ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 1/15 ojú ìwé 5-8
  • Ìkún-Omi naa Ninu Ìtàn-Àròsọ Ayé

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìkún-Omi naa Ninu Ìtàn-Àròsọ Ayé
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Awọn Ifarajọra Afafiyesi
  • Awọn Ìtàn-Àròsọ Ìkún-Omi Igbaani
  • Ìtàn-Àròsọ ti Ila-Oorun Jíjìnnàréré
  • Ni Awọn Ilẹ America
  • South Pacific ati Asia
  • Ipilẹṣẹ Kan Naa
  • Ṣé Ìtàn Àròsọ Lásán Ni Ìtàn Nóà àti Ìkún Omi?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Odindi Ayé Kan Pa Run Yán-ányán-án!
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Ìkún-Omi Ìgbà Ayé Nóà—Òótọ́ Pọ́ńbélé Ni, Kì Í Ṣe Ìtàn Àròsọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Ìkún Omi Náà Òtítọ́ Tàbí Àròsọ?
    Jí!—1997
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 1/15 ojú ìwé 5-8

Ìkún-Omi naa Ninu Ìtàn-Àròsọ Ayé

ÌKÚN-OMI ọjọ Noa jẹ́ iru àjálù ojiji apanirun kan tobẹẹ ti araye kò lè gbagbe rẹ̀ lae. Ni ohun ti ó ju 2,400 ọdun lẹhin naa, Jesu Kristi sọrọ nipa rẹ̀ gẹgẹ bi otitọ kan ninu ìtàn. (Matiu 24:37-39) Iṣẹlẹ abanilẹru yii tẹ iru èrò kan ti kò ṣee parẹ mọ iran eniyan lọkan debi pe ó ti di onítàn-àròsọ ni gbogbo ayé.

Ninu iwe naa Myths of Creation, Philip Freund foju diwọn rẹ̀ pe ìtàn-àròsọ Ìkún-omi ti ó ju 500 lọ ni 250 ẹ̀yà èdè ati awọn eniyan ń sọ. Gẹgẹ bi a ti lè reti, pẹlu ikọjalọ ọpọlọpọ ọrundun, awọn ìtàn-àròsọ wọnyi ni a ti sọ lasọdun gidigidi pẹlu awọn iṣẹlẹ ati awọn eniyan ti a finúrò. Bi o ti wu ki o ri, ninu gbogbo wọn, ifarajọra ipilẹ diẹ ni a lè rí.

Awọn Ifarajọra Afafiyesi

Bi awọn eniyan ti ṣí kuro ni Mesopotamia lẹhin Ìkún-omi, wọn gbé awọn irohin àjálù ojiji naa lọ si gbogbo awọn apa ilẹ-aye. Nipa bayii, awọn olugbe Asia, awọn erekuṣu Guusu Pacific, North America, Central America, ati South America ní ìtàn iṣẹlẹ awọnilọ́kàn yii. Ọpọlọpọ ìtàn-àròsọ Ìkún-omi ti wà tipẹtipẹ ṣaaju ki awọn eniyan wọnyi tó dojulumọ Bibeli. Sibẹ, awọn ìtàn-àròsọ naa ní awọn koko ipilẹ melookan ni ìjọra pẹlu akọsilẹ Àkúnya ti Bibeli.

Awọn ìtàn-àròsọ diẹ mẹnukan awọn òmìrán oniwa-ipa ti wọn ń gbé lori ilẹ-aye ṣaaju Ìkún-omi. Lọna ti ó ṣee fiwera, Bibeli fihan pe ṣaaju Àkúnya naa awọn angẹli alaigbọran gbe ẹran-ara wọ̀, wọn gbé papọ pẹlu awọn obinrin bi alajọgbeyawo, wọn sì bí ẹ̀yà iran awọn òmìrán ti a pè ni Nefilimu.—Jẹnẹsisi 6:1-4; 2 Peteru 2:4, 5.

Awọn ìtàn-àròsọ Ìkún-omi saba maa ń fihan pe ọkunrin kan ni a kilọ fun nipa àkúnya ti ń bọ̀ tí ó ni ipilẹṣẹ atọrunwa. Gẹgẹ bi Bibeli ti wí, Jehofa Ọlọrun kilọ fun Noa pe Oun yoo pa awọn ẹni buburu ati oniwa-ipa run. Ọlọrun sọ fun Noa pe: “Opin gbogbo ẹran-ara ti de iwaju mi, nitori pe ilẹ-aye kún fun iwa-ipa gẹgẹ bi iyọrisi wọn; ati nihin-in ni emi ń mú wọn wá sí iparun papọ pẹlu ilẹ-aye.”—Jẹnẹsisi 6:13, New World Translation (Gẹẹsi).

Awọn ìtàn-àròsọ nipa Ìkún-omi ni gbogbogboo fihan pe ó mu iparun yika ayé wa. Bakan naa, Bibeli wi pe: “Omi sì gbilẹ gidigidi lori ilẹ; ati gbogbo oke giga, ti ó wà ni gbogbo abẹ ọrun, ni a bò mọ́lẹ̀. Gbogbo ohun ti ẹmi ìye wà ni ihò imu rẹ̀, gbogbo ohun ti o wà ni iyangbẹ ilẹ si kú.”—Jẹnẹsisi 7:19, 22.

Ọpọjulọ awọn ìtàn-àròsọ Ìkún-omi sọ pe ọkunrin kan la Àkúnya naa já papọ pẹlu ẹnikan tabi awọn ẹni pupọ sii miiran. Ọpọlọpọ ìtàn-àròsọ sọ nipa rẹ̀ pe o wá ibi ìsádi ninu ọkọ kan ti ó ti kàn, wọn sì sọ pe ó gunlẹ sori oke kan. Lọna ti o ṣee fiwera, Iwe Mimọ sọ pe Noa kan aaki kan. Wọn tun sọ pe: “Noa nikan ni o kù, ati awọn ti ó wà pẹlu rẹ̀ ninu ọkọ̀.” (Jẹnẹsisi 6:5-8; 7:23) Gẹgẹ bi Bibeli ti wí, lẹhin Àkúnya naa ‘ọkọ̀ naa kanlẹ̀ lori oke Ararati,’ nibi ti Noa ati idile rẹ̀ ti sọkalẹ. (Jẹnẹsisi 8:4, 15-18) Awọn ìtàn-àròsọ tun fihan pe awọn olùla Ìkún-omi já bẹrẹ sii fi eniyan kún ilẹ-aye lakọtun, gẹgẹ bi Bibeli ti fihan pe idile Noa ti ṣe.—Jẹnẹsisi 9:1; 10:1.

Awọn Ìtàn-Àròsọ Ìkún-Omi Igbaani

Pẹlu awọn koko ti a ṣẹṣẹ sọ tan yii ni ọkan, ẹ jẹ ki a gbe awọn ìtàn-àròsọ Ìkún-omi diẹ yẹwo. Ki a sọ pe a bẹrẹ pẹlu awọn ara Sumeria, awọn eniyan igbaani ti wọn gbé Mesopotamia. Ẹ̀dà ìtàn Àkúnya tiwọn ni a rí lara wàláà alámọ̀ kan ti a hú jade ninu àlàpà Nippur. Wàláà yii sọ pe awọn ọlọrun Sumeria Anu ati Enlil pinnu lati pa araye run pẹlu ìkún-omi ńlá kan. Bi a ti kilọ fun un nipasẹ ọlọrun naa Enki, Ziusudra ati idile rẹ̀ ni o ṣeeṣe fun lati là á já ninu ọkọ̀ fàkìàfakia kan.

Orin-ewì akọni Gilgamesh ti Babiloni ní ọpọlọpọ awọn kulẹkulẹ ninu. Gẹgẹ bi ó ti wi, Gilgamesh bẹ Utnapishtim babanla rẹ wò, ẹni ti a ti yọnda ìyè ayeraye fun lẹhin lila Ìkún-omi já. Ninu ijumọsọrọpọ ti o waye lẹhin naa, Utnapishtim ṣalaye pe a sọ fun oun lati kan ọkọ̀ oju omi kan ki oun sì kó awọn ẹran-ọ̀sìn, awọn ẹranko, ati idile oun sinu rẹ̀. Ó kan ọkọ̀ oju omi naa bii irisi apoti titobi ti ó jẹ́ 200 ẹsẹ bata lẹgbẹẹ kọọkan, pẹlu àjà mẹfa. Ó sọ fun Gilgamesh pe òjò oníjì líle naa rọ̀ fun ọjọ mẹfa ati òru mẹfa, ati lẹhin naa o wi pe: “Nigba ti ọjọ keje dé, ìjì lile naa, Àkúnya naa, ìpayà ìjà ogun naa ni a fopin sí, eyi ti o ti ṣakọlu gẹgẹ bi ẹgbẹ ogun. Okun di eyi ti ó parọrọ, ìjì àfẹ́yíká naa rọlẹ̀, Àkúnya naa dáwọ́ duro. Mo wo oju okun ìró awọn ohùn sì ti dopin. Gbogbo araye sì ti yipada di amọ̀.”

Lẹhin ti ọkọ̀ naa ti fìdí kanlẹ lori Oke Nisir, Utnapishtim tú oriri kan silẹ eyi ti ó pada sinu ọkọ̀ naa nigba ti kò lè ri ibi isinmi. Lẹhin naa ni ẹyẹ oriri kan ti oun pẹlu tun pada. Ẹyẹ ìwo kan ni a tú silẹ lẹhin naa, nigba ti kò si pada, ó mọ pe omi naa ti lọ silẹ. Utnapishtim tú awọn ẹran silẹ lẹhin naa ó sì ṣe irubọ kan.

Itan àròsọ ìgbà atijọ yii ni ó jọra pẹlu akọsilẹ ti Bibeli nipa Ìkún-omi lọna kan ṣáá. Bi o ti wu ki o ri, kò ni awọn kulẹkulẹ kínníkínní ati iṣekedere ti akọsilẹ Bibeli ni, kò si funni ni ìwọ̀n ti ó bọgbọnmu fun aaki naa tabi pese saa akoko ti a fihan ninu Iwe Mímọ́. Fun apẹẹrẹ, Orin-ewi Gilgamesh sọ pe òjò oníjì líle naa rọ̀ fun ọjọ mẹfa ati òru mẹfa, nigba ti Bibeli sọ pe “ojo naa sì wà lori ilẹ ni ogoji ọsan ati ogoji òru”—ojo àrọ̀ọ̀rọ̀dá ti ń baa lọ tí ó bo gbogbo obirikiti ilẹ-aye pẹlu omi.—Jẹnẹsisi 7:12.

Bi o tilẹ jẹ pe Bibeli mẹnukan awọn olùla Ìkún-omi naa já ti wọn jẹ́ mẹjọ, ninu ìtàn-àròsọ Giriiki kiki Deucalion ati aya rẹ̀, Pyrrha, ni wọn là á já. (2 Peteru 2:5) Gẹgẹ bi ìtàn-àròsọ yii ti sọ, ṣaaju Ìkún-omi ilẹ-aye ni awọn eniyan oniwa-ipa ti a pe ni awọn ọkunrin àdàlù bàbà ati tánńganran ń gbe. Zeus ọlọrun naa pinnu lati pa wọn run pẹlu ìkún-omi ńlá ó sì sọ fun Deucalion lati kan apoti titobi kan ki ó sì wọnu rẹ̀. Nigba ti ìkún-omi naa rọlẹ, apoti naa wá sinmi sori Oke Parnassus. Deucalion ati Pyrrha sọkalẹ lati ori oke wọn sì bẹrẹ araye lẹẹkan sii.

Ìtàn-Àròsọ ti Ila-Oorun Jíjìnnàréré

Ni India ìtàn-àròsọ Ìkún-omi kan wà ninu eyi ti Manu ti jẹ́ ẹni ti o là á já. Ó ba ẹja kekere kan ti ó dagba di ńlá ṣọ̀rẹ́ ó sì kilọ fun un nipa ìkún-omi ti ń panirun kan. Manu kan ọkọ̀ kan, eyi ti ẹja naa fà titi ti ó fi kanlẹ lori oke kan ninu awọn oke Himalaya. Nigba ti ìkún-omi naa rọlẹ, Manu sọkalẹ lati ori oke ati pẹlu Ida, apẹẹrẹ pipe ti ẹbọ rẹ̀, ó tun iran eniyan sọdọtun.

Gẹgẹ bi ìtàn-àròsọ ìkún-omi awọn ara China ti wí, ọlọrun àrá fun awọn ọmọde meji, Nuwa ati Fuxi ni eyín. Ó fun wọn nítọ̀ọ́ni lati gbìn ín ati lati sápamọ́ sinu akèrègbè ti yoo so lati inu rẹ̀. Igi kan hù lọ́gán lati inu eyín naa ó sì so akeregbe kan. Nigba ti ọlọrun àrá ṣokunfa ojo alágbàrá ńlá, awọn ọmọde naa gun ori akèrègbè naa. Bi o tilẹ jẹ pe ìkún-omi ti o tibẹ ṣẹlẹ pa gbogbo ìyókù awọn olugbe ilẹ-aye, Nuwa ati Fuxi là á já wọn sì fi eniyan olùgbé kun gbogbo ayé pada.

Ni Awọn Ilẹ America

Awọn ará India ti North America ni oniruuru ìtàn-àròsọ ti ó ni ẹṣin-ọrọ kan naa ti ìkún-omi ti ó pa gbogbo eniyan run ayafi iwọnba awọn eniyan. Fun apẹẹrẹ, Arikara, awọn eniyan Caddo, sọ pe ilẹ-aye ni iran awọn eniyan kan ń gbé nigba kan rí ti wọn jẹ́ alagbara gan-an debi pe wọn fi awọn ọlọrun ṣẹlẹya. Ọlọrun naa Nesaru pa awọn òmìrán wọnyi run nipasẹ ìkún-omi kan ṣugbọn ó pa awọn eniyan rẹ̀, awọn ẹran rẹ̀, ati agbado mọ sinu ihò kan. Awọn eniyan Havasupai sọ pe ọlọrun Hokomata ṣokunfa ìkún-omi kan ti ó pa araye run. Bi o ti wu ki o ri, ọkunrin naa Tochopa tọju Pukeheh ọmọbinrin rẹ̀ pamọ nipa dídì í pa mọnu ìtì igi oniho kan.

Awọn ará India ni Central ati South America ní ìtàn-àròsọ ìkún-omi ti o ní awọn ifarajọra ṣiṣekoko. Awọn ará Maya ti Central America gbagbọ pe ejo ńlá olójò kan pa aye run nipasẹ ọ̀gbàrá omi. Ni Mexico ẹ̀dà ìtàn awọn Chimalpopoca sọ pe ìkún-omi kan bo awọn oke. Tezcatlipoca ọlọrun naa kilọ fun ọkunrin naa Nata, ẹni ti o gbẹ́ ihò sinu ìtì igi kan nibi ti oun ati aya rẹ̀, Nena, ti ri ibi ìsádi titi omi naa fi rọlẹ.

Ni Peru awọn ará Chincha ní ìtàn-àròsọ ti ìkún-omi ọlọjọ marun-un kan ti ó pa gbogbo eniyan ayafi ẹnikan tí ẹran llama tí ń fọhun bi eniyan ṣamọna lọ si ibi aabo lori oke kan. Awọn ará Aymara ti Peru ati Bolivia sọ pe ọlọrun Viracocha jade lati inu Adágún omi Titicaca ó sì dá aye ati awọn ọkunrin alagbara, ti wọn tobi lọna òdì. Nitori pe iran akọkọ yii mu un binu, Viracocha pa wọn run pẹlu ìkún-omi kan.

Awọn ará India ẹya Tupinamba ti Brazil sọrọ nipa akoko kan nigba ti ìkún-omi ńlá kan pa gbogbo awọn babanla wọn run ayafi awọn wọnni ti wọn là á já ninu awọn ọkọ̀ òbèlè tabi ni ori awọn igi giga. Awọn ará Cashinaua ti Brazil, awọn Macushi ti Guyana, awọn Carib ti Central America, ati awọn Ona ati Yahgan ti Tierra del Fuego ni South America wà lara awọn ọpọlọpọ ẹ̀yà ti wọn ni ìtàn-àròsọ ìkún-omi.

South Pacific ati Asia

Jakejado South Pacific, awọn ìtàn-àròsọ ìkún-omi ti o ni iwọnba eniyan diẹ ti wọn yèbọ́ ninu wọ́pọ̀. Fun apẹẹrẹ, ni Samoa ìtàn-àròsọ kan wà nipa ìkún-omi ni awọn ìgbà ijimiji ti ó pa gbogbo eniyan run ayafi Pili ati aya rẹ̀. Wọn rí aabo lori apata kan, ati lẹhin ìkún-omi naa wọn fi eniyan kun ilẹ-aye lẹẹkansii. Ni awọn Erekuṣu Hawaii, ọlọrun naa Kane binu si awọn eniyan ó sì ran ìkún-omi lati pa wọn run. Kiki Nuʹu ni ó yèbọ́ ninu ọkọ̀ oju omi ńlá kan ti ó kanlẹ lẹhin-ọ-rẹhin lori oke kan.

Lori Erekuṣu Mindanao ni Philippines, awọn Ata sọ pe ilẹ-aye ni a fi omi ti ó ṣekupa gbogbo eniyan kún nigba kan rí ayafi awọn ọkunrin meji ati obinrin kan. Iban ti Sarawak, Borneo, sọ pe kiki iwọnba awọn eniyan diẹ ni wọn yebọ lọwọ àkúnya kan nipa sisalọ sori oke gigajulọ. Ninu ìtàn-àròsọ Igorot ti Philippines, kiki arakunrin ati arabinrin kan ni wọn yèbọ́ nipa wiwa ìsádi lori Oke Pokis.

Awọn Soyot ti Siberia, Russia, sọ pe ọ̀pọ̀lọ́ ńlá kan, eyi ti o gbé ayé ró, yẹra ó sì fa ki omi kún bo ayé. Ọkunrin arugbo kan ati idile rẹ̀ là á já lori adipọ igi líléfòó ti ó ti ṣe. Nigba ti omi naa lọ silẹ, adipọ igi líléfòó naa kanlẹ lori oke giga kan. Awọn ara Ugria ti iha iwọ-oorun Siberia ati Hungary tun sọ pe awọn olùla ìkún-omi já lo adipọ igi líléfòó ṣugbọn wọn wọ́ lọ si awọn apá ọtọọtọ ni ilẹ-aye.

Ipilẹṣẹ Kan Naa

Ki ni a lè pari ero sí lati inu ọpọlọpọ awọn ìtàn-àròsọ Ìkún-omi wọnyi? Bi o tilẹ jẹ pe wọn yatọ sira gidigidi ní kulẹkulẹ alaye, wọn ni awọn iha jijọra diẹ. Iwọnyi tọkasi orisun kan ninu awọn àjálù ojiji ńláǹlà ti ó sì jẹ́ mánigbàgbé. Laika oniruuru iyatọ ninu ìtàn naa la ọpọ ọrundun já sí, ẹṣin-ọrọ wọn dabi fọ́nrán òwú ti o so wọn pọ mọ iṣẹlẹ ńlá kan—Àkúnya yika aye ti a sọ ninu akọsilẹ rirọrun, ti a ko fikun ninu Bibeli.

Niwọn bi a ti ri ìtàn-àròsọ Ìkún-omi ni gbogbogboo laaarin awọn eniyan ti wọn kò mọ Bibeli titi fi di ọrundun ẹnu aipẹ yii, yoo jẹ aṣiṣe lati jiyan pe akọsilẹ Iwe Mimọ nipa lori wọn. Siwaju sii, The International Standard Bible Encyclopedia sọ pe: “Kikari ti awọn akọsilẹ ìkún-omi naa kari gbogbo agbaye ni a saba maa ń gbà gẹgẹ bi ẹ̀rí fun iparun iran eniyan kari ayé nipasẹ ìkún-omi kan . . . Siwaju sii, diẹ lara awọn akọsilẹ igbaani ni awọn eniyan ti wọn lodi gidigidi si aṣa atọwọdọwọ awọn Heberu ati Kristẹni kọ.” (Idipọ 2, oju-iwe 319) Nitori naa a lè fi igbọkanle pari èrò pe ìtàn-àròsọ Ìkún-omi jẹwọ ijotiitọ akọsilẹ Bibeli.

Gẹgẹ bi a ti ń gbé ninu aye kan ti iwa-ipa ati iwa palapala kun, ó dara ki a ka akọsilẹ Bibeli nipa Ìkún-omi naa, gẹgẹ bi a ti ṣakọsilẹ rẹ ninu Jẹnẹsisi ori 6 de 8. Bi a bá ronu jinlẹ lori idi fun Àkúnya yika ayé yẹn—ṣiṣe ohun ti ó jẹ́ buburu loju Ọlọrun—awa yoo ri ikilọ ti ó ṣe pataki ninu rẹ̀.

Laipẹ eto igbekalẹ awọn nǹkan buburu isinsinyi ni yoo niriiri idajọ alailojurere Ọlọrun. Bi o ti wu ki o ri, lọna ti ó muni layọ, awọn olùlá á já yoo wà. Iwọ lè wà laaarin wọn bi iwọ ba kọbiara si awọn ọrọ apọsiteli Peteru pe: “Nipa eyi ti omi bo ayé ti ó wà nigba [Noa], ti o sì ṣègbé. Ṣugbọn awọn ọrun ati ayé, ti ń bẹ nisinsinyi, nipa ọ̀rọ̀ kan naa ni a ti tojọ bi iṣura fun iná, a pa wọn mọ́ de ọjọ idajọ ati iparun awọn alaiwa-bi-Ọlọrun. . . . Ǹjẹ́ bi gbogbo nǹkan wọnyi yoo ti yọ́ nì, iru eniyan wo ni ẹyin ìbá jẹ́ ninu iwa mímọ́ gbogbo ati iwa-bi-Ọlọrun, ki ẹ maa reti, ki ẹ si maa mura giri de dide ọjọ Ọlọrun.”—2 Peteru 3:6-12.

Iwọ yoo ha pa dídé ọjọ Jehofa mọ pẹkipẹki sọ́kàn bi? Bi o ba ṣe bẹẹ ti o sì gbegbeesẹ ni ibamu pẹlu ifẹ-inu Ọlọrun, iwọ yoo gbadun awọn ibukun ńláǹlà. Awọn wọnni ti wọn tipa bayii wu Jehofa Ọlọrun lè ni igbagbọ ninu ayé titun eyi ti Peteru ń tọka si nigba ti ó fikun un pe: “Ṣugbọn gẹgẹ bi ileri rẹ̀, awa ń reti awọn ọrun titun ati ayé titun, ninu eyi ti ododo ń gbé.”—2 Peteru 3:13.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Itan àròsọ ìkún-omi awọn ara Babiloni ni a ta latare lati ọwọ iran kan si omiran

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Iwọ ha ń kọbiara si ikilọ Peteru nipa pipa ọjọ Jehofa mọ sọ́kàn bi?

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́