ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w94 9/15 ojú ìwé 15-20
  • Ẹ Mú Awọn Wòlíì Ọlọrun Gẹ́gẹ́ Bí Àpẹẹrẹ Àwòṣe

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ẹ Mú Awọn Wòlíì Ọlọrun Gẹ́gẹ́ Bí Àpẹẹrẹ Àwòṣe
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Wọn Jìyà Ibi
  • Wọn Mú Sùúrù
  • “Wọn Ṣe Bẹ́ẹ̀ Gẹ́gẹ́”
  • Wọn Ní Ẹ̀mí Ìfojúsọ́nà-Fún-Rere
  • Awọn Orísun Ìṣírí
  • Ìtara ati Ìṣarasíhùwà Adúródeni
  • Mímú Sùúrù Lónìí
  • Fi Ìgboyà Wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2004
  • “Ẹ Pòkìkí Èyí Láàárín Àwọn Orílẹ̀-èdè”
    Máa Fi Ọjọ́ Jèhófà Sọ́kàn
  • Ẹ Máa Mú Sùúrù Bíi Ti Jèhófà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2006
  • Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Àwọn Wòlíì—Ámósì
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2013
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1994
w94 9/15 ojú ìwé 15-20

Ẹ Mú Awọn Wòlíì Ọlọrun Gẹ́gẹ́ Bí Àpẹẹrẹ Àwòṣe

“Ẹyin ará, ẹ mú awọn wòlíì, awọn tí wọn sọ̀rọ̀ ní orúkọ Jehofa gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ àwòṣe jíjìyà ibi ati mímú sùúrù.”​—⁠JAKỌBU 5:10, NW.

1. Kí ní ń ran awọn ìránṣẹ́ Jehofa lọ́wọ́ lati dunnú àní nígbà tí a bá ń ṣe inúnibíni sí wọn?

AWỌN ìránṣẹ́ Jehofa ń kún fún ayọ̀ láìka àìnírètí tí ó wọ́pọ̀ ninu ayé sí ní awọn ọjọ́ ìkẹyìn wọnyi. Èyí rí bẹ́ẹ̀ nitori tí wọn mọ̀ pé awọn ń ṣe ohun tí ó dùnmọ́ Ọlọrun. Awọn Ẹlẹ́rìí fún Jehofa tún ń lo ìforítì lábẹ́ inúnibíni ati àtakò sí iṣẹ́-òjíṣẹ́ ìtagbangba wọn nitori wọn mọ̀ pé awọn ń jìyà nitori òdodo. Jesu Kristi sọ fún awọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Alábùkún-fún ní ẹyin, nígbà tí wọn bá ń kẹ́gàn yin, tí wọn bá ń ṣe inúnibíni sí yin, tí wọn bá ń fi èké sọ̀rọ̀ búburú gbogbo sí yin nitori emi. Ẹ máa yọ̀, kí ẹyin kí ó sì fò fún ayọ̀: nitori èrè yin pọ̀ ní ọ̀run: bẹ́ẹ̀ ni wọn ṣáà ṣe inúnibíni sí awọn wòlíì tí ó ti ń bẹ ṣáájú yin.” (Matteu 5:​10-⁠12) Ní tòótọ́, nígbàkigbà tí awọn ìránṣẹ́ Ọlọrun bá dojúkọ àdánwò ìgbàgbọ́, wọn ń kà ìwọ̀nyí sí ìdùnnú.​—⁠Jakọbu 1:​2, 3.

2. Ní ìbámu pẹlu Jakọbu 5:10, kí ni ó lè ràn wá lọ́wọ́ lati mú sùúrù?

2 Ọmọ-ẹ̀yìn naa Jakọbu kọ̀wé pé: “Ẹyin ará, ẹ mú awọn wòlíì, awọn tí wọn sọ̀rọ̀ ní orúkọ Jehofa gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ àwòṣe jíjìyà ibi ati mímú sùúrù.” (Jakọbu 5:10, NW) W. F. Arndt ati F. W. Gingrich túmọ̀ ọ̀rọ̀-èdè Griki tí a túmọ̀ níhìn-⁠ín bí “àpẹẹrẹ àwòṣe” (hy·poʹdeig·ma) gẹ́gẹ́ bí “àpẹẹrẹ, àwòṣe, àpẹẹrẹ àwòṣe, lọ́nà tí ó bọ́gbọ́nmu gẹ́gẹ́ bí ohun kan tí ń sún tabi tí ó níláti sún ẹnìkan lati ṣàfarawé rẹ̀.” Gẹ́gẹ́ bí a ti fihàn ninu Johannu 13:15, “èyí ju àpẹẹrẹ kan lásán lọ. Ó jẹ́ àpẹẹrẹ-ìṣáájú tí ó ṣe pàtó.” (Theological Dictionary of the New Testament) Wàyí o, nígbà naa, awọn ìránṣẹ́ Jehofa òde-òní lè mú awọn wòlíì rẹ̀ olùṣòtítọ́ gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ àwòṣe nígbà tí ó bá kan ọ̀ràn “jíjìyà ibi” ati “mímú sùúrù.” Kí ni ohun mìíràn tí a tún lè fòyemọ̀ nígbà tí a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nipa ìgbésí-ayé wọn? Bawo ni èyí sì ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ ninu ìgbòkègbodò wíwàásù wa?

Wọn Jìyà Ibi

3, 4. Bawo ni wòlíì Amosi ṣe hùwàpadà sí àtakò Amasiah?

3 Awọn wòlíì Jehofa jìyà ibi tabi ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ lọ́pọ̀ ìgbà. Fún àpẹẹrẹ, ní ọ̀rúndún kẹsàn-⁠án B.C.E., àlùfáà olùjọsìn ọmọ màlúù naa Amasiah fi inú burúkú tako wòlíì Amosi. Amasiah fi èké jẹ́wọ́ pé Amosi dìtẹ̀ mọ́ Jeroboamu II nípa sísọtẹ́lẹ̀ pé ọba naa yoo ti ojú idà ṣubú ati pé a óò kó Israeli lọ sí ìgbèkùn. Amasiah sọ fún Amosi tẹ̀gàn-tẹ̀gàn pé: “Iwọ aríran, lọ, sálọ sí ilẹ̀ Juda, sì máa jẹun níbẹ̀, sì máa sọtẹ́lẹ̀ níbẹ̀: ṣugbọn máṣe sọtẹ́lẹ̀ mọ́ ní Beteli: nitori ibi mímọ́ ọba ni, ààfin ọba sì ni.” Láì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rírorò yii dẹ́rùba oun, Amosi fèsì pé: “Emi kìí ṣe wòlíì rí, bẹ́ẹ̀ ni emi kìí ṣe ọmọ wòlíì, ṣugbọn olùṣọ́-àgùtàn ni emi tií ṣe rí, ati ẹni tí íti máa ká èso ọ̀pọ̀tọ́: Oluwa sì mú mi, bí mo ti ń tọ agbo-ẹran lẹ́yìn, Oluwa sì wí fún mi pé, Lọ, sọtẹ́lẹ̀ fún Israeli ènìyàn mi.”​—⁠Amosi 7:​10-⁠15.

4 Ẹ̀mí Jehofa fún Amosi ní agbára lati sọtẹ́lẹ̀ tìgboyà-tìgboyà. Fojú inú wo ìhùwàpadà Amasiah gẹ́gẹ́ bí Amosi ti wí pé: “Gbọ́ ọ̀rọ̀ Oluwa: Iwọ wí pé, Máṣe sọtẹ́lẹ̀ sí Israeli, má sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ kán sílẹ̀ sí ilé Isaaki. Nitori naa bayii ní Oluwa wí; Obìnrin rẹ yoo di panṣágà ní ìlú, ati awọn ọmọ rẹ ọkùnrin ati awọn ọmọ rẹ obìnrin, yoo ti ipa idà ṣubú; ilẹ̀ rẹ ni a óò sì fi okùn pín; iwọ óò sì kú ni ilẹ̀ àìmọ́: nítòótọ́, a óò sì kò Israeli lọ ní ìgbèkùn kúrò ni ilẹ̀ rẹ̀.” Àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ní ìmúṣẹ. (Amosi 7:​16, 17) Ẹ wo bí jìnnìjìnnì yoo ti bá Amasiah apẹ̀yìndà tó!

5. Ìjọra wo ni a lè rí fàyọ ninu ipò awọn ìránṣẹ́ Jehofa òde-òní ati ti wòlíì Amosi?

5 Èyí rí bákan naa pẹlu ipò awọn ènìyàn Jehofa lónìí. A ń jìyà ibi gẹ́gẹ́ bí awọn wọnni tí ń polongo ìhìn-iṣẹ́ Ọlọrun, ọ̀pọ̀ awọn ènìyàn sì ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn nipa ìgbòkègbodò ìwàásù wa. Lóòótọ́, ọlá-àṣẹ wa lati wàásù kò wá lati ọwọ́ ilé-ẹ̀kọ́ ìsìn oyè àlùfáà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ Jehofa ní ó ń sún wa lati pòkìkí ìhìnrere Ìjọba naa. Awa kìí yí ìhìn-iṣẹ́ Ọlọrun padà tabi kí a bomi là á. Dípò èyí, gẹ́gẹ́ bí Amosi, a ń fí pẹlu ìgbọràn polongo rẹ̀ láìka ìhùwàpadà awọn tí ń gbọ́ wa sí.​—⁠2 Korinti 2:​15-⁠17.

Wọn Mú Sùúrù

6, 7. (a) Kí ni ó sàmì sí àsọtẹ́lẹ̀ Isaiah? (b) Bawo ni awọn ìránṣẹ́ Jehofa òde ìwòyí ṣe ń hùwà bíi Isaiah?

6 Awọn wòlíì Ọlọrun mú sùúrù. Fún àpẹẹrẹ, Isaiah, tí ó ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bí wòlíì Jehofa ní ọ̀rúndún kẹjọ B.C.E. fi bí a ṣe lè mú sùúrù hàn. Ọlọrun sọ fún un pé: “Lọ, kí o sì wí fún awọn ènìyàn yii, Ní gbígbọ́, ẹ gbọ́, ṣugbọn òye kì yoo yé yin; ní rírí, ẹ rí, ṣugbọn ẹ̀yin kì yoo sì mọ òye. Mú kí àyà awọn ènìyàn yii kí ó sébọ́, sì mú kí etí wọn kí ó wúwo, kí o sì dì wọn ní ojú, kí wọn kí o má baà fi etí wọn gbọ́, kí wọn kí ó má baà fi ọkàn wọn mọ̀, kí wọn kí ó má baà yípadà, kí a má bàá mú wọn ní ara dá.” (Isaiah 6:​9, 10) Níti tòótọ́ awọn ènìyàn naa hùwàpadà lọ́nà yẹn. Ṣugbọn èyí ha mú kí Isaiah jáwọ́ bí? Rárá o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó fi pẹlu sùúrù ati ìtara polongo awọn ìhìn-iṣẹ́ ìkìlọ̀ Jehofa. Bí a ṣe gbé awọn ọ̀rọ̀ Ọlọrun tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ fàyọ naa kalẹ̀ lédè Heberu faramọ́ èrò “bíbáa nìṣó láìdáwọ́dúró” ti ìpolongo wòlíì naa, èyí tí awọn ènìyàn gbọ́ “léraléra.”​—⁠Gesenius’ Hebrew Grammar.

7 Lónìí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ń hùwàpadà sí ìhìnrere naa gan-⁠an gẹ́gẹ́ bí awọn ènìyàn ṣe hùwàpadà sí awọn ọ̀rọ̀ Jehofa tí a fi rán Isaiah. Bí ó ti wù kí ó rí, gẹ́gẹ́ bíi wòlíì olùṣòtítọ́ yẹn, a ń tún ìhìn-iṣẹ́ Ìjọba naa sọ “léraléra.” A ń ṣe bẹ́ẹ̀ pẹlu ìtara ati sùúrù onífaradà nitori èyí jẹ́ ìfẹ́-inú Jehofa.

“Wọn Ṣe Bẹ́ẹ̀ Gẹ́gẹ́”

8, 9. Ní awọn ọ̀nà wo ni Mose wòlíì Jehofa gbà jẹ́ àpẹẹrẹ rere?

8 Wòlíì Mose jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ ninu mímú sùúrù ati ṣíṣe ìgbọràn. Ó yàn lati mú ìdúró rẹ̀ pẹlu awọn ọmọ Israeli tí wọn wà ní oko ẹrú, ṣugbọn ó níláti fi sùúrù dúró títí di ìgbà ìdáǹdè wọn. Lẹ́yìn naa ó gbé ní Midiani fún 40 ọdún títí di ìgbà tí Ọlọrun lò ó lati sín awọn ọmọ Israeli jáde kúrò lábẹ́ ìsìnrú. Nígbà tí Mose ati Aaroni arákùnrin rẹ̀ wà níwájú aláàkóso Egipti, wọn sọ ohun tí Ọlọrun ti paláṣẹ wọn sì ṣe é pẹlu ìgbọràn. Ní tòótọ́, “wọn ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́.”​—⁠Eksodu 7:​1-⁠6, NW; Heberu 11:​24-⁠29.

9 Mose fi sùúrù farada 40 ọdún oníṣòro mímúná tí awọn ọmọ Israeli lò ninu aginjù. Ó tún fi ìgbọràn tẹ̀lé ìtọ́sọ́nà àtọ̀runwá nígbà kíkọ́ àgọ́ ìsìn awọn ọmọ Israeli ati ṣíṣe awọn nǹkan mìíràn tí wọn lò ninu ìjọsìn Jehofa. Wòlíì naa tẹ̀lé awọn ìtọ́ni Ọlọrun tímọ́tímọ́ tóbẹ́ẹ̀ tí a fi kà pé: “Bẹ́ẹ̀ ni Mose ṣe: gẹ́gẹ́ bí èyí tí Oluwa paláṣẹ fún un, bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe.” (Eksodu 40:16) Bí a bá ti ń mú iṣẹ́-òjíṣẹ́ wa ṣẹ ní kíkẹ́gbẹ́pọ̀ pẹlu ètò-àjọ Jehofa, ẹ jẹ́ kí a rántí ìgbọràn Mose kí a sì fi àmọ̀ràn aposteli Paulu sílò lati ‘máa gbọ́ ti awọn tí ń ṣe olórí wa.’​—⁠Heberu 13:⁠17.

Wọn Ní Ẹ̀mí Ìfojúsọ́nà-Fún-Rere

10, 11. (a) Kí ni ó fihàn pé wòlíì Hosea ní ojú-ìwòye ìfojúsọ́nà-fún-rere? (b) Bawo ni a ṣe lè pa ìṣarasíhùwà ìfojúsọ́nà-fún-rere mọ́ nígbà tí a bá ń tọ awọn ènìyàn lọ ní agbègbè ìpínlẹ̀ wa?

10 Ó yẹ kí awọn wòlíì ní ẹ̀mí ìfojúsọ́nà-fún-rere bí wọn ti ń kéde ìhìn-iṣẹ́ ìdájọ́ ati awọn àsọtẹ́lẹ̀ tí ń fi ìfẹ́ alánìíyàn tí Ọlọrun ní fún awọn olùṣòtítọ́ tí a fọ́n káàkiri Israeli hàn. Èyí jẹ́ òtítọ́ níti Hosea, ẹni tí ó jẹ́ wòlíì fún ohun tí kò dín ní 59 ọdún. Lọ́nà tí ó fi ìfojúsọ́nà-fún-rere hàn, ó ń báa nìṣó ní kíkéde ìhìn-iṣẹ́ Jehofa ó sì mú ìwé alásọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ wá sí ìparí pẹlu awọn ọ̀rọ̀ naa: “Ta ni ó gbọ́n, tí ó lè mòye nǹkan wọnyi? Ta ni ó ní òye, tí ó lè mọ̀ wọn? nitori ọ̀nà Oluwa tọ́, awọn olódodo yoo sì máa rìn ninu wọn: ṣugbọn awọn alárèékọjá ni yoo ṣubú sínú wọn.” (Hosea 14:9) Níwọ̀n ìgbà tí Jehofa bá ṣì ń fàyègbà wá lati fúnni ní ìjẹ́rìí, ẹ jẹ́ kí a ní ẹ̀mí ìfojúsọ́nà-fún-rere kí a sì máa báa nìṣó lati wá awọn wọnnì ti yoo fi orí pípé tẹ́wọ́gba inúrere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Ọlọrun.

11 Lati ‘wá awọn ẹni yíyẹ rí,’ a níláti faradà á kí a sì máa wo awọn ọ̀ran pẹlu ìfojúsọ́nà-fún-rere. (Matteu 10:11) Fún àpẹẹrẹ, bí a bá sọ awọn kọ́kọ́rọ́ wa nù, a lè tọ ipasẹ̀ wa padà kí a sì wá gbogbo ibi tí a ti rìn dé. A lè rí wọn kìkì lẹ́yìn ìgbà tí a bá ti ṣe èyí léraléra. Ẹ jẹ́ kí a máa faradà á bákan naa ní wíwá awọn ẹni bí àgùtàn rí. Ẹ wo bí ìdùnnú wa ti ń pọ̀ tó nígbà tí wọn bá dáhùnpadà sí ìhìnrere naa ní awọn agbègbè ìpínlẹ̀ tí a ń ṣe lemọ́lemọ́! Ẹ sì wo bí a ṣe ń kún fún ayọ̀ tó pé Ọlọrun ń bùkún iṣẹ́ wa ní awọn ilẹ̀ tí ìfòfindè ti pààlà sí iṣẹ́-òjíṣẹ́ wa ní gbangba!​—⁠Galatia 6:⁠10.

Awọn Orísun Ìṣírí

12. Àsọtẹ́lẹ̀ Joeli wo ni ó ń ní ìmúṣẹ ti ọ̀rúndún lọ́nà ogún, bawo sì ni?

12 Ọ̀rọ̀ awọn wòlíì Jehofa lè pèsè ìṣírí ńláǹlà fún wa ninu iṣẹ́-òjíṣẹ́ wa. Fún àpẹẹrẹ, gbé àsọtẹ́lẹ̀ Joeli yẹ̀wò. Ó ní nínú awọn ìhìn-iṣẹ́ onídàájọ́ tí a darí rẹ̀ sí awọn ọmọ Israeli apẹ̀yìndà ati awọn mìíràn ní ọ̀rúndún kẹsàn-⁠án B.C.E. Síbẹ̀, a mísí Joeli pẹlu lati sọtẹ́lẹ̀ pé: “Níkẹyìn emi [Jehofa] óò tú ẹ̀mí mi jáde sí ara ènìyàn gbogbo; ati awọn ọmọ yin ọkùnrin, ati awọn ọmọ yin obìnrin yoo máa sọtẹ́lẹ̀, awọn arúgbó yin yoo máa lá àlá, awọn ọ̀dọ́mọkùnrin yin yoo máa ríran: Ati pẹlu sí ara awọn ọmọ-ọ̀dọ̀ ọkùnrin, ati sí ara awọn ọmọ-ọ̀dọ̀ obìnrin, ni èmi óò tú ẹ̀mí mi jáde ní ọjọ́ wọnnì.” (Joeli 2:​28, 29) Èyí jásí òtítọ́ níti awọn ọmọlẹ́yìn Jesu bẹ̀rẹ̀ lati Pentekosti 33 C.E. Ẹ sì wo ìmúṣẹ títóbilọ́lá ti àsọtẹ́lẹ̀ yii tí a ń rí ní ọ̀rúndún lọ́nà ogún yii! Lónìí a ní àràádọ́ta ọ̀kẹ́ tí ‘ń sọtẹ́lẹ̀,’ tabi pòkìkí ìhìn-iṣẹ́ Jehofa​—⁠iye tí ó ju 600,000 lára wọn wà ninu iṣẹ́-ìsìn aṣáájú-ọ̀nà alákòókò kíkún.

13, 14. Kí ni ó lè ran awọn Kristian ọ̀dọ́ lọ́wọ́ lati rí ìdùnnú ninu iṣẹ́-òjíṣẹ́ pápá?

13 Ọ̀pọ̀ lara awọn olùpòkìkí Ìjọba jẹ́ ọ̀dọ́. Kìí fi ìgbà gbogbo rọrùn fún wọn lati bá awọn tí wọn dàgbà jù wọn lọ sọ̀rọ̀ nipa Bibeli. Nígbà mìíràn a máa ń sọ fún awọn ọ̀dọ́ ìránṣẹ́ Jehofa pé: ‘Ẹ ń fi àkókò yin ṣòfò ní wíwàásù,’ ati pé ‘ẹ jẹ́ lọ wá nǹkan mìíràn ṣe.’ Awọn ọ̀dọ́ Ẹlẹ́rìí fún Jehofa lè dọ́gbọ́n fèsì pé ó ṣe awọn láàánú pé ẹni naa ronú lọ́nà yẹn. Ọ̀dọ́ oníwàásù ìhìnrere kan rí i pé ó ṣèrànwọ́ lati fikún un pé: “Mo nímọ̀lára pé mo ń jàǹfààní níti tòótọ́ ninu bíbá awọn ènìyàn tí wọn dàgbà díẹ̀ bíi tiyín sọ̀rọ̀, mo sì ń gbádùn rẹ̀.” Dájúdájú, wíwàásù ìhìnrere kìí ṣe fífi àkókò ṣòfò rárá. Ìwàláàyè wà ninu ewu. Nípasẹ̀ Joeli, Ọlọrun polongo síwájú síi pé: “Yoo sì ṣe ẹnikẹ́ni tí ó bá ké pe orúkọ Oluwa ni a ó gbàlà.”​—⁠Joeli 2:⁠32.

14 Awọn ọmọ tí wọn ń kẹ́gbẹ́pọ̀ pẹlu awọn òbí wọn ninu ìgbòkègbodò wíwàásù Ìjọba ń tẹ́wọ́gba ìrànwọ́ awọn òbí ní gbígbé awọn góńgó ara-ẹni kalẹ̀. Irú awọn ògowẹẹrẹ bẹ́ẹ̀ ń tẹ̀síwájú lati orí kíka ìwé mímọ́ sí ṣíṣàlàyé awọn ìrètí wọn tí a gbéka Bibeli ati fífi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tí ó yẹ lọ awọn olùfìfẹ́hàn. Bí wọn ṣe ń rí ìtẹ̀síwájú tiwọn fúnraawọn ati ìbùkún Jehofa, awọn akéde Ijọba ń rí ìdùnnú ńláǹlà ninu wíwàásù ihinrere.​—⁠Orin Dafidi 110:⁠3; 148:12, 13.

Ìtara ati Ìṣarasíhùwà Adúródeni

15. Bawo ni àpẹẹrẹ Esekieli ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ lati tún dánámọ́ ìtara wa fún iṣẹ́ wíwàásù Ìjọba naa?

15 Awọn wòlíì Ọlọrun pẹlu jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ ninu fífi ìtara ati ìṣarasíhùwà adúródeni hàn​—⁠awọn ìwà-ànímọ́ tí a nílò nínú iṣẹ́-òjíṣẹ́ wa lónìí. Nígbà tí a kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ninu Ọ̀rọ̀ Ọlọrun, ó ṣeéṣe kí ó ti jẹ́ pé ìtara naa tí a koná mọ́ ni ó sún wa lati sọ̀rọ̀ jáde láìṣojo. Ṣugbọn ọ̀pọ̀ ọdún ti lè kọjá lẹ́yìn naa, a sì ti lè kárí awọn ìpínlẹ̀ tí a tí ń jẹ́rìí léraléra. Ó lé jẹ́ pé awọn ènìyàn díẹ̀ ni wọn ń tẹ́wọ́gba ìhìn-iṣẹ́ Ìjọba naa nísinsìnyí. Èyí ha ti mú kí ìtara wa dínkù síi bí? Bí ó bá rí bẹ́ẹ̀, gbé ọ̀ràn wòlíì Esekieli yẹ̀wò, ẹni tí orúkọ rẹ̀ túmọ̀sí “Ọlọrun Ń Fúnnilókun.” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Esekieli dojúkọ awọn ènìyàn ọlọ́kàn líle ní Israeli ìgbàanì, Ọlọrun fún un lókun ó sì tún mú kí iwájú orí rẹ̀ lekoko ju òkúta ìbọn lọ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Nipa bayii, ó ṣeéṣe fún Esekieli lati ṣe iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún yálà awọn ènìyàn fetísílẹ̀ tabi wọn kò ṣe bẹ́ẹ̀. Àpẹẹrẹ rẹ̀ fihàn pé a lè ṣe ohun kan naa, ó sì lè ràn wá lọ́wọ́ lati tún dánámọ́ ìtara wa fún iṣẹ́ ìwàásù naa.​—⁠Esekieli 3:8, 9; 2 Timoteu 4:⁠5.

16. Ìṣarasíhùwà tí Mika ni wo ni a níláti mú dàgbà?

16 Ẹni tí sùúrù rẹ̀ yẹ fún àfiyèsí ni Mika, tí ó sọtẹ́lẹ̀ ní ọ̀rúndún kẹjọ B.C.E. Ó kọ̀wé pé, “Nitori naa emi óò ní ìrètí sí Oluwa: emi óò dúró de Ọlọrun ìgbàlà mí: Ọlọrun mi yoo gbọ́ tèmi.” (Mika 7:7) Ìgbọ́kànlé Mika ní gbòǹgbò rẹ̀ ninu ìgbàgbọ́ rẹ̀ lílágbára. Gẹ́gẹ́ bíi wòlíì Isaiah, Mika mọ̀ pé ohun ti Jehofa ti ṣèlérí ní Oun yoo ṣe dandan. Awa pẹlu mọ èyí. (Isaiah 55:11) Nitori naa ẹ jẹ́ kí a mú ìṣarasíhùwà adúródeni dàgbà síhà ìmúṣẹ awọn ìlérí Ọlọrun. Ẹ sì jẹ́ kí a máa wàásù ìhìnrere naa pẹlu ìtara, àní ní awọn agbègbè tí awọn ènìyàn kò ti fi ọkàn-ìfẹ́ pupọ hàn ninu ìhìn-iṣẹ́ Ìjọba naa.​—⁠Titu 2:14; Jakọbu 5:​7-⁠10.

Mímú Sùúrù Lónìí

17, 18. Awọn àpẹẹrẹ ìgbàanì ati ti òde-òní wo ni ó lè ràn wá lọ́wọ́ lati mú sùúrù?

17 Awọn kan lára awọn wòlíì Jehofa fi sùúrù tẹpẹlẹ mọ́ iṣẹ́ àyànfúnni wọn fún ọ̀pọ̀ ọdún ṣugbọn wọn kò rí ìmúṣẹ awọn àsọtẹ́lẹ̀ wọn. Síbẹ̀, sùúrù onífaradà wọn, lọ́pọ̀ ìgbà tí wọn bá ń jìyà ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, ń ràn wá lọ́wọ́ lati mọ̀ pé a lè mú iṣẹ́-òjíṣẹ́ wa ṣẹ. A tún lè jàǹfààní láti inú àpẹẹrẹ awọn olùṣòtítọ́ ẹni-àmì-òróró ní ìbẹ̀rẹ̀ awọn ẹ̀wádún ọ̀rúndún lọ́nà ogun. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò rí ìmúṣẹ ìrètí tí òkè ọ̀run wọn ní kíákíá bí wọn ṣe tètè ń retí tó, wọn kò fàyègba ìjákulẹ̀ lórí ohun kan tí ó dàbí ìjáfara lati dín ìtara wọn kù fún ṣíṣe ìfẹ́-inú Ọlọrun bí oun ti ṣípayá rẹ̀ fún wọn.

18 Fún ọ̀pọ̀ ọdún, ọ̀pọ̀ lara awọn Kristian wọnyi ń pín Ilé-Ìṣọ́nà ati ìwé ìròyìn kejì rẹ̀, Jí!, (tí a ń pè ní The Golden Age tẹ́lẹ̀rí ati lẹ́yìn naa Consolation) déédéé. Wọn fi tìtara tìtara mú kí awọn ìwé ìròyìn ṣíṣeyebíye yii wà lárọ̀ọ́wọ́tó awọn ènìyàn ní òpópónà ati ninu ilé wọn nípasẹ̀ ọ̀nà tí a ń pè ní ipa ọ̀nà ìwé ìròyìn lónìí. Arábìnrin àgbàlagbà kan tí ó parí ipa ọ̀nà rẹ̀ ti orí ilẹ̀-ayé ni awọn èrò tí ń lọ tí ń bọ̀ tí wọn ti sábà máa ń rí i tí ń jẹ́rìí ní òpópónà tètè nímọ̀lára pé awọn kò rí mọ́. Ẹ wo irú ẹ̀rí tí ó jẹ́ lákòókò ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ìṣẹ́-ìsìn àfòtítọ́ṣe rẹ̀, bí ọ̀rọ̀ ìmọrírì awọn wọnnì tí wọn ti ṣàkíyèsí iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ̀ ní gbangba ti fihàn! Gẹ́gẹ́ bí olùpòkìkí Ìjọba, iwọ ha ń fi Ilé-Ìṣọ́nà ati Jí! sóde lọ́dọ̀ awọn wọnnì tí o bá pàdé ninu iṣẹ́-òjíṣẹ́ rẹ bí?

19. Ìṣírí wo ni Heberu 6:​10-⁠12 fifún wa?

19 Pẹ̀lúpẹ̀lù, gbé sùúrù ati iṣẹ́-ìsìn àfòtítọ́ṣe ti awọn arákùnrin tí wọn ń ṣiṣẹ́sìn gẹ́gẹ́ bíi mẹ́ḿbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa yẹ̀wò. Mélòókan lára wọn wà ní ẹ̀wádún kẹsàn-⁠án tabi ẹ̀kẹwàá ìgbésí-ayé wọn bayii, ṣugbọn wọn ṣì jẹ́ olùpòkìkí Ìjọba tí ń fi tìtara-tìtara bójútó iṣẹ́ tí a yàn fún wọn. (Heberu 13:7) Kí sì ni nipa ti awọn àgbàlagbà mìíràn tí wọn ní ìrètí ti ọ̀run ati awọn kan lára “awọn àgùtàn mìíràn” pàápàá tí wọn ti ń gòkè àgbà? (Johannu 10:16) Wọn lè ní ìdánilójú pé Ọlọrun kìí ṣe aláìṣòdodo tí yoo fi gbàgbé iṣẹ́ wọn ati ìfẹ́ tí wọn fihàn fún orúkọ rẹ̀. Papọ̀ pẹlu awọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wọn tí wọn kéré sí wọn lọ́jọ́ orí, ǹjẹ́ kí awọn arúgbó tí wọn jẹ́ Ẹlẹ́rìí fún Jehofa máa tẹ̀síwájú ní ṣíṣe ohun tí wọn bá lè ṣe, ní lílo ìgbàgbọ́ ati fífi sùúrù hàn ninu iṣẹ́-ìsìn Ọlọrun. (Heberu 6:​10-⁠12) Nígbà naa, yálà nipa àjíǹde, gẹ́gẹ́ bí yoo ti rí ninu ọ̀ràn ti awọn wòlíì ìgbàanì, tabi nipa lílàájá ní tààràtà gba inú “ìpọ́njú ńlá” naa tí ń bọ̀ wá, wọn yoo ká èso jìngbìnnì ti ìyè ayérayé.​—⁠Matteu 24:⁠21.

20. (a) Kí ni o ti kọ́ lati inú “àpẹẹrẹ àwòṣe” awọn wòlíì? (b) Bawo ni sùúrù bíi ti awọn wòlíì ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?

20 Ẹ wo irú àpẹẹrẹ àwòṣe dídára tí awọn wòlíì Ọlọrun ti fi lélẹ̀ fún wa! Nitori pé wọn farada ìjìyà, wọn mú sùúrù, tí wọn sì fi awọn ànímọ́ mìíràn bíi ti Ọlọrun hàn, wọn ní àǹfààní lati sọ̀rọ̀ nipa orúkọ Jehofa. Gẹ́gẹ́ bí awọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ òde-òní, ẹ jẹ́ kí a dàbí wọn kí a sì ṣe ìpinnu fífẹsẹ̀rinlẹ̀ bíi ti wòlíì Habakkuku, ẹni tí ó kéde pé: “Lórí ibùṣọ́ mi ni èmi óò dúró, emi ó sì gbé ara mi ka orí alóre, emi óò sì ṣọ́ lati rí ohun tí [Ọlọrun] yoo sọ fún mi.” (Habakkuku 2:1) Ẹ jẹ́ kí a ní irú ìpinnu kan naa bí a ṣe ń mú sùúrù tí a sì ń fi tayọ̀tayọ̀ báa nìṣó lati ṣe ìpolongo ní gbangba sí orúkọ lílókìkí ti Atóbilọ́lá Ẹlẹ́dàá wa, Jehofa!​—⁠Nehemiah 8:10; Romu 10:⁠10.

Iwọ Ha Lóye Awọn Kókó Wọnyi Bí?

◻ Àpẹẹrẹ onígboyà wo ni wòlíì Amosi fi lélẹ̀?

◻ Ní awọn ọ̀nà wo ni wòlíì Mose gbà jẹ́ àwòfiṣàpẹẹrẹ?

◻ Bawo ni awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lóde òní ṣe lè hùwà bíi Amosi ati Isaiah?

◻ Kí ni awọn Kristian òjíṣẹ́ lè kọ́ ninu ìhùwàsí Hosea ati Joeli?

◻ Bawo ni a ṣe lè jàǹfààní láti inú awọn àpẹẹrẹ Esekieli ati Mika?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Ẹ̀mí Jehofa fún Amosi ní agbára lati sọtẹ́lẹ̀ tìgboyà-tìgboyà láìka àtakò gbígbóná janjan ti Amasiah sí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Awọn olùṣòtítọ́ ẹni-àmì-òróró ti fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nipa mímú sùúrù ninu iṣẹ́-ìsìn Jehofa

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́