APÁ KẸRIN
“Èmi Yóò Fi Ìtara Gbèjà Orúkọ Mímọ́ Mi”—Ìjọsìn Mímọ́ Borí Àtakò
OHUN TÍ APÁ YÌÍ DÁ LÉ: Jèhófà máa dáàbò bo àwọn èèyàn rẹ̀ nígbà ìpọ́njú ńlá
Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn, síbẹ̀, ó máa ń fẹ́ ká jíhìn fún ohunkóhun tá a bá ṣe. Báwo ló ṣe máa ń rí lára rẹ̀ táwọn tó pe ara wọn ní olùjọ́sìn rẹ̀ bá ń ṣe ohun tó tàbùkù sí i? Báwo ló ṣe máa pinnu ẹni tó máa la ìpọ́njú ńlá já? Kí sì nìdí tí Jèhófà, Ọlọ́run tó nífẹ̀ẹ́ aráyé fi máa pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ẹni burúkú run?