ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 5/1 ojú ìwé 30
  • Otitọ Bibeli Sọ Obinrin Ajẹ́jẹ̀ẹ́ Anìkàndágbé Dominira ni Bolivia

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Otitọ Bibeli Sọ Obinrin Ajẹ́jẹ̀ẹ́ Anìkàndágbé Dominira ni Bolivia
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Àwọn Òbí Kọ̀ Mí Sílẹ̀—Ṣùgbọ́n Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Mi
    Jí!—2001
  • Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Ń Waasu Lọna Àìjẹ́-bí-àṣà Pẹlu Abajade Didara
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Bí A Ṣe Pa Òùngbẹ Tẹ̀mí Tó Ń Gbẹ Mí
    Jí!—2003
  • Obinrin kan Ti O Jẹ Ajẹjẹ Anikandagbe Fun 25 Ọdun Kẹkọọ Otitọ Nikẹhin
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 5/1 ojú ìwé 30

Awọn Olupokiki Ijọba Rohin

Otitọ Bibeli Sọ Obinrin Ajẹ́jẹ̀ẹ́ Anìkàndágbé Dominira ni Bolivia

ỌPỌLỌPỌ awọn eniyan alailabosi ọkan ń sá kuro ninu ijọsin èké, wọn ń kẹkọọ otitọ Bibeli, wọn sì ń wá lati jọsin Jehofa, Ọlọrun tootọ naa. Iye ti ó ju 7,600 ti ṣe bẹẹ ni Bolivia, papọ pẹlu obinrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé kan.

Nigba ti o jẹ́ kìkì ọmọ ọdun mẹsan-an, M—— ṣalábàápàdé Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fun ìgbà akọkọ. Ó dahun ìpè ẹnu ọ̀nà nigba ti Ẹlẹ́rìí ṣebẹwo si ile rẹ̀, ati fun ìgbà akọkọ, ó gbọ ti a pe orukọ Ọlọrun, Jehofa. Ó fi sọkan fun ọpọ ọdun.

Niwọn bi ó ti jẹ́ pe oun nikan ni ọmọdebinrin ti ó wà ninu idile naa, a pinnu rẹ̀ pe ki o di obinrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé kan. “Ẹ wo bi mo ti layọ tó pe emi yoo wà ninu iṣẹ-isin Ọlọrun—ó keretan, ohun ti mo rò niyẹn,” ni M—— sọ. Ṣugbọn ayọ rẹ̀ yipada di ijanikulẹ nigba ti o ri aiṣedajọ ododo ati ojuṣaaju ti a ń ṣe ninu ile awọn obinrin ajẹjẹ̀ẹ́ anìkàndágbé. Ó sọ pe: “Boya emi kò ni gbagbe awọn ikọluni ikarisọ wọnni ati awọn ìluni nipa ti ara ati nipa ti ẹmi ti ń kanni lárá gógó gbáà, ti ń mú kí n wo Ọlọrun, kì í ṣe gẹgẹ bii Ọ̀kan ti ó jẹ́ ti ifẹ, bikoṣe gẹgẹ bi Ọ̀kan ti ń fiya jẹni laisi ìyọ́nú.”

Ó ń ba a lọ pe: “Ni akoko ti mo di obinrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé, emi kò tii ṣaṣeyọri ninu riri orukọ Jehofa ninu Bibeli. Mo rí kìkì ‘Yahweh,’ iyẹn sì dáyàfò mi. Ni ọjọ kan mo jade lọ lati lọ wá awọn eniyan wọnni ti wọn sọrọ nipa Jehofa, ṣugbọn emi kò ri wọn.

“Akoko kọja, ati ni ọjọ kan nigba ti mo ń lọ si agbo ile wa, mo ri àmì kan, ‘Gbọngan Ijọba Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa.’ Mo fẹ́ lati sọ fun wọn pe wolii èké ni wọn, ṣugbọn kò sí ẹnikẹni ninu gbọngan naa. Mo pada ni ọjọ Sunday. Ipade kan ń lọ lọwọ, ọpọlọpọ ni ẹnu sì yà lati ri obinrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé ti ó wà ninu aṣọ àwọ̀kanlẹ̀ ti o wá sibẹ. Lẹhin ipade, mo gbiyanju lati yára jade. Sibẹ, ọ̀kan lara Awọn Ẹlẹ́rìí naa kí mi, nitori naa mo beere lọwọ rẹ̀ pe, ‘Eeṣe ti ẹ fi tabuku sí Ẹni Mimọ nipa jíjẹ́ orukọ yẹn?’ Ibeere mi ṣamọna si ijiroro Bibeli, mo sì ṣe awọn ètò fun un lati ṣebẹwo sọdọ mi ni ile idile wa. Awọn obi mi lé e jade. Bi o ti wu ki o ri, a pade lẹẹkan sii, ni oṣu meji lẹhin naa, ó sì ké sí mi si ile rẹ̀ fun ikẹkọọ Bibeli kan. Isọfunni ti o fihan mi mú ori mi wú, ni fifihan pe awọn Kristẹni gbọdọ lo orukọ Ọlọrun. Ẹ̀rí yẹn fun mi ni okun ti mo nilo lati kọ gbogbo awọn nǹkan ti kò wulo ti a ti fi kọ́ mi gẹgẹ bi obinrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé kan.

“Mo ranti ọpọlọpọ nǹkan nipa igbesi-aye mi ninu ile ti awọn obinrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé ń gbé. Fun apẹẹrẹ, lẹẹkan rí mo nilo ounjẹ pupọ sii lati jẹ. Nitori naa mo kọwe mo sì sọ fun awọn obi mi lati fi diẹ ranṣẹ si mi, laimọ pe awọn lẹta yẹn ni a tú wò ninu ile awọn obinrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé naa. Ni akoko ounjẹ ti o tẹle e, ọpọ rẹpẹtẹ burẹdi ati ohun ti a fi ń jẹ burẹdi ni a gbeka iwaju mi, a sì fi ipá mú mi lati jẹ gbogbo rẹ̀ tán. Nisinsinyi mo jẹ ounjẹ ti ó pọ̀ jù. Mo sọ eyi fun awọn ọ̀rẹ́ mi, ọ̀kan sì damọran pe ki n rún burẹdi ti emi kò lè jẹ ki n sì fọ́n ọn dà silẹ. Nigba ti mo ṣe iyẹn, obinrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé kan yára gbá mi mú ó sì tì mi lulẹ, pẹlu aṣẹ gbígbójú naa pe mo gbọdọ pọ́n gbogbo ilẹ naa lá mọ tonitoni pẹlu ahọ́n mi. Iyàrá naa tobi. Nigba ti mo ń ṣegbọran si aṣẹ naa, mo gbọ ọpọlọpọ ẹ̀rín kèékèé—kò si aanu ti a fi hàn bi o ti wu ki ó mọ.

“Mo lè ri nisinsinyi bi o ti jẹ́ agbayanu tó lati di ominira kuro ninu gbogbo iyẹn. Gẹgẹ bi a ti lè reti, isọdominira yii wémọ́ awọn irubọ. Fun ohun kan, baba mi lé mi sode kuro ninu ile. Sibẹ, ṣaaju ki n tó fi ile awọn obinrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé silẹ, mo ni anfaani riran awọn ọdọ obinrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé miiran lọwọ lati kẹkọọ otitọ. Mo layọ lati sọ pe diẹ ninu wa ti ya igbesi-aye wa si mimọ fun Jehofa Ọlọrun!

“Lẹhin ti mo fi ile awọn obinrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé silẹ, ó ṣoro fun baba mi lati loye idi ti mo fi kọ awọn iṣẹ ti ń mowo wọle daradara ṣugbọn ti o n jẹ akoko silẹ. Bi o ti wu ki o ri, mo fẹ akoko pupọ sii fun iṣẹ-isin Ọlọrun. Mo ń ṣiṣẹsin nisinsinyi gẹgẹ bi aṣaaju-ọna deedee, pẹlu igbesi-aye ti kò lọ́júpọ̀ ati sibẹ ti ń tẹnilọrun gidigidi. Ati si ayọ ńlá mi, ìyá mi ati awọn arakunrin mi ti darapọ mọ mi ninu iṣẹ-isin Jehofa.”

Lootọ, otitọ Bibeli ń sọ ẹnikan dominira kuro ninu eto igbekalẹ isin èké ayé yii, ó sì ń mú ayọ ati idunnu pipẹtiti wá.—Johanu 8:32.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́