ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • be ẹ̀kọ́ 39 ojú ìwé 220-ojú ìwé 222 ìpínrọ̀ 6
  • Ìparí Ọ̀rọ̀ Múná Dóko

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìparí Ọ̀rọ̀ Múná Dóko
  • Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìparí Ọ̀rọ̀ Tó Dára
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Jẹ́ Kí Kókó Ọ̀rọ̀ Fara Hàn Kedere
    Tẹra Mọ́ Kíkàwé Àti Kíkọ́ni
  • Ṣíṣe Ìlapa Èrò
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
  • Ìnasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Tí Ń Múni Nífẹ̀ẹ́ Sí Ọ̀rọ̀
    Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
Àwọn Míì
Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run
be ẹ̀kọ́ 39 ojú ìwé 220-ojú ìwé 222 ìpínrọ̀ 6

Ẹ̀KỌ́ 39

Ìparí Ọ̀rọ̀ Múná Dóko

Kí ló yẹ kí o ṣe?

Nígbà tí o bá ń parí ọ̀rọ̀ rẹ, ó yẹ kí o dìídì sọ nǹkan kan tí yóò sún àwùjọ láti ṣiṣẹ́ lórí ohun tí wọ́n gbọ́.

Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì?

Ohun téèyàn bá sọ níparí ọ̀rọ̀ ló sábà máa ń pẹ́ jù lọ́kàn àwùjọ. Ó máa nípa lórí bí gbogbo ohun tá a sọ ṣe máa ṣàṣeyọrí tó.

Ó ṢEÉ ṣe kí o ti fara balẹ̀ ṣèwádìí kí o sì ti ṣètò àlàyé àárín ọ̀rọ̀ rẹ dáadáa. O tún lè ti ṣètò ìnasẹ̀ ọ̀rọ̀ tí ń múni nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀. Síbẹ̀, ó ṣì ku ohun kan, ohun náà sì ni ìparí ọ̀rọ̀ tó múná dóko. Má fọwọ́ yẹpẹrẹ mú un o. Ohun tó o sọ kẹ́yìn ló sábà máa ń pẹ́ lọ́kàn àwọn èèyàn jù lọ. Bí ìparí ọ̀rọ̀ rẹ kò bá lè súnni ṣiṣẹ́ kò ní jẹ́ kí gbogbo àlàyé àtẹ̀yìnwá tí o ti ń ṣe bọ̀ múná dóko.

Kíyè sí ohun tó tẹ̀ lé e yìí: Lápá ìgbẹ̀yìn ayé Jóṣúà, ó sọ àsọyé mánigbàgbé kan fún àwọn àgbà ọkùnrin orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Lẹ́yìn tí Jóṣúà mẹ́nu kan àwọn ọ̀nà tí Jèhófà ti ń gbà bá Ísírẹ́lì lò bọ̀ láti ìgbà ayé Ábúráhámù, ṣe ó kàn tún àwọn kókó pàtàkì sọ gẹ́gẹ́ bí ẹni ń ṣàkópọ̀ ọ̀rọ̀ ni? Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló fi tinútinú rọ àwọn èèyàn náà pé: “Ẹ bẹ̀rù Jèhófà, kí ẹ sì máa sìn ín ní àìlálèébù àti ní òtítọ́.” Fúnra rẹ ka ìparí ọ̀rọ̀ Jóṣúà yìí nínú Jóṣúà 24:14, 15.

Ọ̀rọ̀ pàtàkì mìíràn wà nínú Ìṣe 2:14-36, èyí tí àpọ́sítélì Pétérù sọ fún àwùjọ kan ní Jerúsálẹ́mù nígbà àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa. Ó kọ́kọ́ ṣàlàyé fún wọn pé àsọtẹ́lẹ̀ tí Jóẹ́lì sọ nípa bí Ọlọ́run yóò ṣe tú ẹ̀mí rẹ̀ lé àwọn kan lórí ni wọ́n rí tó ń ṣẹ yìí. Ó wá sọ bí èyí ṣe kan àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà tí ìwé Sáàmù sọ nípa ti àjíǹde Jésù Kristi àti nípa bí a ṣe máa gbé e ga sí ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run. Lẹ́yìn náà, ní ìparí ọ̀rọ̀, Pétérù sọ ojú abẹ níkòó fún àwọn tó ń gbọ́rọ̀ rẹ̀. Ó sọ ohun pàtàkì tí ń bẹ níwájú gbogbo wọn. Ó ní: “Nítorí náà, kí gbogbo ilé Ísírẹ́lì mọ̀ dájúdájú pé, Jésù yìí tí ẹ kàn mọ́gi ni Ọlọ́run fi ṣe Olúwa àti Kristi.” Àwọn tó wà níbẹ̀ wá béèrè pé: “Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ̀yin ará, kí ni kí àwa ṣe?” Pétérù bá fèsì pé: “Ẹ ronú pìwà dà, kí a sì batisí olúkúlùkù yín ní orúkọ Jésù Kristi.” (Ìṣe 2:37, 38) Lọ́jọ́ yẹn, ẹgbẹ̀ẹ́dógún [3,000] èèyàn lára àwọn tó gbọ́rọ̀ rẹ̀ tó sì wọ̀ wọ́n lọ́kàn ló tẹ́wọ́ gba òótọ́ ọ̀rọ̀ tí wọ́n gbọ́ nípa Jésù Kristi.

Àwọn Kókó Tó Yẹ Kí O Fi Sọ́kàn. Ó yẹ kí ohun tó o bá sọ níparí ọ̀rọ̀ rẹ wé mọ́ ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ ní tààràtà. Ó ní láti jẹ́ ibi tó yẹ kí àlàyé àwọn kókó tó o sọ̀rọ̀ lé lórí forí tì sí. Lóòótọ́ ó dára kí o fi ọ̀rọ̀ pàtàkì látinú ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ kún un, àmọ́ kì í ṣe dandan pé kí o kúkú tún ẹṣin ọ̀rọ̀ yẹn sọ pátápátá.

Ó dájú pé ìdí tó o fi ń sọ̀rọ̀ yìí ni pé o fẹ́ gba àwọn èèyàn níyànjú láti ṣe nǹkan kan nípa ohun tí wọ́n gbọ́. Ọ̀kan nínú àwọn ìdí pàtàkì tí ìparí ọ̀rọ̀ sì wà fún ni pé kí ó fi ohun tó yẹ kí àwùjọ ṣe gan-an hàn wọ́n. Nígbà tí ò ń yan ẹṣin ọ̀rọ̀ àti àwọn kókó tí o máa ṣàlàyé, ǹjẹ́ o fara balẹ̀ ronú nípa ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí àwọn olùgbọ́ rẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí àti ohun tó o máa fẹ́ kí ọ̀rọ̀ yẹn sún wọn ṣe? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé o ti mọ ìgbésẹ̀ tó o fẹ́ kí wọ́n gbé. Nísinsìnyí, ó yẹ kí o wá ṣàlàyé bí ìgbésẹ̀ yẹn ṣe jẹ́ àti bí wọ́n ṣe máa gbé e.

Láfikún sí fífi ohun tó yẹ kí àwùjọ ṣe hàn wọ́n, ó yẹ kí ìparí ọ̀rọ̀ rẹ gúnni ní kẹ́ṣẹ́. Ó yẹ kí o sọ ìdí gúnmọ́ tó fi yẹ kí àwùjọ ṣiṣẹ́ lórí ohun tí wọ́n gbọ́ àti àǹfààní tí yóó tìdí rẹ̀ wá. Bí o bá fara balẹ̀ wá àgbà ọ̀rọ̀ fún ìparí ọ̀rọ̀ rẹ tó o sì fi gbólóhùn tó jíire gbé e yọ, ńṣe ni yóò jẹ́ kí gbogbo ohun tí àwùjọ gbọ́ túbọ̀ máa ró lọ́kàn wọn.

Má gbàgbé pé ńṣe lò ń parí ọ̀rọ̀. Ó yẹ kí ohun tó o bá máa sọ fi hàn bẹ́ẹ̀. Ó sì yẹ kí ọ̀nà tó ò ń gbà sọ ọ́ tún bá a mu. Má kàn máa sọ̀rọ̀ bọ̀ gbuurugbu kí o sì wá dákẹ́ wẹ́lo lẹ́ẹ̀kan náà. Ṣùgbọ́n kì í tún ṣe pé kí o wá rọra máa rẹ ohun sílẹ̀ títí tí àwùjọ ò fi ní gbọ́ mọ́. Ó yẹ kí ohùn rẹ ròkè tó ṣùgbọ́n kó má pọ̀ jù. Ó yẹ kí àwọn gbólóhùn tí o máa sọ kẹ́yìn fi hàn pé o ti fẹ́ parí ọ̀rọ̀ rẹ. Ńṣe ló sì yẹ kí o fi ìtara ọkàn sọ ọ́ pẹ̀lú ìdánilójú. Nígbà tí o bá ń múra bó o ṣe máa sọ ọ̀rọ̀ rẹ, má gbàgbé láti fi ìparí ọ̀rọ̀ rẹ dánra wò.

Báwo ló ṣe yẹ kí ìparí ọ̀rọ̀ rẹ gùn tó? Kì í ṣe ohun tá a kàn lè fi agogo nìkan díwọ̀n. Kò yẹ kí ìparí ọ̀rọ̀ falẹ̀ rárá. Ohun tí a fi ń mọ̀ bóyá ìparí ọ̀rọ̀ kan bá a mu tàbí kò bá a mu ni ipa tó ní lórí àwùjọ. Ìparí ọ̀rọ̀ tó mọ níwọ̀n, tó ṣe tààràtà tó sì gbéni ró ló máa ń dára. Èyí tó bá tiẹ̀ gùn díẹ̀, tó sì ní àpèjúwe tó ṣe ṣókí nínú tún lè múná dóko pẹ̀lú tí a bá fara balẹ̀ gbé e kalẹ̀. Fi ìparí ọ̀rọ̀ ṣókí tó wà fún gbogbo ìwé Oníwàásù, nínú Oníwàásù 12:13, 14, wé ìparí ọ̀rọ̀ gígùn inú Mátíù 7:24-27 tó wà fún Ìwàásù Lórí Òkè. Bẹ́ẹ̀ kẹ̀, Ìwàásù Lórí Òkè kúrú ju ìwé Oníwàásù lọ dáadáa.

Lóde Ẹ̀rí. Kò sí ibi tí èèyàn ti sábà máa ń nílò ìparí ọ̀rọ̀ tó ti òde ẹ̀rí. Tí o bá múra sílẹ̀ tí ire àwọn èèyàn sì jẹ ọ́ lógún dáadáa, wàá ṣe àṣeyọrí tó pọ̀. O ṣì lè lo ìmọ̀ràn tí a ti sọ láwọn ojú ewé tó ṣáájú èyí kódà nígbà ìfọ̀rọ̀wérọ̀ rẹ pẹ̀lú ẹnì kan ṣoṣo pàápàá.

Ìfọ̀rọ̀wérọ̀ náà lè kúrú gan-an. Bóyá ọwọ́ onílé dí. Gbogbo àkókò tó o máa lò lọ́dọ̀ rẹ̀ lè má ju ìṣẹ́jú kan péré lọ. Bí ó bá yẹ bẹ́ẹ̀ o kàn lè sọ pé: “Èmi gan-an rí i pé ọwọ́ yín dí. Ṣùgbọ́n màá fẹ́ kí ẹ kàn fi ọ̀rọ̀ pàtàkì yìí sọ́kàn. Bíbélì fi yé wa pé Ẹlẹ́dàá wa ní ohun àgbàyanu kan tó ń fẹ́ ṣe, ìyẹn ni pé ó fẹ́ sọ ilẹ̀ ayé yìí di ibi táwọn èèyàn yóò ti lè máa gbádùn ayé wọn títí láé. Àwa pẹ̀lú lè wà nínú Párádísè yẹn, ṣùgbọ́n a ní láti kọ́kọ́ mọ àwọn ohun tí Ọlọ́run ń fẹ́ ká ṣe ná.” Tàbí kí o kàn sọ pé wàá padà wá nígbà mìíràn tọ́wọ́ ò bá dí.

Bó bá di pé o kò lè bá a sọ̀rọ̀ lọ títí nítorí pé ó dá ọ̀rọ̀ mọ́ ọ lẹ́nu tàbí ó tiẹ̀ kàn ọ́ lábùkù, bíbà ló bà, kò tíì bà jẹ́. Lo ìmọ̀ràn tó wà nínú Mátíù 10:12, 13 àti Róòmù 12:17, 18. Ìdáhùn pẹ̀lẹ́ rẹ lè mú kí ó padà wá fojú iyì wo àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àṣeyọrí sí rere nìyẹn yóò sì jẹ́.

Ó sì lè ṣẹlẹ̀ pé o ti bá onílé fọ̀rọ̀ wérọ̀ dáadáa. O kò ṣe tún kókó tó o fẹ́ kó fi sọ́kàn sọ lẹ́ẹ̀kan sí i? Sì rọ̀ ọ́ láti ṣiṣẹ́ lórí kókó tó gbọ́ yẹn.

Bí o bá rí i pé wàá tún lè bá onítọ̀hún sọ̀rọ̀ síwájú sí i nígbà mìíràn, gbin nǹkan kan tí onítọ̀hún yóò máa wọ̀nà fún nígbà yẹn sí i lọ́kàn. Bi í ní ìbéèrè kan, bóyá ọ̀kan lára èyí tó wà nínú ìwé Reasoning From the Scriptures tàbí ìwé mìíràn tá a fi ń báni ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nílé. Má gbàgbé ohun tó gbé ọ wá síbẹ̀, èyí tí Jésù sọ, tó sì wà lákọọ́lẹ̀ nínú Mátíù 28:19, 20.

Ṣé o ti fẹ́ parí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí ò ń bá ẹnì kan ṣe lọ́wọ́? Tó o bá tún ẹṣin ọ̀rọ̀ tí ẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ lé lórí sọ yóò mú kí akẹ́kọ̀ọ́ náà lè rántí ohun tí ẹ jọ sọ. Tí o bá lo ìbéèrè láti fi ṣàtúnyẹ̀wò ohun tó o kọ́ ọ, yóò mú kí àwọn kókó pàtàkì inú ọ̀rọ̀ yẹn túbọ̀ wọ akẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́kàn ṣinṣin, pàápàá tí ẹ bá fara balẹ̀ ṣe àtúnyẹ̀wò yẹn. Bí o bá bi akẹ́kọ̀ọ́ léèrè nípa bí ohun tó kọ́ yẹn ṣe lè ṣe é láǹfààní tàbí bí ó ṣe lè sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ fún àwọn ẹlòmíràn, ìyẹn lè mú kí ó ronú nípa bí òun ṣe lè mú ohun tóun kọ́ yẹn lò.—Òwe 4:7.

Rántí pé ìparí ọ̀rọ̀ rẹ máa ń nípa lórí bí gbogbo ọ̀rọ̀ tó o báni sọ ṣe máa múná dóko tó.

BÍ O ṢE LÈ ṢE É

  • Rí i dájú pé ìparí ọ̀rọ̀ rẹ wé mọ́ àwọn kókó tó o ti ṣàlàyé ní tààràtà.

  • Sọ ohun tó yẹ kí àwùjọ ṣe nípa ohun tí wọ́n gbọ́.

  • Jẹ́ kí ohun tí o bá sọ àti ọ̀nà tí o gbà sọ ọ́ gún àwọn olùgbọ́ rẹ ní kẹ́ṣẹ́.

ÌDÁNRAWÒ: Múra ìparí ọ̀rọ̀ oríṣi méjì tó o máa lò lóde ẹ̀rí: (1) ohun tó o máa sọ bí onílé bá dá ọ̀rọ̀ mọ́ ọ lẹ́nu tí kò sì sáyè láti sọ̀rọ̀ lọ títí àti (2) ìbéèrè kan ní pàtó tẹ́ ẹ jọ máa sọ̀rọ̀ lé lórí nígbà tó o bá padà tọ̀ ọ́ lọ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́