. Jésù alára sọ pé: “Bí Baba ti kọ́ mi ni mo ń sọ nǹkan wọ̀nyí . . . Nígbà gbogbo ni mo ń ṣe ohun tí ó wù ú.” (Jòhánù 8:28, 29) Jésù tún gbàdúrà pé: “Kì í ṣe ìfẹ́ mi ni kí ó ṣẹ, bí kò ṣe tìrẹ.”—Lúùkù 22:42.

Kí ló yẹ ká máa gbàdúrà fún?

Torí pé àwọn ẹ̀dá kan ti tàbùkù sórúkọ Ọlọ́run, Jésù sọ pé: “Nítorí náà, kí ẹ máa gbàdúrà ní ọ̀nà yìí: ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́. Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.’” (Mátíù 6:9, 10) A ní láti máa gbàdúrà pé kí Ìjọba Ọlọ́run dé, torí pé Ìjọba yìí ni Ọlọ́run máa lò láti mú kí ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ láyé àti lọ́run. Jésù tún sọ pé a lè gbàdúrà fún “oúnjẹ . . . òòjọ́” wa. A tún lè bẹ Ọlọ́run pé kó pèsè iṣẹ́, ibùgbé àti aṣọ fún wa, pé kó fún wa ní ìlera tó dáa àtàwọn nǹkan míì tó ń jẹ wá lọ́kàn. Yàtọ̀ síyẹn, Jésù sọ pé ká máa gbàdúrà pé kí Ọlọ́run dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá.—Lúùkù 11:3, 4.

Ṣó yẹ ká máa gbàdúrà fáwọn ẹlòmíì?

Jésù gbàdúrà fáwọn ẹlòmíì. Bíbélì sọ pé: “Nígbà náà ni a mú àwọn ọmọ kéékèèké wá sọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí kí ó lè gbé ọwọ́ rẹ̀ lé wọn, kí ó sì gba àdúrà.” (Mátíù 19:13) Jésù sọ fún àpọ́sítélì Pétérù pé: “Èmi ti rawọ́ ẹ̀bẹ̀ nítorí rẹ, kí ìgbàgbọ́ rẹ má bàa yẹ̀.” (Lúùkù 22:32) Jésù gba àwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n máa gbàdúrà fáwọn ẹlòmíì, kódà ó ní kí wọ́n máa gbàdúrà fáwọn tó ń ṣe inúnibíni sí wọn àtàwọn tó ń bú wọn.—Mátíù 5:44; Lúùkù 6:28.

Kí nìdí tó fi yẹ ká máa gbàdúrà láìdabọ̀?

Jésù wá àkókò láti gbàdúrà, ó sì rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n ‘máa gbàdúrà nígbà gbogbo kí wọ́n má sì ṣe juwọ́ sílẹ̀.’ (Lúùkù 18:1) Jèhófà fẹ́ ká máa gbàdúrà sóun láìdabọ̀ lórí àwọn nǹkan tó ń jẹ wá lọ́kàn, ká lè fi hàn pé lóòótọ́ la gbẹ́kẹ̀ lé òun. Jésù sọ pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní bíbéèrè, a ó sì fi í fún yín.” Àmọ́, èyí ò wá túmọ̀ sí pé Jèhófà máa ń lọ́ra láti dáhùn àdúrà àwọn tó ń bọ̀wọ̀ fún un tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ bíi Bàbá. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jésù sọ pé: “Bí ẹ̀yin, tí ẹ tilẹ̀ jẹ́ ẹni burúkú, bá mọ bí ẹ ṣe ń fi ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ yín, mélòómélòó ni Baba tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!”—Lúùkù 11:5-13.

Fún àlàyé síwájú sí i, wo orí 17 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?a

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́