ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwbq àpilẹ̀kọ 156
  • Ṣé Ìtàn Àròsọ Lásán Ni Ìtàn Nóà àti Ìkún Omi?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ṣé Ìtàn Àròsọ Lásán Ni Ìtàn Nóà àti Ìkún Omi?
  • Ohun Tí Bíbélì Sọ
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun tí Bíbélì sọ
  • Ṣé òótọ́ ni àbí àlọ́ lásán?
  • Kí ló fa Ìkún Omi?
  • Ṣé àwọn èèyàn mọ̀ pé Ìkún Omi máa ṣẹlẹ̀?
  • Báwo ni áàkì tí Nóà kàn ṣe rí?
  • Báwo ló ṣe pẹ́ Nóà tó kó tó kan áàkì náà tán?
  • Nóà Kan Áàkì
    Àwọn Ẹ̀kọ́ Tó O Lè Kọ́ Látinú Bíbélì
  • Nígbà Ìkún Omi, Àwọn Wo Ló Tẹ́tí sí Ọlọ́run? Àwọn Wo Ni Kò Tẹ́tí sí I?
    Tẹ́tí sí Ọlọ́run Kó O Lè Wà Láàyè Títí Láé
  • Ìkún Omi Náà Òtítọ́ Tàbí Àròsọ?
    Jí!—1997
  • Ìgbàgbọ́ Nóà Dá Ayé Lẹ́bi
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
Àwọn Míì
Ohun Tí Bíbélì Sọ
ijwbq àpilẹ̀kọ 156
Àwọn erin, àgùnfọn, kìnnìún àtàwọn ẹyẹ ń wọnú ọkọ̀ áàkì

Ṣé Ìtàn Àròsọ Lásán Ni Ìtàn Nóà àti Ìkún Omi?

Ohun tí Bíbélì sọ

Ìkún Omi náà wáyé lóòótọ́. Ṣe ni Ọlọ́run lò ó láti pa àwọn èèyàn burúkú run, àmọ́ ó sọ fún Nóà pé kó kan ọkọ̀ áàkì káwọn èèyàn rere àtàwọn ẹranko lè wọbẹ̀, kí wọ́n má bàa kú. (Jẹ́nẹ́sísì 6:11-20) A lè gbà pé òótọ́ ni Ìkún Omi yẹn ṣẹlẹ̀ torí pé ó wà nínú Ìwé Mímọ́, tí “Ọlọ́run mí sí.”​—2 Tímótì 3:16.

  • Ṣé òótọ́ ni àbí àlọ́ lásán?

  • Kí ló fa Ìkún Omi?

  • Ṣé àwọn èèyàn mọ̀ pé Ìkún Omi máa ṣẹlẹ̀?

  • Báwo ni áàkì tí Nóà kàn ṣe rí?

  • Báwo ló ṣe pẹ́ tó kí Nóà tó parí áàkì náà?

  • Oríṣiríṣi ìtàn, àlọ́ àti ìtàn àròsọ nípa ìkún omi

Ṣé òótọ́ ni àbí àlọ́ lásán?

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ẹnì kan wà tó ń jẹ́ Nóà àti pé Ìkún Omi náà wáyé lóòótọ́, kì í ṣe àlọ́, kì í sì í ṣe ìtàn àròsọ.

  • Àwọn tó kọ Bíbélì gbà pé ẹnì kan wà tó ń jẹ́ Nóà. Bí àpẹẹrẹ, òpìtàn tó jáfáfá ni Ẹ́sírà àti Lúùkù, wọ́n wà lára àwọn tó kọ Bíbélì, wọ́n sì kọ orúkọ Nóà mọ́ àkọsílẹ̀ ìdílé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. (1 Kíróníkà 1:4; Lúùkù 3:36) Mátíù àti Máàkù táwọn náà wà lára àwọn tó kọ àwọn Ìwé Ìhìn Rere ṣàkọsílẹ̀ ohun tí Jésù sọ nípa Nóà àti Ìkún Omi.—Mátíù 24:37-39; Lúùkù 17:26, 27.

    Yàtọ̀ síyẹn, wòlíì Ìsíkíẹ́lì àti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé Nóà ní ìgbàgbọ́, ó sì jé olódodo. (Ìsíkíẹ́lì 14:14, 20; Hébérù 11:7) Tó bá jẹ́ pé òótọ́ ni Nóà ò gbáyé rí, ṣé ó máa bọ́gbọ́n mu kí àwọn òǹkọ̀wé yìí máa sọ̀rọ̀ ẹ̀ pé àpẹẹrẹ rere ló jẹ́? Ó ṣe kedere pé àpẹẹrẹ rere tó ṣeé tẹ̀ lé ni Nóà àtàwọn míì lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n nígbàgbọ́, torí pé èèyàn gidi ni wọ́n, wọ́n sì gbé ayé rí.—Hébérù 12:1; Jémíìsì 5:17.

  • Bíbélì ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa Ìkún Omi náà. Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa Ìkún Omi tó wáyé yẹn, kò sọ ọ́ bí ẹni ń pa àlọ́, báwọn èèyàn ṣe máa ń sọ pé “Àlọ́ o.” Dípò ìyẹn, ṣe ni Bíbélì sọ ọdún, oṣù àti ọjọ́ tí àwọn ohun tó wáyé nígbà Ìkún Omi náà ṣẹlẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 7:11; 8:4, 13, 14) Ó tún sọ bí áàkì tí Nóà kàn ṣe rí, bó ṣe gùn tó, bó ṣe fẹ̀ tó àti bó ṣe ga tó. (Jẹ́nẹ́sísì 6:15) Àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ yìí jẹ́ ká rí i pé Ìkún Omi tí Bíbélì sọ wáyé lóòótọ́, kì í ṣe ìtàn àròsọ.

Kí ló fa Ìkún Omi?

Bíbélì sọ pé, ṣáájú Ìkún Omi, “ìwà burúkú èèyàn pọ̀ gan-an.” (Jẹ́nẹ́sísì 6:5) Ó tún sọ pé “Ọlọ́run tòótọ́ rí i pé ayé ti bà jẹ́” torí pé ìwà ipá àti ìṣekúṣe ló gbalẹ̀ kan.—Jẹ́nẹ́sísì 6:11; Júùdù 6, 7.

Bíbélì sọ pé àwọn áńgẹ́lì burúkú tó fi ọ̀run sílẹ̀ wá máa bá àwọn obìnrin lò pọ̀ láyé ló fa èyí tó pọ̀ jù nínú wàhálà yìí. Néfílímù ni wọ́n ń pe àwọn ọmọ tí àwọn áńgẹ́lì yẹn bí, wọ́n ni àwọn èèyàn ayé ìgbà yẹn lára gan-an, wọ́n sì fojú wọn gbolẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 6:1, 2, 4) Ọlọ́run wá pinnu pé òun máa pa àwọn ẹni burúkú run kúrò láyé, kí àwọn èèyàn rere lè bẹ̀rẹ̀ ìgbé ayé ọ̀tun.—Jẹ́nẹ́sísì 6:6, 7, 17.

Ṣé àwọn èèyàn mọ̀ pé Ìkún Omi máa ṣẹlẹ̀?

Bẹ́ẹ̀ ni. Ọlọ́run sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ fún Nóà, ó sì sọ fún un pé kó kan ọkọ̀ áàkì, kó lè gba ẹ̀mí ìdílé rẹ̀ àtàwọn ẹranko là. (Jẹ́nẹ́sísì 6:13, 14; 7:1-4) Nóà kìlọ̀ fáwọn èèyàn pé ìparun ń bọ̀, àmọ́ etí ikún ni wọ́n kọ sí ọ̀rọ̀ rẹ̀. (2 Pétérù 2:5) Bíbélì sọ pé: “Wọn ò fiyè sí i títí Ìkún Omi fi dé, tó sì gbá gbogbo wọn lọ.”—Mátíù 24:37-39.

Báwo ni áàkì tí Nóà kàn ṣe rí?

Àpótí ńlá kan ni áàkì náà, ó gùn tó ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé mẹ́tàdínlógójì (437) ẹsẹ̀ bàtà, ó fẹ̀ tó ẹsẹ̀ bàtà mẹ́tàléláàádọ́rin (73), ó sì ga tó ilé alájà mẹ́rin tàbí ẹsẹ̀ bàtà mẹ́rìnlélógójì (44).a Igi olóje ló lò fún áàkì náà, ó sì fi ọ̀dà bítúmẹ́nì bò ó tinú tòde. Àjà mẹ́ta ló ní, ó sì ní àwọn yàrá díẹ̀. Ilẹ̀kùn kan wà ní ẹ̀gbẹ́ áàkì náà, ó sì jọ pé wíńdò wà lápá òkè rẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òrùlé áàkì náà ga sókè ní àárín, kó wá dagun sí ẹ̀gbẹ́ méjèèjì, èyí á jẹ́ kí omi tó bá dà sórí òrùlé náà lè máa ṣàn dà nù.—Jẹ́nẹ́sísì 6:14-16.

Àtẹ kan jẹ́ ká rí bí ọkọ̀ áàkì, ọkọ̀ òfuurufú àti erin ṣe gùn tó tá a bá fi wọ́n wéra

Báwo ló ṣe pẹ́ Nóà tó kó tó kan áàkì náà tán?

Bíbélì ò sọ bó ṣe pẹ́ Nóà tó kó tó kan áàkì náà tán, àmọ́ ó jọ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ló gbà á kó tó parí rẹ̀. Nóà ti lé lẹ́ni ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) ọdún nígbà tó bí ọmọkùnrin rẹ̀ àkọ́kọ́, Nóà sì ti pé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (600) ọdún nígbà tí Ìkún Omi náà wáyé.b—Jẹ́nẹ́sísì 5:32; 7:6.

Nígbà tí Ọlọ́run sọ fún Nóà pé kó kan ọkọ̀ áàkì, àwọn ọmọ ẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ti dàgbà, wọ́n sì ti fẹ́yàwó. Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti lo nǹkan bí àádọ́ta (50) sí ọgọ́ta (60) ọdún. (Jẹ́nẹ́sísì 6:14, 18) Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, á jẹ́ pé ó bọ́gbọ́n mú ká gbà pé áàkì náà máa gbà wọ́n tó ogójì (40) sí àádọ́ta (50) ọdún kí wọ́n tó parí rẹ̀.

Oríṣiríṣi ìtàn, àlọ́ àti ìtàn àròsọ nípa ìkún omi

Oríṣiríṣi ìtàn tó yàtọ̀ sí èyí tí Bíbélì sọ ló wọ́pọ̀ kárí ayé táwọn èèyàn máa ń sọ nípa Ìkún Omi, àmọ́ ọ̀pọ̀ nínú wọn ṣì fi àwọn nǹkan kan jọ ti èyí tó wà nínú Bíbélì. Bí àwọn àtọmọdọ́mọ Nóà ṣe ń tàn káàkiri ayé, ó jọ pé kálukú ń tún ìtàn yẹn sọ fáwọn míì. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àtibẹ̀ ni àbùmọ́ ti ń wọ̀ ọ́, tó fi di pé bí ẹnì kan bá ṣe sọ ọ́ máa yàtọ̀ sí bí ẹlòmíì ṣe máa sọ ọ́. Wo àwọn àpẹẹrẹ mélòó kan.

Ìtàn àròsọ àwọn Gíríìkì: Wọ́n sọ fún ọkùnrin àti obìnrin tó la ìkún omi já pé kí àwọn méjèèjì máa ju òkúta sẹ́yìn. Àwọn òkúta yẹn ló wá di ọmọ lọ́kùnrin lóbìnrin tó kún inú ayé.

Ìtàn àròsọ àwọn ẹlẹ́sìn Híńdù: Ẹja kan kìlọ̀ fún ọkùnrin kan pé ìkún omi máa ṣẹlẹ̀, tó máa pa aráyé rẹ́. Ẹja náà sọ fún ọkùnrin náà pé kó ṣe ọkọ̀ ojú omi. Ọkùnrin náà sì la ìkún omi ọ̀hún já torí pé ẹja yẹn darí ọkọ̀ ojú omi náà títí ó fi gúnlẹ̀ ayọ̀.

Ìtàn àròsọ àwọn ará Bábílónì: Ọkùnrin àti obìnrin tó la ìkún omi já di ẹni tí kò lè kú mọ́, wọ́n sì di òòṣà.

Ìtàn àròsọ àwọn ará America ti Àárín: Ọkùnrin kan, ìyàwó ẹ̀ àtàwọn ọmọ wọn la ìkún omi já, àmọ́ gbogbo àwọn tó kù di ẹja.

a Ìgbọ̀nwọ́ ni Bíbélì fi ṣàlàyé ìwọ̀n ọkọ̀ áàkì. “Ìgbọ̀nwọ́ táwọn Hébérù sábà máa ń lò jẹ́ nǹkan bíi sẹ̀ǹtímítà mẹ́rìnlélógójì àti ààbọ̀ (44.45 cm).”—The Illustrated Bible Dictionary, Ìdìpọ̀ Tá A Tún Ṣe, Apá 3, ojú ìwé 1635

b Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa bí ìgbésí ayé àwọn èèyàn bíi Nóà ṣe gùn tó, wo àpilẹ̀kọ tá a pè ní “Ǹjẹ́ Àwọn Èèyàn Máa Ń Pẹ́ Láyé Gan-an Ní Àkókò Tí Wọ́n Ń Kọ Bíbélì?” nínú Ilé Ìṣọ́ December 1, 2010

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́