Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Nígbà tí Jésù ní káwọn ọmọlẹ́yìn òun “máa wínni láìsí èlé, láìretí ohunkóhun padà,” ṣé ohun tó ń sọ ni pé wọn ò tiẹ̀ gbọ́dọ̀ gba owó tí wọ́n yani pàápàá padà?
Mímọ ohun tí Òfin Mósè sọ lórí ọ̀rọ̀ yìí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti lóye gbólóhùn Jésù yìí ní Lúùkù 6:35. Nínú Òfin yìí, Ọlọ́run pàṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé wọ́n ní láti máa yá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bíi tiwọn tí nǹkan nira fún gan-an tí wọ́n sì nílò ìrànlọ́wọ́ lówó, àmọ́ wọn ò gbọ́dọ̀ gba èlé lórí owó náà. (Ẹ́kísódù 22:25; Léfítíkù 25:35-37; Mátíù 5:42) Wọn ò ní láti sọ yíyánilówó di òwò ṣíṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí àwọn ẹ̀yáwó tí kò ní èlé bẹ́ẹ̀ wà fún ni láti dín ìṣẹ́ àwọn aláìní kù àti ìnira tó ń bá wọn fínra. Nítorí, bí ẹnì kan bá tún ń jèrè lára aládùúgbò rẹ̀ tí nǹkan ò rọrùn fún, ìyẹn ò fìfẹ́ hàn rárá. Síbẹ̀, ẹni tó yani lówó lẹ́tọ̀ọ́ láti gba owó tó yáni padà, ó sì lè gba ohun ìdógò (ohun tí kò ní jẹ́ kí owó rẹ̀ wọgbó) nígbà míì.—Diutarónómì 15:7, 8.
Jésù fara mọ́ Òfin yìí, kódà ó tún sọ ọ̀nà tá a lè gbà túbọ̀ fi í sílò nípa sísọ pé ẹni tó ń ṣèrànwọ́ náà kò gbọ́dọ̀ retí “ohunkóhun padà.” Bíi tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ìgbà míì máa ń wà tí nǹkan kì í lọ déédéé fáwọn Kristẹni tàbí tí nǹkan kan á ṣẹlẹ̀ tí èyí á sì sọ wọ́n di aláìní tàbí kí wọ́n tiẹ̀ dẹdun arinlẹ̀ pàápàá. Bí Kristẹni tó bára rẹ̀ nínú irú ìṣòro ńlá bẹ́ẹ̀ bá wá ìrànlọ́wọ́ owó wá, ǹjẹ́ kò ní dáa ká ràn án lọ́wọ́? Ní tòótọ́, ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn yóò sún Kristẹni kan láti ṣèrànwọ́ fún arákùnrin rẹ̀ tó bára rẹ̀ nínú ìṣòro àtijẹ àtimu láìṣe ẹ̀bi rẹ̀. (Òwe 3:27) A lè fún irú arákùnrin tó dí aláìní bẹ́ẹ̀ lówó, bó tilẹ̀ jẹ́ pé owó náà lè máà tó iye tí à bá yá a.—Sáàmù 37:21.
Ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, ìjọ Kristẹni yan àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti Bánábà láti mú ohun táwọn Kristẹni ní Éṣíà Kékeré fi ṣètọrẹ lọ fáwọn arákùnrin wọn ní Jùdíà nítorí ìyàn kan tó ń mú níbẹ̀. (Ìṣe 11:28-30) Lónìí náà, nígbà tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, àwọn Kristẹni sábà máa ń fi ẹ̀bùn ránṣẹ́ sáwọn arákùnrin wọn tó di aláìní. Ohun tí wọ́n ń ṣe yìí tún jẹ́ ìwàásù lọ́tọ̀ fáwọn ẹlòmíràn. (Mátíù 5:16) Síbẹ̀, wọ́n ní láti gbé ipò ẹni tó ń wá ìrànlọ́wọ́ náà àti ìṣesí rẹ̀ yẹ̀ wò. Kí ló sọ ọ́ di aláìní? Wọ́n á fi ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ sọ́kàn pé: “Bí ẹnikẹ́ni kò bá fẹ́ ṣiṣẹ́, kí ó má ṣe jẹun.”—2 Tẹsalóníkà 3:10.
Bí arákùnrin tó ń bẹ̀bẹ̀ fún ẹ̀yáwó kò bá sí nínú ìṣòro ńlá àmọ́ tó kàn ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́ díẹ̀ kó lè dìde padà lẹ́yìn tí nǹkan ti lọọlẹ̀ fún un, ó lè dára láti yá a lówó láìgba èlé lórí rẹ̀. Ní irú ipò báyìí, téèyàn bá yá a lówó tó sì ní in lọ́kàn láti gba gbogbo owó náà padà, ìyẹn kò ta ko ohun tí Jésù sọ ní Lúùkù 6:35. Wọ́n ní láti kọ àdéhùn wọn sílẹ̀, ẹni tó yá owó náà sì gbọ́dọ̀ sa gbogbo ipá rẹ̀ láti dá owó náà padà níbàámu pẹ̀lú ohun tí wọ́n jọ ṣàdéhùn lé lórí. Ká sòótọ́, ìfẹ́ Kristẹni yẹ kó sún arákùnrin tó yá owó láti san owó náà padà bí ìfẹ́ ṣe sún ẹni tó yá a lówó.
Ó tún yẹ kí ẹni tó ń gbèrò láti yani lówó (tàbí láti fi owó tọrẹ) wo ipò tí ìdílé òun alára wà. Bí àpẹẹrẹ, ṣé ìrànlọ́wọ́ tó fẹ́ ṣe yóò pa bíbójútó ìdílé rẹ̀ lára, èyí tó gbọ́dọ̀ gbapò iwájú gẹ́gẹ́ bí ìlànà Ìwé Mímọ́ ti wí? (2 Kọ́ríńtì 8:12; 1 Tímótì 5:8) Síbẹ̀, àwọn Kristẹni ṣì máa ń wá àwọn ọ̀nà tí wọ́n lè gbà fi ìfẹ́ hàn síra wọn, wọ́n sì máa ń fi ìfẹ́ yìí hàn lónírúurú ọ̀nà tó bá ìlànà Bíbélì mu.—Jákọ́bù 1:27; 1 Jòhánù 3:18; 4:7-11.