“Ẹ Maṣe Juwọsilẹ Ninu Ṣiṣe Ohun Ti O Tọna”
Awọn Kókó Ìtẹnumọ́ Lati inu Tẹsalonika Keji
ANIYAN apọsteli Pọọlu fun awọn Kristian ni ilu nla Masidonia ti Tẹsalonika sun un lati kọ lẹta rẹ̀ keji si wọn, ni nnkan bii 51 C.E. Awọn kan ninu ijọ nsọ laitọ pe wíwànihin in Jesu Kristi ku si dẹ̀dẹ̀. Ani boya lẹta kan ti a kasi ti Pọọlu lọna aitọ ni a tumọsi gẹgẹ bi eyi ti nfihan pe “ọjọ Jehofa” ti de.—2 Tẹsalonika 2:1, 2.
Nitorinaa ironu awọn ara Tẹsalonika diẹ nbeere fun itunṣe bọsipo. Ninu lẹta rẹ keji, Pọọlu gboriyin fun wọn fun igbagbọ wọn ti ndagba, ifẹ ti npọ sii ati ifarada oluṣotitọ. Ṣugbọn oun tun fihan pe ipẹhinda yoo wa ṣaaju wiwa nihin-in Jesu. Nitori naa awọn akoko iṣoro nbẹ niwaju, lẹta apọsteli naa yoo si ran wọn lọwọ lati kọbiarasi iṣileti rẹ: “Ẹ maṣe juwọsilẹ ninu ṣiṣe ẹtọ.” (2 Tẹsalonika 3:13) Awọn ọrọ Pọọlu le ran wa lọwọ ni ọna kan naa.
Iṣipaya ati Wiwa Nihin-in Jesu
Pọọlu kọkọ sọrọ nipa itura alaafia kuro ninu ipọnju. (1:1-12) Eyi yoo wá “nigba iṣipaya Jesu Oluwa lati ọrun wa pẹlu awọn alagbara angeli rẹ.” Iparun ayeraye ni a o muwa nigba naa sori awọn wọnni ti wọn kii ṣegbọran si ihinrere. O ntunininu lati ranti eyi nigba ti a ba njiya ipọnju lọwọ awọn oninunibini.
Lẹhin eyi, Pọọlu tọkajade pe “ọkunrin iwa ailofin” naa ni a o ṣipaya ṣaaju wiwa nihin-in Kristi. (2:1-17) Awọn ara Tẹsalonika ni a ko nilati rusoke nipa ihin iṣẹ eyikeyii ti nmu un wa sọkan pe “ọjọ Jehofa” ti de ba wọn na. Lakọọkọ, ipẹhinda naa yoo waye ti a o si ṣí ọkunrin iwa ailofin naa paya. Lẹhin igba naa, Jesu yoo sọ ọ di asan, ni ṣiṣe bẹẹ ni igba ifihan wiwa nihin-in Rẹ̀. Laaarin akoko naa, Pọọlu gbadura pe ki Ọlọrun ati Kristi tu ọkan-aya awọn ara Tẹsalonika ninu ki o si mu wọn “fidi mulẹ ṣinṣin ninu iṣe ati ọ̀rọ̀ daradara gbogbo.”
Biba Awọn Oníségesège Lò
Laaarin awọn ọrọ Pọọlu siwaju sii ni awọn itọni lori biba awọn eniyan oníségesège lò. (3:1-18) Oun fi igbọkanle han pe Oluwa yoo fun awọn ara Tẹsalonika lokun yoo si pa wọn mọ kuro lọwọ ẹni buruku naa, Satani Eṣu. Ṣugbọn wọn nilo lati gbe igbesẹ fun anfaani tiwọn funraawọn nipa tẹmi. Wọn nilati fasẹhin kuro lọdọ awọn oníségesège, awọn wọnni ti wọn ntojubọ awọn ọran tí kò kan wọn ti wọn sì nkọ lati ṣiṣẹ. Pọọlu wipe, “Bi ẹnikẹni ko ba fẹ ṣiṣẹ, ki o ma si ṣe jẹun.” Iru awọn ẹni bẹẹ ni a nilati samisi, ko gbọdọ si ibakẹgbẹ ajọṣe kankan pẹlu wọn, bi o tilẹ jẹ pe a nilati gba wọn niyanju gẹgẹ bi ará. Awọn Kristian oluṣotitọ ara Tẹsalonika ni wọn ko nilati juwọsilẹ ninu ṣiṣe ohun ti o tọ, Pọọlu si nifẹẹ ọkan pe ki inurere ailẹtọọsi Oluwa Jesu Kristi wa pẹlu gbogbo wọn.
Lẹta Pọọlu keji si awọn ara Tẹsalonika fun awọn Ẹlẹrii Jehofa ni idaniloju pe itura alaafia kuro ninu ipọnju wọn yoo de nigbati Kristi ati awọn angẹli rẹ ba mu ẹsan wa sori awọn wọnni ti wọn ko ṣegbọran si ihin rere. O tun nfun igbagbọ lokun lati mọ pe “ọkunrin iwa ailofin naa” (ẹgbẹ awujọ alufaa Kristendom) ati gbogbo isin eke ni a o muwa si opin laipẹ jọjọ. Ki o to di ìgbà naa, ẹ jẹ ki a kọbiarasi igbaniniyanju Pọọlu pe kí á má juwọsilẹ ninu ṣiṣe ẹtọ.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Ọrọ Jehofa Ntẹsiwaju Niṣo Pẹlu Iyarakankan: “Ẹ kun fun adura fun wa,” ni Pọọlu kọwe, “ki ọrọ Jehofa baa le maa tẹsiwaju niṣo pẹlu iyarakankan [tabi, “baa le maa sare”] ki a si maa ṣee logo gan-an gẹgẹ bi o ti ri lọdọ yin niti tootọ.” (2 Tẹsalonika 3:1; Kingdom Interlinear) Awọn ọmọwe akẹkọọjinlẹ kan ti dabaa pe apọsteli Pọọlu ńpàṣamọ̀ mọ́ awọn saresare ti wọn nyarakankan niṣo ninu eré sísá. Nigba ti iyẹn jẹ alaidaniloju, Pọọlu nbeere fun adura awọn Kristian ara Tẹsalonika ki oun ati awọn alajọṣiṣẹpọ rẹ baa le maa tan ọrọ otitọ kalẹ pẹlu kanjukanju ati laisi idilọwọ. Nitori pe Ọlọrun ndahun irufẹ awọn adura bẹẹ, ọrọ rẹ “ntẹsiwaju niṣo pẹlu iyarakankan” niwọnbi a ti waasu ihin rere naa pẹlu kanjukanju ni awọn ọjọ ikẹhin wọnyi. Ọrọ Jehofa ni a tun ‘ṣe logo,’ ti a gbeniyi lọna giga lati ọwọ́ awọn onigbagbọ gẹgẹbi “agbara Ọlọrun fun igbala,” gẹgẹbi o ti ri laaarin awọn ara Tẹsalonika ti wọn tẹwọgba a. (Romu 1:16; 1 Tẹsalonika 2:13) Bawo ni a ti layọ to pe Ọlọrun nbukun awọn olupokiki Ijọba o si nmu òtú awọn olujọsin pọ sii pẹlu iyarakankan!—Aisaya 60:22.