ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w99 7/15 ojú ìwé 29-31
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • “Ẹ Maṣe Juwọsilẹ Ninu Ṣiṣe Ohun Ti O Tọna”
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Bá A Ṣe Lè Jẹ́ Kí Ìjọ Wà ní Mímọ́ Kí Àlàáfíà sì Jọba
    A Ṣètò Wa Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà
  • “Ẹ Ní Ẹ̀mí Ìkanisí Fún Àwọn Tí Ń Ṣiṣẹ́ Kára Láàárín Yín”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
w99 7/15 ojú ìwé 29-31

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ṣé ìjọ ló yẹ kó ṣe ‘sísàmì’ tí a mẹ́nu kàn nínú 2 Tẹsalóníkà 3:14 ni, àbí olúkúlùkù Kristẹni ló lè ṣe é nípa sísára fún irú àwọn aláìgbọràn bẹ́ẹ̀?

Lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sáwọn ará Tẹsalóníkà fi hàn pé àwọn alàgbà ìjọ ní ipa tó ṣe kedere láti kó nínú irú ‘sísàmì’ bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n, olúkúlùkù Kristẹni yóò wá ṣe é láṣetán, wọ́n a sì ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ète tẹ̀mí lọ́kàn. A lè lóye èyí dáadáa báa bá gbé ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù yẹ̀ wò pẹ̀lú àyíká tó ti kọ lẹ́tà náà ní ìpilẹ̀ṣẹ̀.

Pọ́ọ̀lù ṣèrànwọ́ láti dá ìjọ Tẹsalóníkà sílẹ̀, ó ran tọkùnrin tobìnrin lọ́wọ́ láti di onígbàgbọ́. (Ìṣe 17:1-4) Lẹ́yìn náà ó kọ̀wé láti Kọ́ríńtì láti gbóríyìn fún wọn, kó sì fún wọn níṣìírí. Pọ́ọ̀lù tún fún wọn nímọ̀ràn tí wọ́n nílò. Ó rọ̀ wọ́n ‘láti máa gbé ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́, láti má ṣe yọjú sí ọ̀ràn ọlọ́ràn, àti láti máa fi ọwọ́ ara wọn ṣiṣẹ́.’ Àwọn kan ò ṣe bẹ́ẹ̀ o, ni Pọ́ọ̀lù bá fi kún un pé: “A ń gbà yín níyànjú, ẹ̀yin ará, kí ẹ máa fún àwọn tí ń ṣe ségesège ní ìṣílétí, ẹ máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ọkàn tí ó soríkọ́, ẹ máa ṣètìlẹyìn fún àwọn aláìlera.” Ó ṣe kedere pé, “àwọn tí ń ṣe ségesège”a wà láàárín wọn, wọ́n sì nílò ìmọ̀ràn.—1 Tẹsalóníkà 1:2-10; 4:11; 5:14.

Ní oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà rẹ̀ kejì sí àwọn ará Tẹsalóníkà, ó wá fi àlàyé nípa wíwàníhìn-ín Jésù lọ́jọ́ ọ̀la kún un. Pọ́ọ̀lù tún wá pèsè ìmọ̀ràn kíkún nípa báa ṣe lè bá àwọn tí ń ṣe ségesège lò, àwọn tí ‘kì í ṣiṣẹ́ ṣùgbọ́n tí wọ́n ń tojú bọ ohun tí kò kàn wọ́n.’ Ìgbésẹ̀ wọn kó bá àpẹẹrẹ tí Pọ́ọ̀lù fi lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ aláápọn mú, ó sì tún tako àṣẹ ṣíṣe kedere tó pa nípa ṣíṣiṣẹ́ láti lè gbọ́ bùkátà ẹni. (2 Tẹsalóníkà 3:7-12) Pọ́ọ̀lù ní kí wọ́n gbé àwọn ìgbésẹ̀ pàtó. Àwọn ìgbésẹ̀ wọ̀nyí yóò wáyé lẹ́yìn tí àwọn alàgbà bá ti ṣe ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe ní ti fífún ẹni tí ń ṣe ségesège náà ní ìṣílétí àti gbígbà á nímọ̀ràn. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé:

“Wàyí o, a ń pa àṣẹ ìtọ́ni fún yín, ẹ̀yin ará, . . . pé kí ẹ fà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ olúkúlùkù arákùnrin tí ń rìn ségesège, tí kì í sì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú àṣà àfilénilọ́wọ́ tí ẹ gbà láti ọ̀dọ̀ wa. Ní tiyín, ẹ̀yin ará, ẹ má ṣe juwọ́ sílẹ̀ ní ṣíṣe ohun tí ó tọ́. Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni kò bá jẹ́ onígbọràn sí ọ̀rọ̀ wa nípasẹ̀ lẹ́tà yìí, ẹ sàmì sí ẹni yìí, ẹ dẹ́kun bíbá a kẹ́gbẹ́, kí ojú lè tì í. Síbẹ̀, ẹ má kà á sí ọ̀tá, ṣùgbọ́n ẹ máa bá a lọ ní ṣíṣí i létí gẹ́gẹ́ bí arákùnrin.”—2 Tẹsalóníkà 3:6, 13-15.

Nítorí náà àwọn ìgbésẹ̀ táa lè gbé síwájú sí i ni pé, kí a fà sẹ́yìn fún àwọn tí ń ṣe ségesège, kí a sàmì sí wọn, kí a dẹ́kun ṣíṣe wọléwọ̀de pẹ̀lú wọn, síbẹ̀ kí a máa ṣí wọn létí gẹ́gẹ́ bí arákùnrin. Kí ló lè mú kí àwọn mẹ́ńbà ìjọ gbé irú ìgbésẹ̀ yẹn? Gẹ́gẹ́ bí ìrànwọ́ láti mú kí ọ̀ràn yìí yéni yéké, ẹ jẹ́ kí a mọ àwọn ipò mẹ́ta tí Pọ́ọ̀lù kò darí àfiyèsí sí níhìn-ín lámọ̀dunjú.

1. A mọ̀ pé aláìpé làwọn Kristẹni, olúkúlùkù sì ní àléébù tiẹ̀. Síbẹ̀, ìfẹ́ jẹ́ àmì ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́, tó ń béèrè pé ká jẹ́ ẹni tó ń fòye báni lò, tó sì lè dárí ji àwọn ẹlòmíràn bí wọ́n bá ṣàṣìṣe. Fún àpẹẹrẹ, inú lè bí Kristẹni kan gan-an, gẹ́gẹ́ bó ti ṣẹlẹ̀ láàárín Bánábà àti Pọ́ọ̀lù. (Ìṣe 15:36-40) Ó sì lè jẹ́ nítorí pé ó rẹ ẹnì kan, ó lè mú kí ó sọ̀rọ̀ líle tàbí ọ̀rọ̀ kòbákùngbé. Nínú irú àwọn ipò bẹ́ẹ̀, báa bá fi ìfẹ́ hàn, táa sì fi ìmọ̀ràn Bíbélì sílò, a lè mọ́kàn kúrò lórí àṣìṣe náà, ká máa bá ìgbésí ayé wa lọ, ká máa kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa, ká sì máa bá wọn ṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́. (Mátíù 5:23-25; 6:14; 7:1-5; 1 Pétérù 4:8) Ó ṣe kedere pé, kì í ṣe irú ìkùdíẹ̀-káàtó yìí ni Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nínú 2 Tẹsalóníkà.

2. Ohun tí Pọ́ọ̀lù ń jíròrò kì í ṣe ọ̀ràn kan tó mú kí Kristẹni kan fúnra rẹ̀ pinnu láti dín wọléwọ̀de rẹ̀ pẹ̀lú ẹnì kan kù nítorí àwọn ìwà tàbí ìgbésẹ̀ onítọ̀hún tí kò dára—fún àpẹẹrẹ, bóyá ẹnì kan ti jẹ́ kí eré ìnàjú tàbí ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́nì gba òun lọ́kàn. Òbí kan sì lè má yọ̀ǹda kí ọmọ rẹ̀ bá àwọn èwe tí òbí wọn kò jọ lójú rìn, àwọn eléré egéle tàbí àwọn eléérepá, tàbí àwọn tí kò náání ẹ̀sìn Kristẹni. Irú àwọn ìpinnu bẹ́ẹ̀ wúlẹ̀ jẹ́ ti ara ẹni, èyí tó wà ní ìbámu pẹ̀lú ohun táa kà nínú Òwe 13:20, tó sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.”—Fi wé 1 Kọ́ríńtì 15:33.

3. Nínú lẹ́tà Pọ́ọ̀lù sí àwọn ará Kọ́ríńtì, ohun tó ní lọ́kàn yàtọ̀ pátápátá sí àwọn táa ti gbé yẹ̀ wò, nítorí ó kọ̀wé nípa ẹnì kan tó ti sọ ìwà burúkú dàṣà, tí kò sì lẹ́mìí ìrònúpìwàdà. Yíyọ ló yẹ kí wọ́n yọ irú ẹlẹ́ṣẹ̀, tí kò lẹ́mìí ìrònúpìwàdà bẹ́ẹ̀ kúrò nínú ìjọ. Ká sọ ọ́ lọ́nà àpèjúwe, ṣe ló yẹ kí wọ́n fa ‘ẹni burúkú’ náà lé Sátánì lọ́wọ́. Lẹ́yìn ìyẹn, àwọn Kristẹni adúróṣinṣin kò ní bá àwọn ẹni burúkú bẹ́ẹ̀ ṣe wọléwọ̀de mọ́; àpọ́sítélì Jòhánù tilẹ̀ rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n má ṣe kí wọn lóhùn ẹnu lásán. (1 Kọ́ríńtì 5:1-13; 2 Jòhánù 9-11) Àmọ́ ṣá o, èyí yàtọ̀ sí ìmọ̀ràn tó wà nínú 2 Tẹsalóníkà 3:14.

Gẹ́gẹ́ bí a ti jíròrò rẹ̀ nínú 2 Tẹsalóníkà, “àwọn tí ń ṣe ségesège,” yàtọ̀ sí ipò mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tí a mẹ́nu kàn lókè yìí. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé ‘arákùnrin’ ṣì ni àwọn wọ̀nyí, ó ní ká máa ṣí wọn létí, kí a sì máa bá wọn lò bẹ́ẹ̀. Nípa báyìí, ìṣòro tí “àwọn tí ń ṣe ségesège” ní kì í ṣe ọ̀ràn ara ẹni tó lè wáyé láàárín àwọn Kristẹni, bẹ́ẹ̀ sì ni kì í ṣe ọ̀ràn tó lágbára, tí àwọn alàgbà ìjọ lè tìtorí ẹ̀ yọni lẹ́gbẹ́, gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ti ṣe nínú ọ̀ràn ti oníṣekúṣe tó wà ní Kọ́ríńtì. “Àwọn tí ń ṣe ségesège” kò jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ ńlá, gẹ́gẹ́ bíi ti ọkùnrin tí wọ́n yọ lẹ́gbẹ́ níjọ Kọ́ríńtì.

Ohun tí “àwọn tí ń ṣe ségesège” ní Tẹsalóníkà jẹ̀bi rẹ̀ ni pé, wọ́n ti ń ṣáko kúrò nínú ẹ̀sìn Kristẹni. Wọn ò ní ṣiṣẹ́, bóyá tìtorí tí wọ́n rò pé Kristi ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé tàbí kó jẹ́ pé ọ̀lẹ afàjò ni wọ́n. Síwájú sí i, wàhálà tí wọ́n ń dá sílẹ̀ kò kéré, nípa ‘yíyọjú sí ohun tí kò kàn wọ́n.’ Àfàìmọ̀ làwọn alàgbà ìjọ kò ti kì wọ́n nílọ̀ léraléra, ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù nínú lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́ sí wọn àti nínú àwọn ìmọ̀ràn àtọ̀runwá mìíràn tí wọ́n ti rí gbà. (Òwe 6:6-11; 10:4, 5; 12:11, 24; 24:30-34) Síbẹ̀, wọn ò jáwọ́ nínú àpọ̀n tí ò yọ̀, wọ́n ṣì ń hù ìwà tó ń kó ẹrẹ̀ yí ìjọ lára, tó sì lè yí àwọn Kristẹni yòókù pàápàá lára. Nítorí náà, Kristẹni alàgbà náà, Pọ́ọ̀lù, láìdárúkọ àwọn onítọ̀hún, pe àfiyèsí àwọn èèyàn sí ìwà ségesège wọn, nípa títú ìwà àìdáa wọn fó.

Ó tún jẹ́ kí ìjọ mọ̀ pé yóò jẹ́ ohun yíyẹ fún wọn gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni kọ̀ọ̀kan láti ‘sàmì’ sí oníwà ségesège náà. Èyí túmọ̀ sí pé olúkúlùkù ní láti kíyè sí àwọn èèyàn tí wọ́n hu ìwà táa ti ki gbogbo ìjọ nílọ̀ nípa rẹ̀. Pọ́ọ̀lù gbà wọ́n nímọ̀ràn pé, kí wọ́n “fà sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ olúkúlùkù arákùnrin tí ń rìn ségesège.” Dájúdájú, ìyẹn kò ní túmọ̀ sí pé kí wọ́n pa ẹni náà tì pátápátá, nítorí wọ́n ní láti máa ‘ṣí i létí gẹ́gẹ́ bí arákùnrin.’ Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, wọ́n á ṣì máa ní ìfarakanra ní ìpàdé, ó sì lè jẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́. Wọ́n á máa retí pé lọ́jọ́ ọjọ́ kan, arákùnrin wọn yóò gbọ́ ìṣílétí tí wọ́n ń fún un, yóò sì pa ìwà jágbajàgba rẹ̀ tì.

Lọ́nà wo ni wọn yóò fi wá “fà sẹ́yìn” kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀? Láìsí àní-àní, èyí yóò jẹ́ ní ti ìfararora ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà. (Fi wé Gálátíà 2:12.) Kíkọ̀ tí wọ́n bá kọ̀ láti ní ìfararora ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà pẹ̀lú rẹ̀, tí wọn kò sì bá a ṣe eré ìnàjú ṣeé ṣe kó jẹ́ kó mọ̀ pé àwọn tí wọ́n ń tẹ̀ lé ìlànà kò fẹ́ràn ọ̀nà tí òun ń tọ̀. Kódà bójú ò bá tì í, kí ó sì torí bẹ́ẹ̀ yí padà, bó ti wù kó rí, àwọn mí-ìn kò ní fẹ́ kọ́ àpẹẹrẹ rẹ̀, kí wọ́n sì dà bí tirẹ̀. Lọ́wọ́ kan náà, olúkúlùkù Kristẹni wọ̀nyí ní láti pọkàn pọ̀ sórí àwọn ohun tó dáa. Pọ́ọ̀lù gbà wọ́n nímọ̀ràn pé: “Ní tiyín, ẹ̀yin ará, ẹ má ṣe juwọ́ sílẹ̀ ní ṣíṣe ohun tí ó tọ́.”—2 Tẹsalóníkà 3:13.

Ó ṣe kedere pé, ìmọ̀ràn àpọ́sítélì yìí kì í ṣe ohun táa wá lè gùn lé láti máa fojú pa àwọn arákùnrin wa rẹ́ tàbí ká máa ṣèdájọ́ wọn nígbà tí wọ́n bá ṣàṣìṣe tí kò tó nǹkan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ète ìmọ̀ràn náà ni láti ran ẹni tó ń hùwà jágbajàgba tó tako ìlànà ẹ̀sìn Kristẹni lọ́wọ́.

Pọ́ọ̀lù kò gbé ìlànà tó kárí gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ kalẹ̀ bí ẹni pé ó fẹ́ gbé ìlànà tó díjú kalẹ̀. Ṣùgbọ́n ó ṣe kedere pé àwọn alàgbà ní láti kọ́kọ́ gbani nímọ̀ràn, kí wọ́n sì gbìyànjú láti ran ẹni tó ń ṣe ségesège náà lọ́wọ́. Bí onítọ̀hún kó bá gbọ́, tó ṣáà ń bá ìwà jágbajàgba rẹ̀ lọ, tó sì ṣeé ṣe kó kéèràn ran àwọn ẹlòmíràn, wọ́n lè dé ìparí èrò pé kí a mú ọ̀ràn náà wá sí àfiyèsí ìjọ. Wọ́n lè ṣètò àsọyé kan tí yóò dá lórí ìdí tí a fi ní láti yẹra fún irú ìwà ségesège bẹ́ẹ̀. Wọn ò ní dárúkọ ẹnikẹ́ni o, ṣùgbọ́n fífi àsọyé náà ṣèkìlọ̀ yóò ṣèrànwọ́ láti dáàbò bo ìjọ nítorí pé àwọn elétíìgbọ́ yóò ṣọ́ra dáadáa láti dín wọléwọ̀de wọn kù ní ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà pẹ̀lú ẹnikẹ́ni tó bá hàn gbangba pé ó ń ṣe ségesège.

Ó ṣeé ṣe kó ṣẹlẹ̀ pé, láìpẹ́ ojú yóò bẹ̀rẹ̀ sí ti ẹni tí ń ṣe ségesège náà, èyí yóò sì sún un láti yí padà. Nígbà tí àwọn alàgbà àti àwọn mìíràn nínú ìjọ bá rí ìyípadà náà, olúkúlùkù wọn lè pinnu láti fòpin sí bí wọ́n ṣe ń sára fún un ní ti ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà.

Ní ṣókí, ohun tí à ń sọ rèé: Àwọn alàgbà ìjọ ni yóò mú ipò iwájú láti pèsè ìrànwọ́ àti ìmọ̀ràn tí ẹnì kan bá ń rìn ségesège. Bí kò bá rí àṣìṣe níbi tí òun forí lé, tí kò dẹ́kun àtijẹ́ ẹni tí ń kó èèràn rán àwọn ẹlòmíràn, àwọn alàgbà lè lo àsọyé tó mú kí ojú ìwòye Bíbélì ṣe kedere láti ki ìjọ nílọ̀—bóyá nípa dídá ọjọ́ àjọròde pẹ̀lú aláìgbàgbọ́, tàbí ohun yòówù tí ìwà tí kò bójú mu náà lè jẹ́. (1 Kọ́ríńtì 7:39; 2 Kọ́ríńtì 6:14) Nípa báyìí, àwọn Kristẹni tí a ti kì nílọ̀ nínú ìjọ lè wá pinnu láti dín wọléwọ̀de wọn kù pẹ̀lú ẹnì kan tó hàn gbangba pé kò tí ì jáwọ́ nínú ìwà ségesège, ṣùgbọ́n tó ṣì jẹ́ arákùnrin.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ọ̀rọ̀ Gíríìkì yìí kan náà la lò fún àwọn sójà tí kò dúró ní ipò táa fi wọ́n sí tàbí tí wọn kò tẹ̀ lé ìlànà iṣẹ́ wọn, àti àwọn ọmọléèwé tó jẹ́ ìsáǹsá, àwọn tí wọ́n máa ń pa iléèwé jẹ.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Àwọn Kristẹni alàgbà ń sì àwọn tí ń rìn ségesège létí, síbẹ̀ wọ́n kà wọ́n sí onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́