ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 1/15 ojú ìwé 22
  • Ẹ Wa Ni Sẹpẹ fun Ọjọ Jehofa!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Wa Ni Sẹpẹ fun Ọjọ Jehofa!
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Funni ni Ọrọ Iwuri ati Iṣiri
  • Duro Ni Wiwa Lojufo nipa Tẹmi!
  • Ẹ Máa Múra Sílẹ̀ De Ọjọ́ Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • “Ẹ Maṣe Juwọsilẹ Ninu Ṣiṣe Ohun Ti O Tọna”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Jèhófà Máa Dáàbò Bò Ẹ́—Lọ́nà Wo?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2021
  • Ireti—Idaabobo Ṣiṣekoko Ninu Ayé Amúnirẹ̀wẹ̀sì Kan
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1993
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 1/15 ojú ìwé 22

Ẹ Wa Ni Sẹpẹ fun Ọjọ Jehofa!

Awọn Kókó Itẹnumọ Lati Inu Tẹsalonika Kìn-ínní

ỌJỌ Jehofa! Awọn Kristian ni Tẹsalonika igbaani ronu pe o ti ku si dẹdẹ. Wọn ha tọna bi? Nigba wo ni yoo de? Iyẹn jẹ ọran pataki kan ti a bojuto ninu lẹta akọkọ apọsteli Pọọlu si awọn ara Tẹsalonika, ti a fi ranṣẹ lati Kọrinti ni nnkan bii ọdun 50 ti Sanmanni Tiwa.

Pọọlu ati Sila fidii ijọ mulẹ ni Tẹsalonika, ibujokoo ti ipinlẹ akoso Romu ti Masidonia. (Iṣe 17:1-4) Lẹhin naa, ninu lẹta rẹ akọkọ si awọn ara Tẹsalonika, Pọọlu sọ ọrọ iwuri, pese iṣileti, o si jiroro ọjọ Jehofa. Awa pẹlu le janfaani lati inu lẹta yii, paapaa bi ọjọ Jehofa ti sunmọle nisinsinyi gan an.

Funni ni Ọrọ Iwuri ati Iṣiri

Pọọlu kọkọ fun awọn ara Tẹsalonika ni ọrọ iwuri. (1:1-10) Ọrọ iwuri yẹ nitori iṣẹ iṣotitọ ati ifarada wọn. O yẹ fun ọrọ iwuri pẹlu, pe wọn “gba ọrọ naa ninu ipọnju ọpọlọpọ, pẹlu ayọ Ẹmi Mimọ.” Iwọ nha fun awọn ẹlomiran ni ọrọ iwuri gẹgẹbi Pọọlu ti ṣe bi?

Apọsteli naa ti fi apẹẹrẹ rere lelẹ. (2:1-12) Laika ihuwasi alafojudi ni Filippi si, oun ti ‘ni igboya ninu Ọlọrun lati sọrọ ihinrere’ fun awọn ara Tẹsalonika. Oun ti yẹ apọnle, ojukokoro, ati wiwa ogo silẹ. Pọọlu ko di ẹru-inira amuni nawonara ṣugbọn o jẹ ẹni pẹlẹ pẹlu wọn gẹgẹbi abiyamọ ti jẹ pẹlu ọmọ rẹ. Ẹ wo apẹẹrẹ rere kan ti o jẹ́ fun awọn alagba lonii!

Awọn ọ̀rọ̀ Pọọlu ti o tẹle e fun awọn ara Tẹsalonika ni iṣiri lati duro gbọnyingbọnyin nigbati a ba nṣe inunibini si wọn. (2:13–3:13) Wọn ti farada inunibini lati ọdọ awọn ara ilu wọn, Timoti si ti mu irohin rere wa fun Pọọlu nipa ipo tẹmi wọn. Apọsteli naa gbadura pe ki wọn pọ gidigidi ninu ifẹ ati pe ki a ṣe awọn ọkan-aya wọn giri. Lọna ti o farajọra, Ẹlẹrii Jehofa nisinsinyi gbadura fun awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ wọn ti a nṣe inunibini si, wọn nfun wọn ni iṣiri bi o ba ṣeeṣe, wọn sì nyọ ninu awọn irohin iṣotitọ wọn.

Duro Ni Wiwa Lojufo nipa Tẹmi!

Awọn ara Tẹsalonika gba imọran tẹle e. (4:1-18) Wọn nilati rin lọna kikun sii ni ipa ọna ti o wu Ọlọrun, fifi ifẹ ara hansode sii ati ṣiṣiṣẹ pẹlu ọwọ araawọn lati kaju aini wọn. Ju bẹẹ lọ, wọn nilati tu araawọn ẹnikinni ẹnikeji ninu pẹlu ireti naa pe ni igba wíwànihin in Jesu awọn onigbagbọ ti a fi ẹmi yan ti wọn ti ku ni a o kọ́kọ́ gbedide ti wọn yoo si sopọṣọkan pẹlu rẹ̀. Lẹhin igba naa, awọn ẹni ami ororo ti wọn walaaye nigba iku ati ajinde wọn yoo darapọ mọ Kristi ati awọn wọnni ti a ti jinde si iye ti ọrun ṣaaju.

Pọọlu jiroro ọjọ Jehofa tẹle e o si pese imọran siwaju sii. (5:1-28) Ọjọ Jehofa nbọ gẹgẹ bi ole, pẹlu iparun ojiji ti o daju lẹhin igbe naa: “Alaafia ati ailewu!” Nitori naa awọn ara Tẹsalonika nilati wa lojufo nipa tẹmi niṣo, ti a daabobo wọn nipasẹ àwo ìgbàyà ti igbagbọ ati ifẹ ati nipasẹ ireti ti igbala gẹgẹ bi àṣíborí. Wọn nilati ni ọ̀wọ̀ jijinlẹ fun awọn wọnni ti wọn nṣe alaga ninu ijọ wọn si nilati fasẹhin kuro ninu iwa buruku, gẹgẹ bi awa ti gbọdọ ṣe.

Lẹta Pọọlu akọkọ si awọn ara Tẹsalonika nilati ta wa ji lati fi ọrọ iwuri ati iṣiri fun awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ wa. O nilati tun sun wa lati jẹ awofiṣapẹẹrẹ ninu iwa ati iṣesi. Dajudaju imọran rẹ̀ sì le ran wa lọwọ lati wa ni sẹpẹ fun ọjọ Jehofa.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

Àwo Ìgbàyà ati Àṣíborí: Ni rirọni lati jíkalẹ̀ nipa tẹ̀mí, Pọọlu kọwe pe: “Ki a maa pa oye-imọlara wa mọ ki a si gbe awo igbaya igbagbọ ati ifẹ wọ̀, ireti igbala gẹgẹbi aṣibori.” (1 Tẹsalonika 5:8, NW) Àwo ìgbàyà jẹ ihamọra idaabobo àyà jagunjagun kan, o ni ninu awọn ìpẹ́, ọ̀gbàrà-ẹ̀wọ̀n, tabi irin lile korankoran. Lọna ti o farajọra, awo igbaya ti igbagbọ daabobo wa nipa tẹmi. Ki sì ni nipa aṣibori igbaani? Niye igba a ṣe e pẹlu irin, o jẹ ìgbàrí ológun ti a wewee lati daabobo jagunjagun kan lakooko ogun. Gẹgẹbi àṣíborí ti daabobo orí jagunjagun kan, bẹẹ ni ireti igbala daabobo awọn agbara ero-ori, ti o tipa bayii mu ki Kristian kan lè di iwatitọ mu. Bawo ni o ti ṣepataki to pe ki awọn eniyan Jehofa gbe irufẹ ihamọra tẹmi bẹẹ wọ̀!—Efesu 6:11-17.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́