ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w02 3/1 ojú ìwé 3-5
  • Odindi Ayé Kan Pa Run Yán-ányán-án!

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Odindi Ayé Kan Pa Run Yán-ányán-án!
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Lóòótọ́ Ni Ayé Ìgbàanì Kan Pa Run?
  • Ìkún-Omi naa Ninu Ìtàn-Àròsọ Ayé
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ṣé Ìtàn Àròsọ Lásán Ni Ìtàn Nóà àti Ìkún Omi?
    Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ìkún-Omi Ìgbà Ayé Nóà—Òótọ́ Pọ́ńbélé Ni, Kì Í Ṣe Ìtàn Àròsọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2008
  • Àkọsílẹ̀ Nípa Ọjọ́ Nóà—Ǹjẹ́ ó Ṣe Pàtàkì Fún wa?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2002
w02 3/1 ojú ìwé 3-5

Odindi Ayé Kan Pa Run Yán-ányán-án!

Wo ayé wa yìí. Wo àwọn ìlú ńlá inú rẹ̀. Wo onírúurú àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ tó wà níbẹ̀. Wo ibi tó ti tẹ̀ síwájú dé nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀. Tún wo ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tí ń gbénú rẹ̀. Kò jọ pé mìmì kan lè mì í láé, àbí ó jọ bẹ́ẹ̀? Ǹjẹ́ o rò pé ayé yìí lè pòórá lọ́jọ́ kan? Ṣàṣà lẹni tó máa rò bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ o mọ̀ pé ìwé kan tí kì í fìkan pe méjì sọ fún wa pé ayé kan tó wà ṣáájú ayé tiwa yìí pa run yán-ányán-án?

KÌ Í ṣe ayé kan tí kò lajú là ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ o. Ayé ọ̀làjú layé tó ṣègbé ọ̀hún. Ayé tó ní àwọn ìlú ńláńlá ni, tí kò sì kẹ̀rẹ̀ nínú iṣẹ́ ọnà. Ayé onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ni. Síbẹ̀, àkọsílẹ̀ Bíbélì sọ fún wa pé lójijì, ní ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù kejì, ọdún méjìdínláàádọ́ta dín nírínwó [352] ká tó bí baba ńlá náà Ábúráhámù, ìkún omi kan dé tó gbá gbogbo ayé yẹn lọ ráúráú.a

Ṣé òótọ́ lohun tí àkọsílẹ̀ yẹn sọ? Ṣé òótọ́ ni nǹkan tó jọ bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀? Ṣé òótọ́ layé kan wà ṣáájú ayé òde òní tó jẹ́ ayé ọ̀làjú, àmọ́ tó pa run nígbà tó yá? Tó bá rí bẹ́ẹ̀ lóòótọ́, kí nìdí tó fi pa run? Kí ló ṣẹlẹ̀? Ǹjẹ́ a lè rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú ohun tó fa ìparun rẹ̀?

Ṣé Lóòótọ́ Ni Ayé Ìgbàanì Kan Pa Run?

Bó bá jẹ́ pé òótọ́ ni irú àjálù ńlá bẹ́ẹ̀ ṣẹlẹ̀, kò tíì lè pa rẹ́ pátápátá nínú ìtàn. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé àwọn nǹkan kan wà tí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ṣì fi ń rántí ìparun yẹn. Bí àpẹẹrẹ, ṣàkíyèsí ọjọ́ pàtó tí Ìwé Mímọ́ sọ pé ó ṣẹlẹ̀. Oṣù kejì nínú kàlẹ́ńdà ìgbàanì bẹ̀rẹ̀ láti àárín October tiwa, títí lọ dé àárín November. Nítorí náà, ọjọ́ kẹtàdínlógún oṣù náà á bọ́ sí nǹkan bí ọjọ́ kìíní November. Fún ìdí yìí, kò lè jẹ́ pé ó ṣèèṣì bọ́ sí i pé àyájọ́ yìí ni wọ́n máa ń ṣọdún àwọn tó ti kú láwọn ibì kan.

Àwọn ẹ̀rí míì tó fi hàn pé Ìkún Omi ṣẹlẹ̀ ṣì ń bẹ nínú àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ aráyé. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ìran ènìyàn ló ní ìtàn àtẹnudẹ́nu tó fi hàn pé àwọn baba ńlá wọn la ìkún omi kan tó kárí ayé já. Àwọn Kúrékùré ilẹ̀ Áfíríkà, àwọn ẹ̀yà Celt ilẹ̀ Yúróòpù, àwọn ará Inca tí ń gbé ní Gúúsù Amẹ́ríkà—gbogbo wọn ló ní ìtàn àtẹnudẹ́nu tó jọra, bẹ́ẹ̀ náà ni a tún ń gbọ́ irú ìtàn bẹ́ẹ̀ lẹ́nu àwọn èèyàn Alaska, China, Íńdíà, Lithuania, Mẹ́síkò, Micronesia, New Zealand, Ọsirélíà, àtàwọn ibì kan ní Àríwá Amẹ́ríkà, ká kàn mẹ́nu kan àwọn díẹ̀.

Àmọ́ ṣá o, bọ́dún ti ń gorí ọdún ni wọ́n ń bù mọ́ àwọn ìtàn náà. Síbẹ̀ gbogbo irú ìtàn bẹ́ẹ̀ ló ní àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tó fi hàn pé ìṣẹ̀lẹ̀ kan náà ni wọ́n ń tọ́ka sí, èyíinì ni pé: ìwà ibi aráyé mú kí ìbínú Ọlọ́run ru. Ó fi ìkún omi ńlá kan bá wọn jà. Ó pa gbogbo aráyé run. Àmọ́, ó dá àwọn olóòótọ́ díẹ̀ sí. Àwọn olóòótọ́ wọ̀nyí kan ọkọ̀ kan tí àwọn èèyàn àtàwọn ẹranko tó là á já wọnú rẹ̀. Nígbà tó yá, wọ́n rán àwọn ẹyẹ jáde láti lọ wò ó bóyá wọ́n á rí ilẹ̀ gbígbẹ. Níkẹyìn, ọkọ̀ náà gúnlẹ̀ sórí òkè kan. Ẹbọ làwọn tó là á já kọ́kọ́ rú bí wọ́n ṣe bọ́ọ́lẹ̀.

Kí ni èyí fi hàn? Àwọn ìtàn wọ̀nyí kò kàn lè ṣèèṣì jọra. Àwọn ẹ̀rí tá a rí nínú ìtàn wọ̀nyí fi hàn pé òótọ́ lohun tí Bíbélì sọ tipẹ́tipẹ́ pé látọ̀dọ̀ àwọn tó là á já nígbà ìkún omi tó pa ayé kan run ni gbogbo ẹ̀dá ènìyàn ti ṣẹ̀ wá. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé a ò ní láti gba ìtàn àtẹnudẹ́nu tàbí ìtàn àròsọ gbọ́ ká tó mọ ohun tó ṣẹlẹ̀. Ìtàn ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an wà nínú àkọsílẹ̀ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù nínú Bíbélì.—Jẹ́nẹ́sísì, orí kẹfà sí ìkẹjọ.

Bíbélì ṣe àkọsílẹ̀ tó ní ìmísí nípa ìtàn ìgbà tí ìwàláàyè bẹ̀rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹ̀rí fi hàn pé kì í ṣe ìwé ìtàn lásán. Àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ àti ọgbọ́n jíjinlẹ̀ tí ń bẹ nínú rẹ̀ fi hàn pé òótọ́ lohun tó sọ—pé ìsọfúnni tí Ọlọ́run fi ránṣẹ́ sáráyé ló wà nínú rẹ̀. Láìdàbí àwọn ìtàn àròsọ, Bíbélì ní orúkọ àti ọjọ́ àti ìsọfúnni kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ìlà ìdílé àwọn èèyàn àti ọ̀gangan ibi tí àwọn ìtàn tó wà nínú rẹ̀ ti ṣẹlẹ̀. Ó sọ nípa bí ìgbésí ayé ṣe rí kí Ìkún Omi tó dé. Ó ṣàlàyé ìdí tí ayé kan lódindi fi ṣàdédé wá sópin.

Kí lohun tó wọ́ nínú ọ̀ràn àwùjọ ẹ̀dá èèyàn tó wà láyé ṣáájú ìkún omi? Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e yóò dáhùn ìbéèrè yẹn. Ìbéèrè pàtàkì ni fáwọn tó bá fẹ́ mọ̀ bóyá ọjọ́ ọ̀la tó ṣeé gbára lé wà fún ayé ọ̀làjú tá a wà yìí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Jẹ́nẹ́sísì 7:11; 11:10-25, 32; 12:4.

[Àtẹ Ìsọfúnnni tó wà ní ojú ìwé 4]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Àwọn Ìtàn Àtẹnudẹ́nu Kárí Ayé Nípa Ìkún Omi

Orílẹ̀-Èdè Ìbáramu 1 2 3 4 5 6 7 8 9 10

Gíríìsì 7 ◆ ◆ ◆ ◆ ◆ ◆ ◆

Róòmù 6 ◆ ◆ ◆ ◆ ◆ ◆

Lithuania 6 ◆ ◆ ◆ ◆ ◆ ◆

Ásíríà 9 ◆ ◆ ◆ ◆ ◆ ◆ ◆ ◆ ◆

Tanzania 7 ◆ ◆ ◆ ◆ ◆ ◆ ◆

Íńdíà - Híńdù 6 ◆ ◆ ◆ ◆ ◆ ◆

New Zealand - Maori 5 ◆ ◆ ◆ ◆ ◆

Micronesia 7 ◆ ◆ ◆ ◆ ◆ ◆ ◆

Washington U.S.A. - Yakima 7 ◆ ◆ ◆ ◆ ◆ ◆ ◆

Mississippi U.S.A. - Choctaw 7 ◆ ◆ ◆ ◆ ◆ ◆ ◆

Mẹ́síkò - Michoacan 5 ◆ ◆ ◆ ◆ ◆

Gúúsù Amẹ́ríkà - Quechua 4 ◆ ◆ ◆ ◆

Bolivia - Chiriguano 5 ◆ ◆ ◆ ◆ ◆

Guyana - Arawak 6 ◆ ◆ ◆ ◆ ◆ ◆

1: Ìwà ibi mú kí inú bí Ọlọ́run

2: Ìparun nípasẹ̀ ìkún omi

3: Iṣẹ́ ọwọ́ Ọlọ́run ni

4: Ọlọ́run kìlọ̀

5: Àwọn èèyàn díẹ̀ là á já

6: Wọ́n wọ ọkọ̀ ìgbàlà

7: A gba àwọn ẹranko là

8: A rán ẹyẹ tàbí ẹ̀dá mìíràn jáde

9: Níkẹyìn, ó gúnlẹ̀ sórí òkè kan

10: Wọ́n rúbọ

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́