ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w06 3/15 ojú ìwé 8-9
  • “Ẹ̀jẹ̀ Iyebíye” Ni Ọlọ́run Fi Dá Wa Nídè

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Ẹ̀jẹ̀ Iyebíye” Ni Ọlọ́run Fi Dá Wa Nídè
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ìtúsílẹ̀ Nípasẹ̀ Ìràpadà
  • Ìràpadà Ń Ràn Wá Lọ́wọ́ Ó sì Ń Fún Wa Ní Ìrètí
  • Ìràpadà Kristi Ọ̀nà Tí Ọlọ́run Là Sílẹ̀ Fún Ìgbàlà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
  • Ìràpadà—Ẹ̀bùn Tó Ṣeyebíye Jù Lọ Tí Ọlọ́run Fúnni
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Ìràpadà Ni Ẹ̀bùn Tó Dáa Jù Lọ Tí Ọlọ́run Fún Wa
    Kí Ni Bíbélì Kọ́ Wa?
  • Ìgbà Tí Ẹ̀ṣẹ̀ Kò Ní Sí Mọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
w06 3/15 ojú ìwé 8-9

“Àwa Gbọ́dọ̀ Ṣègbọràn Sí Ọlọ́run Gẹ́gẹ́ Bí Olùṣàkóso Dípò Àwọn Ènìyàn”

“Ẹ̀jẹ̀ Iyebíye” Ni Ọlọ́run Fi Dá Wa Nídè

Ọ̀NÀ tó ga jù lọ tí Jèhófà gbà fi ìfẹ́ hàn ni rírán tó rán Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo wá sórí ilẹ̀ ayé kí Ọmọ rẹ̀ yìí lè di ẹ̀dá èèyàn pípé kí ó sì wá fi ẹ̀mí rẹ̀ ṣe ìràpadà fún wa. Àwa ẹ̀dá ẹlẹ́ṣẹ̀ nílò ìràpadà náà gan-an ká bàa lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀, nítorí pé kò sí ẹ̀dá aláìpé kankan “tí ó lè tún arákùnrin kan pàápàá rà padà ní ọ̀nà èyíkéyìí, tàbí kí ó fún Ọlọ́run ní ìràpadà nítorí rẹ̀ . . . tí yóò ṣì fi wà láàyè títí láé.” (Sáàmù 49:6-9) A mà dúpẹ́ o pé Ọlọ́run “fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun”!—Jòhánù 3:16.

Báwo ni ìràpadà ṣe lè dá wa nídè? Ẹ jẹ́ ká wo ọ̀nà mẹ́rin tí ìràpadà tó jẹ́ ìfẹ́ ńláǹlà tí Jèhófà Ọlọ́run fi hàn sí wa yìí lè gbà sọ wá dòmìnira.

Ìtúsílẹ̀ Nípasẹ̀ Ìràpadà

Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ẹbọ Jésù lè dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ tá a ti jogún. Inú ẹ̀ṣẹ̀ ni wọ́n bí gbogbo wa sí. Bẹ́ẹ̀ ni o, àní kó tó di pé a bẹ̀rẹ̀ sí rú òfin Jèhófà rárá la ti jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀? Róòmù 5:12 sọ pé: ‘Ẹ̀ṣẹ̀ tipasẹ̀ ènìyàn kan [Ádámù] wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀.’ Àwa àtọmọdọ́mọ Ádámù ẹlẹ́ṣẹ̀ ti jogún àìpé lọ́dọ̀ rẹ̀. Àmọ́, níwọ̀n bí Ọlọ́run ti bá wa san ìràpadà, ó ti wá ṣeé ṣe fún wa báyìí láti dòmìnira kúrò lọ́wọ́ ìgbèkùn ẹ̀ṣẹ̀ àjogúnbá yìí. (Róòmù 5:16) Jésù “tọ́ ikú wò fún olúkúlùkù ènìyàn,” tó túmọ̀ sí pé ó jẹ ìyà ẹ̀ṣẹ̀ tó tọ́ sí àwa àtọmọdọ́mọ Ádámù.—Hébérù 2:9; 2 Kọ́ríńtì 5:21; 1 Pétérù 2:24.

Èkejì, ìràpadà lè tú wa sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àwọn ohun ìbànújẹ́ tí ẹ̀ṣẹ̀ ń fà. “Owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú.” (Róòmù 6:23) Ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀. Ṣùgbọ́n ikú tí Ọmọ Ọlọ́run kú láti fi ara rẹ̀ rúbọ ló jẹ́ kí ìyè ayérayé ṣeé ṣe fún àwọn èèyàn onígbọràn. Bíbélì sọ pé: “Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ ní ìyè àìnípẹ̀kun; ẹni tí ó bá ń ṣàìgbọràn sí Ọmọ kì yóò rí ìyè.”—Jòhánù 3:36.

Ṣàkíyèsí pé tá a bá gba Ọmọ Ọlọ́run gbọ́ nìkan la máa tó lè rí ìdáǹdè lọ́wọ́ àwọn ohun ìbànújẹ́ tí ẹ̀ṣẹ̀ ń fà. Lára ohun tí èyí ń béèrè ni pé ká ṣe àwọn àyípadà tó yẹ nígbèésí ayé wa, ká sì rí i pé à ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. A gbọ́dọ̀ jáwọ́ nínú gbogbo ohun àìtọ́ tá a bá ń ṣe, ká sì rí i pé ohun tó tọ́ lójú Ọlọ́run là ń ṣe. Àpọ́sítélì Pétérù sọ pé a ní láti ‘ronú pìwà dà, kí a sì yí padà, kí a lè pa àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa rẹ́.’—Ìṣe 3:19.

Ẹ̀kẹta, ẹbọ ìràpadà Jésù kò ní jẹ́ kí ẹ̀rí ọkàn máa dá wa lẹ́bi. Gbogbo àwọn tó bá ti ya ara wọn sí mímọ́ sí Jèhófà tí wọ́n sì ti di ọmọlẹ́yìn Jésù tó ti ṣèrìbọmi máa ń rí ìtura. (Mátíù 11:28-30) Bí a tiẹ̀ jẹ́ aláìpé, inú wa ń dùn gan-an nítorí pé ẹ̀rí ọkàn mímọ́ la fi ń sin Ọlọ́run. (1 Tímótì 3:9; 1 Pétérù 3:21) Tí a bá jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa tá a sì jáwọ́ nínú wọn, Ọlọ́run yóò darí jì wá, ẹ̀rí ọkàn wa ò sì ní máa nà wá ní pàṣán mọ́.—Òwe 28:13.

Ìràpadà Ń Ràn Wá Lọ́wọ́ Ó sì Ń Fún Wa Ní Ìrètí

Paríparí rẹ̀, tá a bá ní ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà náà, a ò ní máa bẹ̀rù pé bóyá ni Ọlọ́run ń fojú rere wò wá. Àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá dá ẹ̀ṣẹ̀, àwa ní olùrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ Baba, Jésù Kristi.” (1 Jòhánù 2:1) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa bí Jésù ṣe jẹ́ olùrànlọ́wọ́, ó ní: “Ó lè gba àwọn tí ń tọ Ọlọ́run wá nípasẹ̀ rẹ̀ là pátápátá pẹ̀lú, nítorí tí òun wà láàyè nígbà gbogbo láti jírẹ̀ẹ́bẹ̀ fún wọn.” (Hébérù 7:25) Bí a bá ṣì wà lábẹ́ ìgbèkùn ẹ̀ṣẹ̀, kò sí bí a kò ṣe ní nílò ìrànlọ́wọ́ Jésù Kristi tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà, kí ó lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè rí ojú rere Ọlọ́run. Báwo ni Jésù ṣe ń ṣiṣẹ́ àlùfáà àgbà fún wa?

Ní ogójì ọjọ́ lẹ́yìn tí Jésù jíǹde ní ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, ó gòkè re ọ̀run, ó sì fún Ọlọ́run ní ìtóye “ẹ̀jẹ̀ iyebíye” rẹ̀. Ohun tí Jésù ṣe yìí ni yóò mú kí gbogbo èèyàn onígbọràn bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú láìpẹ́.a (1 Pétérù 1:18, 19) Tó bá wá rí bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ kò yẹ ká nífẹ̀ẹ́ Jésù ká sì máa ṣègbọràn sí i?

Bákan náà, ó yẹ ká nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run ká sì máa ṣègbọràn sí i. Ọlọ́run fi tìfẹ́tìfẹ́ mú ká rí “ìtúsílẹ̀ nípasẹ̀ ìràpadà.” (1 Kọ́ríńtì 1:30) Agbára rẹ̀ la fi wà láàyè lónìí. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, òun ló tún lè jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti gbádùn ìyè ayérayé lọ́jọ́ iwájú. Nítorí náà, a gbọ́dọ̀ rí i pé à ń “ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.”—Ìṣe 5:29.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo oṣù March àti April nínú kàlẹ́ńdà àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ọdún 2006.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

ǸJẸ́ O MỌ̀?

• Pé orí Òkè Ólífì ni Jésù ti gòkè re ọ̀run.—Ìṣe 1:9, 12.

• Pé àwọn àpọ́sítélì Jésù tó jẹ́ olóòótọ́ nìkan ló rí i nígbà tó ń gòkè lọ.—Ìṣe 1:2, 11-13.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́