ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • lff ẹ̀kọ́ 55
  • Máa Ṣètìlẹyìn fún Ìjọ

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Ṣètìlẹyìn fún Ìjọ
  • Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀
  • KÓKÓ PÀTÀKÌ
  • ṢÈWÁDÌÍ
  • A Dúpẹ́ Lọ́wọ́ Jèhófà Torí Ìfẹ́ Tẹ́ Ẹ̀ Ń Fi Hàn
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
  • “Ẹ̀bùn Tá A Mú Dání Wá fún Jèhófà”
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2018
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Iṣẹ́ àti Owó
    Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
  • Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Fún Ẹni Tó Ni Ohun Gbogbo Ní Nǹkan?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
Àwọn Míì
Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìjíròrò Látinú Bíbélì
lff ẹ̀kọ́ 55
Ẹ̀kọ́ 55. Àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ń ṣiṣẹ́ ní ìta ilé ìpàdé wọn.

Ẹ̀KỌ́ 55

Máa Ṣètìlẹyìn fún Ìjọ

Bíi Ti Orí Ìwé
Bíi Ti Orí Ìwé
Bíi Ti Orí Ìwé

Ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló ń fayọ̀ sin Jèhófà ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìjọ tó wà kárí ayé. Wọ́n mọyì àwọn ìtọ́ni tí wọ́n ń gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà, wọ́n sì ń fi tinútinú ṣètìlẹyìn fún ìjọ láwọn ọ̀nà tó yàtọ̀ síra. Ṣé ó wu ìwọ náà láti máa ṣètìlẹyìn fún ìjọ tó o wà?

1. Àwọn nǹkan wo lo lè ṣe láti ṣètìlẹyìn fún ìjọ?

Gbogbo wa la lè ṣe ohun kan tàbí òmíì láti ran ìjọ lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, ṣé àwọn àgbàlagbà tàbí àwọn tí ara wọn ò yá wà nínú ìjọ yín? Ṣé o lè gbé wọn lọ sípàdé? Ṣé o lè bá wọn ṣe àwọn nǹkan míì bíi kó o bá wọn ra nǹkan lọ́jà tàbí kó o bá wọn tún ilé ṣe? (Ka Jémíìsì 1:27.) A tún lè yọ̀ǹda ara wa láti tún ibi ìjọsìn wa ṣe. Kò sẹ́ni tó ń fipá mú wa pé ká ṣe àwọn nǹkan yìí. Ṣe la máa ń “yọ̀ǹda ara [wa] tinútinú,” torí pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àtàwọn ará.​—Sáàmù 110:3.

Àwọn nǹkan míì tún wà táwọn tó ti ṣèrìbọmi lè ṣe láti ṣètìlẹyìn fún ìjọ. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ àwọn nǹkan tó yẹ káwọn arákùnrin ṣe kí wọ́n lè máa ṣiṣẹ́ sin ìjọ. Àwọn tó bá ń ṣe àwọn nǹkan yìí lè di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́, tó bá sì yá wọ́n lè di alàgbà. Gbogbo àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló láǹfààní láti di aṣáájú-ọ̀nà kí wọ́n lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Àwọn kan lè yọ̀ǹda ara wọn láti kọ́ àwọn ilé tá à ń lò fún ìjọsìn, àwọn míì sì lè ṣí kúrò ládùúgbò wọn kí wọ́n lè lọ ran ìjọ míì lọ́wọ́.

2. Báwo la ṣe lè fi ohun ìní wa ṣètìlẹyìn fún ìjọ?

A lè “fi àwọn ohun ìní [wa] tó níye lórí bọlá fún Jèhófà.” (Òwe 3:9) A mọyì àǹfààní tá a ní láti fi owó àti ohun ìní wa ṣètìlẹyìn fún ìjọ àti fún iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe kárí ayé. (Ka 2 Kọ́ríńtì 9:7.) Wọ́n tún máa ń lo ọrẹ wa láti bójú tó àwọn ará wa tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí. Ọ̀pọ̀ àwọn ará ló máa ń “ya ohun kan sọ́tọ̀” déédéé kí wọ́n lè fi ṣètìlẹyìn. (Ka 1 Kọ́ríńtì 16:2.) A lè fi owó tá a fẹ́ fi ṣètìlẹyìn sínú àpótí láwọn ibi tá à ń lò fún ìjọsìn, a sì lè ṣètọrẹ látorí ìkànnì donate.jw.org. Jèhófà fún wa láǹfààní láti máa lo ohun ìní wa lọ́nà tó tọ́ ká lè fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ òun.

KẸ́KỌ̀Ọ́ JINLẸ̀

Jẹ́ ká wo àwọn nǹkan tó o lè ṣe láti ṣètìlẹyìn fún ìjọ.

3. A lè fi ohun ìní wa ṣètìlẹyìn

Jèhófà àti Jésù nífẹ̀ẹ́ àwọn tó jẹ́ ọ̀làwọ́. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí opó kan tó jẹ́ aláìní fi ohun tó ní ṣètìlẹyìn, Jésù kíyè sí i, ó sì mọyì ohun tó ṣe. Ka Lúùkù 21:1-4, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Ṣé ó dìgbà tá a bá fi owó ńlá ṣètìlẹyìn kínú Jèhófà tó dùn sí wa?

  • Báwo ló ṣe máa ń rí lára Jèhófà àti Jésù tá a bá fi tinútinú ṣètìlẹyìn?

Kó o lè mọ bí wọ́n ṣe ń ná owó tá a fi ń ṣètọrẹ, wo FÍDÍÒ yìí. Lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

FÍDÍÒ: ‘Wọ́n Mú Ẹ̀bùn Wá fún Jèhófà’ (4:47)

  • Báwo ni wọ́n ṣe ń lo owó tá a fi ń ṣètọrẹ kó lè ṣe àwọn ará wa láǹfààní kárí ayé?

Arábìnrin àgbàlagbà kan ń fi owó sínú àpótí ọrẹ.

4. A lè yọ̀ǹda ara wa

Nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, àwọn èèyàn Jèhófà máa ń fìtara bójú tó ibi tí wọ́n ti ń jọ́sìn. Àmọ́, ìyẹn kọjá pé kí wọ́n fi owó ṣètìlẹyìn. Ka 2 Kíróníkà 34:9-11, lẹ́yìn náà kó o dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Kí ló fi hàn pé gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ló ṣètìlẹyìn kí wọ́n lè tún ilé Jèhófà ṣe?

Kó o lè rí bí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yẹn, wo FÍDÍÒ yìí. Lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

FÍDÍÒ: Bá A Ṣe Lè Máa Bójú Tó Àwọn Ibi Ìjọsìn Wa (3:31)

Àwòrán apá kan látinú fídíò ‘Bá A Ṣe Lè Máa Bójú Tó Àwọn Ibi Ìjọsìn Wa.’ Àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin, lọ́mọdé lágbà ń tún ilé ìpàdé wọn ṣe.
  • Kí nìdí tó fi yẹ ká máa tún ilé ìpàdé wa ṣe déédéé, ká sì rí i pé ó ń wà ní mímọ́ tónítóní?

  • Àwọn nǹkan wo lo lè ṣe kí ilé ìpàdé lè máa wà ní mímọ́ tónítóní?

Àwọn ará yọ̀ǹda ara wọn láti kọ́ ọ̀kan lára àwọn ilé tá à ń lò fún ìjọsìn.

5. Àwọn arákùnrin lè gbìyànjú láti ṣe púpọ̀ sí i nínú ìjọ

Ìwé Mímọ́ gba àwọn arákùnrin níyànjú pé kí wọ́n ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti ran ìjọ lọ́wọ́. Kó o lè rí àpẹẹrẹ kan, wo FÍDÍÒ yìí. Lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè tó tẹ̀ lé e.

FÍDÍÒ: Ẹ̀yin Arákùnrin​—Ẹ Wá Bẹ́ Ẹ Ṣe Máa Ṣe Púpọ̀ Sí I Nínú Iṣẹ́ Ọlọ́run (5:19)

  • Nínú fídíò yẹn, kí ni Ryan ṣe kó lè túbọ̀ máa ran àwọn ará lọ́wọ́?

Bíbélì jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan táwọn arákùnrin gbọ́dọ̀ máa ṣe kí wọ́n tó lè di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ àti alàgbà. Ka 1 Tímótì 3:1-13, lẹ́yìn náà kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  • Irú ẹni wo ni Bíbélì sọ pé àwọn arákùnrin gbọ́dọ̀ jẹ́ kí wọ́n tó lè di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ tàbí alàgbà?

  • Àwọn nǹkan wo ni Bíbélì sọ pé ó yẹ kí àwọn tó wà nínú ìdílé ẹni náà máa ṣe?​—Wo ẹsẹ 4 àti 11.

  • Àǹfààní wo ló máa ṣe ìjọ táwọn arákùnrin bá gbìyànjú láti máa ṣe àwọn nǹkan tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ?

Ọ̀dọ́kùnrin kan ń ti àgbàlagbà kan lórí kẹ̀kẹ́ arọ, àwọn méjèèjì wà lóde ẹ̀rí.

ẸNÌ KAN LÈ BÉÈRÈ PÉ: “Ibo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń rówó tí wọ́n ń ná?”

  • Kí ni wàá sọ?

KÓKÓ PÀTÀKÌ

Jèhófà mọyì bá a ṣe ń lo okun wa, àkókò wa àti ohun ìní wa láti ṣètìlẹyìn fún ìjọ.

Kí lo rí kọ́?

  • Báwo la ṣe lè lo okun àti àkókò wa láti ṣètìlẹyìn fún ìjọ?

  • Báwo la ṣe lè fi ohun ìní wa ṣètìlẹyìn fún ìjọ?

  • Àwọn nǹkan wo ni wàá fẹ́ ṣe láti ṣètìlẹyìn fún ìjọ?

Ohun tó yẹ kó o ṣe

ṢÈWÁDÌÍ

Ka àpilẹ̀kọ yìí kó o lè mọ ìdí tí Ọlọ́run ò fi retí pé kí àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ lónìí máa san ìdá mẹ́wàá.

“Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ìdá Mẹ́wàá?” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)

Bíbélì sọ pé Ọlọ́run fún àwọn ọkùnrin tí wọ́n ti ṣèrìbọmi láǹfààní láti ṣe àwọn iṣẹ́ kan nínú ìjọ. Ka ìwé yìí kó o lè mọ ohun tó yẹ kí obìnrin kan tó ti ṣèrìbọmi ṣe tó bá fẹ́ bójú tó irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀.

“Mọyì Ipò Orí Tí Jèhófà Ṣètò Nínú Ìjọ” (Ilé Ìṣọ́, February 2021)

Wo fídíò yìí kó o lè rí bí àwọn arákùnrin tó jẹ́ onígboyà ṣe ń yọ̀ǹda ara wọn láti kó ìwé lọ fún àwọn ará.

Bí A Ṣe Ń Pín Àwọn Ìwé Tó Ṣàlàyé Bíbélì Lórílẹ̀-Èdè Congo (4:25)

Ka àpilẹ̀kọ yìí kó o lè rí i pé bá a ṣe ń rí owó yàtọ̀ sí bí àwọn ẹlẹ́sìn tó kù ṣe ń rí owó.

“Ibo Làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ti Ń Rówó Tí Wọ́n Ń Ná?” (Àpilẹ̀kọ orí ìkànnì)

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́