Isin Kinni O Fa Àìnífẹ̀ẹ́ Si I?
“ENIYAN kan ti ko ni isin dabi ile ti ko ni fèrèsé.” Bayii ni Ọkunrin ara Japan kan ṣe ṣalaye aini fun ìlàlóye isin fun ọmọkunrin rẹ̀, Mitsuo. Bi o ti wu ki o ri, Mitsuo ko fọwọ pataki mu awọn ọrọ baba rẹ. Iye awọn eniyan ti npọsii ní Japan, bii ti ibomiran, jọ bi ẹnipe wọn nimọlara lọna kannaa. Wọn nitẹlọrun lati jẹ ‘awọn ile ti kò ni ferese’ pẹlu ifẹ diẹ ninu jijẹ ki imọlẹ isin tan sinu igbesi-aye wọn.
Fun idi yii, nigbati Japan ṣe Iwadii Itẹsi Ironu Kari Orilẹ-ede, ipin 69 ninu ọgọrun-un awọn eniyan ilu ni wọn sọ pe wọn ko ka ara wọn si onisin. Láàárín awọn ọdọ, iṣiro ifiwera naa tilẹ ga sii paapaa. Lọna ti o farajọra, ni orilẹ-ede Thailand onisin Buddha ti wọn jẹ ẹlẹmii isin tẹlẹri, ipin 75 ninu ọgọrun-un awọn wọnni ti wọn ngbe ni agbegbe ijọba ilu ni wọn kii lọ si awọn tẹmpili Buddha mọ. Ni England laaarin ọgbọ̀n ọdun ti o kọja sẹhin o fẹrẹẹ to ìdá kan ninu mẹjọ awọn ṣoọsi Anglican ti a ti tì pa nitori a kò lò wọn mọ.
Ṣugbọn, ni Japan, awọn ohun ọ̀ṣọ́ isin ṣi farahan gbangba gan-an sibẹ. Ṣugbọn bii awọn ẹyọ àwo ṣáínà agbowolori, a maa nmu wọn jade kiki ni awọn akoko ayẹyẹ alaiwọpọ—iru bi igbeyawo ati isinku. Isin ni a tubọ kasi iyebiye fun ipa ti o nko ninu pipa iṣẹdalẹ adugbo ati ohun ajogunba idile mọ́ ju fun ilaloye tẹmi. Ọpọlọpọ wo isin ni ṣakala gẹgẹbi oogun itura fun awọn alailera ati awọn ti a dalaamu; wọn kuna lati ri awọn anfaani gidi eyikeyi miiran jèrè lati inu rẹ. ‘Isin dara bi iwọ ba ni aye fun un tabi nimọlara pe o nilo rẹ,’ ni awọn kan sọ, ‘ṣugbọn iwọ nilati gbẹkẹle ara rẹ lati wa ọna àtijẹ ki o si san gbèsè ti o jẹ.’
Kinni o wa lẹhin ẹmi agunla yii? Iye awọn idi melookan ni a le fi funni. Lakọkọ, ayika ẹgbẹ-oun-ọgba wa. Ọpọlọpọ awọn ọdọ́ ti gba idalẹkọọ isin ti ko to nnkan tabi ki wọn má gbà rara. Ko yanilẹnu pupọ pe ọpọlọpọ awọn wọnni ti ngbe ninu awujọ kan ti o gbe ijẹpataki nlanla karí ohun ti ara dagba lati jẹ awọn agbalagba onifẹ ọrọ alumọni.
Ni awọn orilẹ-ede kan iwa láìfí atiniloju ti awọn oniwaasu oniwọra ati oniwapalapala ori Tẹlifiṣọn ati awọn aṣaaju isin ayọri ọla miiran ti yi awọn eniyan pada kuro ninu isin, gẹgẹbi ikowọnu isin ninu awọn àlámọ̀rí oṣelu ati isapa ogun ti ṣe. Eyi ni a ṣakawe nipa ohun ti o ṣelẹ niti isin Shinto ni Japan. “Pẹlu opin ogun [Ogun Agbaye Keji] ni August 1945 ti o yọrisi ipadanu ogun, awọn ojubọ Shinto dojukọ yanpọnyanri mimuna kan,” ni Encyclopædia of the Japanese Religions ṣakiyesi. Shinto ti o fẹna si igbonayaya ogun naa, ti o si ṣeleri ijagunmolu, já awọn eniyan naa kulẹ. Imọ-ọran naa pe ko si Ọlọrun kankan tabi Buddha yara tan kalẹ.
Bi o ti wu ki o ri, awa ha nilati ni itẹlọrun pẹlu awọn oju-iwoye aláìríran jinna, onimọtara-ẹni-nikan—ti isinsinyi gan-an? Ọpọjulọ awọn eniyan ní èrò-inú tí nṣewadii. Wọn yoo fẹ lati mọ ibi tí wọn ti wá, ibi ti wọn nlọ, idi ti wọn fi walaaye, ati bi wọn yoo ṣe maa gbe. Wọn a maa jàyọ̀yọ̀ ninu ireti. Titi awọn ibeere nipa iwalaaye sẹgbẹkan, tabi titẹ wọn rì pẹlu ero naa pe “awọn nkan wọnyi ni a ko le mọ,” ni ko tẹ́ wọn lọrun. Ani aláìgbọlọ́rungbọ́ naa Bertrand Russell paapaa sọ nipa nini “irora aláìṣeépamọ́ra ti ẹmi itọpinpin—iwakiri fun ohun kan ti o rekọja ohun ti o wa ninu ayé.” Isin tootọ le fopin si iwakiri yẹn. Ṣugbọn bawo? Ẹri wo ni o wa nibẹ pe isin eyikeyi yẹ ni fifọwọ pataki mú un bẹẹ?