ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 10/15 ojú ìwé 25-28
  • Yíyá Awọn Kristẹni Ẹlẹgbẹ wa Lówó

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Yíyá Awọn Kristẹni Ẹlẹgbẹ wa Lówó
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣiṣiro Iye Ti Owo Yiya Yoo Náni
  • ‘Sisọ Otitọ’ fun Awọn Ayanilowo
  • Fifi Ofin Oniwura Silo Ninu Iṣẹ́-ajé
  • Awọn Ayanilowo Oniṣọọra
  • Ìkùnà
  • Ó Ha Yẹ Kí N Yáwó Lọ́wọ́ Arákùnrin Mi Bí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Yíyá Àwọn Ọ̀rẹ́ Lówó àti Yíyáwó Lọ́wọ́ Wọn
    Jí!—1999
  • Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kí N Yá Owó?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 10/15 ojú ìwé 25-28

Yíyá Awọn Kristẹni Ẹlẹgbẹ wa Lówó

PEDRO ati Carlos jẹ ọrẹ kòríkòsùn.a Wọn jumọ jẹ Kristẹni, idile ẹnikọọkan wọn sì maa ngbadun ibakẹgbẹ ọlọyaya pẹlu araawọn. Nitori naa nigba ti Carlos nilo owo diẹ fun iṣẹ aje rẹ̀, Pedro ko lọ́tìkọ̀ lati fẹ ya a. “Niwọn bi a ti jẹ ọrẹ kòríkòsùn,” ni Pedro ṣalaye, “emi ko bikita.”

Bi o ti wu ki o ri, ni ohun ti kò ju oṣu meji lọ lẹhin naa, iṣẹ aje Carlos foriṣanpọn, awọn isanpada owo sì dawọduro. Pedro wá mọ̀ si iyalẹnu rẹ̀ pe Carlos ti lo ọpọjulọ lara owo naa ti o ti yá lati fi san awọn gbese ti ko jẹmọ iṣẹ-ajé pada ati lati gbọ́ bùkátà aṣa igbesi-aye onifaaji kan. Ọran naa ni a ko yanju si itẹlọrun Pedro ani lẹhin awọn ibẹwo ati lẹta kikọ fun ọdun kan paapaa. Lati inu ijakulẹ, Pedro lọ sọdọ awọn alaṣẹ ti o si jẹ ki Carlos—ti o jẹ ọrẹ ati arakunrin rẹ̀—di ẹni ti a tì mọ́lé.b Eyi ha jẹ ipa ọna bibojumu lati gbà bi? Awa yoo rii.

Awọn aifohunṣọkan ati edekoyede lori owo ti a fi yani jẹ́ okunfa ti ńba ipo ọrẹ jẹ́ lemọlemọ laaarin awọn eniyan yika aye. Nigba miiran o tilẹ le jẹ okunfa ainirẹẹpọ laaarin awọn ti wọn jẹ́ Kristẹni paapaa. Ni ọpọlọpọ ilẹ ó ṣoro lati ri ẹ̀yáwó banki gbà, nitori naa o wọpọ fun awọn eniyan ti wọn wà ninu aini ọ̀ràn inawo lati tọ awọn ọrẹ ati ibatan lọ. Bi o ti wu ki o ri, iriri abanininujẹ ti Pedro ati Carlos fihan pe ayafi bi ẹni ti a yalowo ati ẹni ti o yanilowo bá tẹle awọn ilana Bibeli, awọn iṣoro wiwuwo lè dide. Nigba naa, ki ni ọna ti o bojumu lati gbà bojuto ibeere fun ẹ̀yáwó fun Kristẹni ẹlẹgbẹ ẹni kan?

Ṣiṣiro Iye Ti Owo Yiya Yoo Náni

Bibeli kò fun yiyawo lainidii niṣiiri. ‘Ẹ maṣe jẹ ẹnikẹni ni gbese ohun kan, bikoṣe pe ki ẹ fẹran ọmọnikeji yin,’ ni apọsiteli Pọọlu gbaniniyanju. (Roomu 13:8) Nitori naa ṣaaju kikowọnu gbese, ṣiro iye ti yoo ná ọ fun ṣiṣe bẹẹ. (Fiwe Luuku 14:28.) Aini fun owo yiya niti gidi ha wà bi? O ha jẹ ọran bibojuto ọna atijẹ rẹ ki o baa lè bojuto idile rẹ ni bi? (1 Timoti 5:8) Tabi iwa iwọra kan ha wé mọ—boya ifẹ lati gbe igbesi-aye ti o tubọ ṣe gbẹdẹmukẹ sii?—1 Timoti 6:9, 10.

Koko pataki miiran ni boya kikowọnu gbese yoo fipa mu ọ lati ṣiṣẹ fun wakati gigun sii ati boya ki o pa awọn ipade ati iṣẹ-isin pápá tì. Pẹlupẹlu, agbara rẹ ha gbe e niti gidi lati fi owo ẹlomiran wewu bi? Ki ni bi iṣẹ aje tabi ohun àdáwọ́lé naa ba foriṣanpọn? Ranti, “awọn eniyan buburu wín, wọn ko si pada san.”—Saamu 37:21.

‘Sisọ Otitọ’ fun Awọn Ayanilowo

Lẹhin gbigbe awọn koko bẹẹ yẹwo, sibẹ iwọ lè nimọlara pe ẹ̀yáwó fun iṣẹ aje kan pọndandan. Bi iwọ kò bá lè ri i gba nipasẹ ọna ìdákalẹ̀ ti aye, ko fi dandan ṣaitọ lati tọ Kristẹni ẹlẹgbẹ ẹni kan lọ, nitori ó wọpọ lati yijusi awọn ọrẹ lakooko aini, gẹgẹ bi Jesu ṣe sọ ni Luuku 11:5. Sibẹ ẹnikan gbọdọ rọju “sọ otitọ.” (Efesu 4:25) Ṣalaye gbogbo otitọ ti o wémọ́ ọn lọna ailabosi—papọ pẹlu awọn ewu ti ó ṣeeṣe, ani awọn wọnni ti wọn lè dabi eyi ti ko tanmọ́ ọn paapaa. Ma sì ṣe gbà á sí ibinu bi ẹni ti o ṣeeṣe ki o di ayanilowo naa ba beere ọgọọrọ awọn ibeere ṣàkó kí ó baa lè da a loju pe oun loye ipo naa lọna pipeye.c

Yoo ha jẹ sisọ otitọ lati yawo fun ete kan ati lẹhin naa ki a lo owo àkànlò naa fun ohun miiran bi? Kii ṣe bẹẹ niti gidi. Oniṣowo banki ara Latin America kan ṣalaye pe: “Banki kan yoo fagile gbese ti o jẹ, bi iwọ ko ba si san gbese rẹ lọgan, wọn yoo gba aṣẹ ile ẹjọ lati fipa gba awọn ohun ìní rẹ.” Bi a ba ya owo ni ero wi pe yoo mu ere iṣẹ aje kan pọ sii, lati lò ó fun ete miiran nitootọ yoo mu ki ayanilowo naa ṣaini idaniloju pe owo ti a yá naa ni a le san pada. Nitootọ, iwọ lè má bẹru igbẹsan ti ofin nigba ti o ba yawo lọwọ Kristẹni ẹlẹgbẹ rẹ kan. Laika eyiini sí, “ayáwó ni iranṣẹ ẹni naa ti nyanilowo,” iwọ sì ni ẹru-iṣẹ lati jẹ alailabosi pẹlu rẹ̀.—Owe 22:7, NW.

Fifi Ofin Oniwura Silo Ninu Iṣẹ́-ajé

Jesu wi pe: “Nitori naa gbogbo ohunkohun ti ẹyin ba nfẹ ki eniyan ki o ṣe si yin, bẹẹ ni ki ẹyin ki o sì ṣe si wọn gẹgẹ.” (Matiu 7:12) Ẹ wò bi o ti ṣe pataki tó pe ki ofin yii bori nigba ti a ba nṣe iṣẹ aje pẹlu onigbagbọ ẹlẹgbẹ ẹni kan! Fun apẹẹrẹ, bawo ni iwọ yoo ṣe huwapada bi arakunrin kan ba yẹ ibeere rẹ fun ẹ̀yáwó silẹ? Iwọ yoo ha nimọlara pe ó jẹ alaiduroṣinṣin si ipo ọrẹ yin? Tabi iwọ yoo ha bọwọ fun ẹtọ rẹ lati kọ ibeere rẹ silẹ, ni mimọ pe oun pẹlu lè nilo awọn owo akanlo rẹ̀ tabi le ṣayẹwo awọn ewu gẹgẹ bi eyi ti o tubọ wuwo ju bi iwọ ti ṣe lọ? Oun le fi ailabosi gbe ibeere dide si agbara rẹ lati bojuto owo akanlo naa lọna gbigbeṣẹ. Ninu iru ọran kan bẹẹ, kikọ rẹ̀ lè jẹ́ eyi ti o bọgbọnmu ati onifẹẹ.—Owe 27:6.

Bi ọrẹ kan ba gbà lati yá ọ ni owo diẹ, awọn kulẹkulẹ ni a nilati kọ silẹ ketekete, papọ pẹlu iye ti a ti yá, ohun ti a o lo owo naa fun, awọn ohun wo ni a fi duro bi aabo fun owo ti a fi yani naa, bawo ati nigba wo ni a o san an pada. Ninu awọn ọran diẹ o tilẹ mọ́gbọ́ndání lati jẹ ki agbẹjọro kan ṣakọsilẹ tabi bojuto adehun naa ki o si fi pamọ sọdọ awọn alaṣẹ. Ohun yoowu ki o lè ṣẹlẹ, gbàrà ti a ba ti fọwọ si iwe adehun kan, “jẹ ki ọrọ yin jẹ Bẹẹni, bẹẹni; Bẹẹkọ, bẹẹkọ.” (Matiu 5:37) Maṣe ṣi anfaani inurere ọrẹ rẹ lò nipa kikuna lati fi ọwọ pataki mu aigbọdọmaṣe rẹ si i gẹgẹ bi iwọ yoo ti ṣe si banki kan.

Awọn Ayanilowo Oniṣọọra

Ki ni bi a ba tọ ọ wa fun ẹ̀yáwó kan? Ọpọjulọ yoo sinmi lori awọn ipo ti o we mọ ọn. Fun apẹẹrẹ, arakunrin Kristẹni kan le ṣubu sinu òfò ọrọ aje, nipasẹ ẹbi ti kii ṣe tirẹ funraarẹ. Bi iwọ ba ni ohun ìní lati ṣe bẹẹ, ifẹ Kristẹni yoo sun ọ lati ‘fun un ni ohun ti ara rẹ̀ nfẹ.’—Jakọbu 2:15, 16.

Ẹ wò bi yoo ti jẹ ainifẹẹ tó lati janfaani lati inu ipọnju arakunrin kan nipa bibu èlé lé e ninu iru ọran kan bẹẹ! Jesu rọni pe: “Ẹ maa baa lọ lati nifẹẹ awọn ọta yin ati lati ṣe rere ati lati wínni laisi èlé, ki ẹ má sì reti lati gba ohunkohun pada.”—Luuku 6:35, NW; fiwe Lefitiku 25:35-38.

Bi o ti wu ki o ri, ki ni bi a ba wulẹ sọ fun ọ lati pese owo nina fun ìdágbálé iṣẹ aje kan tabi lati wá ẹ̀yáwó kan gba? Ni gbogbogboo, iru awọn ọran bẹẹ ni a nbojuto ni ọna ti o dara julọ gẹgẹ bi ìfowódókòwò. Bibeli ni kedere parọwa iṣọra, ni gbigbani niyanju pe: “Maṣe wà ninu awọn ti nṣe ìgbọ̀wọ́, tabi ninu awọn ti o duro fun gbese.”—Owe 22:26.

Bi iyẹn ti jẹ bẹẹ, iwọ gbọdọ kọkọ pinnu bi agbara rẹ ba le gbé ìdókòwò naa nitootọ. Yoo ha fa ipadanu ọ̀ràn inawo fun ọ bi iṣẹ aje naa ba foríṣánpọ́n tabi bi ẹni ti o yawo naa ko ba le san ẹ̀yáwó naa pada lakooko? Bi agbara rẹ ba le gbe ẹ̀yáwó naa ti èrè yoo si tibẹ yọ, iwọ tun ni ẹtọ lati ṣajọpin ninu wọn nipa gbigbe èlé ti o bọgbọnmu kari ẹ̀yáwó rẹ. (Fiwe Luuku 19:22, 23.) Owe 14:15 kilọ pe: “Ope eniyan gba ọrọ gbogbo gbọ́: ṣugbọn amoye eniyan wo ọna araarẹ rere.” Awọn oniṣowo kan ti wọn gbọ́nṣáṣá lọna deedee ti huwa laifarabalẹ nigba ti wọn bá nṣe iṣẹ aje pẹlu awọn Kristẹni ẹlẹgbẹ wọn. Ìdẹlọ ti èlé giga ti a o san ti fa awọn kan sinu okòwò alainironu ninu eyi ti wọn ti padanu owo wọn ati ipo ọrẹ wọn pẹlu awọn Kristẹni ẹlẹgbẹ wọn.

Lọna ti o gbadunmọni, awọn oniṣẹ banki ni lemọlemọ ni wọn maa ńgbé awọn koko mẹta yẹwo ninu didiyele bi ẹ̀yáwó kan ti le lewu tó: (1) iwa ẹni naa ti nbeere fun ẹ̀yáwó, (2) agbara rẹ̀ lati sanwo pada, ati (3) awọn ipo ti o gbilẹ ninu ila iṣẹ aje rẹ̀. Ki yoo ha fi “ọgbọn ti o ṣee fisilo” han lati gbe awọn ọran yẹwo bakan naa nigba ti o ba nronu nipa fifi owo tí o fi òógùn oju rẹ rí yá ẹnikan bi?—Owe 3:21, NW.

Fun apẹẹrẹ, ki ni ìfùsì arakunrin naa ti nbeere fun owo naa? A ha mọ ọn si ẹni ti o ṣee fọkantan ti o si ṣee gbarale tabi alaibikita ati alaiduro deedee bi? (Fiwe 1 Timoti 3:7.) Bí ó bá nfẹ lati mu iṣẹ aje rẹ̀ gbooro si, oun ha ti fi aṣeyọri si rere bojuto o titi de ori koko yii bi? (Luuku 16:10) Bi ko ba ri bẹẹ, itilẹhin ti ó bọgbọnmu ninu bibojuto owo rẹ̀ le tubọ ṣeranwọ lẹhin-ọ-rẹhin ju yiya a ni owo ti o le ṣìlò.

Koko miiran yoo jẹ agbara arakunrin naa lati san an pada. Èló ni owo ti nwọle fun un? Gbese wo ni ó jẹ? O wulẹ bọgbọnmu pe ki oun jẹ alaifotitọ pamọ fun ọ. Laika eyiini si, ifẹ Kristẹni gbọdọ bori sibẹ. Fun apẹẹrẹ, iwọ le fẹ lati daabobo ẹ̀yáwó naa pẹlu awọn ohun ìní arakunrin naa ti o ṣee tà gẹgẹ bi ifiduro. Ofin Mose dẹbi fun fifipa gba yálà ọna atijẹ ọkunrin kan tabi awọn ohun ìní rẹ pataki ki a baa le daabobo ẹ̀yáwó kan. (Deutaronomi 24:6, 10-12) Nipa bayii, arakunrin ara South Africa kan ti o jẹ oniṣowo wi pe oun yoo yáni ní kiki idaji owo ohun ìní ifiduro ti o ṣee tà ti arakunrin naa. “Emi kii sii ka awọn ohun eelo iṣẹ rẹ tabi ile rẹ gẹgẹ bi ohun ifiduro ti o ṣee tà kan,” ni o ṣalaye. “Dajudaju emi ki yoo fẹ lati le arakunrin mi jade si oju popo ki nsi fipa gba ile rẹ̀ ki nbaa le ri owo mi gbà pada.”

Nikẹhin, iwọ gbọdọ fi otitọ gidi gbé awọn ipo iṣẹ aje ni gbogbogboo nibi ti o ngbe yẹwo. A ngbe ni “awọn ọjọ ikẹhin,” lakooko eyi ti awọn eniyan jẹ olufẹ owo, . . . onikupani.” (2 Timoti 3:1-4, NW) Nigba ti ọrẹ ati arakunrin rẹ lè jẹ alailabosi, ẹnikeji rẹ̀ ninu iṣẹ aje, awọn ẹni agbasiṣẹ rẹ̀, ati awọn onibaara rẹ̀ le ma jẹ bẹẹ. Gẹgẹ bi Kristẹni kan, oun ko le yiju si fifunni lowo ẹ̀hìn ati píparọ́—awọn ọgbọn ẹwẹ ti awọn abanidije rẹ̀ le lo fun ire wọn. Eyi ti a tun nilati gbeyẹwo ni iparun ti “ìgbà ati èèṣì.” (Oniwaasu 9:11) Iye ọja kan le lọ silẹ lojiji. Ifosoke owo ọja le pa iṣẹ aje kan run tabi pa iye ti ẹ̀yáwó kan tó rẹ́. Ole jija, jàm̀bá, ìjà ìgboro, ati awọn ìṣèṣe jẹ́ otitọ abanininujẹ ti iṣẹ-aje pẹlu. Iwọ nilati gbe gbogbo ìhà wọnyi yẹwo ninu ṣiṣe ipinnu rẹ.

Ìkùnà

Nigba miiran, laika gbogbo iṣọra sí, Kristẹni kan ko wulẹ le san ẹ̀yáwó rẹ pada. Ofin Oniwura naa nilati sun un lati jumọsọrọpọ deedee pẹlu ayanilowo rẹ̀. Boya kiki owo sisan diẹ ni yoo ṣeeṣe fun akoko kan. Laika eyiini sí, Kristẹni kan ko nilati nimọlara pe awọn owo sisan gbà mapoorọwọ mi yọọda rẹ̀ kuro ninu ṣiṣe awọn irubọ gidi lati mu awọn ẹru-iṣẹ rẹ̀ ṣẹ. (Saamu 15:4) Ayanilowo kan ti o jẹ Kristẹni ni a tun mu un pọndandan fun lati fi ifẹ han. Bi ó ba nimọlara pe a ti ba oun lò lọna èrú, oun le fi imọran ti o wà ni Matiu 18:15-17 silo.

Mimu awọn alaṣẹ ti aye wọ̀ ọ́, gẹgẹ bi Pedro ninu ọran ti a mẹnukan ni ibẹrẹ ti ṣe, ni kii figba gbogbo bọgbọnmu. Apọsiteli Pọọlu wi pe: “Ẹnikẹni ninu yin, ti o ni ọran kan si ẹnikeji rẹ̀, ha gbọdọ lọ pe e ni ẹjọ niwaju awọn alaiṣootọ, ki o ma si jẹ niwaju awọn eniyan mimọ? . . . O ha le jẹ bẹẹ pe ko si ọlọgbọn kan ninu yin ti yoo le ṣe idajọ laaarin awọn arakunrin rẹ̀? Ṣugbọn arakunrin npe arakunrin ni ẹjọ, ati eyiini niwaju awọn alaigbagbọ. Njẹ nisinsinyi, abuku ni fun yin patapata pe ẹyin nba araayin ṣe ẹjọ. Eeṣe ti ẹyin ko kuku gba iya? Eeṣe ti ẹyin ko kuku jẹ ki a rẹ yin jẹ?”—1 Kọrinti 6:1-7.

Awọn ipo kan le wà—iru eyi ti o wémọ́ awọn alajọṣiṣẹ alaigbagbọ, olùgbọ́jà fúnni ẹni aye, tabi awọn ọran ìbánigbófò—ti o jọ bi ẹni pe o beere ìyanjú ni ile ẹjọ aye kan tabi nipasẹ aṣoju ijọba. Ṣugbọn ninu ọran ti o wọpọ julọ, Kristẹni kan yoo wulẹ yọọda fun ipadanu ọ̀ràn inawo kan ju ki o fi ijọ sabẹ itiju tí gbigbe arakunrin kan lọ sile ẹjọ lori ẹ̀yáwó ti a ko san yoo mu wa.

Ninu ọpọ julọ awọn ọran iru awọn abajade buburu bẹẹ ni a le yẹra fun. Bawo? Ṣaaju ki ó to yá arakunrin kan lówó tabi ki o tó yawo lọwọ arakunrin kan, mọ awọn ewu ti o ṣeeṣe ki o ṣẹlẹ. Lo iṣọra ati ọgbọn. Ju gbogbo rẹ lọ, ‘ẹ maa jẹ ki gbogbo alaamọri yin,’ papọ pẹlu awọn alaamọri iṣẹ aje, ‘ṣẹlẹ pẹlu ifẹ.’—1 Kọrinti 16:14, NW.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Awọn orukọ naa ni a ti yipada.

b Ni awọn ilẹ kan ìwọkoogbèsè ati kikuna lati san awọn owo ti a yá nyọrisi ifini sinu tubu lọna ti o wọpọ sibẹ.

c Awọn kan ti ya owo kekere lọwọ ọpọlọpọ awọn ayanilowo. Ayanilowo kọọkan, nigba ti wọn ko mọ otitọ nipa gbogbo ipo ti o yi i ká, lè ronu pe ẹni ti o ya owo naa yoo le san án pada pẹlu irọrun.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́