Awọn Ìran Ataniji Ti Nfun Igbagbọ Lokun
Awọn Koko Itẹnumọ Lati Inu Iṣipaya
Johanu iranṣẹ Jehofa wà ni erekuṣu kekere ti Patimosi, lọna jinjin si etikun iwọ-oorun Asia Kekere. Nibẹ apọsteli arugbo yii ri awọn ohun agbayanu—alámì apẹẹrẹ, ti nmuni ta gìrì lọpọ igba, ti o si ni ijẹpataki nitootọ! Oun wà ni ọjọ Oluwa, ti o bẹrẹ lati igba ìgbégorí itẹ Jesu ni 1914 titi di opin Iṣakoso Ẹlẹgbẹrun Ọdun rẹ. Bi o tilẹ jẹ pe Johanu ri awọn iṣẹlẹ ti yoo ṣẹlẹ laaarin wakati araye ti o ṣokunkun julọ, bawo ni iwoye ọjọ iwaju rẹ nipa Ẹgbẹrun Ọdun Iṣakoso Kristi ti ni ogo ẹwa tó! Ẹ wo ibukun ti araye onigbọran yoo gbadun nigba naa!
Johanu kọ awọn iran wọnyi silẹ ninu iwe Bibeli ti Iṣipaya. Ti a ṣakọsilẹ rẹ ni nnkan bi 96 C.E., o le fun igbagbọ wa ninu Ọlọrun alasọtẹlẹ, Jehofa, ati ninu Ọmọkunrin rẹ Jesu Kristi lokun.—Fun kulẹkulẹ, wo iwe naa Revelation—Its Grand Climax At Hand!, ti a tẹjade lati ọwọ Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc.
Kristi Funni Ni imọran Onifẹẹ
Ni ibẹrẹ iṣipaya lati ọdọ Ọlọrun nipasẹ Kristi ni awọn lẹta si awọn ijọ meje ti awọn ẹlẹgbẹ ajumọ jogun Ijọba pẹlu Jesu ti farahan. (1:1–3:22) Ni gbogbogboo, awọn lẹta naa funni ni igboriyin, o dá awọn iṣoro mọyatọ, o pese itọsọna tabi iṣiri, ti o si tọkasi awọn ibukun ti njẹyọ lati inu fifi iṣotitọ ṣegbọran. Bi o tilẹ jẹ pe awọn ara Efesu ti foritì í, wọn ti fi ifẹ wọn akọkọ silẹ. Ijọ Simina ọlọrọ nipa tẹmi naa ni a fun niṣiri lati duro ninu iṣotitọ nigba ipọnju. Inunibini ko tii bori ijọ Pergamum naa, ṣugbọn o ti gba iyapa laaye. Laika igbokegbodo ti a mupọ sii nipasẹ awọn Kristian ni Tiatira, agbara idari Jesibẹli kan ṣi wa nibẹ. Ijọ Sadisi nilo lati wà lojufo nipa tẹmi, eyi ti o wa ni Filadefia ni a rọ̀ pe ki ó rọ̀ mọ́ ohun ti o ti ní, ìlọ́wọ́ọ́wọ́ awọn ara Laodekia nbeere iwosan tẹmi.
Iru awọn ọrọ rere wo ni wọn jẹ fun idalẹkọọ awọn ọba ti ọrun ni ọjọ iwaju—niti tootọ, gbogbo awọn Kristian! Fun apẹẹrẹ, eyikeyii ninu wa ha ti di onilọwọọwọ? Nigba naa gbe igbesẹ! Dabii ẹni ti ntunilara gẹgẹ bi ife omi tutu ni ọjọ ti o mooru ṣugbọn ki o tún bẹrẹ sii ṣaṣehan itara gbigbona fun Jehofa ati iṣẹ-isin rẹ.—Fiwe Matiu 11:28, 29; Johanu 2:17.
Ọdọ-agutan Naa Ṣí Ìwé-àkájọ Kan
Jehofa ni a ri tẹle e lori itẹ ninu ogo ẹwa. (4:1–5:14) Oun ni a rọgba yika nipasẹ awọn alagba mẹrinlelogun ati awọn ẹda alaaye mẹrin. Iwe-akajọ ti a dí pẹlu awọn èdìdí meje wa ni ọwọ rẹ. Ta ni o le ṣi iwe-akajọ naa? Họọwu, Ọdọ agutan naa, Jesu Kristi, tootun lati ṣe bẹẹ!
Awọn iṣẹlẹ amuni jígììrì ṣí si ojutaye bi Ọdọ agutan naa ti ṣi mẹfa ninu awọn edidi naa (6:1–7:17) Bi a ṣe ṣi edidi akọkọ, Kristi farahan lori ẹṣin funfun, o gba ade kan (ni 1914), ti o si jade lọ ni ṣiṣẹgun. Bi awọn edidi mẹta pupọ sii ti di ṣiṣi, awọn ẹlẹṣin miiran mu ogun, iyan, ati iku wa fun araye. Pẹlu ṣiṣi edidi ikarun, awọn ti ó kú iku ajẹriiku nitori Kristi kigbe jade fun igbẹsan ẹjẹ wọn, ẹnikọọkan wọn ni a fun ni “aṣọ funfun,” ti o tumọsi iduro ododo wọn ti o niiṣe pẹlu ajinde wọn lati jẹ awọn ẹda ẹmi alaileeku pẹlu awọn anfaani ọlọba. (Fiwe Iṣipaya 3:5; 4:4.) Nigba ti a ṣi edidi ikẹfa, ọjọ ibinu Ọlọrun ati ti Ọdọ agutan naa ni a kede nipasẹ iṣẹlẹ kan. Ṣugbọn “afẹfẹ mẹrẹẹrin aye,” ti o ṣapẹẹrẹ idajọ oniparun, ni a fawọ rẹ sẹhin titi di igba ti a o fi fi èdìdí dí 144,000 awọn iranṣẹ Ọlọrun. Nigba ti a fami yàn wọn pẹlu ẹmi Ọlọrun ti a si sọ wọn dọmọ gẹgẹ bi awọn ọmọkunrin tẹmi rẹ, wọn gba ẹri iṣaaju kan—èdìdí, tabi ìjẹ́jẹ̀ẹ́—ti ìjogún wọn ti ọrun. O jẹ kiki lẹhin idanwo ni ìfèdìdí dí naa yoo di eyi ti o wà titilọ lae. (Roomu 8:15-17; 2 Kọrinti 1:21, 22) Bawo ni yoo ti jẹ agbayanu to fun Johanu lati ri “ogunlọgọ nla” lati inu gbogbo awọn orilẹ-ede—ogidigbo kan pẹlu ireti iye ayeraye ninu paradise ilẹ aye kan! Wọn jade wa lati inu “ipọnju nla,” akoko wahala alailafiwe fun araye.
Iru awọn iṣẹlẹ amunitagiri wo ni o bẹ́ silẹ bi a ṣe ṣi edidi keje! (8:1–11:14) Iparọrọ onidaji wakati, ti o fi ààyè silẹ fun adura awọn ẹni mimọ lati di eyi ti a gbọ́, ni fifi ina sọko sori ilẹ-aye lati ori pẹpẹ naa tẹlé. Lẹhin naa awọn angẹli meje mura tan lati fọn awọn ipe ti nkede awọn egbe Ọlọrun lori Kristẹndọm. Awọn ipe naa ni a fọn jalẹjalẹ akoko opin titi di igba ipọnju nla naa. Awọn ipe mẹrin kede egbe sori ilẹ-aye, okun, awọn orisun omi, ati oorun, oṣupa, ati awọn irawọ. Fífun ikarun pe awọn eéṣú jade ti o yaworan awọn Kristian ẹni ami-ororo ti wọn tu yìì jade lati ja ija-ogun lati 1919 siwaju. Pẹlu fifun ipe kẹfa, ikọlu ajagun ẹlẹṣin ṣẹlẹ. Ni imuṣẹ rẹ̀, awọn ẹni ami-ororo, ni a tubọ fun lokun lati 1935 nipasẹ “ogunlọgọ nla” naa, ti wọn polongo awọn ihin iṣẹ idajọ adaniloro lodisi awọn aṣaaju isin Kristẹndọm.
Johanu jẹ iwe akajọ kekere kan tẹle e, ti o tumọsi pe awọn ẹni ami-ororo tẹwọgba iṣẹ ti a yan fun wọn ti wọn si ngba ọrọ amunilokun lati inu apakan ninu Ọrọ Ọlọrun ti o ní awọn ọrọ idajọ atọrunwa ti wọn npolongo lodisi Kristẹndọm nínú. Apọsteli naa ni a paṣẹ fun lati diwọn ibujọsin tẹmpili, ti o tumọsi imuṣẹ awọn ete Jehofa kan bayii nipa iṣeto tẹmpili ki awọn wọnni ti wọn ni isopọ pẹlu rẹ si de oju ila ọpa idiwọn atọrunwa yẹn ni a nilati doju rẹ nipasẹ. Lẹhin naa “awọn Ẹlẹrii meji” ẹni ami-ororo Ọlọrun sọtẹlẹ ninu aṣọ ọfọ, a pa wọn, ṣugbọn a ji wọn dide. Eyi tọkasi 1918-1919, nigba ti iṣẹ iwaasu wọn fẹrẹẹ di eyi ti a sọ di oku nipasẹ awọn olodi, ṣugbọn awọn iranṣẹ Jehofa ni a mu sọji lọna iṣẹ iyanu fun iṣẹ ojiṣẹ wọn.
A Bi Ijọba Naa!
Fifun ipe keje naa kede ibi Ijọba naa. (11:15–12:17) Ninu ọrun obinrin iṣapẹẹrẹ kan (eto-ajọ Jehofa Ọlọrun ti ọrun) bi ọmọ ọkunrin kan (Ijọba Ọlọrun pẹlu Kristi gẹgẹbi Ọba), ṣugbọn dragoni naa (Satani) gbiyanju lasan lati faaya pẹrẹpẹrẹ. Ni mimu ogun naa de òtéńté ninu ọrun tẹle ibi Ijọba naa ni 1914, Maikẹli aṣẹgun (Jesu Kristi) le dragoni ati awọn angẹli rẹ jade wa sori ilẹ-aye. Nibẹ dragoni naa nbaa lọ lati jagun lodisi aṣẹku ẹni ami-ororo ti iru ọmọ obinrin ti ọrun naa.
Johanu ri ẹranko ẹhanna kan tẹle e eyi ti a ṣe aworan asuni fun irira kan fun. (13:1-18) Ẹranko ẹhanna oṣelu olori meje ati iwo mẹwaa yii jade wa lati inu “okun,” iwọjọpọ araye ti ńrugùdù lati inu eyi ti ijọba eniyan ti jade wa. (Fiwe Daniẹli 7:2-8; 8:3-8, 20-25.) Ki ni orisun aṣẹ ẹda alaaye iṣapẹẹrẹ yii? Họọwu, kii ṣe elomiran ju Satani, dragoni naa! Sì rò ó wò na! Ohun àràmàǹdà oṣelu abanilẹru yii ni a ri ẹranko oniwo meji kan (Agbara Aye Gẹẹsi ati America) ti o ṣe “aworan,” kan fun ti a mọ bayii gẹgẹ bi Iparapọ Awọn Orilẹ-ede. Ọpọlọpọ ni a fagbara mu lati jọsin ẹranko ẹhanna naa ati lati tẹwọgba “ami” rẹ nipa ṣiṣe awọn nnkan ni ọna rẹ ati jijẹ ki o ṣakoso awọn igbesi aye wọn. Ṣugbọn awọn Ẹlẹrii Jehofa nfi pẹlu iduroṣinṣin kọ ami ẹlẹmi eṣu ti ẹranko ẹhanna naa silẹ!
Awọn Iranṣẹ Jehofa Gbé Igbesẹ
Oniruuru awọn iranṣẹ Ọlọrun ni a ri lẹnu iṣẹ bi awọn awokòtò meje ibinu rẹ ti ndi eyi ti a ńdà jade. (14:1–16:21) Fetisilẹ! Lori Oke Sioni ti ọrun, Johanu ngbọ ti awọn 144,000 nkọrin bi ẹnipe orin titun kan. Angẹli kan ti nfo ni agbedemeji ọrun ni ihinrere ainipẹkun lati polongo fun awọn olugbe ilẹ-aye. Ki ni ohun ti eyi fihan? Pe awọn Ẹlẹrii Jehofa ni iranlọwọ ti angẹli ninu pipolongo ihin-iṣẹ Ijọba naa.
Johanu ni a gbọdọ ti yà lẹnu lati ri ọgba ajara ilẹ aye ti a kore ti gbogbo awọn orilẹ-ede si di eyi ti a tẹfọ bi ìfúntí irunu Ọlọrun ṣe di eyi ti a fẹsẹ̀ tẹ̀ mọlẹ. (Fiwe Aisaya 63:3-6; Joẹli 3:12:14.) Labẹ aṣẹ Jehofa, awọn angẹli meje da awọn àwokòtò meje ti ibinu atọrunwa jade. Ilẹ-aye, okun, awọn orisun omi, ati bakan naa pẹlu oorun, itẹ ẹranko ẹhanna naa, ati Odo Eufureti ni a nipa lé lori nigba ti a da awọn àwokòtó mẹfa akọkọ jade. Woye itara ayọ Johanu bi oun ṣe sakiyesi pe ìgbékèéyíde ẹmi eṣu nko awọn ọba eniyan jọ papọ si ogun Ọlọrun ti Amagẹdọn. Awọn abajade rẹ si jẹ apanirun raurau bi a ṣe da àwokòtò keje jade sori afẹfẹ.
Awọn Obinrin Iṣapẹẹrẹ Meji
Dajudaju, Johanu ni a ru lọkan soke lati ṣe ẹlẹrii opin Babiloni Nla, ilẹ-ọba isin eke agbaye, ati lati kiyesi awọn iṣẹlẹ onidunnu ti o tẹle iparun rẹ. (17:1–19:10) O ti mu amupara ẹjẹ awọn eniyan mimọ, oun ni a ri ti o gun ẹranko ẹhanna alawọ pupa pẹlu ori meje ati iwo mẹwaa (Imulẹ Awọn Orilẹ-ede ati arọpo rẹ, Iparapọ Awọn Orilẹ-ede). Áà, ẹ wo iru iparun dahoro ti oun jiya rẹ bi awọn iwo naa ti yiju pada lodisi!
Awọn ohùn ninu ọrun ni a gbọ́ ti nyin Jáà fun iparun Babiloni Nla naa. Ẹ wo iru iyin asán bi àrá ti o kede igbeyawo Ọdọ agutan naa ati iyawo rẹ, awọn ẹni ami-ororo ti a ti ji dide!
Kristi Ṣẹgun O Si Nṣakoso
Johanu ri Ọba awọn ọba tẹle e bi oun ṣe nṣiwaju ẹgbẹ ọmọ-ogun ọrun ninu pipa awọn etọ igbekalẹ Satani run. (19:11-21) Bẹẹni, Jesu, “Ọrọ Ọlọrun,” jagun lodisi awọn orilẹ-ede. Apọsteli naa ri ẹranko ẹhanna naa (eto-ajọ iṣelu Satani) ati wolii eke naa (Agbara Aye Gẹẹsi ati America) ti a fi sọko sinu “adagun ina,” ti o ṣapẹẹrẹ iparun ayeraye.
Ki ni o tẹle e? Họọwu, Johanu ṣakiyesi jiju Satani sinu ọgbun. Iwoye ọjọ iwaju si Iṣakoso Ẹlẹgbẹrun Ọdun Kristi ni tẹle e, laaarin eyi ti Jesu ati awọn alajumọ ṣakoso rẹ ti a ji dide ṣedajọ araye, ni mimu awọn onigbọran eniyan wa sinu ijẹpipe! (20:1-10) O to akoko bayii fun idanwo ikẹhin. Bi a ti tú u silẹ lati inu ọgbun naa, Satani yoo jade lọ lati ṣi araye ti a ti sọ di pipe perepere lọna, ṣugbọn iparun yoo mu opin de ba iṣẹ igbesi aye gbogbo ẹmi eṣu ati iṣọtẹ eniyan lodi si Ọlọrun.
Ni pipada sẹhin ninu akoko, bawo ni a ti gba afiyesi Johanu to lati ri gbogbo awọn wọnni ti wọn wà ninu iku, Hades (saree araye lapapọ), ati ninu okun ti a ji dide ti a si ṣedajọ wọn niwaju Ọlọrun, Ẹniti ti o joko lori itẹ funfun nla! (20:11-15) Iru itura wo ni awọn aduroṣinṣin naa yoo gbadun nigba ti iku ati Hades ba di eyi ti a jù sinu adagun ina, ti ki yoo tẹwọgba awọn ojiya ipalara mọ laelae!
Bi awọn iran Johanu ti nwa si opin, oun ri Jerusalẹmu Titun. (21:1–22:21) Ilu nla ti Ijọba yẹn ni o sọkalẹ lati ọrun ti o si mu imọlẹ wa sori awọn orilẹ-ede. “Odo omi iye” ni nṣan jade la aarin Jerusalẹmu Titun kọja, ti o yaworan otitọ Iwe Mimọ ati gbogbo ipese miiran ti Ọlọrun fifunni ti a gbekari ẹbọ Jesu fun imupadabọsipo araye onigbọran lati inu ẹṣẹ ati iku ati fifun wọn ni iye ayeraye. (Johanu 1:29; 17:3; 1 Johanu 2:1, 2) Ni bebe ìkíní keji odo yii, Johanu ri awọn igi pẹlu awọn ewe ti nṣewosan, ti o yaworan apa kan ninu awọn ipese Jehofa fun fifun araye onigbọran ni iye ayeraye. Ikesini kan ni o tẹle ikadii awọn ihin-iṣẹ lati ọdọ Ọlọrun ati Kristi. Bawo ni o ti jẹ agbayanu to lati gbọ ẹmi ati iyawo ti nkesi olukuluku eniyan ti orungbẹ ngbẹ lati ‘wá gba omi iye lọfẹẹ’! Bi awa ṣe nka awọn ọrọ ipari ti Iṣipaya, laisiyemeji awa ṣalabaapin ipolongo onitara ti Johanu pe: “Amin! Maa bọ, Jesu Oluwa.”
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]
Wà Lojufo: Laaarin awọn ọrọ alasọtẹlẹ nipa ogun Ọlọrun ti Ha–Magẹdọn (Amagẹdọn), a sọ pe: “Kiyesi i mo [Jesu Kristi] nbọ bi ole. Ibukun ni fun ẹni ti nṣọna ti o si npa aṣọ rẹ mọ, ki o ma baa rin ni ihoho, wọn a si ri itiju rẹ.” (Iṣipaya 16:15) Eyi le jẹ itọka si ẹru iṣẹ awọn alaboojuto, tabi awọn ijoye oṣiṣẹ, ti tẹmpili naa ti a gbekalẹ sinu Jerusalẹmu. Lakooko iṣọna, oun yoo lọ jalẹ gbogbo tẹmpili naa lati ri yala awọn ẹṣọ rẹ̀ ti iṣe awọn Lefi wa lojufo tabi wọn ti sun lọ fọnfọn ni awọn ipo wọn. Ẹṣọ eyikeyii ti a ba ri ti o nsun ni a maa nlù pẹlu igi kan, aṣọ awọleke rẹ ni a le jo gẹgẹbi ijiya akotiju bani. Pẹlu Amagẹdọn ti o sunmọ tosi bayii, aṣẹku ẹni ami-ororo naa ti “olu alufaa,” tabi “ile tẹmi,” ti pinnu lati wà lojufo nipa tẹmi. Bẹẹ gẹgẹ ni awọn alabaakẹgbẹpọ wọn, “ogunlọgọ nla” naa pẹlu ireti ilẹ-aye, nitori awọn naa pẹlu nṣe iṣẹ isin mimọ ọlọwọ si Ọlọrun ni tẹmpili naa. (1 Peteru 2:5, 9; Iṣipaya 7:9-17, NW) Paapaa julọ awọn alaboojuto Kristian gbọdọ maa baa lọ ni ṣiṣọna lodisi idagba soke awọn ipo buburu ninu ijọ. Nitori pe wọn wà lojufo, gbogbo awọn olujọsin aduroṣinṣin ninu tẹmpili tẹmi Ọlọrun wọ “awọn aṣọ àwọ̀lékè” wọn, ti o tumọ si iṣẹ isin ọlọwọ wọn gẹgẹbi Ẹlẹrii Jehofa.