ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • lmd ẹ̀kọ́ 9
  • Máa Fọ̀rọ̀ Ro Ara Ẹ Wò

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Máa Fọ̀rọ̀ Ro Ara Ẹ Wò
  • Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn—Máa Sọ Wọ́n Dọmọ Ẹ̀yìn
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Jésù Ṣe
  • Kí La Rí Kọ́ Lára Jésù?
  • Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù
  • Ẹ̀mí Ìfọ̀rọ̀rora- Ẹni-Wò—Ń Jẹ́ Ká Ní Ojú Àánú àti Ìyọ́nú
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Máa Fọ̀rọ̀ Ro Ara Ẹ Wò
    Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2021
  • Máa Gba Tàwọn Èèyàn Rò
    Jí!—2020
  • “Àánú Ṣe É”
    “Máa Tọ̀ Mí Lẹ́yìn”
Àwọn Míì
Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn—Máa Sọ Wọ́n Dọmọ Ẹ̀yìn
lmd ẹ̀kọ́ 9

PA DÀ LỌ

Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ sọ̀ kalẹ̀ nínú ọkọ̀ ojú omi, wọ́n ń rìn lọ sọ́dọ̀ èrò rẹpẹtẹ tó ń dúró dè wọ́n létíkun.

Máàkù 6:30-34

Ẹ̀KỌ́ 9

Máa Fọ̀rọ̀ Ro Ara Ẹ Wò

Ìlànà: “Ẹ máa yọ̀ pẹ̀lú àwọn tó ń yọ̀; ẹ máa sunkún pẹ̀lú àwọn tó ń sunkún.”—Róòmù 12:15.

Ohun Tí Jésù Ṣe

Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn ẹ̀ sọ̀ kalẹ̀ nínú ọkọ̀ ojú omi, wọ́n ń rìn lọ sọ́dọ̀ èrò rẹpẹtẹ tó ń dúró dè wọ́n létíkun.

FÍDÍÒ: Àánú Àwọn Èèyàn Ṣe Jésù

1. Wo FÍDÍÒ yìí, tàbí kó o ka Máàkù 6:30-34. Lẹ́yìn náà, kó o dáhùn àwọn ìbéèrè yìí:

  1. Kí nìdí tí Jésù àtàwọn àpọ́sítélì ẹ̀ fi fẹ́ lọ síbi “tí àwọn nìkan máa wà”?

  2. Kí ló mú kó wu Jésù láti kọ́ èrò rẹpẹtẹ náà?

Kí La Rí Kọ́ Lára Jésù?

2. Tá a bá ń fọ̀rọ̀ àwọn èèyàn ro ara wa wò, kì í ṣe ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nìkan la máa sọ fún wọn, àá tún ràn wọ́n lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà míì.

Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Jésù

3. Máa fetí sílẹ̀ dáadáa. Jẹ́ kí ẹni náà sọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀. Má ṣe já lu ọ̀rọ̀ ẹ̀, má sì fojú kéré ìṣòro ẹ̀ àti bí nǹkan ṣe rí lára ẹ̀. Bákan náà, má ṣe bínú tí kò bá fara mọ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì kan. Tó o bá fetí sílẹ̀ dáadáa, ẹni náà á rí i pé o ka ọ̀rọ̀ òun sí.

4. Máa ronú nípa ẹni náà. Ronú nípa ohun tẹ́ ẹ jọ sọ, kó o sì bi ara ẹ pé:

  1. ‘Kí nìdí tó fi yẹ kó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́?’

  2. ‘Tó bá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ kí ìgbé ayé ẹ̀ àti ọjọ́ iwájú ẹ̀ dáa sí i?’

5. Sọ ohun tó máa ràn án lọ́wọ́. Tètè jẹ́ kó rí i pé tó bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó máa rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè ẹ̀, ayé ẹ̀ á sì dáa sí i.

TÚN WO

Róòmù 10:13, 14; Fílí. 2:3, 4; 1 Pét. 3:8

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́