ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 12/1 ojú ìwé 24-27
  • Rírọ̀ Timọtimọ Mọ́ Eto-ajọ Ọlọrun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Rírọ̀ Timọtimọ Mọ́ Eto-ajọ Ọlọrun
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Akoko Idanwo Kan
  • Atunṣebọsipo Lati Ṣe Aṣaaju-ọna
  • Ṣiṣe Aṣaaju-ọna Ni Guusu
  • Iṣẹ-isin Bẹtẹli
  • Iyipada Iṣẹ
  • Ìgbésí Ayé Alárinrin Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • “Ohun Tí Ó Yẹ Kí A Ṣe Ni A Ṣe”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1998
  • Jèhófà Bù Kún Ìpinnu Tí Mo Ṣe
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2018
  • Jèhófà Kọ́ Mi Láti Ìgbà Èwe Mi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 12/1 ojú ìwé 24-27

Rírọ̀ Timọtimọ Mọ́ Eto-ajọ Ọlọrun

GẸGẸ BI ROY A. RYAN TI SỌ Ọ

Sandhill, Missouri, jẹ́ orukọ ti o ṣe wẹku, niwọn bi o ti fi diẹ tobi ju oke nla oniyanrin kan ni gbalasa abuleko oloke kan. Abule ti ó wà ni ìkóríta yii ni a kọ́ ni nǹkan bii ibusọ mẹta si iwọ oorun ilu Rutledge ti ó sì ni kiki ile mẹjọ tabi mẹsan-an, ṣọọṣi Mẹtọdiisi kan, ati ṣọọbu alagbẹdẹ kekere kan. Nibẹ ni a ti bí mi ni October 25, 1900.

BABA mi ni alagbẹdẹ abule naa. Bi o tilẹ jẹ pe awọn obi mi kii fi bẹẹ lọ sí ṣọọṣi, Iya mi bẹrẹ si rán mi lọ si ile-ẹkọ ọjọ Isinmi ni Ṣọọṣi Mẹtọdiisi naa. Emi kò fẹran orukọ naa Mẹtọdiisi, ni gbigbagbọ pe ẹnikan ni a nilati pe ni Kristẹni; sibẹ mo mu òùngbẹ fun otitọ Bibeli ati ifẹ ọkan ninu ìyè ayeraye dagba.

Nigba ti mo jẹ́ ọmọ ọdun 16, mo lọ lati ṣiṣẹ nibi ọna ọkọ oju irin ti ó lọ si Santa Fe. Ọ̀kan ninu awọn International Bible Students (bi a ṣe npe awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nigba naa) ti orukọ rẹ̀ njẹ Jim wá lati bá ẹgbẹ́ ti nṣe ọna ọkọ oju irin naa ṣiṣẹ, ti oun ati emi si maa nṣiṣẹ papọ loorekoore. Jim sọrọ, emi sì fetisilẹ si ohun ti ó ni lati sọ nipa Bibeli. O dun bi ohun rere kan si mi, nitori naa mo beere bí mo bá lè yá ọ̀kan ninu awọn iwe rẹ̀.

Jim yá mi ni idipọ akọkọ Studies in the Scriptures, ti a tẹjade lati ọwọ C. T. Russell ti International Bible Students Association. Nigba ti mo da a pada, mo mu ki ó wá awọn idipọ pupọ sii fun mi. Ni akoko kukuru lẹhin naa, Jim fi ọna ọkọ oju irin naa silẹ, ìgbà miiran ti mo sì rii jẹ ni oju opopona ni Rutledge, ó ngba awọn iwe ibeere fun iwe alaworan naa Scenario of the Photo-Drama of Creation. Lẹhin naa ó ké si mi wá si ikẹkọọ awujọ ti a nṣe ninu ile rẹ̀. Ni ọjọọjọ Sunday, emi yoo rin ibusọ mẹta lọ si ilu Rutledge fun ipade naa.

Nigba ti iwe irohin Golden Age (Ji! nisinsinyi) di eyi ti a kọ́kọ́ mú jade ni 1919, mo fẹ lati bẹrẹ ninu iṣẹ ojiṣẹ pápá. Akẹkọọ Bibeli titun miiran kan ati emi pinnu lati ṣe ipinkiri iwe irohin titun yii lati ẹnu ọna de ẹnu ọna. A nimọlara ipaya lọna kan ṣaa nipa kikesi awọn eniyan ninu ilu wa, nitori naa a wọ ọkọ oju irin a sì lọ si ilu kan ti kò jinna si wa. Nigba ti a débẹ̀ ni owurọ, ọkọọkan wa gba ọna tirẹ lọ a sì bẹrẹ sii kan ilẹkun awọn eniyan titi o fi di ọsan, koda bi o tilẹ jẹ pe a kò ni idanilẹkọọ eyikeyii ninu iṣẹ yii. Mo gba iwe ibeere fun asansilẹ-owo meji, ọkan lati ọdọ ọkunrin kan ti mo bá ṣiṣẹ papọ lori ọna ọkọ oju irin naa.

Ni October 10, 1920, a bamtisi mi ninu adagun omi kan lẹ́bàá Rutledge. Awọn obi mi ṣe atako si didi ẹni ti ó ni ajọṣepọ pẹlu awọn International Bible Students. Eyi jẹ́ nitori atako tí awọn alufaa súnná sí ti awọn Akẹkọọ Bibeli niriiri rẹ̀ ni awọn ọdun ogun 1914 si 1918. Lẹhin naa, bi o ti wu ki o ri, baba mi bẹrẹ sii wa si diẹ lara ipade awọn Akẹkọọ Bibeli, ti oun si tun ka The Golden Age. Ṣaaju ki o tó ku, iya mi di ẹni ti o tubọ ni ojurere si òye wa nipa otitọ Bibeli. Sibẹ kò sí ọkan ninu idile mi ti ó sọ otitọ yii di tirẹ.

Akoko Idanwo Kan

Ni awọn ọjọ ibẹrẹ wọnni, kiki awọn mẹta ni ó wà yatọ si mi ti wọn nwa deedee si awọn ipade ikẹkọọ Bibeli ni Rutledge. Awọn mẹta wọnyi lẹhin-ọ-rẹhin fi eto-ajọ naa silẹ. Ọkan jẹ́ olubanisọrọ titayọ, ti yoo sọ awiye itagbangba lori Bibeli ni agbegbe naa. Bi o ti wu ki o ri, ó di agberaga nitori òye rẹ̀ ti o sì nimọlara pe o bu oun kù lati nipin-in ninu iṣẹ iwaasu ile-de-ile bi awọn Kristẹni ijimiji ti ṣe.—Iṣe 5:42; 20:20.

Nigba ti awọn mẹta wọnyi ṣiwọ didarapọ mọ International Bible Students, mo ranti pe mo nimọlara bii ti apọsiteli Peteru nigba ti Jesu ba awọn eniyan sọrọ nipa ‘jíjẹ ẹran-ara Jesu ati mímu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.’ Lori iṣẹlẹ yii ọpọlọpọ fi i silẹ, nitori ti ẹkọ rẹ̀ jẹ́ ikọsẹ fun wọn. Nitori bẹẹ, Jesu beere lọwọ awọn apọsiteli pe: “Ẹyin pẹlu nfẹ lọ bi?” Peteru dahun pe: “Oluwa ọdọ ta ni awa yoo lọ? Iwọ ni o ní ọrọ ìyè ainipẹkun.”—Johanu 6:67, 68.

Bi o tilẹ jẹ pe Peteru kò loye kulẹkulẹ ohun ti Jesu ni lọkan nipa ‘jijẹ ẹran ara Jesu ati mimu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀,’ ó mọ daju pe Jesu ni awọn ọrọ ìyè. Bi imọlara mi nipa eto-ajọ naa ṣe rí niyẹn. Ó ní otitọ naa koda bi o tilẹ jẹ pe emi kò fi ìgbà gbogbo loye gbogbo nǹkan ti emi nka ninu awọn itẹjade lẹkun-unrẹrẹ. Sibẹ, nigbakigba ti a ba sọ ohun kan ti emi ko loye, emi kò jẹ́ jiyan lodi si i. Lọjọ iwaju, ọran naa ni a o mu ṣe kedere, tabi ki a ṣe atunṣebọsipo oju-iwoye nigba miiran. Ìgbà gbogbo ni mo nlayọ pe mo ti fi suuru duro de imuṣekedere.—Owe 4:18.

Atunṣebọsipo Lati Ṣe Aṣaaju-ọna

Ni July 1924, mo lọ si apejọpọ agbaye kan ni Columbus, Ohio. Iwe The Golden Age ṣapejuwe rẹ̀ gẹgẹ bi “apejọpọ awọn Akẹkọọ Bibeli ti ó tii tobi julọ ti a ṣe laaarin awọn sanmani naa.” Nibẹ ni ipinnu arunisoke naa “Ẹsun ẹṣẹ” di eyi ti a tẹwọgba. Isọfunni ti a rí gba ati ẹmi ti a fihan ni apejọpọ naa fun mi nisiiri lati di ojiṣẹ alakooko kikun kan, tabi aṣaaju-ọna.

Nigba ti mo pada de lati apejọpọ naa, mo fi iṣẹ mi pẹlu ọna ọkọ oju irin naa silẹ, ti emi ati Akẹkọọ Bibeli ẹlẹgbẹ mi kan si bẹrẹ sii ṣiṣẹsin papọ gẹgẹ bi aṣaaju-ọna. Bi o ti wu ki o ri, lẹhin nǹkan bi ọdun kan, ilera awọn obi mi bẹrẹ sii jorẹhin dé àyè ti wọn fi nilo iranlọwọ mi. Mo ṣiwọ ṣiṣe aṣaaju-ọna ti mo sì ri iṣẹ lọdọ kọmpini ti nṣe iṣẹ gbigbe ọpa irin oniho gba abẹ ilẹ, ṣugbọn niwọn bi awọn eniyan ti nṣiṣẹ nibẹ ko ti lo agbara idari rere lori mi, mo fi iṣẹ naa silẹ ti mo sì bọ́ sinu iṣẹ́-òwò titọju awọn kokoro oyin ati tita afárá wọn.

Ni ìgbà ẹrun 1933, awọn obi mi mejeeji ti kú, wọn sì fi mi silẹ laini awọn ẹrù-iṣẹ́ aigbọdọmaṣe eyikeyii. Nitori naa ni akoko iruwe ni 1934, mo fi awọn oyin mi sábẹ́ abojuto ẹlomiran, mo kan ile agberin kekere kan fun gbigbe, mo sì bẹrẹ iṣẹ-ojiṣẹ alakooko kikun lẹẹkan sii gẹgẹ bi aṣaaju-ọna. Lakọọkọ, mo ṣiṣẹ pẹlu agbalagba Ẹlẹ́rìí kan ni agbegbe Quincy, Illinois. Nigba ti ó yá mo pada lọ si Missouri, nibi ti mo ti darapọ mọ ẹgbẹ awọn aṣaaju-ọna kan.

Ni 1935 ọ̀dá lilekoko kan ṣẹlẹ ni Agbedemeji iwọ-oorun, niwọn bi awa sì ti nṣiṣẹ ni agbegbe ti ó wà fun kiki awọn oniṣẹ ọgbin, awọn nǹkan nira fun wa. Kò si ẹnikẹni ninu wa ti ó ni owo, nitori naa awọn eniyan ti wọn moore saba maa nfun wa ni ounjẹ tabi awọn ohun èèlò miiran nigba ti a ba fi iwe silẹ fun wọn.

Ṣiṣe Aṣaaju-ọna Ni Guusu

Ni akoko otutu yẹn a ṣí lọ si Arkansas lati bọ lọwọ ipo ọjọ olotutu naa. Ó ṣeeṣe fun wa lati pin awọn iwe pupọ sii ni agbegbe naa ti a sì gba gbogbo ohun jíjẹ inu agolo ti a lè lò. A saba maa ntẹwọgba awọn ohun miiran ti a lè pada sọ di owo, titi kan awọn ohun èèlò ayọ́ ogbologboo, awọn idẹ tabi bàbà ti o ti gbó, awọn ẹrọ ti nmu ẹnjinni ọkọ tutu ati awọn batiri ti ó ti gbó. Eyi fun wa ni owo fun epo ọkọ Model A Ford mi, eyi ti a nlo ninu iṣẹ-ojiṣẹ naa.

A ṣiṣẹsin ni awọn ẹkun Newton, Searcy, ati Carroll ni agbegbe oloke titẹju Ozark. Awọn iriri ti a ni ninu wiwaasu laaarin awọn eniyan Ilẹ oloke pẹrẹsẹ ti Arkansas yoo kún inu iwe kan. Niwọn bi awọn ọna ti jẹ́ ti atijọ tabi ti kò tilẹ si rara ni awọn ọjọ wọnni, a ṣe pupọ ninu iṣẹ wa ni ririnsẹ. Diẹ lara awọn aṣaaju-ọna ninu ẹgbẹ wa saba maa ngun ẹṣin lati kàn sí awọn eniyan ni awọn apa ori oke giga naa.

Lẹẹkanri a gbọ́ nipa ọkunrin olufifẹhan kan ti orukọ rẹ̀ njẹ Sam, ẹni ti a rí lẹhin-ọ-rẹhin ti ngbe ni ori oke giga kan. Ó fọyaya kí wa kaabọ ó sì layọ lati mu ki a sun mọju. Bi o tilẹ jẹ pe aya Sam ko nifẹẹ si ihin-iṣẹ wa, Rex, ọmọkunrin rẹ̀ ẹni ọdun mẹrindinlogun nifẹẹ sii. Nigba ti a fi ibẹ silẹ, Sam tun ké si wa pada. Nitori naa ni ọsẹ meji lẹhin naa, a tun gbé pẹlu wọn.

Lẹhin ti a fi ibẹ silẹ lẹẹkeji, aya Sam ni ó tun késí wa pada. Oun sọ pe awa ti ni ipa rere kan lori Rex. “Oun jẹ́ ọmọ buruku gbáà kan ti ó maa nlo awọn ọrọ eebu,” ni obinrin naa ṣalaye, “ti emi kò si lero pe oun tun lo awọn ọrọ eebu ti ó pọ̀ tó ti tẹlẹ lati igba ti ẹyin ọkunrin wọnyi ti wà nihin-in.” Ọpọ ọdun lẹhin naa mo tun pade Rex nigba ti ó lọ si ile-ẹkọ ojihin iṣẹ Ọlọrun ti Gilead ni South Lansing, New York. Awọn iriri bi iwọnyi ti mu itẹlọrun ńláǹlà wá fun mi la awọn ọdun ja.

Iṣẹ-isin Bẹtẹli

Nigba ti mo kọwe beere lati jẹ́ aṣaaju-ọna kan, mo tun beere bakan naa lati ṣiṣẹsin ni orile-iṣẹ awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni New York, ti a npe ni Bẹtẹli. Ni igba iruwe ọdun 1935, a fi tó mi leti pe iwe ibeere fun iṣẹ mi ni a ti tẹwọgba ati pe mo nilati farahan ni Kingdom Farm ti Watchtower Society ti ó wà ni South Lansing, New York, lati bẹrẹ iṣẹ-isin Bẹtẹli mi. Mo ṣe awọn eto lẹsẹkẹsẹ fun Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ mi kan lati bẹrẹ sii lo ọkọ onile agberin mi fun iṣẹ-isin aṣaaju-ọna.

Mo wa ọkọ Model A Ford ayọkẹlẹ mi lọ si New York, ati ni nǹkan bi agogo mẹwaa abọ ni owurọ May 3, 1935, mo gunlẹ sibẹ. Ni ọwọ́ aago kan ọsan ọjọ naa, a mu mi bẹrẹ iṣẹ ni lila awọn igi. Ni ọjọ keji, a sọ fun mi lati farahan ni ọgba awọn ẹranko lati ṣeranwọ ni fifun wàrà awọn maluu. Mo ṣiṣẹ ninu ọgba ti a ti nfun wàrà yii fun ọdun melookan, nigba miiran ni fifun wàrà ni owurọ ati ni aṣalẹ ati ni ṣiṣiṣẹ pẹlu awọn oṣiṣẹ ninu ọgba ewebẹ ati ninu ọgba irè oko ni ọsan. Mo nbojuto awọn kokoro oyin ti mo sì nkore oyin fun idile Bẹtẹli. Ni 1953, a ṣí mi nipo pada lọ si ẹka ti nṣe wàràkàṣì.

Ọ̀kan ninu awọn wọnni ti ó nipa lori igbesi-aye mi nitori awọn apẹẹrẹ titayọ ti irẹlẹ, iduroṣinṣin, ati igbọran si Jehofa ni Walter John “Pappy” Thorn. Oun jẹ́ ọkan lara awọn Akẹkọọ Bibeli 21 ti a yàn ni 1894 lati jẹ́ awọn arinrin-ajo akọkọ—awọn ọkunrin ti wọn nṣe iṣẹ kan naa ti o farajọra pẹlu ti awọn alaboojuto ayika lonii—ti wọn nṣebẹwo si awọn ijọ melookan lati fun wọn niṣiiri. Lẹhin ọpọ ọdun ninu iṣẹ irinrin-ajo, Arakunrin Thorn pada wa si Kingdom Farm ó sì ṣiṣẹ ni ile awọn adiyẹ. Lọpọ igba ni emi ti gbọ ọ ti o sọ pe: “Nigbakigba ti mo ba bẹrẹ sii ronu nipa ara mi ju bi ó ṣe yẹ lọ, emi a mú araami lọ si kọrọ kan, ki a sọ ọ lọna bẹẹ, ti emi yoo sì sọ pe: ‘Iwọ ekuru kíún lasanlasan yii. Ki ni ohun ti iwọ ni lati maa fi gberaga?’”

Ọkunrin oniwọntunwọnsi miiran ti ó di ẹni awofiṣapẹẹrẹ kan fun mi ni John Booth, ti ó jẹ́ mẹmba kan ninu Ẹgbẹ Oluṣakoso ti awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nisinsinyi. Oun ni a ti ṣe asọtunsọ awọn ọrọ rẹ̀ la ọpọ ọdun já ni sisọ pe: “Ibi ti o ti nṣiṣẹsin kò ni pupọ ṣe bikoṣe ẹni ti iwọ nṣiṣẹsin ni ó ṣe pataki nitootọ.” Gbolohun rirọrun kan ṣugbọn bawo ni ó ti jẹ́ otitọ tó! Ṣiṣiṣẹsin Jehofa ni eyi ti ó tobi julọ ninu gbogbo awọn anfaani!

Ọkan ninu awọn koko gbigbafiyesi ninu iṣẹ-isin Bẹtẹli mi ni ti ṣiṣi ile-ẹkọ ojihin iṣẹ Ọlọrun ti Gilead ni Kingdom Farm ni 1943. Kikẹgbẹpọ pẹlu awọn aṣaaju-ọna lati apa ibi pupọ ninu ayé jẹ́ ohun ti ó wúni lori niti gidi. Ni awọn ọjọ wọnni nǹkan bi ọgọrun-un akẹkọọ ni o wà ninu kilaasi kọọkan, nitori naa ni oṣu mẹfa mẹfa ọgọrun-un kan awọn ẹni titun ni wọn nwa si Kingdom Farm. Ayẹyẹ ikẹkọọyege jẹ eyi ti nfa ẹgbẹẹgbẹrun awọn eniyan wa si awọn ibi ohun èèlò idanilẹkọọ yii ni ilu igberiko apa oke New York.

Iyipada Iṣẹ

Nigba ti a ṣí ile-ẹkọ Gilead lọ si Brooklyn ti a sì ta awọn ile gbigbe ati yara ikawe ti ó wa ni South Lansing, ibi ọsin fun fífún wàrà maluu naa ni a ṣí lọ si Watchtower Farms ni Wallkill, New York. Nitori naa ni akoko iwọwe 1969, a ṣí mi nipo pada lọ si oko ti ó wà ni Wallkill, mo sì nbaa lọ lati maa ṣe wàràkàṣì titi di 1983. Nigba naa ni a tun fun mi ni iyipada kan ninu iṣẹ mi, ti mo sì bẹrẹ sii ṣiṣẹ ni fifi eweko ṣe oju ilẹ lọṣọọ.

Nigba ti a nfọrọ wa mi lẹnu wo ni akoko kan sẹhin, a beere lọwọ mi nipa ohun ti mo rò nipa yiyi iṣẹ mi pada lẹhin ọgbọn ọdun ninu ṣiṣe wàràkàṣì. “Kò daamu ọkàn mi rara,” ni mo ṣalaye lai fọrọ sabẹ ahọn, “nitori pe o ṣetan emi kò fẹran ṣiṣe wàràkàṣì.” Koko naa ni pe a lè layọ ni ṣiṣiṣẹsin Jehofa ninu iṣẹ ayanfunni eyikeyii bi a ba pa oju-iwoye titọna mọ ti a sì fi irẹlẹ juwọ araawa silẹ fun idari atọrunwa. Nitori naa bi o tilẹ jẹ pe emi kò fẹran ṣiṣe wàràkàṣì niti tootọ, mo gbadun iṣẹ ayanfunni mi nitori ó ṣeranlọwọ fun idile Bẹtẹli. Bi a ba fi tootọ tootọ ati airahun ṣiṣẹsin atobilọla Ọlọrun wa, Jehofa, awa lè layọ laika ohun yoowu ti iṣẹ ayanfunni wa jẹ́ sí.

Ni awọn akoko ti ara mi ti ndi kẹ́gẹkẹ̀gẹ, emi kò lero pe mo tun lè wà ni ipo ti ó dara ju ṣiṣiṣẹsin ni Bẹtẹli lọ. A ntọju mi dardara ti mo sì lè maa baa lọ ni ṣiṣe awọn iṣẹ ayanfunni mi koda bi emi tilẹ ti di ẹni 90 ọdun. Fun ọpọ ọdun nisinsinyi, mo ti ni anfaani jíjẹ́ alaga nibi itolẹsẹẹsẹ ijọsin owurọ ti idile Bẹtẹli nihin-in ni Watchtower Farms ni igba ti ó bá yipo kàn mi. Gẹgẹ bi emi ti ni anfaani rẹ̀, emi nfun awọn ẹni titun ni Bẹtẹli ni iṣiri lati lo gbogbo anfaani iṣẹ-isin ti a fun wọn lọna rere ki wọn sì kẹkọọ lati ni itẹlọrun ki wọn sì layọ pẹlu wọn.

La awọn ọdun ja, o ti ṣeeṣe fun mi ni ọpọ igba lati ṣebẹwo si awọn ilẹ okeere—India, Nepal, Ila Oorun Jijinna réré, ati Europe. Imọran ti ó tẹle e yii lè jẹ́ iranlọwọ fun awọn wọnni ti wọn wà lẹnikọọkan ninu ijọ awọn eniyan Ọlọrun yika ayé: Ẹ jẹ alayọ ki ẹ sì ni itẹlọrun ninu awọn ipo ayika ti isinsinyi ki ẹ sì maa yọ itanna lọna ti ẹmi ninu ilẹ ti a gbìn yin sí.

Emi ti yàn lati wà ni apọn, niwọn bi eyi ti mu ki ó ṣeeṣe fun mi lati maa baa lọ laini ipinya ọkàn ninu iṣẹ-isin mi si Ọlọrun. Gẹgẹ bi èrè fun iṣotitọ, Ọlọrun wa titobilọla ti funni ni ireti iwalaaye titilae. Fun ọpọlọpọ, eyi yoo tumọsi iwalaaye ailopin ninu ile paradise nihin-in lori ilẹ-aye. Awọn miiran lara wa nfojusọna si iwalaaye ailopin ninu awọn ọrun, ni bibojuto iṣẹ ayanfunni eyikeyii ti a lè fun wa.

Awọn diẹ lè lero pe 90 ọdun mi ti jẹ́ iwalaaye gigun kan, ti ó dọ́ṣọ̀. Igbesi-aye mi ti jẹ́ ọkan ti ó dọ́ṣọ̀ ṣugbọn ti kò ṣe bẹẹ gùn tó. Nipa rirọ timọtimọ mọ́ eto-ajọ Ọlọrun ati awọn ọrọ otitọ rẹ̀, awa lè mu iwalaaye wa gùn siwaju sii titi laelae.a

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ni akoko ti Roy Ryan nṣe akọsilẹ awọn iriri igbesi-aye rẹ̀, ipo ilera rẹ̀ yipada bìrí si eyi ti ó burujai. Ó pari ọna igbesẹ rẹ̀ ori ilẹ-aye ni July 5, 1991, laipẹ pupọ si ìgbà ti ó kó ipa rẹ̀ gẹgẹ bi alaga ti ó maa nyika deedee nibi ijọsin owurọ ni Watchtower Farms.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Arakunrin Ryan ni awọn ọdun ibẹrẹ rẹ̀ lẹbaa ọkọ Model T Ford

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́