ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w98 11/15 ojú ìwé 24-27
  • Ó Ha Yẹ Kí N Yáwó Lọ́wọ́ Arákùnrin Mi Bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ó Ha Yẹ Kí N Yáwó Lọ́wọ́ Arákùnrin Mi Bí?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Rò Ó Dáadáa
  • Ṣàlàyé Ohun Tí O Fẹ́ Fi Owó Náà Ṣe
  • Ẹ Ṣèwé
  • Ṣọ́ra Nípa Yíyáni Lówó
  • Fọgbọ́n Ṣe É
  • Yíyá Awọn Kristẹni Ẹlẹgbẹ wa Lówó
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • Yíyá Àwọn Ọ̀rẹ́ Lówó àti Yíyáwó Lọ́wọ́ Wọn
    Jí!—1999
  • Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kí N Yá Owó?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
w98 11/15 ojú ìwé 24-27

Ó Ha Yẹ Kí N Yáwó Lọ́wọ́ Arákùnrin Mi Bí?

ÈYÍ tó kéré jù lọ lára àwọn ọmọ Simon ń ṣàìsàn, ó sì yẹ kó tètè lo oògùn. Àmọ́, Simon kúṣẹ̀ẹ́ gan-an, kò sì lówó tó lè fi rà á. Kí ló lè ṣe sí i? Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan tí ń jẹ́ Michael sì rí jájẹ jù ú lọ. Bóyá Michael yóò yá a lówó. Àmọ́, Simon mọ̀ lọ́kàn rẹ̀ pé òun lè máà rówó náà san padà.a

Nígbà tí Simon lọ bá Michael, ọ̀rọ̀ náà di ẹtì sí Michael lọ́rùn. Ó rí i pé Simon nílò owó náà ní ti gidi, àmọ́, ó ronú pé kò ní lè rówó náà san padà nítorí agbára káká ló fi ń bọ́ ìdílé rẹ̀. Kí wá ni kí Michael ṣe?

Ní orílẹ̀-èdè púpọ̀, iṣẹ́ tí àwọn ènìyàn fi ń gbọ́ bùkátà lè bọ́ lọ́wọ́ wọn lọ́sàn-án-kan-òru-kan, kí wọ́n sì di ẹni tí kò lówó tàbí ohun ìbánigbófò láti fi san owó oògùn ìtọ́jú ara. Ó lè máà rí owó yá ní báǹkì, tàbí kí èlé orí rẹ̀ pọ̀ jù. Bí ìṣòro pàjáwìrì bá dé, ó lè jọ pé lílọ yáwó lọ́wọ́ ọ̀rẹ́ kan ni ọ̀nà àbáyọ kan ṣoṣo tó wà. Ṣùgbọ́n, kí o tó lọ yáwó, o ní láti gbé àwọn ọ̀ràn pàtàkì kan yẹ̀ wò.

Rò Ó Dáadáa

Ìwé Mímọ́ pèsè ìtọ́sọ́nà fún ayánilówó àti ẹni tó lọ yáwó. Nípa fífi ìmọ̀ràn yìí sílò, èdèkòyédè àti ìbínú kò ní máa ṣẹlẹ̀.

Fún àpẹẹrẹ, Bíbélì rán wa létí pé kò yẹ kí a fọwọ́ yẹpẹrẹ mú ọ̀ràn owó yíyá. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni tó wà ní Róòmù nímọ̀ràn pé: “Kí ẹ má ṣe máa jẹ ẹnikẹ́ni ní gbèsè ẹyọ ohun kan, àyàfi láti nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì; nítorí ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ̀ ti mú òfin ṣẹ.” (Róòmù 13:8) Ohun tó dára jù lọ ni pé ìfẹ́ nìkan ni kí Kristẹni kan jẹ ẹlòmíràn ní gbèsè rẹ̀. Nítorí náà, a lè kọ́kọ́ bi ara wa léèrè pé, ‘Ǹjẹ́ owó tí mo fẹ́ yá yìí tilẹ̀ pọndandan?’

Bí ìdáhùn wa bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, nígbà náà, ó bọ́gbọ́n mu kí a ronú nípa àwọn ohun tó lè tìdí gbèsè jíjẹ yọ. Jésù Kristi fi hàn pé láti ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì, a ní láti ronú, kí a sì ṣètò tìṣọ́ratìṣọ́ra. Ó bi àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ léèrè pé: “Ta ni nínú yín tí ó fẹ́ kọ́ ilé gogoro kan tí kò ní kọ́kọ́ jókòó, kí ó sì gbéṣirò lé ìnáwó náà, láti rí i bí òun bá ní tó láti parí rẹ̀?” (Lúùkù 14:28) Ìlànà yìí wúlò nígbà tí a bá ń ronú nípa bóyá kí a yáwó lọ́wọ́ arákùnrin kan. Ríro ọ̀ràn owó yíyá dáadáa tún kan ríro bí a óò ṣe rí i san padà àti ìgbà tí a óò san án.

Ayánilówó ní ẹ̀tọ́ láti mọ bí a óò ṣe rí owó náà san padà àti ìgbà tí a óò san án. Tí a bá fìṣọ́ra gbé ọ̀ràn náà yẹ̀ wò, a óò lè fún un ní ìdáhùn tí ó mọ́yán lórí. Ǹjẹ́ a ti ronú dáadáa nipa bí a ó ṣe tètè rí owó náà san padà? Òótọ́ ni pé yóò rọrùn láti wí fún arákùnrin wa pé: “N óò san án padà láìpẹ́ láìjìnnà. Ẹ gbà mí gbọ́.” Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ kò yẹ kí a fọwọ́ tí ó túbọ̀ ṣe pàtàkì mú ọ̀ràn náà? Láti ìbẹ̀rẹ̀ ni a gbọ́dọ̀ ti ní in lọ́kàn pé a óò san owó náà padà, nítorí ohun tí Jèhófà ń fẹ́ kí a ṣe nìyẹn. Sáàmù 37:21 sọ pé: “Ẹni burúkú ń yá nǹkan, kì í sì í san án padà.”

Nípa ríro bí a óò ṣe rí owó náà san padà àti ìgbà tí a óò san án, a ń rán ara wa létí bí àdéhùn tí a ń ṣe ti ṣe pàtàkì tó. Èyí ń dín ṣíṣeéṣe pé kí a jẹ gbèsè láìnídìí kù. Àǹfààní pọ̀ nínú rẹ̀, bí a bá lè wà láìjẹgbèsè. Òwe 22:7 kìlọ̀ pé: “Ayá-nǹkan sì ni ìránṣẹ́ awínni.” Kódà, bí ayánilówó àti ẹni tó yá owó bá jẹ́ arákùnrin nípa tẹ̀mí, dé àyè kan, owó yíyá lè ba àjọṣe wọn jẹ́. Èdèkòyédè lórí owó yíyá tilẹ̀ ti ba àlàáfíà àwọn ìjọ kan jẹ́.

Ṣàlàyé Ohun Tí O Fẹ́ Fi Owó Náà Ṣe

Ayánilówó lẹ́tọ̀ọ́ láti mọ bí a ṣe fẹ́ ná owó náà gan-an. Yàtọ̀ sí owó tí a ń yá lọ́wọ́ ẹni yìí, ǹjẹ́ a tún fẹ́ yáwó lọ́wọ́ àwọn mìíràn? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ ṣàlàyé rẹ̀, nítorí ó ní í ṣe pẹ̀lú agbára àtirí owó náà san padà.

Ó ṣe pàtàkì gidi láti fìyàsọ́tọ̀ sí yíyáni lówó ṣe òwò àti owó tí a nílò láti fi yanjú àwọn ìṣòro pàjáwìrì kan. Ìwé Mímọ́ kò sọ ọ́ di ọ̀ranyàn fún arákùnrin kan láti yáni lówó ṣe òwò, àmọ́, ó lè fẹ́ ran arákùnrin kan lọ́wọ́ bí onítọ̀hún kò bá rówó ra àwọn ohun kòṣeémánìí bí oúnjẹ, aṣọ, tàbí oògùn fún ìtọ́jú tí ó pọn dandan, tí kì í sì í ṣe ẹ̀bí rẹ̀. Àìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ àti sísọ òótọ́ nínú àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí yóò ṣèrànwọ́ kí èdèkòyédè má bàa ṣẹlẹ̀.—Éfésù 4:25.

Ẹ Ṣèwé

Àkọsílẹ̀ àdéhùn tí a ṣe jẹ́ ìgbésẹ̀ pàtàkì bí a kò bá fẹ́ kí èdèkòyédè ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. Ó rọrùn láti gbà gbé àwọn ohun pàtó inú àdéhùn kan àyàfi tí a bá kọ wọ́n sílẹ̀. Ó yẹ kí a kọ iye tí a yá àti ìgbà tí a óò rí i san. Yóò bọ́gbọ́n mu kí ayánilówó àti ẹni tí ó yáwó ṣe ìwé àdéhùn, kí wọ́n sì buwọ́ lù ú, kí olúkúlùkù wọn sì gba ẹ̀dà kọ̀ọ̀kan. Bíbélì sọ pé a gbọ́dọ̀ ṣàkọsílẹ̀ àdéhùn iṣẹ́ òwò. Ṣáájú kí àwọn ará Bábílónì tó pa Jerúsálẹ́mù run, Jèhófà ní kí Jeremáyà ra ilẹ̀ kan lọ́wọ́ ọ̀kan lára àwọn ẹbí rẹ̀. A lè jàǹfààní nínú ṣíṣàyẹ̀wò bí ó ṣe ṣe é.

Jeremáyà sọ pé: “Mo tẹ̀ síwájú láti ra pápá tí ó wà ní Ánátótì lọ́wọ́ Hánámélì ọmọkùnrin arákùnrin mi láti ìdí ilé baba mi. Mo sì wọn owó fún un, ṣékélì méje àti ẹyọ fàdákà mẹ́wàá. Lẹ́yìn náà, mo kọ ìwé àdéhùn, mo sì fi èdìdì sí i, mo sì gba àwọn ẹlẹ́rìí bí mo ti ń wọn owó náà lórí òṣùwọ̀n. Lẹ́yìn náà, mo mú ìwé àdéhùn ọjà rírà, èyí tí a fi èdìdì dì ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ àti ìlànà, àti èyí tí a ṣí sílẹ̀; mo sì wá fi ìwé àdéhùn ọjà rírà náà fún Bárúkù, ọmọkùnrin Neráyà, ọmọkùnrin Maseáyà, lójú Hánámélì ọmọkùnrin arákùnrin mi láti ìdí ilé baba mi àti lójú àwọn ẹlẹ́rìí, àwọn tí ó kọ̀wé sínú ìwé àdéhùn ọjà rírà náà, lójú gbogbo Júù tí wọ́n jókòó sí Àgbàlá Ẹ̀ṣọ́.” (Jeremáyà 32:9-12) Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àpẹẹrẹ tí a ń sọ nípa rẹ̀ yìí kì í ṣe ti yíyánilówó bí kò ṣe, ti ríra nǹkan, ó fi ìjẹ́pàtàkì bíbójútó ọ̀ràn owó lọ́nà tí ó ṣe kedere hàn.—Wo Ile-Iṣọ Na, August 15, 1974, ojú ìwé 511 àti 512.

Bí ìṣòro bá yọjú, àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ gbìyànjú láti yanjú rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ràn Jésù tí a ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀ nínú Mátíù 18:15-17. Ṣùgbọ́n alàgbà kan tí ó ti gbìyànjú láti ṣèrànwọ́ nínú irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀ sọ pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé nínú gbogbo irú ọ̀ràn bẹ́ẹ̀, wọn kò ṣe ìwé àdéhùn kankan. Nítorí náà, àwọn méjèèjì kò lóye ara wọn dáradára nípa bí a óò ṣe san owó náà padà. Ó dá mi lójú pé ṣíṣe ìwé nínú àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí jẹ́ àmì ìfẹ́, kì í ṣe ti pé a kò gbẹ̀kẹ́ lé onítọ̀hún.”

Gbàrà tí a bá ti ṣe àdéhùn, a gbọ́dọ̀ gbìyànjú láti pa á mọ́. Jésù gbani níyànjú pé: “Kí ọ̀rọ̀ yín Bẹ́ẹ̀ ni sáà túmọ̀ sí Bẹ́ẹ̀ ni, Bẹ́ẹ̀ kọ́ yín, Bẹ́ẹ̀ kọ́; nítorí ohun tí ó bá ju ìwọ̀nyí lọ wá láti ọ̀dọ̀ ẹni burúkú náà.” (Mátíù 5:37) Bí àwọn ìṣòro àìròtẹ́lẹ̀ kan kò bá jẹ́ kí a lè rí owó náà san padà nígbà tí a ṣàdéhùn pé a óò san án, a gbọ́dọ̀ lọ ṣàlàyé bí nǹkan ṣe rí fún ẹni tó yá wa lówó náà lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Bóyá yóò jẹ́ kí a máa san owó náà díẹ̀díẹ̀ tí yóò fi àkókò díẹ̀ ré kọjá ìgbà tí a dá.

Síbẹ̀, ìṣòro àìròtẹ́lẹ̀ kò ní kí a má ṣe ojúṣe wa. Ẹni tí ó bẹ̀rù Jèhófà yóò sa gbogbo ipá rẹ̀ láti mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ. (Sáàmù 15:4) Bí nǹkan kò bá tilẹ̀ rí bí a ṣe retí kí ó rí, ó yẹ kí a múra láti yááfì àwọn ohun kan kí a bàa lè san gbèsè tí a jẹ, nítorí pé ó jẹ́ àìgbọdọ̀máṣe fún wa bí Kristẹni.

Ṣọ́ra Nípa Yíyáni Lówó

Lóòótọ́, ẹni tó wá yáwó nìkan kọ́ ló yẹ kó fìṣọ́ra gbé ọ̀ràn náà yẹ̀ wò. Arákùnrin kan tí a fẹ́ yáwó lọ́wọ́ rẹ̀ pẹ̀lú ní láti rò ó dáadáa. Kí a tó yá ẹnì kan lówó, ó bọ́gbọ́n mu kí a kọ́kọ́ fara balẹ̀ ro ọ̀ràn náà dáadáa. Bíbélì rọ̀ wá láti ṣọ́ra, ó wí pé: “Má di ara àwọn tí ń gba ọwọ́, ara àwọn tí ń ṣe onídùúró fún ohun yíyá.”—Òwe 22:26.

Kí o tó kiwọ́ bọ̀wé, ronú nípa ohun tí ó lè ṣẹlẹ̀ bí arákùnrin náà kò bá rí i san padà. Ǹjẹ́ ó lè wá kó ìwọ alára sí ìṣòro owó? Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tí arákùnrin náà ní lọ́kàn dára gan-an, nǹkan lè yíwọ́ tàbí kí ó ṣàṣìṣe nínú ìṣirò tó ṣe. Jákọ́bù 4:14 rán gbogbo wa létí pé: “Ẹ kò mọ ohun tí ìwàláàyè yín yóò jẹ́ lọ́la. Nítorí ìkùukùu ni yín tí ń fara hàn fún ìgbà díẹ̀ àti lẹ́yìn náà tí ń dàwátì.”—Fi wé Oníwàásù 9:11.

Ní pàtàkì, yóò bọ́gbọ́n mu láti gbé ìfùsì ẹni tí ó wá yá owó yẹ̀ wò tó bá jẹ́ òwò ló fẹ́ fi owó tó wá yá ṣe. Ǹjẹ́ a mọ̀ ọ́n sí ẹni tí ó ṣeé fọkàn tán, tí ó sì ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, àbí ẹni tí kò tóótun nínú ọ̀ràn àbójútó owó ni? Ǹjẹ́ ó máa ń yáwó káàkiri lọ́wọ́ àwọn ará nínú ìjọ? Ó bọ́gbọ́n mu láti fi àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sọ́kàn pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ aláìní ìrírí ń ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”—Òwe 14:15.

Nígbà mìíràn, owó tí ẹnì kan lọ yá tilẹ̀ lè má ṣe é láǹfààní. Ó lè fìrọ̀rùn di ohun ìnira fún un, kí ó máà jẹ́ kí ó láyọ̀. Ǹjẹ́ a fẹ́ kí irú arákùnrin bẹ́ẹ̀ di “ìránṣẹ́” wa? Ǹjẹ́ yíyá tí a yá a lówó lè ba àjọṣe wa jẹ́, kí ó fa ìdààmú tàbí ìtìjú pàápàá bí kò bá rí i san padà?

Bí àìní gidi kan bá dìde, a ha lè ronú nípa fífún un lówó bí ẹ̀bùn dípò yíyá a, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé owó náà lè kéré? Ìwé Mímọ́ rọ̀ wá láti fi ìyọ́nú hàn tí a bá rí arákùnrin wa ní ipò àìní. Onísáàmù náà kọrin pé: “Olódodo ń fi ojú rere hàn, ó sì ń fúnni ní ẹ̀bùn.” (Sáàmù 37:21) Ó yẹ kí ìfẹ́ sún wa ṣe ohun tí a bá lè ṣe láti ṣèrànwọ́ gidi fún àwọn ará tí wọ́n ṣaláìní.—Jákọ́bù 2:15, 16.

Fọgbọ́n Ṣe É

Níwọ̀n bí owó yíyá ti lè jẹ́ orísun èdèkòyédè, dípò tí yóò fi jẹ́ ohun tí a óò kọ́kọ́ yàn, a lè wò ó bí ohun tí a lè yàn nígbà tí kò bá sí ọ̀nà mìíràn tí a lè gbé e gbà mọ́. Gẹ́gẹ́ bí a ti sọ ṣáájú, ẹni tó wá yáwó kò gbọ́dọ̀ fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ fún ayánilówó, ó yẹ kí wọ́n ṣèwé bí yóò ṣe san owó tí ó yá padà àti ìgbà tí yóò rí i san. Tí ó bá sì wà nínú ìpọ́njú ní gidi, fífún un ní ẹ̀bùn lè jẹ́ ojútùú tí ó dára jù lọ.

Michael kò yá Simon lówó tí ó ní kó yá òun. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Michael fún un ní ìwọ̀nba owó díẹ̀ bí ẹ̀bùn. Simon dúpẹ́ fún ìrànlọ́wọ́ tó jẹ́ kí ó lè sanwó oògùn ọmọ rẹ̀. Inú Michael sì dùn pé òun lè fi ìfẹ́ ará òun hàn lọ́nà tí ó gbéṣẹ́. (Òwe 14:21; Ìṣe 20:35) Michael àti Simon ń fojú sọ́nà fún ìgbà tí Kristi “yóò dá òtòṣì tí ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́ nídè,” tí kì yóò sì sí ẹni tí yóò sọ pé, “àìsàn ń ṣe mí” lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba náà. (Sáàmù 72:12; Aísáyà 33:24) Kó tó di ìgbà yẹn, ẹ jẹ́ kí a fi ọgbọ́n ṣe é bí ó bá tilẹ̀ di dandan pé kí a yáwó lọ́wọ́ arákùnrin kan.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ wọ̀nyẹn padà.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Ṣíṣe ìwé àdéhùn owó yíyá jẹ́ àmì ìfẹ́, kì í ṣe ti pé a kò gbẹ́kẹ̀ lé onítọ̀hún

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́