ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • th ẹ̀kọ́ 20 ojú ìwé 23
  • Ìparí Ọ̀rọ̀ Tó Dára

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìparí Ọ̀rọ̀ Tó Dára
  • Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìparí Ọ̀rọ̀ Múná Dóko
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Jẹ́ Kí Ìdí Tó O Fi Ka Ìwé Mímọ́ Ṣe Kedere
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Rẹ Wọni Lọ́kàn
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Sọ Bí Ọ̀rọ̀ Rẹ Ṣe Wúlò
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
Àwọn Míì
Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
th ẹ̀kọ́ 20 ojú ìwé 23

Ẹ̀KỌ́ 20

Ìparí Ọ̀rọ̀ Tó Dára

Ẹsẹ Bíbélì tí a tọ́ka sí

Oníwàásù 12:13, 14

KÓKÓ PÀTÀKÌ: Nígbà tí o bá ń parí ọ̀rọ̀ rẹ, rọ àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ pé kí wọ́n fi ohun tí wọ́n gbọ́ sọ́kàn, kí wọ́n sì ṣe ohun tó yẹ.

BÓ O ṢE LÈ ṢE É:

  • Jẹ́ kí ìparí ọ̀rọ̀ rẹ bá ohun tí ọ̀rọ̀ rẹ dá lé mu. Tún àwọn kókó pàtàkì inú ọ̀rọ̀ rẹ sọ, tàbí ko o gba ọ̀nà míì ṣàlàyé àwọn kókó náà àti àkòrí ọ̀rọ̀ rẹ.

  • Fún àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ ní ìṣírí. Sọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe, kó o sì sọ ìdí tó fi yẹ kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Jẹ́ kó hàn pé ohun tí ò ń sọ dá ẹ lójú, kó o sì sọ̀rọ̀ látọkàn wá.

  • Jẹ́ kí ìparí ọ̀rọ̀ rẹ rọrùn, kó sì ṣe ṣókí. Má ṣe mú kókó túntun wọlé ní ìparí ọ̀rọ̀ rẹ. Jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ ṣe ṣókí, kó o sì gba àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ níyànjú láti ṣe ohun tó yẹ.

    Àwọn àbá

    Má ṣe sáré sọ ìparí ọ̀rọ̀ rẹ, má sì ṣe jẹ́ kí ohùn rẹ bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sílẹ̀. Ó yẹ kí àwọn gbólóhùn tó o máa sọ kẹ́yìn fi hàn pé o ti fẹ́ parí ọ̀rọ̀ rẹ.

LẸ́NU IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

Nígbà tó o bá ń parí ọ̀rọ̀ rẹ, tún sọ àwọn kókó pàtàkì tó o fẹ́ kí ẹni tí ò ń bá sọ̀rọ̀ rántí. Tó bá jẹ́ pé ńṣe ni ẹnì kan tiẹ̀ dá ọ̀rọ̀ mọ́ ẹ lẹ́nu, ìwọ ṣáà rí i pé ọ̀rọ̀ tó dára lo fi parí ọ̀rọ̀ rẹ. Kódà, tí ẹnì kan bá kàn ẹ́ lábùkù, ọ̀rọ̀ tútù ni kó o fi dá a lóhùn, torí èyí lè jẹ́ kí onítọ̀hùn fetí sílẹ̀ nígbà míì.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́