“Alaboojuto Kan Nilati Jẹ́ Ẹni Ti . . . Ó Ńkó Ara Rẹ̀ Nijaanu”
“Alaboojuto kan nilati jẹ ẹni ti . . . ó ńkó ara rẹ̀ nijaanu.”—TITU 1:7, 8, NW.
1, 2. Apẹẹrẹ ikalọwọko wo ni William ti ilu Orange pese, pẹlu awọn iyọrisi ṣiṣanfaani wo sì ni?
ỌRỌ itan pese apẹẹrẹ agbafiyesi julọ ti ó wémọ́ ìká ero imọlara lọ́wọ́kò. Ni ilaji ọgọrun-un ọdun Kẹrindinlogun, ọmọ ọba ara Dutch naa William ti ilu Orange wà lẹnu irin ajo ọdẹ ṣiṣe pẹlu Ọba Henry Keji ti France. Ọba naa ṣipaya eto ti oun ati ọba Spain ti ṣe lati nu gbogbo Protẹstanti nù kuro ni France ati ni Netherlands fun William—nitootọ, ninu gbogbo Kristẹndọmu. Ọba Henry ní ero pe William ọdọ jẹ́ Katoliki olufọkansin kan bii oun funraarẹ ati nitori naa ó tú aṣiiri gbogbo kulẹkulẹ idimọlu naa. Ohun ti William gbọ́ dẹruba a gidigidi nitori ọpọlọpọ awọn ọrẹ rẹ̀ timọtimọ jẹ́ Protẹstanti, ṣugbọn oun kò fi imọlara rẹ̀ han; kaka bẹẹ, ó fi ifẹ giga han ninu gbogbo kulẹkulẹ ti ọba naa fun un.
2 Bi o ti wu ki o ri, gbàrà ti William ti lè ṣe bẹẹ, ó bẹrẹ awọn iwewee lati sọ idimọlu naa dòfo, eyi sì jálẹ̀ sí sisọ Netherlands dominira kuro lọwọ itẹloriba Katoliki ti Spain ni asẹhinwa-asẹhinbọ. Nitori pe William lo ikora-ẹni-nijaanu nigba ti ó kọkọ gbọ idimọlu naa, ó di ẹni ti a mọ gẹgẹ bii “William Onidaakẹjẹ.” William ti ilu Orange ṣaṣeyọri si rere gan-an debi pe a sọ fun wa pe: “Oun gan-an ni oludasilẹ ominira ati itobi Ijọba adaṣe ti Dutch.”
3. Ta ni njanfaani nigba ti awọn alagba ba lo ikora-ẹni-nijaanu?
3 Nitori ikara ẹni lọwọko rẹ̀, William Onidaakẹjẹ ṣanfaani gidigidi fun araarẹ ati awọn eniyan rẹ̀. Ni ọna ti o ṣee fiwera, ikora-ẹni-nijaanu eso ẹmi mimọ ni awọn alagba Kristẹni, tabi awọn alaboojuto gbọdọ fihan lonii. (Galatia 5:22, 23) Nipa lilo animọ yii, wọn nṣanfaani fun araawọn ati fun awọn ijọ. Ni ọwọ keji ẹwẹ, ikuna ni iha ọdọ tiwọn lati lo ikora-ẹni-nijaanu lè fa ipalara ńláǹlà.
Ikora-ẹni-nijaanu—Koṣeemanii Fun Awọn Alagba
4. Imọran apọsiteli Pọọlu wo ni ó tẹnumọ aini fun awọn alagba lati lo ikora-ẹni-nijaanu?
4 Pọọlu, tí oun funraarẹ jẹ́ alagba kan, mọriri ijẹpataki ikora-ẹni-nijaanu. Nigba ti ó ngba awọn alagba ti wọn ti wá sọdọ rẹ̀ lati Efesu nimọran, ó sọ fun wọn pe: “Ẹ kiyesi araayin, ati si gbogbo agbo.” Laaarin awọn nǹkan miiran, kikiyesi araawọn ni aini lati lo ikora-ẹni-nijaanu ninu, lati ṣọ iwa wọn. Ni kikọwe si Timoti, Pọọlu sọ koko kan naa, ni wiwi pe: “Fiyesi araarẹ nigba gbogbo ati si ikọnilẹkọọ rẹ.” Iru imọran bẹẹ fihan pe Pọọlu mọ nipa itẹsi eniyan ni iha ọdọ awọn kan lati jẹ ẹniti o daniyan nipa wiwaasu ju ṣiṣe ohun ti wọn nwaasu rẹ̀ lọ. Nitori naa, ó kọkọ tẹnumọ aini naa lati ṣakiyesi araawọn.—Iṣe 20:28; 1 Timoti 4:16, NW.
5. Bawo ni a ṣe yan awọn Kristẹni alagba sipo, nibo ni a sì ṣakọsilẹ ẹ̀rí itootun wọn sí ninu Iwe mimọ?
5 Jalẹ awọn ọdun, ipa ti awọn alagba lọna ti o ba Iwe mimọ mu ni o ti nṣe kedere sii ni kẹrẹkẹrẹ. Lonii, a rii pe ipo alagba jẹ́ ipo ti a ńyanni si. Awọn alagba ni a ńyàn sípò nipasẹ Ẹgbẹ Oluṣakoso ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa tabi awọn aṣoju rẹ̀ taarata. Ẹgbẹ yẹn, ni tirẹ, duro fun “ẹrú oluṣotitọ ati ọlọgbọn inu naa.” (Matiu 24:45-47, NW) Ẹ̀rí itootun fun didi alaboojuto, tabi Kristẹni alagba kan, ni apọsiteli Pọọlu fi funni ni pataki ni 1 Timoti 3:1-7 ati Titu 1:5-9.
6, 7. Awọn ẹ̀rí itootun pato wo ti awọn alagba ni ó beere fun ikora-ẹni-nijaanu?
6 Pọọlu wi ni 1 Timoti 3:2, 3 pe alaboojuto kan gbọdọ jẹ́ oniwọntunwọnsi ninu iwa. Eyi ati aini naa fun alagba kan lati wa letoleto beere fun lilo ikora-ẹni-nijaanu. Ọkunrin kan ti ntootun lati di alaboojuto kan kii ṣe aluni kii sii ṣe onija. Awọn ẹ̀rí itootun wọnyi tun beere pe ki alagba kan jẹ́ olukora-ẹni-nijaanu. Siwaju sii, fun alagba kan lati maṣe jẹ́ ọmuti alariwo, ti ó ni aṣa mimu ọti, oun gbọdọ lo ikora-ẹni-nijaanu.—Tun wo alaye eti iwe Reference Bible si 1 Timoti 3:2, 3.
7 Ni Titu 1:7 (NW), Pọọlu ní pàtó sọ pe alagba kan gbọdọ jẹ́ olukora-ẹni-nijaanu. Bi o ti wu ki o ri, ṣakiyesi, meloo ninu awọn ohun abeere fun miiran ti a tò lẹsẹẹsẹ ninu awọn ẹsẹ wọnyi ni ó wémọ́ ikora-ẹni-nijaanu. Fun apẹẹrẹ, alaboojuto gbọdọ bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀sùn, bẹẹni, alailẹgan. Dajudaju, alagba kan kò lè dé oju iwọn awọn ohun abeere fun wọnni ayafi bi ó ba lo ikora-ẹni-nijaanu.
Nigba ti Ó Bá Nba Awọn Ẹlomiran Lò
8. Awọn animọ wo ti awọn alagba nilo ninu fifunni ni imọran ni ó tẹnumọ aini fun ikora-ẹni-nijaanu?
8 Lẹhin naa pẹlu, alaboojuto kan gbọdọ jẹ́ onisuuru ati onipamọra ninu biba awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ rẹ̀ lò, eyi sì beere ikora-ẹni-nijaanu. Fun apẹẹrẹ, ni Galatia 6:1 (NW) a kà pe: “Ẹyin ará, ani bi eniyan kan bá tilẹ ṣi ẹsẹ gbé ki ó tó mọ nipa rẹ̀, ẹyin ti ẹ ní ẹ̀rí titootun ti ẹmi [awọn alagba ni pataki] nilati gbiyanju lati tun irú eniyan bẹẹ ṣe bọsipo ninu ẹmi iwapẹlẹ, bi olukuluku yin ti nkiyesi araarẹ, ni ibẹru pe a lè dẹ ẹyin naa wò pẹlu.” Lati fi ẹmi iwapẹlẹ han gba ikora-ẹni-nijaanu. Fun idi yẹn, ikora-ẹni-nijaanu tun wémọ́ kikiyesi ara ẹni pẹlu. Bakan naa, nigba ti ẹnikan ti ó wà ninu ipọnju ba kesi alagba kan fun iranlọwọ, ikora-ẹni-nijaanu ṣe pataki gan-an. Laika ohun ti alagba naa lè rò nipa ẹni naa sí, oun gbọdọ jẹ́ oninuure, onisuuru, ati oloye. Dipo yiyara funni ni imọran, alagba naa gbọdọ muratan lati fetisilẹ ki ó sì fun ẹni naa niṣiiri lati sọ ohun ti ó jọ bii pe ó ńdà á láàmú niti gidi.
9. Awọn alagba gbọdọ ni imọran wo lọkan nigba ti wọn ba nba awọn ará ti idaamu ti bá gan-an lò?
9 Ni pataki nigba ti ó ba nba awọn ẹni ti idaamu ti bá gan-an lò ni imọran yii ti ó wa ninu Jakobu 1:19 tó ṣe wẹ́kú pe: “Ẹyin mọ eyi, ẹyin ará mi olufẹ; ṣugbọn jẹ ki olukuluku eniyan ki o maa yara lati gbọ́, ki o lọra lati fọhùn, ki o lọra lati binu.” Bẹẹni, ni pataki nigba ti ó ba ṣalabaapade awọn iṣarasihuwa onibiinu tabi onigbonara ni alagba kan gbọdọ ṣọra lati maṣe dahunpada ni ọna kan naa. Ó gba ikora-ẹni-nijaanu lati maṣe fi awọn ọrọ onirusoke igbonara fesi awọn ọrọ onirusoke igbonara, lati maṣe “fi buburu san buburu.” (Roomu 12:17) Lati dahunpada ni iru ọna kan naa wulẹ mu ki awọn ọran buburu tubọ di buburu sii ni. Nitori naa nihin-in lẹẹkan sii ni Ọrọ Ọlọrun fun awọn alagba ni imọran rere, ni rírán wọn leti pe “idahun pẹlẹ yi ibinu pada.”—Owe 15:1.
Ikora-ẹni-nijaanu Ni Ipade Awọn Alagba ati Gbigbọ Ọran Idajọ
10, 11. Ki ni ó ti ṣẹlẹ ninu ipade awọn alagba, ti nfi aini fun ikora-ẹni-nijaanu ni iru akoko bẹẹ han?
10 Agbegbe miiran nibi ti awọn Kristẹni alaboojuto ti nilati ṣọra lati lo ikora-ẹni-nijaanu ni lakooko ipade awọn alagba. Lati fi pẹlẹtu sọrọ nitori ire otitọ ati idajọ-ododo niye igba gba ikora-ẹni-nijaanu nla. Ó tun gba ikora-ẹni-nijaanu lati yẹra fun gbigbiyanju lati jẹgaba lori ijiroro kan. Nibi ti alagba kan ba ti ni iru itẹsi bẹẹ, yoo jẹ́ inurere fun alagba miiran lati fun un ni imọran.—Fiwe 3 Johanu 9.
11 Lẹhin naa pẹlu, ni ipade awọn alagba, alagba kan ti ó ni itara ju ni a lè dẹwo lati di onigboonara, ki ó tilẹ sọrọ soke fatafata paapaa. Bawo ni iru iwa bẹẹ ṣe fi aini ikora-ẹni-nijaanu han tó! Wọn jẹ́ apara-ẹni láyò lọna onipele meji. Lọna kìn-ín-ní, dé iwọn ti ẹnikan bá padanu ikora-ẹni-nijaanu, dé iwọn yẹn ni oun ndin agbara ọran rẹ̀ kù nipa fifaye gba igbonara lati ṣiji bo ọgbọn ironu. Lọna keji ẹ̀wẹ̀, dé iwọn ibi ti ẹnikan ba ni igbonara dé, oun ní itẹsi lati mu ọran sú tabi tako awọn alagba ẹlẹgbẹ rẹ̀ paapaa. Yatọ si iyẹn, ayafi bi awọn alagba bá ṣọra, awọn ironu yiyatọ gidigidi lè ṣokunfa ipinya ninu ẹgbẹ wọn. Eyi nṣiṣẹ si ipalara tiwọn ati ti ijọ.—Fiwe Iṣe 15:36-40.
12. Ni didojukọ awọn ipo wo ni awọn alagba gbọdọ ṣọra lati lo ikora-ẹni-nijaanu?
12 Ikora-ẹni-nijaanu ni awọn alagba tun nilo gidigidi lati yẹra fun ṣíṣègbè tabi ṣiṣi agbara wọn lò. Ó rọrun lati juwọsilẹ fun idẹwo, lati jẹ ki awọn ohun ti eniyan alaipe kàsí lo agbara idari lori ohun ti a sọ tabi ṣe! Leralera, awọn alagba ti kuna lati gbegbeesẹ pẹlu ipinnu nigba ti a bá rí ọkan lara awọn ọmọ wọn tabi ibatan miiran paapaa ti ó jẹbi iwa aitọ. Ni iru awọn ipo bẹẹ ó gba ikora-ẹni-nijaanu lati maṣe jẹ ki ìdè ibatan idile dí iwa idajọ-ododo lọwọ.—Deutaronomi 10:17.
13. Eeṣe ti awọn alagba fi nilo ikora-ẹni-nijaanu ni ibi gbigbọ ọrọ idajọ?
13 Ipo miiran ninu eyi ti ikora-ẹni-nijaanu ti ṣe pataki gan-an ni nigba ti gbigbọ ọran idajọ bá wà. Awọn alagba gbọdọ lo ikora-ẹni-nijaanu nla ki igbonara ma baa nipa lori wọn lọna ti kò yẹ. Ẹkún kò gbọdọ fi tirọruntirọrun nipa lori wọn lati yi ironu wọn pada. Lakooko kan naa, alagba kan gbọdọ ṣọra ki ó maṣe padanu iwa jẹ́jẹ́ rẹ̀ nigba ti wọn bá nsọko ọrọ ẹ̀sùn sira ti a sì le sọ ọrọ ibanijẹ sii, gẹgẹ bi ọran ti lè ri nigba ti ó ba ńrí si awọn apẹhinda. Nihin-in awọn ọrọ Pọọlu baamu rẹ́gí gan-an: “Ẹrú Oluwa kò nilati jà, ṣugbọn ó nilati maa ṣe pẹlẹ si ẹni gbogbo.” Ó gba ikora-ẹni-nijaanu lati lo iwa jẹ́jẹ́ labẹ ikimọlẹ. Pọọlu nbaa lọ lati fihan pe “ẹrú Oluwa” gbọdọ maa “fa araarẹ sẹhin kuro ninu ibi, ki ó maa fi iwapẹlẹ kọ́ awọn wọnni ti kò ni itẹsi oloju rere.” Lati fi iwapẹlẹ han ati lati maa ká ara-ẹni lọwọko nigba ti a ba nbojuto atako gba ikora-ẹni-nijaanu nla.—2 Timoti 2:24, 25 NW.
Ikora-ẹni-nijaanu Pẹlu Ẹya Keji
14. Imọran rere wo ni awọn alagba gbọdọ kọbiara si ni biba awọn wọnni ti wọn jẹ́ ẹ̀yà keji lò?
14 Awọn alagba gbọdọ wà lojufo ṣamṣam lati lo ikora-ẹni-nijaanu nigba ti ó bá kan ọran ibalo wọn pẹlu awọn wọnni ti wọn jẹ́ ẹ̀yà keji. Kò ba ọgbọn mu fun alagba kan lati da ṣe ibẹwo oluṣọ agutan sọdọ arabinrin kan. Alagba naa ni alagba miiran tabi iranṣẹ iṣẹ-ojiṣẹ kan nilati tẹle. Boya ni mimọriri iṣoro yii, Pọọlu fun Timoti alagba naa nimọran pe: “Parọwa fun . . . awọn agba obinrin gẹgẹ bi iya, awọn ọdọbinrin gẹgẹ bi arabinrin pẹlu iwa mimọ gbogbo.” (1 Timoti 5:1, 2, NW) Awọn alagba kan ni a ti rí ti wọn ńgbé ọwọ lé arabinrin kan ni iṣesi bii ti baba kan. Ṣugbọn wọn lè maa tan ara wọn jẹ, nitori oofa ọkàn elere ifẹ dipo ifẹni ará mimọgaara ti Kristẹni le jẹ́ ìdí fun iru iṣesi bẹẹ bakan naa.—Fiwe 1 Kọrinti 7:1.
15. Bawo ni iṣẹlẹ kan ṣe tẹnumọ ẹ̀gàn ti ó lè yọrisi lori orukọ Jehofa nigba ti alagba kan kò ba lo ikora-ẹni-nijaanu?
15 Ẹ wo ọpọ ipalara si otitọ ti ó ti jẹyọ nitori pe awọn alagba kan kò lo ikora-ẹni-nijaanu ninu ibalo wọn pẹlu awọn arabinrin ninu ijọ! Ni awọn ọdun diẹ sẹhin, alagba kan ni a yọ lẹgbẹ nitori pe ó dẹṣẹ panṣaga pẹlu arabinrin Kristẹni kan ẹni ti ọkọ rẹ̀ kii ṣe Ẹlẹ́rìí. Ni alẹ ọjọ ti a ṣefilọ iyọlẹgbẹ alagba tẹlẹri naa, ọkọ ti a baninujẹ naa rin wọnu Gbọngan Ijọba pẹlu ibọn rifle kan ó si rọ̀jò ọta lu awọn ẹlẹbi mejeeji naa. Kò si eyikeyii ninu wọn ti a pa, a sì gba ibọn naa ni ọwọ rẹ̀ lọgan, ṣugbọn ni ọjọ keji iwe irohin pataki kan gbe irohin nipa ‘iyinbọnluni ninu ṣọọṣi kan’ jade ni oju ewe iwaju rẹ̀. Ẹ wo iru ẹ̀gàn ti aini ikora-ẹni-nijaanu alagba yẹn ti mu wa sori ijọ ati sori orukọ Jehofa!
Ikora-ẹni-nijaanu ni Awọn Agbegbe Miiran
16. Eeṣe ti awọn alagba fi gbọdọ ṣọra lati lo ikora-ẹni-nijaanu nigba ti wọn ba nsọ asọye fun gbogbo eniyan?
16 Ikora-ẹni-nijaanu ni a tun nilo gidi gan-an nigba ti alagba kan ba nsọ asọye fun gbogbo eniyan. Olubanisọrọ itagbangba kan gbọdọ jẹ́ apẹẹrẹ igboya ati ìséraró. Awọn kan gbiyanju lati pa awọn olugbọ wọn lẹrin-in pẹlu ọpọlọpọ awọn ọrọ ẹ̀fẹ̀ ti a sọ kiki fun ete pipanilẹrin-in. Eyi lè fi jijuwọsilẹ fun idẹwo lati wu awujọ olugbọ wọn han. Nitootọ, gbogbo ijuwọsilẹ fun idẹwo jẹ́ aini ikora-ẹni-nijaanu. A tilẹ lè sọ paapaa pe kikọja akoko nigba ti a ba nsọ asọye fi aini ikora-ẹni-nijaanu, ati imurasilẹ ti kò tó han pẹlu.
17, 18. Ipa wo ni ikora-ẹni-nijaanu kó ninu mimu ti alagba kan nmu oniruuru iṣẹ rẹ̀ wà ni deedee?
17 Olukuluku alagba ti nṣiṣẹ kára gbọdọ koju ipenija naa lati mu ki oniruuru ohun ti ó beere akoko ati okun rẹ̀ wà ni deedee. Ó gba ikora-ẹni-nijaanu lati maṣe lọ si ipẹkun kan tabi omiran. Awọn alagba kan ti daniyan gan-an pẹlu awọn aini kanjukanju ti ijọ debi pe wọn pa awọn idile wọn tì. Nipa bayii, nigba ti arabinrin kan sọ fun aya alagba kan nipa ibẹwo oluṣọ agutan rere ti ó ti ṣe sọdọ rẹ̀, aya alagba naa polongo pe: “Mo daniyanfẹ pe ki oun lè ṣe iru ibẹwo oluṣọ agutan bẹẹ sọdọ mi nigba kan!”—1 Timoti 3:2, 4, 5.
18 Alagba kan tun nilo ikora-ẹni-nijaanu lati mu akoko ti ó nlo lori idakẹkọọ ara ẹni wà ni deedee pẹlu eyi ti ó nlo ninu iṣẹ-ojiṣẹ pápá tabi lori ibẹwo oluṣọ agutan. Ni oju iwoye bi ọkan-aya eniyan ti lè tannijẹ tó, ó rọrun gan-an fun alagba kan lati lo akoko pupọ ju bi ó ti yẹ ki ó ṣe lọ fun ohun ti o gbadun pupọ julọ. Bi ó ba nifẹẹ si iwe, oun bakan naa lè lo akoko pupọ ju lori idakẹkọọ ara ẹni ju bi ó ti yẹ ki ó ṣe lọ. Bi iṣẹ-ojiṣẹ ile de ile bá wulẹ nira fun un, oun lè wá awawi fun ṣiṣa a tì nititori ati lè ṣe ibẹwo oluṣọ agutan.
19. Aigbọdọmaṣe wo ni awọn alagba ni ti ó fi ijẹpataki aini fun ikora-ẹni-nijaanu han?
19 Aigbọdọmaṣe naa lati pa aṣiri mọ́ tun beere pe ki alagba kan wà lojufo lati lo ikora-ẹni-nijaanu gbọnyingbọnyin. Imọran naa ti ó ṣe wẹku nihin-in ni pe: “Aṣiri ẹlomiran ni iwọ kò gbọdọ fihan.” (Owe 25:9) Iriri fihan pe eyi lè jẹ́ ọkan lara awọn ohun abeere fun ti a nṣẹ si lọna ti ó gbooro julọ laaarin awọn alagba. Bi alagba kan bá ni aya ọlọgbọn ati onifẹẹ ti oun maa nba ni ijumọsọrọpọ rere, itẹsi naa lè wà ni iha ọdọ rẹ̀ lati jiroro tabi ki o wulẹ ṣáà mẹnukan awọn ọran ti o jẹ ti aṣiri. Ṣugbọn eyi kò tọna ó sì jẹ́ alaibọgbọnmu julọ. Lakọọkọ ná, ó da igbẹkẹle. Awọn arakunrin ati arabinrin tẹmi wá sọdọ alagba wọn sì fi ọrọ aṣiri si wọn lọwọ nitori pe wọn ni igbọkanle pe ọran naa ni a o kà si aṣiri lọna pataki. Sisọ awọn ọran aṣiri fun aya ẹni kò tọna, kò bọgbọnmu, ó sì jẹ́ alainifẹẹ pẹlu nitori pe eyi gbe ẹrù inira ti a kò beere fun karí rẹ̀.—Owe 10:19; 11:13.
20. Eeṣe ti ó fi ṣe pataki tobẹẹ fun awọn alagba lati lo ikora-ẹni-nijaanu?
20 Laisi aniani, ikora-ẹni-nijaanu mà ṣe pataki gan-an ni o, ati ni pataki ni ó rí bẹẹ fun awọn alagba! Nititori fifi ti a ti fi anfaani mimu ipo iwaju laaarin awọn eniyan Jehofa lé wọn lọwọ, wọn ni ijihin pupọ ju. Niwọn bi a ti fun wọn ni pupọ, pupọ ni a beere lati ọdọ wọn. (Luuku 12:48; 16:10; fiwe Jakobu 3:1.) Ó jẹ́ anfaani ati ẹrù iṣẹ awọn alagba lati fi apẹẹrẹ rere lelẹ fun awọn ẹlomiran. Ju iyẹn lọ, awọn alagba ti a yànsípò wà ni ipo lati ṣe rere pupọ sii tabi ibi pupọ sii ju awọn ẹlomiran lọ, niye ìgbà ó nsinmi lori yala wọn lo ikora-ẹni-nijaanu tabi bẹẹkọ. Abajọ ti Pọọlu fi wi pe: “Alaboojuto kan nilati jẹ ẹni ti . . . ó ńkó ara rẹ̀ nijaanu.”
Iwọ Ha Ranti Bi?
◻ Awọn ohun abeere fun ti Iwe mimọ wo nipa awọn alagba ni ó fihan pe wọn gbọdọ lo ikora-ẹni-nijaanu?
◻ Eeṣe ti awọn alagba fi nilo ikora-ẹni-nijaanu nigba ti wọn ba nba awọn onigbagbọ ẹlẹgbẹ wọn lò?
◻ Bawo ni a ṣe lè lo ikora-ẹni-nijaanu ni ipade awọn alagba?
◻ Ipenija wo ni a gbekalẹ nipa aini naa fun awọn alagba lati pa aṣiri mọ?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Fifi ikora-ẹni-nijaanu han ṣe pataki ni ipade awọn alagba
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]
Awọn Kristẹni alagba gbọdọ lo ikora-ẹni-nijaanu ki wọn sì pa aṣiri mọ