Awọn Olupokiki Ijọba Rohin
Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa Ń Waasu Lọna Àìjẹ́-bí-àṣà Pẹlu Abajade Didara
ỌPỌLỌPỌ ni a kọkọ mu mọ otitọ Bibeli nigba ti ọ̀kan lara awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa waasu fun wọn lọna àìjẹ́-bí-àṣà. Ninu eyi awọn Ẹlẹ́rìí tẹle apẹẹrẹ Jesu Kristi, ẹni ti ó waasu lọna àìjẹ́-bí-àṣà fun obinrin ara Samaria kan leti kanga nigba ti ó wá fa omi. (Johanu, ori 4) Ni Ila-oorun Africa, ọ̀kan lara awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa waasu lọna àìjẹ́-bí-àṣà fun obinrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé Katoliki kan. Ẹka ọfiisi Watch Tower Society rohin ohun ti ó yọrisi:
◻ Ni kutukutu owurọ kan nigba ti ó ń lọ saaarin ilu, Ẹlẹ́rìí naa pade obinrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé Katoliki kan. Ó lo anfaani naa lati beere lọwọ ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé naa pe: “Nibo ni iwọ ń lọ niwoyii?” Idahun naa ni pe: “Mo ń lọ gbadura si Ọlọrun mi.” Ó beere lọwọ obinrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé naa lẹhin naa pe: “Iwọ ha mọ orukọ Ọlọrun rẹ bi?” Orukọ rẹ̀ kii ha ṣe Ọlọrun ni bi?” Obinrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé naa fesi pada. Ẹlẹ́rìí naa sọ imuratan rẹ̀ lati wá si ile rẹ̀ ni ọsan yẹn lati jiroro orukọ Ọlọrun. Lẹhin ijumọsọrọpọ naa obinrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé naa lọ si ṣọọṣi rẹ̀ ó sì beere lọwọ ọ̀kan lara awọn alufaa bi ó ba mọ ohun ti “Jehofa” duro fun. Idahun naa ni pe, “Orukọ Ọlọrun ni.” Obinrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé naa ni ẹnu yà gidigidi lati gbọ pe alufaa mọ eyi ṣugbọn kò tii fi kọ́ ọ.
Ẹlẹ́rìí naa bẹ obinrin naa wò fun awọn ọjọ mẹsan-an leralera ó sì kọ́ ọ ni otitọ nipa Mẹtalọkan, ọkàn, ina hell, ati ireti fun awọn oku. Obinrin naa gba gbogbo rẹ̀ sọ́kàn ó sì sọ fun Ẹlẹ́rìí naa lati fun un ni akoko diẹ lati ronu lori gbogbo awọn ẹkọ titun wọnyi. Lẹhin ọsẹ meji ó kan Ẹlẹ́rìí naa lara lẹẹkansii ó sì beere fun ijumọsọrọpọ siwaju sii. Lakooko yii obinrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé naa ti pinnu lọkan rẹ̀ lati fi ṣọọṣi naa silẹ o sì ti pa awọn ere, awọn ilẹkẹ adura ati agbelebuu rẹ̀ run ṣaaju akoko yii. Alufaa naa gbiyanju lati yi i leropada lati pada, ṣugbọn ó pinnu lati lepa otitọ. A bamtisi rẹ̀ lẹhin naa ó sì ti ṣiṣẹsin gẹgẹ bi aṣaaju-ọna oluranlọwọ deedee fun ọpọlọpọ oṣu laika ilera rẹ̀ ti kò dara tó ati ọjọ ogbó sí.
Niwọn bi ile rẹ ti tobi, ó fi ilo rẹ̀ fun ijọ gẹgẹ bi Gbọngan Ijọba. Awọn arakunrin pààrọ̀ orule ogbologboo, wọn wó awọn ogiri inu lọhun-un, wọn sì sọ apa titobi ile naa di ibi ipade fifanimọra kan. Obinrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàndágbé Katoliki tẹlẹri yii ń gbe ninu yara lẹhin gbọngan naa. Ó layọ gidigidi lati lè ṣe itilẹhin yii fun ijọsin Jehofa.
◻ Iriri miiran ti ó fi ọgbọn jijẹrii lọna àìjẹ́-bí-àṣà han wá lati Kampala, Uganda. Loju ọna si ọfiisi ijọba kan, Ẹlẹ́rìí ojihin iṣẹ Ọlọrun kan sọrọ lọna àìjẹ́-bí-àṣà pẹlu awọn wọnni ti wọn wà ninu ẹrọ agbéniròkè pẹlu rẹ̀. Ọkunrin kan Ọgbẹni L——, fi ifẹ ọkàn han lati tẹwọgba iwe ikẹkọọ ti a filọ ọ ṣugbọn kò lè gbà á ni akoko yẹn. Nitori naa ó fun ojihin iṣẹ Ọlọrun naa ni orukọ rẹ ati adirẹsi ọfiisi rẹ̀. Lẹhin naa ojihin iṣẹ Ọlọrun naa lọ sibẹ ó sì beere Ọgbẹni L——. A pè é jade ṣugbọn si iyalẹnu ojihin iṣẹ Ọlọrun naa, ọkunrin ọtọ ni ó farahan. Awọn ọkunrin meji ti wọn ni orukọ kan naa ni wọn wà ti wọn ń ṣiṣẹ ni ọfiisi yẹn. Ijẹrii ṣoki ni a fifun Ọgbẹni L—— keji naa, ó sì fi ifẹ ara ọtọ han. Nigba ti ó jẹ́ pe Ọgbẹni L—— padanu ifẹ, ikẹkọọ Bibeli ni a bẹrẹ pẹlu Ọgbẹni L—— ẹkeji. Oun jẹ́ Ẹlẹ́rìí ti a ti bamtisi nisinsinyi, aya ati ọmọkunrin rẹ̀ si ń ni itẹsiwaju rere siha bamtisimu.
Jesu Kristi ni Oluṣọ-agutan rere ó sì mọ awọn ẹni bi agutan ti ọkan-aya wọn tẹsiha ododo. Awọn iriri wọnyi ṣapejuwe pe oun ndari awọn ọmọlẹhin rẹ si iru awọn wọnni. Ijẹrii aláìjẹ́-bí-àṣà lè jẹ́ amesojade!—Johanu 10:14.