ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 3/15 ojú ìwé 31
  • Ẹ Kiyesi Ọ̀rọ̀ Alasọtẹlẹ Ọlọrun!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Kiyesi Ọ̀rọ̀ Alasọtẹlẹ Ọlọrun!
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ni Igbẹkẹle ninu Ọ̀rọ̀ Alasọtẹlẹ Naa
  • Ṣọra Fun Awọn Apẹhinda
  • Ọjọ Jehofa Nbọ!
  • Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Jákọ́bù, Ìwé Pétérù Kìíní àti Pétérù Kejì
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ohun Tó Wà Nínú Ìwé 2 Pétérù
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
  • Ṣọ́ra fún Àwọn Olùkọ́ Èké!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Ẹ Jẹ́ Kí A Di Ìgbàgbọ́ Wa Ṣíṣeyebíye Mú Ṣinṣin!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 3/15 ojú ìwé 31

Ẹ Kiyesi Ọ̀rọ̀ Alasọtẹlẹ Ọlọrun!

Awọn Kókó Itẹnumọ Lati Inu Peteru Keji

Ọ̀RỌ̀ alasọtẹlẹ tabi ihin-iṣẹ, Jehofa, dabi fitila ti ntan ninu ibi okunkun, awọn Kristian tootọ sì nilati fiyè gidigidi si i. Iyẹn kò rọrun nigba ti awọn olukọ èké ba gbiyanju lati ṣagbatẹru ipẹhinda. Ṣugbọn a le ṣe e pẹlu iranlọwọ atọrunwa. A sì gbọdọ rọ̀mọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun ṣinṣin bi awa ba nilati la ọjọ Jehofa ti nsunmọle pẹlu iyara kánkán já.

Lẹta onimiisi keji ti apọsteli Peteru le ran wa lọwọ lati fiyesi ọ̀rọ̀ alasọtẹlẹ Ọlọrun. Peteru kọ lẹta gigun yii boya lati Babiloni ni nnkan bii 64 C.E. Ninu lẹta rẹ̀ oun gbèjà otitọ Ọlọrun, o kilọ dide ọjọ Jehofa bi olè fun awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ rẹ̀, o sì ran awọn onkawe rẹ̀ lọwọ lati ma jẹ ki a dẹ wọn lọ nipa iṣina awọn eniyan oluṣaya gbangba pofin nija. Niwọnbi ọjọ Jehofa ti fẹrẹẹ deba wa, awa le jere lọna titobi lati inu awọn ọ̀rọ̀ onimiisi Peteru.

Ni Igbẹkẹle ninu Ọ̀rọ̀ Alasọtẹlẹ Naa

Gẹgẹ bi Kristian, awa nilati lo araawa de gongo lati maa fi awọn animọ oniwa-bi-Ọlọrun han a sì gbọdọ fiyesi ọ̀rọ̀ alasọtẹlẹ naa. (1:1-21) Lati yẹra fun didi alaiṣiṣẹmọ tabi alaimesojade, awa nilati ‘fi iwa mimọ, ìmọ̀, ikora-ẹni-nijanu, ifarada, ifọkansin oniwa-bi-Ọlọrun, ifẹni ará, ati ifẹ kun igbagbọ wa.’ Nigba ti Peteru ri Jesu ti a pa a larada ti o sì gbọ ti Ọlọrun sọrọ nipa Kristi nibi iṣẹlẹ yẹn, ọ̀rọ̀ alasọtẹlẹ ni a tubọ mu da a loju. (Maaku 9:1-8) O yẹ fun wa lati fiye si ọ̀rọ̀ onimiisi yẹn lati ọrun wa.

Ṣọra Fun Awọn Apẹhinda

Nipa fífiyè gidigidi si ọ̀rọ̀ alasọtẹlẹ Ọlọrun, awa lè ṣọra fun awọn apẹhinda ati awọn ẹni oniwa ibajẹ miiran. (2:1-22, NW) Peteru kilọ pe awọn olukọ èké yoo rákòrò wọnu ijọ. Bi o ti wu ki o ri, Jehofa yoo ṣe idajọ alaibarade fun awọn apẹhinda wọnyi, ani gẹgẹ bi oun ti da awọn angẹli alaigbọran, aye alaiwa-bi-Ọlọrun ti ọjọ Noa, ati awọn ilu-nla Sodomu ati Gomora lẹjọ. Awọn olukọ eke tẹmbẹlu aṣẹ ti Ọlọrun fifunni wọn sì re awọn alailera lọ lati darapọ mọ wọn ninu iwa-aitọ. Ìbá ti daraju fun iru awọn apẹhinda bẹẹ ki wọn ma ti mọ̀ “ipa ọna òdodo ju lẹhin ti wọn ti mọ̀ ọ́n lọna pipeye tan lati yipada kuro ninu aṣẹ mimọ ti a fi lelẹ fun wọn.”

Ọjọ Jehofa Nbọ!

Gẹgẹ bi awọn wọnni ti wọn nfiyesi ọ̀rọ̀ alasọtẹlẹ ni awọn ọjọ ikẹhin wọnyi, awa kò gbọdọ yọnda araawa lati jẹ ki awọn apẹ̀gàn ti wọn nfi ihin-iṣẹ nipa wiwanihin-in Jesu ṣẹlẹya lo agbara-idari lori wa. (3:1-18) Wọn gbàgbé pe Ọlọrun ti o ti pete lati pa eto-igbekalẹ awọn nnkan yii run pa aye ti o wà ṣaaju Ikun-omi run. Suuru Jehofa ni a kò nilati wò gẹgẹ bi ìjáfara nitori oun fẹ ki awọn eniyan ronupiwada. Eto-igbekalẹ yii ni a o parun ni “ọjọ Jehofa” ti a o sì rọpo rẹ̀ pẹlu ‘awọn ọ̀run titun ati ilẹ-aye titun kan ninu eyi ti òdodo yoo gbe.’ Nitori naa, awa nilati sa gbogbo ipa wa lati wà “laisi abawọn ati laisi abuku ati ni alaafia.” Dipo didi ẹni ti a ṣìlọ́nà nipasẹ awọn olukọ eke, ẹ jẹ ki a dàgbà ninu imọ Jesu Kristi.

Ẹ jẹ ki a fi awọn ọ̀rọ̀ Peteru sọkan. Ki a maṣe kuna lae lati ṣọra lodisi awọn olukọ èké. Maa gbe igbesi-aye pẹlu mímọ̀ pe ọjọ Jehofa nbọ laipẹ. Maa fiye si ọ̀rọ̀ alasọtẹlẹ ti Ọlọrun nigba gbogbo.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Gbésọ Sinu Tatarọsi: Jehofa ‘kò lọtikọ lati fi ìyà jẹ awọn angẹli ti wọn ṣẹ̀, ṣugbọn, nipa sisọ wọn sinu Tatarọsi, ó fi wọn sinu awọn kòtò òkùnkùn biribiri lati fi wọn pamọ de idajọ.” (2 Peteru 2:4) Eyi kii ṣe Tatarọsi alarosọ atọwọdọwọ ti a ṣapejuwe ninu Iliad ti Homer gẹgẹ bi ibi abẹlẹ kan nibi ti a ti fi awọn ọlọrun èké keekeeke, Cronus ati awọn ẹ̀mí Titan miiran, sẹwọn. Tatarọs ti Bibeli jẹ ipo bi ẹ̀wọ̀n, ti a rẹ̀ wálẹ̀ ninu eyi ti Ọlọrun ju awọn angẹli alaigbọran ni ọjọ Noa si. (Jẹnẹsisi 6:1-8; 1 Peteru 3:19, 20; Juuda 6) “Okunkun biribiri” jẹ iyọrisi lati inu dídí ti Ọlọrun dí imọlẹ tẹmi mọ wọn loju gẹgẹ bi awọn ẹni àléjùsíta kuro ninu idile rẹ̀. Gẹgẹ bi awọn wọnni ti a pamọ de idajọ alaibarade, wọn ni kìkì ireti ọ̀la ti o ṣokunkun. Tatarọsi jẹ ami iṣaaju ti iriri ifinisinu ọgbun-ainisalẹ tí Satani ati awọn ẹmi-eṣu rẹ̀ yoo ni ṣaaju ibẹrẹ Ijọba Ẹgbẹrun Ọdun ti Kristi. Iparun wọn yoo waye lẹhin Iṣakoso Ẹlẹgbẹrun Ọdun Jesu.—Matiu 25:41; Iṣipaya 20:1-3, 7-10, 14.

[Àwòrán]

Zeus gbe awọn ọlọrun kikere ju sinu Tatarọsi alarosọ atọwọdọwọ

[Crdit Line]

Ile Akojọ Ohun Iṣẹmbaye Awalẹpitan ti Orilẹ-ede, Athens, Greece

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́