Awọn Olùpòkìkí Ijọba Rohin
Obinrin kan Ti O Jẹ Ajẹjẹ Anikandagbe Fun 25 Ọdun Kẹkọọ Otitọ Nikẹhin
BIBELI sọtẹlẹ pe “ogunlọgọ nla” lati inu gbogbo awọn orilẹ-ede yoo wa jọsin ni tẹmpili tẹmi ti Jehofa. (Iṣipaya 7:9, NW) Eyi nṣẹlẹ lonii, awa si layọ lati rii pe ọpọlọpọ, pẹlu iranlọwọ otitọ Ọlọrun, ntipa bayii já awọn ẹ̀wọ̀n isin eke. Awọn iriri ti o tẹle e yii ṣapejuwe eyi.
◻ Obinrin kan ni Romu, Italy, rohin pe: “Lati igba ti mo ti wa ni kekere ohun ti mo nagasi julọ ni lati di ajẹjẹẹ anikandagbe kan, niwọnbi mo ti nifẹẹ gbigbonajanjan lati ṣiṣẹsin Ọlọrun pẹlu gbogbo ọkan-aya mi. O ṣeeṣe fun mi lati mu ilepa mi ṣẹ ni ẹni ọdun mejilelọgbọn, ni December 8, 1960, nigba ti mo jẹ́ ẹ̀jẹ̀ mi akọkọ lati jẹ onigbọran, òtòṣì, ati oniwamimọ. Iṣẹ ti a yan fun mi ni lati tọju ni tọ̀sántòru ọgbọ̀n awọn otoṣi ọmọ ti a sì pati ti wọn jẹ alailobii tabi awọn ọmọ ẹlẹwọn. Mo ni itẹlọrun ninu iṣẹ mi.
“Igbagbọ mi mì lẹhin ọdun mẹwaa ti mo ti nṣe iṣẹ-isin nigba ti asọ̀ dide laaarin eto-idasilẹ naa. Mo ṣe kayefi pe, bi Ọlọrun ba ndari wa, eeṣe ti oun yoo fi yọnda iru awọn asọ̀ ati rudurudu bẹẹ ninu ile oun funraarẹ.”
Ajẹjẹẹ anikandagbe naa ní arabinrin kan ti o ngbe ni France ti o si jẹ ọkan lara awọn Ẹlẹrii Jehofa. Oun jẹrii fun ajẹjẹẹ anikandagbe naa nipasẹ lẹta o si fi New World Translation of the Holy Scriptures ranṣẹ si i. Ajẹjẹẹ anikandagbe naa rohin pe: “Lẹhin ọdun mẹtalelogun, iyẹn jẹ ibapade mi akọkọ pẹlu Ọ̀rọ̀ Ọlọrun.” Ẹhin igba naa ni o tẹwọgba ikẹkọọ Bibeli pẹlu awọn Ẹlẹrii Jehofa, o wipe: “Bi mo ti ntẹsiwaju pẹlu ikẹkọọ Bibeli, mo kẹkọọ lati mọ Jehofa Ọlọrun ati awọn ohun ti o beere fun ati awọn animọ agbayanu rẹ̀ pẹlu. Ọkan mi bajẹ nigba ti mo kẹkọọ pe oun kò tẹwọgba lilo awọn ère, niwọnbi eto idasilẹ naa ti kun fun awọn ère oniruuru ati ni oriṣiriṣi iwọn itobi. Mo loye pe bi mo ba fẹ lati wu Jehofa, emi ko le wa titilọ ninu ibẹ yẹn. Lẹhin 25 ọdun ti iṣẹ-isin afitọkantọkan ṣe gẹgẹ bi ajẹjẹẹ anikandagbe kan mo ri otitọ nikẹhin. Nitori naa ni October 1, 1985, mo fi iwe lilọ mi silẹ, si ijakulẹ ojiji awọn aṣaaju mi.
“Awọn arakunrin ati arabinrin mi onifẹẹ ran mi lọwọ nipa tẹmi ati nipa ti ara. Pẹlu ọpẹ si Jehofa ati eto-ajọ rẹ, mo gba iribọmi ni August 30, 1986, mo si fi ẹsẹ mi le oju-ọna si iye ainipẹkun.”
Jehofa Bukun Ifẹ Ọkan Ọdọlangba kan lati Ṣiṣẹsin Ọlọrun
◻ Olukọ kan ní ile-ẹkọ ní Brazil ti o jẹ ọkan lara awọn Ẹlẹrii Jehofa kiyesi nigba ti o nṣe atunṣe awọn iwe ti akẹkọọ kan ẹni ọdun mẹrinla kọ nipa ifẹ-ọkan rẹ lati mọ sii nipa Ọlọrun. O bẹrẹ ikẹkọọ Bibeli pẹlu akẹkọọ naa, ṣugbọn bi ọdọmọbinrin naa ti ntẹsiwaju, idile Katolik rẹ ka ikọnilẹkọọ naa leewọ wọn sì fa iwe ikẹkọọ rẹ ya. Ọdọ akẹkọọ naa bẹrẹsii kẹkọọ Bibeli laaarin akoko isinmi ile ẹkọ, ṣugbọn o hàn sita. Laipẹ nitori naa ikẹkọọ naa ni a nṣe niṣo nipasẹ ifiweranṣẹ. Ṣugbọn, laipẹ, idile naa ri awọn lẹta rẹ wọn sì jó wọn. Baba rẹ̀ bẹrẹ sii fipa mu un lati lọ si Mass. Oun tẹle e lọ ṣugbọn o mu ẹda Ilé-ìṣọ́nà kan lọwọ lati kà laaarin akoko isin, ni fifipamọ saaarin awọn oju-ewe iwe pẹlẹbẹ ṣọọṣi. Eyi nbaalọ fun oṣu mẹfa, titi di ọjọ kan ti oun yọ́ kẹ́lẹ́ jade kuro ninu ile lati lọ si Gbọngan Ijọba. Laaarin akoko ipade naa baba rẹ̀ farahan ni ẹnu ọna o si sọ fun awọn ara lati sọ fun ọmọbinrin rẹ pe oun yoo nà án nigba ti o ba de ile. Isapa lati ọdọ awọn arakunrin lati fi ọgbọ́n fọrọ we ọrọ jasi asan.
Ni ọjọ keji, pẹlu ayọ ati ẹrin musẹ, ọmọbinrin naa lọ ri awọn arakunrin. O fi ọpọlọpọ egbò ni araarẹ̀ han wọn nibi ti baba rẹ̀ ti nà án. Eeṣe, nigba naa, ti oun fi layọ? Lẹhin fifi Gbọngan Ijọba naa silẹ, baba rẹ̀ ti bi awọn eniyan melookan ninu ilu ni ibeere, titikan olori-ilu naa, nipa awọn anfaani ati ipalara ti o wà ninu ki ọmọbinrin rẹ jẹ ọkan lara awọn Ẹlẹrii Jehofa. Olori ilu naa wipe awọn Ẹlẹrii jẹ eniyan rere, ti wọn yẹ fun igbọkanle. Oun fikun un pe wọn tayọ ninu iwarere ati pe yoo dara gan-an lati ni ọmọ ti o ni awọn ọpa-idiwọn wọnyi, eyi ti o ga gan-an ju iwọnni ti wọn jẹ́ ti awọn ọ̀dọ́ ni gbogbogboo.
Laika eyi si, ọdọmọbinrin naa ni a nà. Ṣugbọn baba naa sọ fun un pe oun na an nitori pe o jade ninu ile laigba àṣẹ. O sì tun sọ fun un pe oun yoo na an lẹẹkan sii bi o ba dawọ kikẹkọọ Bibeli tabi lilọ si awọn ipade Ẹlẹrii Jehofa duro lae! Ọmọbinrin naa jẹ akede onitara kan nisinsinyi, diẹ lara awọn idile rẹ si nfi ifẹ han si otitọ.
Nitootọ, Jehofa bukun awọn ọ̀dọ́ ti wọn ni ifẹ-ọkan olotiitọ inu lati ṣiṣẹsin in gẹgẹ bi iriri yii ti fihan.—Saamu 148:12, 13.