Iwọ Ha Ranti Bi?
Iwọ ha mọriri kika awọn itẹjade Ilé-ìṣọ́nà aipẹ yii bi? O dara, wo o bi iwọ ba le dahun awọn ibeere ti wọn tẹle e wọnyi:
◻ Ki ni ipilẹ ti awọn oluṣọ agutan tẹmi ní fun lilo idanuṣe lati lọ sọdọ awọn ẹni ti a ti yọ lẹgbẹ lati ri i bi a ba le sun wọn lati ronupiwada?
Ani nigba ti awọn ọmọ Isirẹli ṣì wà ni igbekun sibẹ ti wọn jẹ alaironupiwada, Jehofa gẹgẹ bi oluṣọ agutan kan lo idanuṣe lati wá wọn kiri, ni rírán awọn wolii rẹ̀ si wọn. Awọn oluṣọ agutan Kristẹni lọkan ifẹ si riran awọn onironupiwada eyikeyii lọwọ ti wọn le dabi agutan ti o ti sọnu. (Fiwe Luuku 15:4-7.)—4/15, oju-iwe 21 si 23.
◻ Bawo ni akawe Jesu nipa ọmọkunrin oninaakunaa ṣe fi ohun ti imọlara wa ati igbesẹ wa gbọdọ jẹ han nigba ti a ba gba ẹnikan sipo pada ninu ijọ Kristẹni? (Luuku 15:22-32)
Gongo wa yẹ ki o jẹ lati ṣafarawe baba naa, ẹni ti o fi ayọ han si pipada ọmọkunrin rẹ oninaakunaa. Nitori idi eyi, awa nilati sọrọ falala pẹlu arakunrin naa ti a gba sipo pada ki a si fun un niṣiiri ni akoko yii lati tẹsiwaju ninu otitọ.—4/15, oju-iwe 25.
◻ Ki ni awọn iṣọra ti a le lo lati yẹra fun didi ojiya iwa ipa?
Nibi ti o ba ti ṣeeṣe, yẹra fun wiwa ni awọn agbegbe elewu ni alẹ. Pa ohun ẹṣọ oniyebiye eyikeyii mọ́, ki o si gbe awọn ohun eelo iru bii kamẹra sinu apo amurọja kan. Ṣọra fun ririn ni igun ẹba ọna, paapaa julọ bi o ba gbe iru apoti ẹru tabi apo eyikeyii dani. (Wo Owe 3:21-23.)—5/1, oju-iwe 5 si 6.
◻ Eeṣe ti asọtẹlẹ ti o wà ni Sefanaya 2:3 fi wipe: “Boya a o pa yin mọ ni ọjọ ibinu Oluwa [“Jehofa,” NW]”?
Igbala si iye sinmi lori iṣotitọ ati ifarada. (Matiu 24:13) Nipa bayii, awọn wọnni ti wọn nba awọn ọpa idiwọn ododo Ọlọrun ṣe deedee ti wọn si nbaa lọ ni sisọ ede mimọgaara naa ni a o pamọ nikọkọ ni ọjọ ibinu Jehofa. (Sefanaya 2:1, 2)—5/1, oju-iwe 14.
◻ Ki ni fifi Ọlọrun ṣe akọkọ ninu igbesi-aye idile ni ninu?
Awọn obi ati awọn ọmọ nilati jọsin Jehofa wọn si gbọdọ doju iwọn ọpa idiwọn rẹ̀ gẹgẹ bi a ṣe la a kalẹ ninu Bibeli.—5/15, oju-iwe 5.
◻ Eeṣe ti Jehofa ko ṣe fi iya jẹ awọn ẹlẹṣẹ loju ẹsẹ?
Idi kan ni pe ki a ba le sọ orukọ rẹ di mímọ̀ ni gbogbo aye. (Fiwe Roomu 9:17.) Idi miiran ni lati fi akoko silẹ fun yiyanju awọn ariyanjiyan ipo ọba-alaṣẹ Ọlọrun ati iwatitọ araye, ti a gbé dide nipasẹ iṣọtẹ ni Edeni. Bakan naa, ipamọra Ọlọrun fun awọn alaṣiṣe ni anfaani lati ronupiwada ki wọn si tun awọn ọna wọn ṣe. (2 Peteru 3:9)—5/15, oju-iwe 11 si 12.
◻ Awọn otitọ wo ni wọn jẹrii sii pe Bibeli ni ipilẹṣẹ ti o ju ti eniyan lọ?
Bibeli ni a kọ nipasẹ nǹkan bii 40 awọn onkọwe ọtọọtọ, ti wọn wá lati oniruuru ipo igbesi-aye ti wọn si gbe lori ilẹ-aye la saa akoko ti o ju 1,600 ọdun já; sibẹsibẹ gbogbo awọn onkọwe wọnyi tẹle ipilẹ ẹṣin ọrọ kanṣoṣo. Iṣọkan inu Bibeli yii ki yoo ṣeeṣe bi a ba ti fi silẹ sọwọ eeṣi tabi itọsọna eniyan lasan.—6/1, oju-iwe 5.
◻ Ki ni iṣe ajeji ati aramanda iṣẹ, ti a sọtẹlẹ ni Aisaya 28:21, ti Jehofa yoo mu ṣe ni ọjọ wa?
Ikilọ ti o wa ni Iṣipaya 17:16 fihan pe awọn àlè oloṣelu ti Babiloni nla yoo yijupada sii ni ọjọ kan. Gẹgẹ bi iyọrisi rẹ, Kristẹndọmu ni a o parun patapata pẹlu gbogbo awọn isin eke yooku. Eyi yoo jẹ ajeji iṣe Jehofa, iṣẹ aramanda rẹ fun ọjọ wa.—6/1, oju-iwe 23.
◻ Ki ni ohun ti awọn Kristẹni obinrin nilati fi sọkan nipa ilo ohun ọṣọ ati eroja iṣaraloge?
Bibeli ko ka lilo iru awọn ohun iṣaraloge bẹẹ leewọ. (Ẹkisodu 32:2, 3; Ẹsita 2:7, 12, 15) Ṣugbọn iwọntunwọnsi nilati bori. Obinrin kan le fi irọrun wa lati ṣafarawe awọn aṣa aye, ni lilo ìtọ́tè, ọ̀dà àkùnsẹ́rẹ̀kẹ́, tabi lẹẹdi ìtọ́sí ìpéǹpéjú, ani gẹgẹ bi Jesebẹli ti ṣe. (2 Ọba 9:30) A nilati lo iṣọra ki a maa baa lo awọn ohun itunraṣe ni aloju ati ki ohun ọsọ maṣe jẹ atànyòyò.—6/1, oju-iwe 30 si 31.
◻ Bawo ni awọn ọmọ Isirẹli ṣe yebọ lọwọ ‘gbogbo arun buburu Ijibiti’ ti o gbodekan ni awọn akoko ijimiji? (Deutaronomi 7:15)
Lọna ti o ṣekedere wọn bọ lọwọ iru awọn ailera bẹẹ kiki nitori ṣisakiyesi awọn aṣa onilera ti o ti rin jinna niti ọlaju ti a palaṣẹ ninu majẹmu Ofin.—6/15, oju-iwe 4.
◻ Eeṣe ti Ọlọrun fi paṣẹ pe eniyan ko gbọdọ jẹ ẹjẹ? (Jẹnẹsisi 9:3, 4; Lefitiku 17:10, 11; Iṣe 15:22-29)
Iwalaaye jẹ ẹbun lati ọdọ Ọlọrun iwalaaye eniyan sì sinmi lori idipọ sẹẹli olomi ti a npe ni ẹjẹ. (Saamu 36:9) Nipa bibọwọ fun ẹjẹ gẹgẹ bi akanṣe, awọn eniyan fi igbarale wọn fun iwalaaye han. Nitori naa, idi pataki ti Ọlọrun fi paṣẹ ofin nipa ẹjẹ ni, pe ẹjẹ ni itumọ akanṣe fun Ọlọrun, kii ṣe pe o le jẹ elewu si ilera.—6/15, oju-iwe 8 si 9.
◻ Bawo ni awọn Kristẹni obi ati awọn ọdọ ṣe le daabobo ṣiṣeeṣe naa pe kikọ ti alaitojubọ kan kọ ifajẹsinilara ni a o bọwọ fun?
Bi o tilẹ jẹ pe kii ṣe agbalagba kan labẹ ofin, Kristẹni ọdọ kan nilati le ṣalaye ni kedere ati ni gbọnyingbọnyin ohun ti atako lilagbara ti isin rẹ jẹ si gbigba ẹjẹ. Awọn obi le ni awọn akoko idanrawo pẹlu awọn ọmọ wọn ki awọn wọnyi ba le jere iriri ninu ṣiṣalaye idaloju tiwọn funraawọn.—6/15, oju-iwe 18.
◻ Bawo ni a ṣe bukun awọn obinrin lọna jingbinni lakooko iṣẹ-ojiṣẹ Jesu lori ilẹ-aye?
Jesu bẹrẹ iṣẹ kan ti o mu itunu, ireti, ati iyì titun wa fun awọn obinrin ẹya iran gbogbo. O kọ awọn obinrin ni awọn otitọ tẹmi jijinlẹ. (Johanu 4:7, 24-26) Lakooko iṣẹ-ojiṣẹ rẹ̀, o tẹwọgba iṣeranṣẹ funni niha ọdọ awọn obinrin gẹgẹ bi oun ti nrinrin-ajo jakejado ilẹ naa. (Maaku 15:40, 41)—7/1, oju-iwe 14 si 15.
◻ Awọn ọna igbakọnilẹkọọ Jesu wo ni awọn obi ti ri pe o gbeṣẹ pẹlu awọn ọmọ wọn?
Awọn obi ṣe daradara lati lo awọn akawe lati mu ki otitọ Kristẹni fa ọkan-aya awọn ọmọ wọn ọ̀dọ́ mọra, wọn si le lo awọn ibeere ti a ronu rẹ jinlẹ lati mọ ohun ti awọn ọmọ wọn agba nro niti gidi. (Fiwe Matiu 17:24-27.)—7/1, oju-iwe 26.
◻ Eeṣe ti a fi nilati lepa iṣeun-ifẹ?
Animọ iṣeun-ifẹ mu wa jẹ ẹni ọ̀wọ́n fun Ọlọrun ati awọn ẹlomiran. O gbé ẹmi alejo ṣiṣe larugẹ o si mu ki a tubọ jẹ agbatẹnirò. O nfun awọn ide laaarin idile ati ijọ Kristẹni lokun. Ju gbogbo rẹ lọ, iṣeun-ifẹ nmu ogo wa fun Jehofa.—7/15, oju-iwe 22.
◻ Eeṣe ti o fi ṣeeṣe fun Kristẹni kan lati di ẹni ti a ṣì lọna ninu ọran ẹgbẹ kiko? (1 Kọrinti 15:33)
Ẹnikan le farahan bi ọrẹ ki o sì ṣee faramọ, ṣugbọn bi oun ko ba ṣajọpin aniyan Kristẹni fun iṣẹ-isin Jehofa tabi ki o tilẹ gba Bibeli gbọ paapaa, oun jẹ olubakẹgbẹ buburu kan. Eeṣe? Nitori pe igbesi-aye rẹ ni a gbekari awọn ilana yiyatọ, awọn ohun ti o si ṣe pataki gan an fun Kristẹni le ma ṣe pataki fun un.—7/15, oju-iwe 23.
◻ Eeṣe ti Ọjọ Idajọ fi jẹ akoko ireti kan?
Ọjọ Idajọ jẹ saa akoko ẹgbẹrun ọdun kan. Oun ni a o bojuto nipasẹ Ọlọrun funraarẹ pẹlu Ọmọkunrin rẹ, Jesu Kristi, ti Ọlọrun yan lati gbegbeesẹ gẹgẹ bi Onidaajọ. Eyi yoo jẹ akoko kan lati mu iwalaaye eniyan pipe ti Adamu gbe sọnu fun awọn ọmọ rẹ padabọsipo fun araye. (1 Kọrinti 15:21, 22)—8/1, oju-iwe 5 si 7.