ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 10/1 ojú ìwé 4-7
  • Bawo Ni Suuru Ọlọrun Yoo Ti Pẹ́ Tó?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Bawo Ni Suuru Ọlọrun Yoo Ti Pẹ́ Tó?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Eeṣe Ti Ọlọrun Fi Mú Suuru Tóbẹ́ẹ̀?
  • Apẹẹrẹ Kan Nipa Suuru Ọlọrun
  • Idi Ti Ọlọrun Fi Mú Suuru Nisinsinyi
  • Ariyanjiyan Nipa Ijọba
  • Janfaani Nisinsinyi Lati Inu Suuru Ọlọrun
  • Ko Ni Pẹ́ Mọ́!
  • Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Sùúrù Jèhófà Àti Jésù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2012
  • Ẹ Máa Mú Sùúrù Bíi Ti Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Ẹ Máa Ní Sùúrù
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • Ìwọ Ha Lè Ṣe Sùúrù Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 10/1 ojú ìwé 4-7

Bawo Ni Suuru Ọlọrun Yoo Ti Pẹ́ Tó?

NI NǸKAN bii 3,000 ọdun sẹhin, ọkunrin ọlọgbọn kan kọwe pe: “Ẹnikan nṣe olori ẹnikeji fun ifarapa rẹ̀.” (Oniwaasu 8:9) Lati igba ti o ti ṣe akiyesi yẹn, ipo awọn nǹkan kò tii gbé pẹ́ẹ́lí sii. Jalẹjalẹ itan, awọn ẹnikọọkan tabi awujọ ti fipa gba iṣakoso, ọkan tẹle omiran, ni jíjẹ gàba ati kiko awọn eniyan miiran nifa. Jehofa Ọlọrun ti fara da eyi pẹlu suuru.

Jehofa ti mú suuru nigba ti awọn ijọba nmu ki araadọta ọkẹ pade iku wọn loju ogun ti wọn sì faaye gba aiṣedajọ ododo ti o burú jáì ninu ọrọ aje. Lonii, oun ṣì ńmú suuru sibẹ gẹgẹ bi awọn eniyan ti npa ibori afẹfẹ ozone run ti wọn si nsọ ayika ati okun di eléèérí. Bawo ni o gbọdọ ti dun un tó lati ri iparun ilẹ amesojade didara ati iparun igbo ẹgàn ati awọn ẹranko lọna wọ̀ǹdùrùkù!

Eeṣe Ti Ọlọrun Fi Mú Suuru Tóbẹ́ẹ̀?

Apejuwe rirọrun kan le ran wa lọwọ lati dahun ibeere yii. Gbe ipa ti eyi yoo ni lori iṣẹ aje kan yẹwo nigba ti ẹnikan ti a gbà siṣẹ bá nba a lọ lati maa pẹ́ lẹhin dé ibi iṣẹ. Ki ni oniṣẹ naa nilati ṣe? Idajọ ododo pọ́n-ńbélé le beere pe ki ó lé ẹni-a-gbà-síṣẹ́ naa lọ ni kiakia. Ṣugbọn oun lè ranti owe Bibeli naa pe “Ẹni ti o bá lọra ati binu, o ni imọ pupọ; ṣugbọn ẹni ti o bá yara binu o gbé were leke.” (Owe 14:29) Iwọnyi le mu ki o duro ṣaaju ki o tó gbegbeesẹ. O le pinnu lati yọnda akoko fun kikọ oṣiṣẹ titun lẹkọọ ki iṣẹ aje naa ma baa di eyi ti a tubọ ṣediwọ fun.

Imọlara fun ẹnikeji tun le mu ki o duro. Ki ni nipa kikilọ fun ẹni-a-gbà-síṣẹ́ ti nfọwọ yẹpẹrẹ muṣẹ naa lati ri bi oun yoo ba tun iwa rẹ ṣe? Eeṣe ti oun ko ba a sọrọ lati rii boya pipẹlẹhin rẹ̀ ti o ti sọ daṣa ni iṣoro kan ti o ṣee yanju tabi iwa buburu kan ti ko ṣee gbà kuro ṣokunfa? Nigba ti ẹni tí ó ni iṣẹ aje naa le pinnu lati mu suuru, bi o ti wu ki o ri, suuru rẹ̀ ki yoo jẹ eyi ti ko láàlà. Ẹni-a-gbà-síṣẹ́ naa yoo nilati tun iwa rẹ ṣe tabi ki o faramọ ki a lé oun lọ. Iyẹn yoo dara fun iṣẹ aje naa funraarẹ ati fun awọn ẹni-a-gbà-síṣẹ́ ti wọn ntẹle ilana.

Ni ọna ti o fara jọ eyi, Jehofa Ọlọrun nmu suuru loju iwa aitọ ki ó baa le yọnda akoko fun wiwa ojutuu ti o ba idajọ ododo mu si awọn iṣoro kan ni pato. Siwaju sii, suuru rẹ̀ fún awọn oluṣe buburu ni anfaani lati yi ọna wọn pada ki wọn si jere anfaani ayeraye. Fun idi yii, Bibeli fun wa niṣiiri lati maṣe jẹ alailayọ pẹlu suuru Ọlọrun. Kaka bẹẹ, o wi pe: “Ki ẹ . . . maa ka a si pe, suuru Oluwa wa igbala ni.”—2 Peteru 3:15.

Apẹẹrẹ Kan Nipa Suuru Ọlọrun

Jehofa Ọlọrun mu suuru ṣaaju Ikun omi nla ti ọjọ Noa. Aye akoko yẹn kún fun iwa ipa o si buru gidigidi. A kà pe: “Ọlọrun [“Jehofa,” New World Translation] sì ri i pe iwa buburu eniyan di pupọ ni aye, . . . Oluwa [“Jehofa,” NW] si wi pe, Emi yoo pa eniyan ti mo ti dá run kuro ni ori ilẹ.” (Jẹnẹsisi 6:5, 7) Bẹẹni, Jehofa ní ojutuu ikẹhin lọkan si iṣoro iwa buburu nigba naa lọhun-un: imukuro awọn eniyan buburu. Ṣugbọn oun ko gbegbeesẹ lẹsẹkẹsẹ. Eeṣe ti ko fi ṣe bẹẹ?

Nitori pe kii ṣe gbogbo eniyan ni o buru. Noa ati idile rẹ̀ jẹ olododo ni oju Ọlọrun. Nitori naa nititori wọn, Jehofa duro pẹlu suuru lati yọnda awọn eniyan olododo diẹ lati murasilẹ fun igbala. Siwaju sii, iduro pẹ́ yẹn fún Noa ni anfaani lati jẹ “oniwaasu ododo,” ni fifun awọn eniyan buburu wọnni ni anfaani lati yi ọna wọn pada. Bibeli wi pe: “Suuru Ọlọrun duro pẹ́ ni saa kan ni ọjọ Noa, nigba ti wọn fi ńkàn ọkọ̀ ninu eyi ti a gba ọkan diẹ là nipa omi, eyiini ni ẹni mẹjọ.”—2 Peteru 2:5; 1 Peteru 3:20.

Idi Ti Ọlọrun Fi Mú Suuru Nisinsinyi

Lonii, ipo naa farajọra. Aye lẹẹkan sii kun fun iwa ipa. Gẹgẹ bi o ti ri ni ọjọ Noa, Ọlọrun ti ṣedajọ aye yii ná, eyi ti, Bibeli wi pe, a “fi pamọ de ọjọ idajọ ati iparun awọn eniyan alaiwa-bi-Ọlọrun.” (2 Peteru 3:7, NW) Nigba ti iyẹn ba ṣẹlẹ, ko ni si pipa ayika run, níni awọn alailera lara, tabi ilokulo agbara lọna iwọra mọ.

Eeṣe, nigba naa, ti Ọlọrun ko fi tii pa awọn eniyan alaiwa-bi-Ọlọrun run tipẹtipẹ sẹhin? Nitori pe awọn ariyanjiyan wa lati yanju ati awọn ọran pataki lati ṣeto. Nitootọ, Jehofa ntẹsiwaju lọ siha ojutuu wiwa pẹtiti kan si iṣoro iwa buburu ti o ni ọpọlọpọ nǹkan ninu, papọ pẹlu gbigba awọn eniyan ọlọkan rere là kuro ninu oko ẹru aisan ati iku.

Pẹlu abajade ti a sọ kẹhin yii ní ọkàn, Jehofa pete lati pese Olugbala kan ti yoo fi araarẹ rubọ fun ẹṣẹ wa. Nipa rẹ, Bibeli wi pe: “Ọlọrun fẹ araye tóbẹ́ẹ̀ gẹẹ, ti o fi Ọmọ bibi rẹ̀ kanṣoṣo funni, ki ẹnikẹni ti o ba gba a gbọ ma baa ṣegbe, ṣugbọn ki o le ni iye ainipẹkun.” (Johanu 3:16) O gba ẹgbẹẹgbẹrun ọdun lati mura ọna silẹ fun Jesu lati wá ki o si fi ẹmi rẹ̀ rubọ nititori araye. Ni gbogbo ọdun wọnni, Ọlọrun fi tifẹtifẹ mu suuru. Ṣugbọn iru ipese kan bẹẹ ko ha yẹ ni diduro fun bi?

Jesu pese irapada naa fun araye ni nǹkan ti o sunmọ ẹgbẹrun ọdun meji sẹhin. Eeṣe, nigba naa, ti Ọlọrun ṣì ńmú suuru sibẹ? Idi kan niyii, iku Jesu sami si ibẹrẹ igbetaasi ikọnilẹkọọ kan. Araye nilati kọ́ nipa ipese onifẹẹ yii ki a si fun wọn ni anfaani lati tẹwọgba a tabi ṣá a tì. Iyẹn yoo gba akoko, ṣugbọn yoo jẹ akoko ti a lò lọna rere. Bibeli wi pe: “Oluwa [“Jehofa,” NW] ko fi ileri rẹ̀ jafara, bi awọn ẹlomiran tii ka ijafara; ṣugbọn o nmu suuru fun yin nitori ko fẹ ki ẹnikẹni ki o ṣègbé, bikoṣe ki gbogbo eniyan ki o wa si ironupiwada.”—2 Peteru 3:9.

Ariyanjiyan Nipa Ijọba

Ọran pataki miiran yoo gba akoko pẹlu. Aini wà lati yanju iṣoro ijọba araye. Ni ibẹrẹ, eniyan wà labẹ ijọba atọrunwa. Ṣugbọn ninu ọgba Edeni, awọn obi wa akọkọ yí ẹhin wọn pada si iyẹn. Wọn yàn lati wà lominira laisi Ọlọrun, ni fifẹ lati ṣakoso araawọn. (Jẹnẹsisi 3:1-5) Bi o ti wu ki o ri, niti gidi, eniyan ni a ko dá lati ṣakoso araarẹ. Wolii Jeremaya kọwe pe: “Oluwa [“Jehofa,” NW], emi mọ pe, ọna eniyan ko si ni ipa ara rẹ: ko si ni ipa eniyan ti ńrìn, lati tọ iṣisẹ rẹ̀.”—Jeremaya 10:23; Owe 20:24.

Sibẹ, niwọn bi o ti jẹ pe ariyanjiyan ijọba ni a gbé dide, Jehofa ti fi suuru yọnda akoko lati yanju rẹ̀. Nitootọ, oun ti fi ọlawọ yọnda ẹgbẹẹgbẹrun ọdun fun araye lati gbiyanju gbogbo oniruuru ijọba ti wọn le rò. Pẹlu abajade wo? O ti han kedere pe ko si ijọba eniyan kankan ti o le mu inira, aidọgba, tabi awọn okunfa ailayọ miiran kuro.

Nitootọ, ni oju iwoye itan eniyan, ẹnikan ha le sọ pe Ọlọrun ko ṣẹtọ nigba ti o polongo ero rẹ lati mu gbogbo ijọba eniyan kuro ki o si fi ọkan ti o jẹ tirẹ rọpo wọn? Dajudaju bẹẹkọ! O daju pe a fi tayọtayọ tẹwọgba imuṣẹ asọtẹlẹ Bibeli yii pe: “Ni ọjọ awọn ọba wọnyi ni Ọlọrun ọrun yoo gbe ijọba kan kalẹ, eyi ti a ki yoo le parun titilae: a ki yoo si fi ijọba naa le orilẹ-ede miiran lọwọ, yoo si fọ gbogbo ijọba wọnyi túútúú, yoo si pa wọn run; ṣugbọn oun yoo duro titi laelae.”—Daniẹli 2:44.

Ọba ọrun ti Ijọba yẹn ni Jesu ti a ti jí dide. Mimura rẹ̀ silẹ fun ipo yẹn—pẹlu yiyan awọn eniyan lati jẹ́ alajumọ ṣakoso pẹlu rẹ̀—ti gba akoko. Laaarin gbogbo akoko yẹn, Ọlọrun ti mu suuru.

Janfaani Nisinsinyi Lati Inu Suuru Ọlọrun

Lonii, araadọta ọkẹ awọn eniyan ní ó kere tan ilẹ 212 njafaani lati inu suuru Ọlọrun. Wọn ti sopọṣọkan ninu ifẹ wọn lati ṣegbọran si Ọlọrun ki wọn si ṣiṣẹsin ijọba rẹ ti ọrun. Nigba ti wọn ba pade papọ ninu Gbọngan Ijọba wọn, wọn nkẹkọọ bi o ti jẹ ohun ti o daraju tó lati fi awọn ilana Bibeli silo ninu igbesi-aye wọn. Wọn ko ṣajọpin ninu oṣelu apinniniya ti aye yii, bi o tilẹ jẹ pe wọn fi araawọn sabẹ awọn ijọba eniyan niwọn igba ti Ọlọrun ba fi suuru yọnda awọn wọnyi lati maa wà.—Matiu 22:21; Roomu 13:1-5.

Iru ifọwọsowọpọ bẹẹ laaarin ọpọ eniyan tóbẹ́ẹ̀ dá Jehofa lare gẹgẹ bi Ẹni naa ti o le mu iṣọkan wà laaarin awọn eniyan olominira ifẹ inu ti wọn nkẹkọọ lati nifẹẹ rẹ̀ ti wọn si fẹ lati ṣiṣẹsin in. Laiṣiyemeji iwọ ti pade awọn wọnyi gẹgẹ bi wọn ti nba iṣẹ kan naa ti Jesu funraarẹ bẹrẹ lọ, iyẹn ni ti wiwaasu ihinrere Ijọba Ọlọrun. Jesu sọ otente opin iṣẹ yii nigba ti o wi pe: “A o si waasu ihinrere Ijọba yii ni gbogbo aye lati ṣe ẹ̀rí fun gbogbo orilẹ-ede; nigba naa ni opin yoo si dé.”—Matiu 24:14.

Ko Ni Pẹ́ Mọ́!

Ami ti o ṣee fojuri fihan pe awọn iṣeto Ọlọrun fun Ijọba ododo lati gba iṣakoso ọjọ de ọjọ lori ilẹ-aye ti fẹrẹẹ pari. Lẹhin ṣiṣapejuwe iyọrisi buburu jai ti ikuna ijọba eniyan ti a ti rí ni ọrundun yii, Jesu wi pe: “Nigba ti ẹyin ba ri nǹkan wọnyi ti nṣẹ, ki ẹyin ki o mọ̀ pe, ijọba Ọlọrun kù si dẹ̀dẹ̀.”—Luuku 21:10, 11, 31.

Laipẹ, Ọlọrun yoo mu awọn ẹni buburu kuro loju iran ilẹ-aye. Awọn ọrọ onisaamu naa yoo ṣee fisilo niti gidi pe: “A o ké awọn oluṣe buburu kuro . . . Nigba diẹ, awọn eniyan buburu ki yoo sí: nitootọ iwọ yoo fi ara balẹ wo ipo rẹ̀, ki yoo sì sí.” (Saamu 37:9, 10) Iwọ ha le foju inu wo aye kan laisi iwa buburu? Ta ni yoo bojuto awọn nǹkan nigba naa? Bibeli wi pe: “Kiyesi i, ọba kan [Kristi Jesu ti a gbe gori itẹ ninu awọn ọrun] yoo jẹ ni ododo, awọn olori [awọn aduroṣiṣin rẹ ti a yan lori ilẹ-aye] yoo fi ẹtọ ṣe akoso. Iṣẹ ododo yoo sì jẹ́ alaafia, ati eso ododo yoo jẹ́ idakẹjẹẹ oun aabo titi lae. Awọn eniyan mi yoo si maa gbe ibugbe alaafia, ati ni ibugbe idaniloju, ati ni ibi isinmi ìparọ́rọ́.”—Aisaya 32:1, 17, 18.

Nipa bayii, ijọba Ọlọrun ti ọrun yoo mu awọn iyọrisi buburu ti aṣiṣe eniyan kuro yoo si ṣeto awọn wọnni ti wọn nireti ninu Rẹ si awujọ eniyan ti o wà ni iṣọkan. Ni ṣiṣapejuwe iṣọkan yii, Bibeli wi pe: “Nitootọ ni ikooko yoo gbe pọ fun igba diẹ pẹlu akọ ọdọ agutan, ati pẹlu ọmọ ewurẹ ni ẹkun funraarẹ yoo dubulẹ, ati ọmọ maluu ati ẹgbọrọ kinniun onígọ̀gọ̀ ati ẹran abọpa gbogbo wọn lapapọ; ọmọkunrin kekere kan lasan yoo si jẹ oludari wọn . . . Wọn ki yoo ṣe ipalara kankan tabi ṣokunfa iparun kankan ni gbogbo oke mimọ mi; nitori pe dajudaju ilẹ-aye yoo kun fun imọ Jehofa gẹgẹ bi omi ti nbo okun gan an.”—Aisaya 11:6-9, NW.

Ẹ wo abajade titobilọla ti eyi jẹ lati inu lílò ti Ọlọrun lo suuru! Fun idi yii, dipo rirahun pe Ọlọrun ti duro pẹ́ jù, eeṣe ti o ko fi lo anfaani suuru rẹ̀ lati mu araarẹ wá sabẹ Ijọba rẹ̀? Kẹkọọ lati inu Bibeli ohun ti awọn ọpa idiwọn rẹ̀ jẹ́ ki o si ṣegbọran si wọn. Kẹgbẹ pẹlu awọn miiran ti wọn fi iṣọkan jẹ ọmọ abẹ rẹ̀. Nigba naa, suuru Ọlọrun yoo yọrisi awọn ibukun ainipẹkun fun ọ.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́