Ṣọra Fun Awọn Wolii Èké!
TỌKỌTAYA ara Brazil kan ti lọ sùn ni alẹ nigba ti wọ́n gbọ́ ti awọn ole ń jalẹkun wọnu ile wọn. Tọkọtaya ti a ti kópayàbá naa runmọ ọn lati sá àsálà gba oju ferese iyàrá ibùsùn wọ́n sì pe awọn ọlọpaa. Ṣugbọn lẹhin eyi aya naa ni iriri naa kó idaamu bá debi pe kò lè sun ninu ile naa ti ó sì nilati lọ sọdọ iya rẹ̀.
Ẹnikẹni ti a bá ti fọ́ ile rẹ̀ tabi ti a ti fi ipá jà lólè ni ọna miiran kan yoo bá a kẹdun. Iru iriri bẹẹ lè kóni láyà jẹ, ati pe, lọna ti kò munilayọ, pupọpupọ awọn eniyan sii ń jiya lọna yii. Bi o ti wu ki o ri, iru ole jíjà kan tí ó ni awọn abayọri wiwuwo lọpọlọpọ sii wà.
Ki ni iru ole jíjà ti ó tubọ wuwo yii, awọn wo sì ni awọn ole naa? Jesu Kristi funni ni isọfunni diẹ nipa rẹ̀ nigba ti, ni sisọrọ nipa awọn ọjọ wa, o wi pe: “Wolii èké pupọ ni yoo sì dide, wọn yoo sì tan ọpọlọpọ jẹ.” (Matiu 24:11) Olè ni awọn wolii èké. Ni ọna wo? Ki ni wọn ń jí? Ole jíjà wọn sopọ mọ sisọ ti wọn ń sọ asọtẹlẹ. Nitori naa ki a baa lè loye ọran naa ni kikun, a nilati kọkọ mọ ohun ti sisọ asọtẹlẹ jẹ́ ni ibamu pẹlu Bibeli.
Ohun Ti Ó Tumọsi Lati Sọtẹlẹ
Nigba ti o ba ronu nipa sisọ asọtẹlẹ, boya ohun akọkọ ti ó wa sọkan rẹ ni sisọ asọtẹlẹ ọjọ-ọla. Nitootọ eyi jẹ́ ìhà kan ninu iṣẹ awọn wolii Ọlọrun igbaani, ṣugbọn kii ṣe pataki iṣẹ wọn. Fun apẹẹrẹ, nigba ti a sọ fun wolii Esikiẹli ninu iran lati “sọtẹlẹ si èémí,” oun ni taarata nilati pa aṣẹ kan ti o ti ọdọ Ọlọrun wá. (Esikiẹli 37:9, 10) Nigba ti Jesu wà ni ìgbẹ́jọ́ niwaju awọn alufaa, a tutọ́ si i lara a sì gba a loju, awọn awọn oluṣenunibini si i sì sọ lọna ìfiniṣẹlẹ́yà pe: “Sọtẹlẹ fun wa, iwọ Kristi, ta ni ẹni ti o ń lù ọ nì?” Kii ṣe pe wọn ń beere lọwọ Jesu lati sọ asọtẹlẹ ọjọ-ọla. Wọn ń pè e nija lati da awọn wọnni ti ń lù ú mọ̀ nipasẹ agbara Ọlọrun.—Matiu 26:67, 68.
Niti tootọ, ero pataki ti a gbé yọ nipasẹ awọn ọrọ èdè Bibeli ipilẹṣẹ ti a tumọ si “sọtẹlẹ” tabi “asọtẹlẹ” ní ipilẹ jẹ́ lati sọ ero inu Ọlọrun jade lori ọran kan tabi, gẹgẹ bi iwe Iṣe ṣe sọ ọ, lati sọ “iṣẹ iyanu ńlá Ọlọrun.” (Iṣe 2:11) Ni itumọ yii ni ọpọlọpọ awọn eniyan di ẹni ti a fipa jà lólè lati ọwọ awọn wolii èké.
Bi o ti wu ki o ri, awọn wo ni awọn wolii èké, ki sì ni wọn ń jí? Lati dahun ibeere yii, ẹ jẹ ki a wo ẹhin pada sí itan orilẹ-ede Isirẹli titi di akoko Jeremaya.