ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 1/15 ojú ìwé 3-5
  • Ìkún-Omi Mánigbàgbé Naa

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìkún-Omi Mánigbàgbé Naa
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Akọsilẹ Bibeli Nipa Ìkún-omi Naa
  • Wíwá Aaki Naa Kiri
  • Ṣé Wọ́n Ti Rí Ọkọ̀ Nóà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ìkún-omi Ńlá
    Ìwé Ìtàn Bíbélì
  • Èèyàn Mẹ́jọ La Ìparun Já
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Kí Ni Àpótí Májẹ̀mú?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 1/15 ojú ìwé 3-5

Ìkún-Omi Mánigbàgbé Naa

NI NǸKAN bii 4,300 ọdun sẹhin, àkúnya alájàálù kan kún bo ilẹ-aye. Ni ìdàyàà ọ̀gbálẹ̀gbáràwé kan, ó pa ohun ti ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo ohun ti ó wà láàyè run. Ó gadabú tobẹẹ debi pe ó tẹ èrò ti kò ṣee parẹ mọ araye lọkan, iran kọọkan sì ta àtaré itan naa si eyi ti ó tẹle e.

Nǹkan bii 850 ọdun lẹhin Ìkún-omi naa, Mose onkọwe lede Heberu naa kọ iṣẹlẹ Àkúnya yika ayé naa sinu iwe. A pa á mọ́ sinu iwe Bibeli ti Jẹnẹsisi, nibi ti a ti lè ka awọn kulẹkulẹ ti ó ṣe kedere ninu ori 6 si 8.

Akọsilẹ Bibeli Nipa Ìkún-omi Naa

Jẹnẹsisi funni ni awọn kulẹkulẹ wọnyi, eyi ti ó han gbangba pe ó jẹ́ ti ẹlẹ́rìí ti ọran ṣoju rẹ̀: “Ni ẹgbẹta ọdun ọjọ ayé Noa, ni oṣu keji, ni ọjọ kẹtalelogun [“kẹtadinlogun,” King James Version (Gẹẹsi)] oṣu, ni ọjọ naa ni gbogbo ìsun ibú nla ya, ati ferese iṣàn omi ọrun sì ṣí silẹ. Ìkún-omi sì wà ni ogoji ọjọ lori ilẹ; omi sì ń wú sii, ó sì mu ọkọ fó soke, ó sì gbera kuro lori ilẹ. Omi sì gbilẹ gidigidi lori ilẹ; ati gbogbo oke giga, ti ó wà ni gbogbo abẹ ọrun, ni a bò mọlẹ.”—Jẹnẹsisi 7:11, 17, 19.

Niti ipa ti Ìkún-omi naa ní lori awọn ohun alaaye, Bibeli wi pe: “Gbogbo ẹ̀dá ti ń rìn lori ilẹ sì kú, ti ẹyẹ, ti ẹran-ọsin, ti ẹranko, ti ohun gbogbo ti ń rákò lori ilẹ ati gbogbo eniyan.” Bi o ti wu ki o ri, Noa ati awọn ẹni meje miiran là á já, papọ pẹlu apẹẹrẹ kan ti olukuluku ẹranko, ẹyẹ, ati ohun ti ń rìn lori ilẹ. (Jẹnẹsisi 7:21, 23) Gbogbo wọn ni a ti tọju pamọ sinu aaki ńlá kan ti ó léfòó ti ó jẹ nǹkan bii 437 ẹsẹ bata ni gigun, 73 ẹsẹ bata ni fífẹ̀, ati 44 ẹsẹ bata ni giga. Niwọn bi ète kanṣoṣo ti aaki naa ń ṣiṣẹ fun ti jẹ́ ki ó má fàyè gba omi ati pe ki ó léfòó, kò ni isalẹ ti ó ṣe rogodo, imú bẹngọ, ohun eelo ìgbọ́kọ̀rìn, tabi ohun eelo fun ìtukọ. Aaki Noa wulẹ jẹ́ ọkọ oju omi onigun mẹrin, ti ó dabi apoti kan ni.

Oṣu marun-un lẹhin ti Àkúnya naa bẹrẹ, aaki naa fidikalẹ lori oke Ararati, ti ó wà ni iha ila-oorun Turkey ti ode-oni. Noa ati idile rẹ̀ jade kuro ninu aaki naa sori ilẹ gbígbẹ ni ọdun kan lẹhin ti Ìkún-omi naa bẹrẹ wọ́n sì mu ọna iṣiṣẹ deedee ti igbesi-aye pọ̀n lakọtun. (Jẹnẹsisi 8:14-19) Bi akoko ti ń lọ, araye ti di pupọ sii lọna ti ó tó lati bẹrẹ kíkọ́ ilu Babeli ati ilé-ìṣọ́ olokiki buruku rẹ̀ lẹbaa Odo Yufirete. Lati ibẹ̀, awọn eniyan ni a fọ́nká ni kẹrẹkẹrẹ si gbogbo apa ilẹ-aye nigba ti Ọlọrun da èdè araye rú. (Jẹnẹsisi 11:1-9) Ṣugbọn ki ni ó ṣẹlẹ si aaki yẹn?

Wíwá Aaki Naa Kiri

Lati ọrundun kọkandinlogun, ọpọlọpọ awọn igbidanwo lati rí aaki naa lori oke Ararati ni ó ti wà. Awọn oke wọnyi ni ṣonṣo yíyọgọmbu meji, ọ̀kan jẹ́ 16,950 ẹsẹ bata ni giga ekeji sì jẹ́ 12,840 ẹsẹ bata. Eyi ti ó gaju ninu awọn mejeeji ni yìnyín ń bò nigba gbogbo. Nitori awọn iyipada oju ọjọ ti ó tẹle Ìkún-omi naa, aaki naa ni yìnyín bò mọ́lẹ̀ laipẹ. Awọn oluwadii kan gbagbọ gbọnyingbọnyin pe aaki naa ṣì wà nibẹ, ti o rì mọlẹ jinlẹ ninu ìṣàn okiti yìnyín. Wọn sọ pe awọn akoko ti wà nigba ti yìnyín naa yọ́ de iwọn ti ó tó lati jẹ́ ki apakan aaki naa farahan fun ìgbà diẹ.

Iwe naa In Search of Noah’s Ark fa ọrọ George Hagopian, ara Armenia kan yọ, ẹni ti ó sọ pe oun gun Oke Ararati ti oun sì ri aaki naa ni 1902 ati lẹẹkansii ni 1904. Ni ibẹwo akọkọ, ó sọ pe, oun gun ori aaki naa niti gidi. “Mo nàró ṣanṣan mo sì wo gbogbo ori ọkọ naa. Ó gùn gbọọrọ. Giga rẹ jẹ́ nǹkan bii ogoji ẹsẹ bata.” Nipa iṣakiyesi rẹ̀ ní ibẹwo rẹ̀ ti ó tẹle, o wi pe: “Emi kò ri ibikibi tí ó pọ̀gbún. Kò dabii ọkọ oju omi eyikeyii miiran ti mo tii rí rí. Ó tubọ farajọ ọkọ-ìgbàjà onidii pẹrẹsẹ kan.”

Lati 1952 si 1969, Fernand Navarra ṣe awọn isapa mẹrin lati rí ẹ̀rí aaki naa. Ni irin-ajo rẹ̀ kẹta sori Oke Ararati, ó wá ọna lọ si isalẹ pàlàpálá kan ninu ìṣàn okiti yìnyín, nibi ti ó ti rí ẹ̀là igi dudu kan ti o rì sinu yìnyín. Ó sọ pe, “o ti nilati pẹ́ gidigidi gan-an, ó sì ṣeeṣe ki ó so mọ apa miiran lara igbekalẹ ọkọ naa sibẹ. Niṣe ni mo kàn lè gé e lati oju ẹ̀là igi titi ti mo fi la ègé kan ti ó jẹ́ nǹkan bi ẹsẹ bata marun-un ni gigun kuro.”

Ọjọgbọn Richard Bliss, ọ̀kan lara awọn ogbontarigi melookan ti ó ṣayẹwo igi naa, wi pe: “Apakan igi Navarra naa jẹ́ ìtì igi ikọle ti a sì fi ọ̀dà ilẹ bò. Ó ni oju ihò àkìbọra. Ó jẹ́ eyi ti a fọwọ́gbẹ́ dajudaju ó sì jẹ́ onigun mẹrin.” Ọjọ-ori ti a foju bù fun igi naa ni a fi si nǹkan bii ẹgbẹrun-un ọdun mẹrin tabi marun-un.

Bi o tilẹ jẹ pe awọn isapa ni a ti ṣe lati rí aaki naa lori Oke Ararati, ẹ̀rí pato naa pe a lo o lati la àjálù àkúnya kan já wà ninu irohin akọsilẹ iṣẹlẹ yẹn ninu iwe Bibeli ti Jẹnẹsisi. Ẹri ti o fi otitọ akọsilẹ yẹn mulẹ ni a lè ri ninu ọpọlọpọ iye ìtàn-àròsọ nipa ìkún-omi laaarin awọn eniyan àtijọ́tijọ̀ ni gbogbo ayé. Gbé ẹ̀rí wọn yẹwo ninu ọrọ-ẹkọ ti o kàn yii.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4, 5]

Aaki naa ni àyè ìkẹ́rùsí ti ó dọgba pẹlu ọkọ̀ ojú irin agbápòótí ẹrù 10 tí ọkọọkan kó nǹkan bii 25 ọkọ apoti ẹrù ti America!

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́