ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwbq àpilẹ̀kọ 155
  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Fífúnni?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Fífúnni?
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun tí Bíbélì sọ
  • Báwo ni Ọlọ́run ṣe fẹ́ ká máa fúnni?
  • Ọ̀nà wo ni Ọlọ́run ò fẹ́ ká máa gbà fúnni?
  • “Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Olùfúnni Ọlọ́yàyà”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2013
  • O Ha Ní Ẹ̀mí Fífúnni Bí?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1995
  • Jehofa Nífẹ̀ẹ́ Awọn Olufunni Ọlọ́yàyà
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Èrè Tó Wà Nínú Fífúnni Ní Nǹkan
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
Àwọn Míì
Ohun Tí Bíbélì Sọ
ijwbq àpilẹ̀kọ 155
Ọkùnrin kan gbé ẹ̀bùn dání

Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Fífúnni?

Ohun tí Bíbélì sọ

Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká máa fúnni látọkàn wá láìretí ohunkóhun pa dà. Ó jẹ́ ká mọ̀ pé àwa àtẹni tá a fún ní nǹkan máa láyọ̀. (Òwe 11:25; Lúùkù 6:38) Jésù sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tó wà nínú rírígbà lọ.”​—Ìṣe 20:35.

  • Báwo ni Ọlọ́run ṣe fẹ́ ká máa fúnni?

  • Ọ̀nà wo ni Ọlọ́run ò fẹ́ ká máa gbà fúnni?

  • Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó sọ̀rọ̀ nípa fífúnni

Báwo ni Ọlọ́run ṣe fẹ́ ká máa fúnni?

Tá a bá ń fúnni látọkàn wá, a máa láyọ̀. Bíbélì sọ pé: “Kí kálukú ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu nínú ọkàn rẹ̀, kì í ṣe pẹ̀lú lílọ́ra tàbí lábẹ́ àfipáṣe, nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ẹni tó ń fúnni pẹ̀lú ìdùnnú.”​—2 Kọ́ríńtì 9:7.

Fífúnni látọkàn wá jẹ́ apá kan “Ìjọsìn tó mọ́” tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà. (Jémíìsì1:27) Ńṣe ni ẹni tó bá lawọ́ sí àwọ́n aláìní ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ọlọ́run , Ọlọ́run máa ń wo irú oore bẹ́ẹ̀ bí ìgbà tá a yá òun ní nǹkan. (Òwe 19:17) Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run máa san onítọ̀hún lẹ́san.​—Lúùkù 14:12-​14.

Ọ̀nà wo ni Ọlọ́run ò fẹ́ ká máa gbà fúnni?

Tó bá jẹ́ pé torí àǹfààní ara wa nìkan la ṣe ń fúnni. Bí àpẹẹrẹ:

  • Torí káwọn èèyàn lè yìn wá.​—Mátíù 6:2.

  • Torí ohun tá a máa gbà pa dà.​—Lúùkù 14:12-14.

  • Ká baà lè rí ìgbàlà.​—Sáàmù 49:6, 7.

Tó bá jẹ́ pé ohun tá a fẹ́ fún ẹnì kan máa ti àwọn àṣà tàbí ìwà tínú Ọlọ́run ò dùn sí lẹ́yìn. Bí àpẹẹrẹ, kò ní bọ́gbọ́n mu tá a bá fún ẹnì kan lówó kó fi ta tẹ́tẹ́, kó fi ra oògùn tàbí ọtí tó fẹ́ lò nílòkulò. (1 Kọ́ríńtì 6:9, 10; 2 Kọ́ríńtì 7:1) Bákan náà, tẹ́nì kan bá lè gbọ́ bùkátà ara rẹ̀ àmọ́ tí ò kọ̀ láti ṣiṣẹ́, kò yẹ ká fún un ní nǹkan.​— Tẹsalóníkà 3:10.

Tí kò bá ní jẹ́ ká ráyè fún ìdílé wa. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn olórí ìdílé gbọ́dọ̀ máa pèsè fún ìdílé wọn. (1 Tímótì 5:8) Kò yẹ kí àwọn olórí ìdílé máa kóyán ìdílé wọn kéré torí pé wọ́n fẹ́ lawọ́ sí àwọn míì. Kódà, Jésù dẹ́bi fún àwọn tó kọ̀ láti bójú tó àwọn òbí wọn tó ti di àgbàlagbà torí wọ́n sọ pé gbogbo nǹkan tí àwọn ní jẹ́ “ẹ̀bùn tí a yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run.”.​—Máàkù 7:9-​13.

Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó sọ̀rọ̀ nípa fífúnni

Òwe 11:25: “Ẹni tó bá lawọ́ máa láásìkí, ẹni tó bá sì ń mára tu àwọn míì, ara máa tu òun náà.”

Ohun tó túmọ̀ sí: Tá a bá ń fúnni, àwa àtẹni táa fún ní nǹkan máa láyọ̀.

Òwe 19:17: “Ẹni tó ń ṣojúure sí aláìní, Jèhófà ló ń yá ní nǹkan, á sì san án pa dà fún un nítorí ohun tó ṣe.”

Ohun tó túmọ̀ sí: Tá a bá ń ran àwọn aláìní lọ́wọ́, ńṣe ni Ọlọ́run máa ń rí irú oore bẹ́ẹ̀ bí ìgbà tí a yá òun ní nǹkan, ó sì ṣèlérí pé òun máa bù kún onítọ̀hún.

Mátíù 6:2: “Tí o bá ń ṣe ìtọrẹ àánú, má ṣe fun kàkàkí ṣáájú ara rẹ, bí àwọn alágàbàgebè ṣe ń ṣe . . . kí àwọn èèyàn lè kan sáárá sí wọn.”

Ohun tó túmọ̀ sí: Kò yẹ ká máa fúnni torí káwọn èèyàn lè yìn wá.

Ìṣe 20:35: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tó wà nínú rírígbà lọ.”

Ohun tó túmọ̀ sí: A máa láyọ̀ tá a bá ń fúnni látọkàn wá.

2 Kọ́ríńtì 9:7: “Kí kálukú ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu nínú ọkàn rẹ̀, kì í ṣe pẹ̀lú lílọ́ra tàbí lábẹ́ àfipáṣe, nítorí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ẹni tó ń fúnni pẹ̀lú ìdùnnú.”

Ohun tó túmọ̀ sí: Tá a bá ń fúnni látọkàn wá, ńṣe là ń múnú Ọlọ́run dùn.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́