Iwọ Ha Ńsẹ́ Awọn Itẹsi Ti Wọn Kún Fun ẸṣẹBi?
“NJẸ MO RÍ niti ofin pe, bi emi ti nfẹ lati maa ṣe rere, buburu a maa wa lọdọ mi. Inu mi saa dun si ofin Ọlọrun nipa ẹni ti inu: ṣugbọn mo ri ofin miiran ninu awọn ẹya ara mi, ti nba ofin inu mi jagun ti o si ńdì mi ni igbekun wá fun ofin ẹṣẹ, ti o nbẹ ninu awọn ẹya ara mi.”—Roomu 7:21-23.
Ó gba irẹlẹ fun apọsiteli Pọọlu lati jẹwọ ohun ti o wa loke yii. Sibẹ, nipa ṣiṣe bẹẹ rẹ, oun ran araarẹ lọwọ lati ká awọn itẹsi alaipe rẹ lọwọ kò lati maṣe bori rẹ̀.
Bakan naa ni ó ri pẹlu awọn Kristẹni tootọ lonii. Nigba ti a wá sinu imọ pipeye ti otitọ Bibeli, a ṣe awọn iyipada ti o pọndandan ninu ọna igbesi-aye wa, ni hihuwa ni ibamu pẹlu awọn ọpa idiwọn Jehofa. Bi o ti wu ki o ri, awọn itẹsi ti o kun fun ẹṣẹ ṣì wà sibẹ, “nitori iro ọkan eniyan ibi ni lati igba ewe rẹ wá.” (Jẹnẹsisi 8:21) Awa ha jẹ alailabosi tó lati jẹwọ awọn itẹsi pato ti nlo ikimọlẹ lori wa? Tabi awa ha ńsẹ́ pe awa ni wọn, boya ni pipari ero pe, “Iwọnyi le jẹ awọn agbegbe iṣoro fun awọn ẹlomiran ṣugbọn kii ṣe fun mi”?
Iru itanra ẹni jẹ bẹẹ le ṣekupani. Àkàwé kan ti a gbekari Bibeli le ran wa lọwọ lati mọriri aini lati mọ awọn itẹsi wa ti o kun fun ẹṣẹ ati lati ṣakoso wọn.
Idi Ti Sísẹ́ Fi Lè Ṣekupani
Ni awọn akoko Bibeli ọpọlọpọ awọn ilu ni a fi ogiri daabobo. Awọn ibode—ti a saba maa nfi igi ṣe—jẹ apa ogiri inu ti o wa ninu ewu ni ifiwera; nitori naa, awọn ni a ndaabobo gidigidi. Awọn olugbe ilu naa ńkọ́ kiki ibode ti o pọ tó bi a ti nilo rẹ fun irinna lakooko alaafia. Awọn ibode onigi ni a saba maa nfi metal bo, lati dena ibajẹ nipasẹ ina. Awọn ile-iṣọ ni a kọ́ sara awọn ogiri naa ki awọn ẹṣọkunrin ti a yàn sinu wọn ba le rí awọn ọta ti nbọ ni ọkankan.
Nisinsinyi ronu: Ki ni yoo ṣẹlẹ bi awọn olugbe ilu kan ba sẹ́ iwa ninu ewu ibode ilu naa ki wọn má si pese aabo ti o tó? Awọn ọmọ-ogun ọta ni yoo rọrun fun lati wọle sinu ilu naa, ti yoo si yọrisi ṣiṣẹgun rẹ.
Bẹẹ ni o ri pẹlu wa. Jehofa mọ ibi ti ẹnikọọkan wa ti ṣí silẹ si ewu. “Ko si si ẹda kan ti ko farahan niwaju rẹ, ṣugbọn ohun gbogbo ni o wà ni ihoho ti a sì ṣipaya fun oju rẹ ẹni ti awa nba lò.” (Heberu 4:13) Satani pẹlu ti le ṣakiyesi itẹsi kan ti o kun fun ẹṣẹ ninu wa, yala o jẹ siha lilọ otitọ po, titete binu, ifẹ ọkan ninu iwa palapala takọtabo, ifẹ ọrọ alumọọni, igberaga, tabi ohunkohun miiran. Bi awa ba sẹ́ pe a ni awọn itẹsi ti wọn kun fun ẹṣẹ, a mu ara wa ṣi silẹ si ewu sii fun igbejakoni Satani lori igbagbọ wa. (1 Peteru 5:8) A le sẹpa wa bi ifẹ ọkan ti ko tọna ṣe ntẹsiwaju rekọja awọn itẹsi lasan ki o si bi ẹṣẹ. (Jakọbu 1:14, 15) A nilati dabi Pọọlu, ni fifi otitọ jẹwọ ‘ibode onigi’ eyikeyi ti o le wa.
Fun Araarẹ Lokun!
Yoo jẹ alaiwulo lati dá awọn itẹsi ti ko tọna mọ ṣugbọn ki a ma ṣe ohunkohun nipa rẹ lẹhin naa. Eyi yoo dabi ọkunrin kan ti o wo araaarẹ ninu digi, o ṣakiyesi agbegbe ti o nilo afiyesi, o si rin lọ laiṣe awọn atunṣe ti o yẹ ni ṣiṣe. (Jakọbu 1:23-25) Bẹẹni, a nilati gbe igbesẹ ninu didaabobo araawa kuro ninu jijẹ ẹni ti a gbamu lojiji nipa awọn itẹsi ti wọn kun fun ẹṣẹ. Bawo ni a ṣe le ṣe eyi?
Niye igba, ni awọn akoko Bibeli, awọn ilu keekeeke, tabi “awọn ilu ti o gbaraleni,” jẹ alailogiri. (Numeri 21:25, 32, NW; Onidaajọ 1:27; 1 Kironika 18:1; Jeremaya 49:2) Awọn olugbe ilu wọnyi le salọ si ilu ologiri bi igbejakoni ọta ba waye. Awọn ilu ti a daabobo tipa bayii jẹ ibi isadi kan fun awọn eniyan ni agbegbe ti o yi wọn ká.
Bibeli ṣapejuwe Jehofa gẹgẹ bi ile-iṣọ, abo isadi, ogiri ninu eyi ti a lè salọ fun idaabobo. (Owe 18:10; Sekaraya 2:4, 5) Nitori naa Jehofa ni olori oludaabobo awọn iranṣẹ rẹ. Adura lemọlemọ si i pọndandan gan an. (1 Tẹsalonika 5:17) Aranṣe miiran ni Bibeli. Ni lilo Ọrọ Ọlọrun, awa ṣe daradara lati farabalẹ ṣewadii awọn agbegbe wọnni ninu eyi ti a ti jẹ alailera. A tun le ya awọn ọrọ-ẹkọ ti a gbekari Bibeli ti o sọrọ lori ‘awọn ibode onigi’ ẹnikọọkan wa sọtọ fun ayẹwo aṣetunṣe.
Pẹlupẹlu, gẹgẹ bi awọn ẹṣọkunrin ninu ile-iṣọ kan, awa le ri ọta lati okeere, gẹgẹ bi o ti rí, ki a si gbegbeesẹ bi o ti yẹ. Bawo? Nipa yiyẹra fun awọn ipo ninu eyi ti a ti le dojukọ adanwo tabi ikimọlẹ. Fun apẹẹrẹ, ẹnikan ti o nṣiṣẹ siha iwọntunwọnsi ninu mímu awọn ohun mímu lile yoo fi ọgbọn yan lati yẹra fun awọn ibi ti lilọ sidii awọn ohun mimu wọnyi ti wọpọ tabi ti a tilẹ ti fun un niṣiiri.
Gbogbo eyi nbeere isapa. Bi o ti wu ki o ri, bi Apọsiteli Pọọlu ba nilati ‘pọn araarẹ loju’ ki o baa le dena awọn itẹsi alaipe, awa pẹlu ko ha nilati lo isapa bi? Iru afiyesi tọkantọkan bẹẹ fun awọn itẹsi wa ti o kun fun ẹṣẹ yoo fihan pe awa ntẹle idari apọsiteli Peteru pe: “Ẹ mura giri, ki a le ba yin ni alaafia, ni ailabawọn, ati ni ailabuku ni oju rẹ.”—1 Kọrinti 9:27; 2 Peteru 3:14.
Gba Ki O Sì Gbegbeesẹ
Iwọ maṣe sọ ireti nù bi, laika awọn isapa rẹ sí, gbogbo awọn itẹsi alaipe rẹ ko ba kuro. Niwọn igba ti a ba ṣì jẹ alaipe, awọn itẹsi ti ko tọ́ yoo ma wà nigba gbogbo dé iwọn kan, gẹgẹ bi o ti jẹ otitọ ninu ọran Pọọlu. Ṣugbọn awa nilati maa baa lọ ni ṣiṣiṣẹ lati ṣedena iwọnyi. Lati pa wọn mọ kuro ninu bibi ẹṣẹ.
Bi o ti wu ki o ri, ní iyatọ ti o wa laaarin titẹwọgba otitọ nipa aipe ati fifayegba a lọkan. Iyẹn ni a le fi ọkunrin kan ti o ni ọkan-aya alailera ninu aya rẹ ṣakawe. Oun nilati dojukọ otitọ yii nipa gbigbidanwo lati pa ọkan-aya rẹ̀ mọ ni ipo rere bi oun ti reti pe oun lè ṣe. Oun ko ni ronu pe niwọn igba ti ọkan-aya gidi rẹ ti jẹ alailera, oun bakan naa le pa gbogbo ìjánu tì ki o si maa gbe bi o ba ti ṣe wù ú.
Mọ, nigba naa, pe okun wa ko sinmi le sísẹ́ awọn itẹsi ti wọn kun fun ẹṣẹ lọna ainironu ṣugbọn ninu gbigba wọn si otitọ ati gbigbe igbesẹ lodi si iwọnyi. Nitori naa maṣe foya lati jẹwọ fun araaarẹ ati fun Jehofa awọn agbegbe ibi ti a ti nfi irọrun dan ọ wo tabi fun ọ ni ikimọlẹ. Iwọ ko nilati din ifẹ ti o ni fun araarẹ kù fun ṣiṣe bẹẹ, bẹẹ ni ifẹ Jehofa fun ọ ki yoo dinku. Nitootọ, gẹgẹ bi iwọ ti nsunmọ Ọlọrun ninu idaniyan afitọkantọkan ṣe fun itẹwọgba rẹ, oun yoo tilẹ fà sunmọ ọ sii.—Jakọbu 4:8.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Awoṣe Mẹgido yii ṣapejuwe ibode alagbara ati awọn ogiri idaabobo ti awọn ilu igbaani
[Credit Line]
Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.