Ọ̀nà Abajade Kan Ha Wà Kuro Ninu Ipo Ẹṣẹ Eniyan Bi?
PẸLU awọn ọmọ rẹ̀ ọdọlangba mẹrin, Chisako maa ń fọ awọn ile itura gbogbogboo ni ilu nla kan ti o jẹ 400 ibusọ si ile rẹ̀. Bi o ti ń ṣe bẹẹ, o ń kọ orin ewì Buddha, eyi ti oun kò loye itumọ rẹ̀. Ó jẹ ọ̀kan lara aṣa awujọ awọn onisin kan ti wọn ń wá ọ̀nà lati ṣawari ohun naa gan-an ti ó wà ni àárín gbungbun gbogbo isin.
“Loju gbogbo aṣa ìṣẹ́ra-ẹni-níṣẹ̀ẹ́ ti ń baa lọ naa,” Chisako sọyeranti, “emi kò lè yi iru ẹni ti mo jẹ pada. Ni isalẹ ọkan-aya mi lọhun un, n kò lè dariji awọn ẹlomiran n kò si lè fi ifẹ hàn pẹlu agbara isunniṣe ti o ti inú ọkan títọ́ wá.”
Koda ni awọn ilẹ Gabasi, nibi ti ọpọjulọ awọn eniyan kò ti ni ero kankan nipa ẹṣẹ bi a ti fi kọni ninu Bibeli, awọn pupọ nimọlara aibalẹ ẹ̀rí-ọkàn nitori awọn itẹsi ti o kún fun ẹ̀ṣẹ̀ wọn, gẹgẹ bi Chisako ti ṣe. (Romu 2:14, 15) Ta ni kò tii jiya imọlara aibarade rí fun ṣiṣai fi inurere hàn si ẹnikan ti o wà ninu ipo kan ti ó kún fun ìkáàánú tabi ti kò tii nimọlara awọn àbámọ̀ arẹnisilẹ kan fun awọn ọrọ ti kò yẹ ki a ti sọ lae? (Jakọbu 4:17) Ibẹru akójìnnìjìnnìbáni ti owú kò ha si farasin ninu tọmọde tagba lọna kan naa bi?
Eeṣe ti awọn eniyan fi ní iru imọlara onidaaamu bẹẹ? Nitori pe, yala wọn mọ̀ ọ́n lẹkun-un-rẹrẹ tabi bẹẹkọ, wọn ni èrò inu lọhun-un ti aitọ, ti ẹ̀ṣẹ̀. Nitootọ, yala awọn eniyan mọ nipa ẹkọ Bibeli nipa ẹṣẹ tabi bẹẹkọ, gbogbo eniyan ni awọn itẹsi ẹ̀ṣẹ̀ nipa lelori. Ogbogi kan lori koko ọrọ yii pari ero nigbakanri pe: “Gbogbo eniyan ni o sa ti ṣẹ̀, ti wọn si kùnà ogo Ọlọrun.”—Romu 3:23.
A Ha Le Fọ Ẹ̀ṣẹ̀ Nù Bi?
Ọpọ eniyan lonii, paapaa ni Kristendom, ni ọwọ́ wọn dí ni gbigbiyanju lati pa awọn imọlara ẹ̀ṣẹ̀ ati ẹ̀bi rẹ́ kuro ninu ẹ̀rí-ọkàn wọn. “Ọrọ naa fúnraarẹ̀ ‘ẹ̀ṣẹ̀’ . . . ti fẹrẹẹ poora,” ni Dokita Karl Menninger sọ ninu iwe rẹ̀ Whatever Became of Sin? Bi o ti wu ki o ri, yiyẹra fun ọrọ naa “ẹ̀ṣẹ̀” kò ṣeranwọ ju bii fífẹ ti agbalagba kan tí ń fẹ́ yẹra fun ọrọ naa “arúgbó” ti ṣeranwọ lọ. A nilati dojukọ otitọ naa pe a ni awọn itẹsi ti o kún fun ẹṣẹ ti a sì nilati gbà wa silẹ kuro ninu ipo bibaninujẹ gidigidi yẹn. Ṣugbọn nipasẹ ta ni?
Kristian aposteli Paulu beere ibeere yẹn lẹhin ti o ti gbà pẹlu awọn itẹsi tirẹ̀ alara lati dẹṣẹ laika bi o ti ń fẹ́ lati ṣe ohun ti o yatọ sí pe: “Emi ẹni òṣì! ta ni yoo gbà mi lọwọ ara iku yii?” Paulu ń baa lọ lẹhin naa lati dahun pe: “Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun nipasẹ Jesu Kristi Oluwa wa.” Eeṣe? Nitori pe Ọlọrun ti ṣeto fun idariji ẹṣẹ nipasẹ ẹbọ irapada Jesu.—Romu 7:14-25.
Bi o ti wu ki o ri, ọpọ ninu awọn 3,500,000,000 ninu aye ti wọn kì í ṣe Kristian (ilọpo meji awọn ti a fẹnu lasan pe ni Kristian) ri ero ẹbọ irapada kan gẹgẹ bi ohun kan ti o ṣoro gan-an lati loye. Fun apẹẹrẹ, ẹkọ irapada di ohun ìkọ̀sẹ̀ ti o tobi julọ fun awọn Musulumi ti wọn ń gbé ni Japan ti wọn kẹkọọ Bibeli fun igba diẹ. Fun ọpọ awọn ará Gabasi, èrò naa pe ọkunrin kan le kú fun gbogbo eniyan jẹ́ àjèjì.
Eyi yéni, niwọn bi awọn kan paapaa ni Kristendom ti ri ẹ̀kọ́ ipilẹ yii gẹgẹ bi ohun ti o ṣoro lati loye. “Ẹ̀kọ́ isin ṣọọṣi nipa Irapada,” ni iwe gbedegbẹyọ naa New Catholic Encyclopedia gbà pe, “ní awọn apa kan ó jẹ́ eyi ti a kò tii ṣaṣepari rẹ̀ o si ń baa lọ lati gbé araarẹ kalẹ gẹgẹ bi iṣoro kan ninu ẹkọ isin ṣọọṣi.”
Iwọn ààyè ti idarudapọ ti báa dé lori ẹkọ igbagbọ yii ni a ṣapejuwe rẹ̀ daradara ninu awọn ọrọ onkọwe onisin naa N. H. Barbour pe: “Iku Kristi kìí tún ṣe ìsanwó fun ìyà awọn ẹ̀ṣẹ̀ eniyan ju bi òbí orí ilẹ̀-ayé kan yoo ṣe wo kíki abẹ́rẹ́ bọ eṣinsin kan ki a si mú un jìyà ki o si kú gẹgẹ bi ọna ti o ba idajọ-ododo mu lati gbà yanju iwa búburú bùrùjà ọmọ rẹ̀.” Ẹni ti o faramọ́ra pẹlu Barbour nigba naa ni Charles T. Russell, ẹni ti o rí aini kanjukanju naa lati gbèjà ẹ̀kọ́ nipa irapada. O ya araarẹ sọtọ kuro lọdọ Barbour o si bẹrẹ sii ṣe iwe irohin titun kan jade ni 1879, eyi ti o wá di iwe irohin naa ti iwọ ń kà. Lati ibẹrẹ rẹ̀, Ilé-Ìṣọ́nà ti jẹ́ òǹgbèjà alatilẹhin fun ẹbọ irapada Jesu Kristi.
Ṣugbọn ẹ̀kọ́ igbagbọ yii ha le jẹ eyi ti awọn ti wọn kò ni ipo iriri ti “Kristian” kan lè gbà bi? Lati ṣewadii, jẹ ki a wo ẹ̀kọ́ yii nipa ọkunrin kan ti o kú fun gbogbo eniyan finnifinni sii.