ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 2/1 ojú ìwé 4-7
  • Eeṣe Ti A Fi Nilati Fọwọ́ Pataki Mu Isin?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Eeṣe Ti A Fi Nilati Fọwọ́ Pataki Mu Isin?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Isin Kan Ti A Nilati Fọwọ Pataki Mú
  • “Awon eso” Isin Tootọ
  • Awọn Èrè Ayeraye Lati Inu Ṣiṣe Isin Tootọ
  • Ìwọ Ha Ti Rí Ìsì Tí Ó Tọ̀nà Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Isin Eyikeyii Ha Dara Tó Bi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Báwo Ni Mo Ṣe Lè Mọ Ìsìn Tòótọ́?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ṣíṣe Isin Mimọgaara fun Lilaaja
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 2/1 ojú ìwé 4-7

Eeṣe Ti A Fi Nilati Fọwọ́ Pataki Mu Isin?

“ENIYAN ko le walaaye nipa akara nikan.” (Matiu 4:4, The New English Bible) Awọn ọrọ wọnyi ti a saba maa nfayọ kàn aini ẹda eniyan ti ọpọlọpọ gbojufoda lonii. Wọn fihan pe awa ní apá tẹmi ninu akopọ ẹ̀dá wa ti a nilati tẹlọrun. Idi niyii ti ẹni naa ti nsọ awọn ọrọ wọnyi, Jesu Kristi fi tun wipe: “Wo bi a ti bukun awọn wọnni ti wọn mọ aini wọn fun Ọlọrun to.”—Matiu 5:3, NEB.

Isin nikan ni o le kaju ‘aini wa fun Ọlọrun.’ Isin nikan ni o le dahun awọn ibeere wa ṣiṣekoko nipa ipilẹṣẹ, ete, ati itumọ igbesi-aye. Isin nikan ni o si le fun igbesi-aye wa ni itumọ ati ijẹpataki tootọ. Ṣugbọn kii wulẹ ṣe isin eyikeyi ni yoo ṣe gbogbo eyi. Jesu wi fun obinrin ara Samaria kan pe: “Awọn olusin tootọ yoo maa sin Baba ni ẹmi ati ni otitọ.” (Johanu 4:23) Jijọsin ‘ni otitọ’ nitumọ ju titẹle awọn ẹkọ atọwọdọwọ ati awọn aato isin onigba pipẹ. Niye igba iwọnyi maa nfun awọn ọmọlẹhin ni imọlara ire alaafia onigba diẹ nigba ti o fi wọn silẹ ninu ebi nipa tẹmi.

Fun apẹrẹ, Edwin O. Reischauer, ikọ U.S. si Japan, ṣalaye pe: “Fun ọpọlọpọ eniyan isin Shinto ati Buddha ti jẹ ọran aṣa ati iṣe ti gbogbogboo tẹwọgba ju awọn igbagbọ ti o kun fun itumọ.” Ki a gba pe, o tẹ́ ọpọlọpọ awọn eniyan Japan lọrun lati ní in ni ọna yii. Ṣugbọn awujọ “awọn isin titun” ní Japan nfi ainitẹlọrun ti npọ sii hàn sí isin atọwọdọwọ.

“Awọn isin titun” tẹsi kiko afiyesi jọ sori awọn aṣaaju alagbara ifanimọra—kii ṣe Ọlọrun. Ọpọ ninu awọn aṣaaju isin wọnyi fi idaniloju sọ pe awọn ní imisi atọrunwa. Ṣugbọn awọn ẹkọ-igbagbọ wọn ni gbogbogboo ko yatọ si àkólùpọ̀ awọn igbagbọ isin Buddha, Shinto, ati awọn igbagbọ miiran—pẹlu iwọn titobi ti imọ-ọran oludasilẹ naa ti a gbe sọ sinu rẹ. Niye igba ohun ti wọn fi nfanimọra sinmi lori ileri igbesi-aye didaraju ati awọn agbara iwosan tabi awo ti wọn sọ pẹlu idaniloju pe awọn ní. Ṣugbọn njẹ iru awọn isin bẹẹ funni ni ẹ̀rí pe wọn nkọ awọn ọmọlẹhin wọn lati jọsin “ni ẹmi ati ni otitọ” bí? Ó tì o. Idi kan niyii, awọn ẹgbẹ awo onisin nitẹsi lati wà lonii ki wọn má sì sí lọla. Iṣesi wọn bi aṣa-igbalode ko funni ni idi kankan lati fọwọ pataki mú wọn.

Isin Kan Ti A Nilati Fọwọ Pataki Mú

Bi o ti wu ki o ri, isin kan nbẹ ti o ti wa tipẹ ju oriṣi isin eyikeyi miiran lọ. O jẹ isin ti a fi kọ́ni ninu Bibeli Mimọ. A bẹrẹsii kọ Bibeli ni nnkan bii 35 ọrúndún sẹhin, ‘awọn ọrọ-itan’ ti a pamọ sinu awọn ori rẹ ibẹrẹ fi ohun ti o ju ẹgbẹrun ọdun pẹ sẹhin ju iyẹn.a O ni akọsilẹ ti o pẹ julọ lori ipilẹṣẹ isin. Iyẹn nikan jẹ idi lati fun isin Bibeli ni igbeyẹwo pataki.

The Encyclopedia Americana sọ nipa Bibeli pe: “Imọlẹ rẹ̀ ‘ti tàn lọ sinu gbogbo aye.’ A fojuwo o nisinsinyi gẹgẹbi iṣura ilana iwahihu ati ti isin eyi ti ẹkọ rẹ ti ko lopin ṣeleri lati jẹ oniyebiye sii paapaa gẹgẹbi ireti ayé ọ̀làjú tí npọsii.” Ṣugbọn bi iwe kan ba jẹ amọna ti o ṣeegbagbọ fun isin tootọ niti gidi, iwọ ki yoo ha reti pe ki a pin in kiri lọna gbigbooro julọ, ki o wà larọọwọto fun gbogbo awọn olù wá otitọ?

Bayii ni ọran ri pẹlu Bibeli. A ti tumọ rẹ lodidi tabi lapakan si ede 1,928, o si jẹ iwe ti ìpínkiri rẹ tankalẹ julọ ninu itan. Siwaju sii, o ti fi ẹ̀rí han pe ó yekooro niti ọrọ itan ati imọ ijinlẹ. Iwalẹpitan ati itan jẹrii si imuṣẹ pipeye awọn asọtẹlẹ Bibeli. O wa lominira kuro lọwọ gbogbo iru biba ẹmi lò ati ohun ijinlẹ awo. Gbogbo eyi ṣedeedee pẹlu ifidaniloju sọ Bibeli pe o ni imisi atọrunwa.b—2 Timoti 3:16.

“Awon eso” Isin Tootọ

Ṣugbọn kii ha ṣe ootọ pe ọpọlọpọ isin fi idaniloju sọ pe wọn ntẹle Bibeli? Rogbodiyan, iṣọta, ati agabagebe ko ha si farahan gbangba laaarin awọn ti wọn fi idaniloju pe araawọn ni Kristian? Bẹẹni, ṣugbọn eyi kii ṣe idi lati ṣaika Bibeli si. Jesu Kristi funraarẹ fihan pe pupọ awọn wọnni ti wọn nfẹnu lasan jẹwọ isin Kristian ni wọn ki yoo ri itẹwọgba Ọlọrun. (Wo Matiu 7:13, 14, 21-23.) Nigba naa, bawo ni ẹnikan ṣe le da awọn wọnni ti wọn nṣe isin tootọ ti a fi kọ́ni ninu Bibeli mọ? Jesu dahun: “Eso wọn ni ẹyin yoo fi mọ wọn. Eniyan a maa ka eso ajara lori ẹ̀gún ọ̀gàn, tabi eso ọpọtọ lara ẹwọn? Gẹgẹ bẹẹ gbogbo igi rere ni iso eso rere; ṣugbọn igi buburu ni iso eso buburu. Nitori naa nipa eso wọn ni ẹyin yoo fi mọ wọn.”—Matiu 7:16, 17, 20.

Bẹẹni, isin tootọ nilati jẹ ipá alagbara fun rere, ti npese awọn iyọrisi alanfaani laaarin awọn olujọsin. Fun apẹẹrẹ, gbé Akinori yẹwo, ọkunrin ara Japan kan ẹniti, gẹgẹ bi oun funraarẹ ṣe sọ ọ “di ògidì apẹẹrẹ ẹmi ibanidije.” Oun fi iyọrisirere le awọn gongo ti kikẹkọọgboye jade ní ile-ẹkọ yunifasiti kan ti o gbapo iwaju ati riri iṣẹ ni ile-iṣẹ onípò-iyì kan. Oun ko ri idi lati mu isin wọnu igbesi-aye rẹ̀. Oun ronu pe, ‘Isin wa fun awọn alailera ti wọn nilo ọ̀pá-ìkẹ́sẹ̀ ninu igbesi-aye.’

Ohun gbogbo nlọ ní geere titi oun fi di alaisan pẹlu arun buburu kan gẹgẹbi iyọrisi másùnmáwo ati àárẹ̀. Ọrun rẹ di lílọ́ kọrọdọ, àgbọ̀n rẹ̀ si “gan” si ejika rẹ òsì. Ọpọlọpọ “awọn ọrẹ” ni ile-iṣẹ Akinori jasi alailefunni ni itunu lakoko idaamu rẹ̀. (Fiwe Owe 17:17.) Nitori naa oun jin sinu iṣoro imukumu ọti lile o tilẹ gbiyanju lati pa ara rẹ.

Ṣugbọn, bi akoko ti nlọ, aya Akinori bẹrẹsii kẹkọọ Bibeli pẹlu awọn Ẹlẹrii Jehofa. Ni ọjọ kan bi ijumọsọrọpọ ti nlọ lọwọ, o sọ fun nipa ẹsẹ iwe mimọ ti o wa ni Galatia 6:7, eyi ti o ka pe: “Ohunkohun ti eniyan ba furungbin, ohun ni yoo ka.” Bi a ti mú un takiji nipa awọn ọrọ wọnyi, Akinori darapọ mọ́ ọn ninu ikẹkọọ naa, ohun ti o si kẹkọọ rẹ̀ yi oju-iwoye rẹ pada niti itumọ igbesi-aye. Gẹgẹbi oju-iwoye Akinori ti nmọlẹ sii, ijẹrora rẹ tí másùnmáwo fà bẹrẹ sii dàwátì! Gẹgẹbi Owe Bibeli kan ti sọ ọ: “Àyà ti o yekooro ni ìyè ara.” (Owe 14:30) Bẹẹni, isin tootọ nmu awọn eso rere jade!

Toshiro jẹ ọkunrin ara Japan miiran ti o wa ri bi isin tootọ ti le jẹ ipá fun rere. Bi o tilẹ jẹ pe oun gbagbọ pe ṣiṣe isin niyelori, oun ko ṣe ohunkohun nipa rẹ̀. Ifẹ rẹ ko afiyesi jọ sori nini ile ti oun funraarẹ. Bi o ti wu ki o ri, lílé gongo yẹn ba ko mu itẹlọrun ti oun fojusọna fun wa. Siwaju sii, gẹgẹbi oun ti wo yika ibi iṣẹ rẹ, oun kiyesi pe awọn iṣe alaboosi jẹ ohun ti o wọpọ ati pe ipo-ibatan buburu laaarin ara ẹni ni o nti ibẹ jade. Toshiro kónírìíra ohun ti o ri.

Ni ọjọ kan aya rẹ kesi alagba kan lati inu ijọ adugbo ti awọn Ẹlẹri Jehofa lati bẹ̀ ẹ́ wò. Kia Toshiro roye pe alagba naa yatọ si awọn alajọṣiṣẹ oun. Idi rẹ? Alagba naa fi awọn ilana Bibeli silo pẹlu otitọ inu ninu igbesi-aye rẹ̀. Bi a ti ṣí i lori nipa eyi, Toshiro tẹwọgba ikesini lati kẹkọọ Bibeli o sii bẹrẹ si fi isin Bibeli ṣe ọna igbesi-aye rẹ̀.

A kesi ọ pẹlu lati di ojulumọ pẹlu awọn Ẹlẹri Jehofa. “Awọn eso” wọn funni ni ẹri pe wọn njọsìn “ni ẹmi ati ni otitọ.” Wọn nṣaapọn lati fi awọn ẹkọ Bibeli si ilo ninu igbesi aye wọn. Nigbati wọn si jẹ alaipe gẹgẹbi ẹnikọọkan, gẹgẹbi awujọ kan wọn ṣapẹẹrẹ bi isin tootọ ti le jẹ ipa tẹmi alagbara fun rere to.

Ẹgbẹẹgbẹrun laaarin Ẹlẹrii naa ti jẹ alailayọ ni igba kan ri pẹlu ọna igbesi-aye wọn. Ṣugbọn nipa fifi awọn ilana Bibeli silo, ọpọlọpọ ninu wọn ti le ṣe awọn iyipada awunilori. Nipa mimu ohun ti Bibeli pe ni “eso ti ẹmi” dagba, tii iṣe awọn animọ ti ifẹ, ayọ, alaafia, ipamọra, iwa pẹlẹ, iṣoore, igbagbọ, iwa tutu, ati ikora-ẹni-nijanu, wọn ti ri kọkọrọ si ayọ ti ara ẹni.—Galatia 5:22, 23.

Awọn Èrè Ayeraye Lati Inu Ṣiṣe Isin Tootọ

Bi o ti wu ki o ri, isin tootọ, gbọdọ ṣe ju yiyi awọn akopọ animọ pada tabi mimu awọn iṣoro ara ẹni fuyẹ. Awọn iṣoro yika aye iru bi isọdeeri, ihalẹmọni ogun atọmik, ati ilokulo ayika nhalẹ ewu pipa planẹti wa meremere run. Awọn iṣoro ìṣúnná-owó ńdí ayọ ati ire aasiki araadọta ọkẹ lọwọ. Ko si isin ti a le fọwọ pataki mu ayafi bi o ba pese awọn ireti kan fun yiyanju awọn iṣoro yika aye wọnyi.

Isin ti Bibeli pese iru ireti bẹẹ. Ọlọrun ṣeleri lati mu aye titun ododo kan wọle labẹ iṣakoso, tabi “ijọba” ti ọrun. (Matiu 6:9, 10; 2 Peteru 3:13; Iṣipaya 21:3, 4) Ijọba yii ni ojutuu fun gbogbo awọn iṣoro araye. Ati niti ìwàpẹ́títí iru awọn èrè kari aye bẹẹ Bibeli mú un da wa loju pe: “Aye . . . nkọja lọ, ati ifẹkufẹ rẹ̀: ṣugbọn ẹni ti o ba nṣe ifẹ Ọlọrun ni yoo duro laelae.” Bẹẹni, iye ainipẹkun ninu ayọ ni ireti olukuluku Kristian tootọ! (1 Johanu 2:17) Ṣugbọn kiki awọn wọnni ti wọn fọwọ pataki mu ṣiṣe isin tootọ ni yoo jere lati inu ijọba ti nbọ yii. Awa nigbanaa rọ̀ ọ́ lati bẹrẹ ikẹkọọ aláìdápàárá ninu Bibeli.c (Johanu 17:3) Gẹgẹbi o ti bẹrẹ sii jẹki imọlẹ ọrọ Ọlọrun tan sinu igbesi-aye rẹ, iwọ yoo niriiri ayọ nla gẹgẹbi a ti ńkún ‘aini rẹ fun Ọlọrun’ ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀. Nitootọ, ibukun ayeraye yoo jẹ tirẹ nitoripe iwọ fọwọ pataki mu isin—isin tootọ.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fun apẹẹrẹ, wo Jẹnẹsisi 2:4; 5:1; 6:9.

b Fun isọfunni siwaju sii, wo iwe naa The Bible—God’s Word or Man’s?, ti a le ri gba lati ọwọ awọn ontẹwe iwe-irohin yii.

c Awọn Ẹlẹrii Jehofa yoo layọ lati ràn ọ lọwọ ni ọna yi. Ikẹkọọ Bibeli inu ile lọfẹẹ ni a le ṣeto nipa kikan yala awọn onṣewe iwe-irohin yii tabi ijọ adugbo awọn Ẹlẹrii Jehofa ni adugbo rẹ lara.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Wiwa larọọwọto Bibeli ni nnkan ti o ju ede 1,900 lọ wa ni iṣọkan pẹlu fifi ti o fihan pe oun ní imisi latọrunwa

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Isin Bibeli nawọ ireti awọn ipo alaafia kari aye labẹ akoso ti ọrun

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́