ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 4/1 ojú ìwé 9-14
  • Kíkókìkí Ayé Titun Olómìnira Ti Ọlọrun

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Kíkókìkí Ayé Titun Olómìnira Ti Ọlọrun
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Sísọ Awọn Eniyan Rẹ̀ Dominira
  • Ominira Tootọ Ninu Ayé Titun Ti Ọlọrun
  • Ìmọ̀-Ẹ̀kọ́ Kari-Aye fun Ìyè
  • Ominira Ńláǹlà Nisinsinyi Paapaa
  • Sísọ Awọn Ẹlomiran Dominira Kuro Ninu Awọn Igbagbọ Èké
  • Ṣàfẹ́rí Jehofa
  • Ohun Tí Ìjọba Ọlọ́run Yóò Ṣe
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Ayé Kan Láìsí Ogun Yóò Dé Láìpẹ́
    Jí!—1996
  • Ayé Titun Iyanu naa ti Ọlọrun Ṣe
    Ọlọrun Ha Bikita Nipa Wa Niti Gidi Bi?
  • Awọn Eniyan Olominira Ṣugbọn Ti Wọn Yoo Jíhìn
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 4/1 ojú ìwé 9-14

Kíkókìkí Ayé Titun Olómìnira Ti Ọlọrun

“[Ọlọrun] yoo . . . nu omije gbogbo nù kuro ni oju wọn, iku ki yoo sì sí mọ́, bẹẹ ni ọ̀fọ̀ tabi igbe tabi irora kì yoo sí mọ́.”—IṢIPAYA 21:4, NW.

1, 2. Ẹnikanṣoṣo wo ni ó lè mú ominira tootọ wa, ki sì ni a lè mọ̀ nipa Rẹ̀ lati inu Bibeli?

ÌTÀN ti fi otitọ ohun ti wolii Jeremaya sọ han pe: “Fun eniyan olùgbé ori ilẹ ni ọna rẹ̀ kì í ṣe tirẹ. Kì í ṣe ti eniyan ti ń rìn koda lati dari iṣisẹ rẹ̀.” Kìkì ta ni ó lè dari iṣisẹ eniyan lọna yiyẹ? Jeremaya ń baa lọ lati wi pe: “Tọ́ mi sọ́nà, Óò Jehofa.” (Jeremaya 10:23, 24, NW) Bẹẹni, Jehofa nikan ni ó lè mú ominira tootọ wá kuro ninu awọn iṣoro ti ń yọ idile eniyan lẹnu.

2 Bibeli ní ọpọlọpọ awọn apẹẹrẹ agbara Jehofa lati mú ominira wá fun awọn wọnni ti ń ṣiṣẹsin in ninu. “Ohunkohun ti a ti kọ tẹlẹ, a ti kọ ọ́ fun kíkọ́ wa, pe nipa suuru ati itunu iwe-mimọ ki a lè ni ireti.” (Roomu 15:4) Awọn idajọ Jehofa lodisi ijọsin èké ni a tun kọsilẹ pẹlu, iwọnyi sì ṣiṣẹ gẹgẹ bi “apẹẹrẹ fun wa . . . awa ẹni ti igbẹhin ayé dé bá.”—1 Kọrinti 10:11.

Sísọ Awọn Eniyan Rẹ̀ Dominira

3. Bawo ni Jehofa ṣe fi agbara rẹ̀ lati dá awọn eniyan rẹ̀ ni Ijibiti silẹ lominira han?

3 Apẹẹrẹ kan ti agbara Ọlọrun lati mú idajọ ṣẹ lodisi ijọsin èké ati lati dá awọn wọnni ti wọn ń ṣe ifẹ rẹ̀ silẹ wáyé nigba ti a mú awọn eniyan rẹ̀ akoko igbaani lẹ́rú ni Ijibiti. Ẹkisodu 2:23-25 sọ pe: “Igbe wọn fun iranlọwọ sì ń baa lọ lati goke lọ sọdọ Ọlọrun otitọ naa nitori isinru naa. Bi akoko ti ń lọ Ọlọrun gbọ́ ikerora wọn.” Ninu ìfàjùlọ han kan ti ń muni kun fun ibẹru ọlọ́wọ̀ lori awọn ọlọrun èké Ijibiti, Ọlọrun Olodumare mú awọn ìyọnu mẹwaa wá sori orilẹ-ede naa. Ìyọnu kọọkan ni a pète lati dojuti ọlọrun Ijibiti kan, ni fifihan pe wọn jẹ́ èké wọn kò sì lè ran awọn ara Ijibiti ti ń jọsin wọn lọwọ. Nipa bayii Ọlọrun sọ awọn eniyan rẹ̀ dominira ó sì pa Farao ati awọn ọmọ ogun rẹ̀ run ninu Okun Pupa.—Ẹkisodu, ori 7 si 14.

4. Eeṣe ti kii fii ṣe aiṣedajọ ododo fun Ọlọrun lati mú awọn idajọ rẹ̀ ṣẹ lodisi awọn ara Kenani?

4 Nigba ti Ọlọrun mú Isirẹli wọ Kenani wá, awọn olùgbé inu rẹ̀ ti ń jọsin ẹmi eṣu ni a parun ti a sì fi ilẹ naa fun awọn eniyan Ọlọrun. Gẹgẹ bi Ọba-alaṣẹ Agbaye, Jehofa ní ẹ̀tọ́ lati mú awọn idajọ rẹ̀ ṣẹ lori awọn isin ayédèrú. (Jẹnẹsisi 15:16) Ati nipa isin awọn ará Kenani, Bible Handbook ti Halley sọ pe: “Ijọsin awọn ọlọrun . . . Kenani ni ariya alariwo yiyẹhanna julọ wémọ́; awọn tẹmpili wọn jẹ́ ibudo igbokegbodo fun ìwà ibi. . . . Awọn ará Kenani jọsin, nipa lilọwọ ninu iwa palapala, gẹgẹ bi aato isin kan, ni iwaju awọn ọlọrun wọn; ati lẹhin naa, nipa pipa awọn àkọ́bí ọmọ wọn, gẹgẹ bi ẹbọ si awọn ọlọrun kan naa wọnyi. Ó dabi pe, ní iwọn titobi, ilẹ Kenani ti di iru Sodomu ati Gomorra kan jakejado orilẹ-ede naa.” Ó fikun un pe: “Ọ̀làjú kan ti o ní iru iwa ìkà ati ibajẹ akoniniriira bẹẹ ninu ha tun ni ẹ̀tọ́ eyikeyii lati wà titilọ bi? . . . Awọn awalẹpitan ti wọn walẹ ninu àwókù awọn ilu Kenani ṣe kayefi pe Ọlọrun kò pa wọn run siwaju akoko ti oun ṣe bẹẹ.

5. Bawo ni dídá ti Ọlọrun dá awọn eniyan rẹ̀ igbaani silẹ lominira ṣe jẹ́ apẹẹrẹ fun akoko wa?

5 Akọsilẹ igbegbeesẹ Ọlọrun lodisi ijọsin èké yii, sísọ awọn eniyan majẹmu rẹ̀ dominira, ati pipese ilẹ ileri kan fun wọn jẹ́ apẹẹrẹ awọn nǹkan ti ń bọ̀. Ó tọka si ọjọ-ọla ti ó sunmọle gan-an nigba ti Ọlọrun yoo fọ́ awọn isin èké ayé ati awọn alatilẹhin wọn tuutuu ti yoo sì mú awọn iranṣẹ rẹ̀ ode-oni wọnu ayé titun ododo kan.—Iṣipaya 7:9, 10, 13, 14; 2 Peteru 3:10-13.

Ominira Tootọ Ninu Ayé Titun Ti Ọlọrun

6. Ki ni diẹ ninu awọn ominira agbayanu ti Ọlọrun yoo pese ninu ayé titun?

6 Ninu ayé titun naa, Ọlọrun yoo bukun awọn eniyan rẹ̀ pẹlu gbogbo ìhà yiyanilẹnu ti ominira naa tí oun ti pète fun idile eniyan. Ominira kuro ninu itẹloriba lati ọwọ awọn awujọ oṣelu, eto ọrọ̀ ajé, ati isin èké yoo wà. Ominira kuro lọwọ ẹṣẹ ati ikú yoo wà, pẹlu awọn eniyan ti wọn ni ireti wiwalaaye titilae lori ilẹ̀-ayé. “Olododo ni yoo jogun ayé, yoo sì maa gbe inu rẹ̀ laelae.”—Saamu 37:29; Matiu 5:5.

7, 8. Ki ni a o niriiri rẹ̀ ninu jijere ilera pipe pada ninu ayé titun?

7 Laipẹ lẹhin ti a bá ti mú ayé titun yẹn wọle dé tan, awọn olùgbé rẹ̀ ni a o mú padabọsipo si ilera pipe lọna iyanu. Joobu 33:25 sọ pe: “Ara rẹ̀ yoo sì jà yọ̀yọ̀ ju ti ọmọ kekere, yoo si tun pada si ọjọ igba ewe rẹ̀.” Aisaya 35:5, 6 ṣeleri pe: “Nigba naa ni oju awọn afọju yoo là, eti awọn aditi yoo sì ṣí. Nigba naa ni awọn arọ yoo fò bi agbọnrin, ati ahọn odi yoo kọrin.”

8 Gbogbo ẹyin ti ẹ ni ailera ti ara nitori ọjọ ogbó tabi ilera ti kò sunwọn, finu woye araarẹ ninu ayé titun naa ti o ń jí dide loroowurọ pẹlu ilera ati okun. Awọn ara rẹ hihunjọ ti faye silẹ fun àwọ̀ ara jíjọ̀lọ̀, tí ó jípépé—kò sí aini fun awọn ipara amárajọ̀lọ̀ mọ́. Awọn oju rẹ tí ń ṣe bàìbàì tabi ti ó ti fọ́ ni a mú padabọsipo iriran kedere—kò sí aini fun awò ojú mọ́. Igbọran lẹkun-un-rẹrẹ ni a ti mú padabọsipo—gbé awọn aranṣe igbọran wọnni sọnù. Awọn eékún ti o yarọ ni a mú lókun ti a sì sọ di odidi—kó awọn ọ̀pá, ìkẹ́sẹ̀, ati awọn kẹ̀kẹ́ arọ wọnni dànù. Kò si aisan mọ́—da gbogbo oogun wọnni nù. Nipa bayii, Aisaya 33:24 sọtẹlẹ pe: “Ati awọn ará ibẹ̀ ki yoo wi pe, Òótù ń pa mi.” Ó tun sọ pe: “Wọn yoo rí ayọ ati inudidun gbà, ikaaanu oun ìmí-ẹ̀dùn yoo sì fò lọ.”—Aisaya 35:10.

9. Bawo ni a o ṣe mú ogun wa si opin titilae?

9 A kò tun ni fi ẹnikẹni rubọ si ogun mọ́. “[Ọlọrun] mú ọ̀tẹ̀ tan de opin ayé; ó ṣẹ́ ọrun, ó sì ké ọ̀kọ̀ meji; ó sì fi kẹ̀kẹ́ ogun jona.” (Saamu 46:9) Awọn ohun ija ogun ni a kò ni fayegba mọ́ lae nipasẹ Oluṣakoso Ijọba Ọlọrun, Kristi Jesu, ẹni ti Aisaya 9:6 pè ni “Ọmọ Alade Alaafia.” Ẹsẹ 7 fikun un pe: “Ijọba yoo bí sii, alaafia ki yoo ni ipẹkun.”

10, 11. Ki ni alaafia patapata yoo tumọsi fun ilẹ̀-ayé?

10 Iru ibukun wo ni yoo jẹ́ fun araye, ati fun ilẹ̀-ayé yii, lati wà lominira kuro lọwọ ohun ìjà ogun! Eeṣe, ni akoko lọwọlọwọ, awọn ohun ìjà ti a lò ninu awọn ogun iṣaaju ṣì ń pa awọn eniyan run. Ni orilẹ-ede kan, France, iye ti ó ju 600 awọn ògbógi ti ń palẹ bọmbu mọ́ ni a ti pa lati 1945 nigba ti wọn ń mú awọn ohun abúgbàù ti ó ṣẹ́kù lati inu awọn ogun iṣaaju kuro. Olori ile-iṣẹ ti ń palẹ bọmbu mọ́ nibẹ sọ pe: “Sibẹsibẹ a ṣì ń ri awọn ọta bọmbu ti ó ṣì gbeṣẹ ti a lò nigba Ogun France-oun-Prussia ti 1870. Awọn adágún wà tí ó kún fọ́fọ́ fun awọn ohun abúgbàù olóró lati ìgbà Ogun Agbaye I wà. Leralera, àgbẹ̀ kan ti ó wà ninu katakata lè wakọ̀ kọja lori bọmbu abẹlẹ tí ń gbógun ti àgbá arọ̀jò-ọta lati ìgbà Ogun Agbaye II àfi gbàù, ikú dé niyẹn. Awọn nǹkan wọnyi wà ni ibi gbogbo.” Ni ọdun meji sẹhin The New York Times sọ pe: “Ni awọn ọdun 45 lati ìgbà ti Ogun Agbaye II ti pari, [ibudo tí ń palẹ bọmbu mọ́] ti gba ilẹ [France] silẹ kuro lọwọ million 16 àgbá ọta àfisọ̀kò, 490,000 bọmbu ati 600,000 àgbá-ọta-abúgbàù abẹ́-omi. . . . Araadọta-ọkẹ eékà ilẹ ni a ta ọgbà yíká, wọn ni awọn ohun ìjà ti wọn kò jìn ju orunkun lọ a sì yi wọn ká pẹlu awọn àkọlé ti ó kilọ pe: ‘Maṣe Fọwọ Kan an. Ó Ń pani!’”

11 Ayé titun yoo ti yatọ tó! Olukuluku yoo ni ibugbe rere, ọpọ yanturu ounjẹ, ati iṣẹ alalaafia, tí ń tẹnilọrun ti yiyi gbogbo ilẹ̀-ayé pada si paradise. (Saamu 72:16; Aisaya 25:6; 65:17-25) Awọn eniyan, ati ilẹ̀ ayé, ni a kò ni kọlu nipasẹ araadọta-ọkẹ irinṣẹ abúgbàù mọ́ lae. Iru ayé titun kan bẹẹ ni Jesu ni lọkan nigba ti ó sọ fun ẹnikan ti ó fi igbagbọ han ninu rẹ̀ pe: “Iwọ yoo wà pẹlu mi ni Paradise.”—Luuku 23:43.

Ìmọ̀-Ẹ̀kọ́ Kari-Aye fun Ìyè

12, 13. Iṣẹ ìmọ̀-ẹ̀kọ́ kari ayé wo ni Jesu ati Aisaya sọtẹlẹ fun akoko wa?

12 Nigba ti ẹnikan bá kẹkọọ nipa ayé titun ti Ọlọrun, oun tun ń kẹkọọ pe ni ọjọ wa, Jehofa ti pese ijọ kari-ayé ti a ṣetojọ fun ijọsin tootọ. Yoo jẹ́ apa pataki ilẹ̀-ayé titun naa, Ọlọrun sì ń lò ó nisinsinyi lati kọ́ awọn miiran nipa awọn ète rẹ̀. Eto-ajọ Kristẹni yii ń ṣe iṣẹ ìmọ̀-ẹ̀kọ́ kari ayé kan irú ati iwọn eyi ti a kò tii rí rí. Jesu sọtẹlẹ pe eyi yoo di ṣiṣe. Ó sọ pe: “A o sì waasu ihinrere ijọba yii ni gbogbo ayé lati ṣe ẹ̀rí fun gbogbo orilẹ-ede; nigba naa ni opin yoo sì dé.”—Matiu 24:14.

13 Aisaya tun sọrọ nipa iṣẹ ìmọ̀-ẹ̀kọ́ yika ayé yii pe: “Yoo sì ṣe ni ọjọ ikẹhin [ni akoko tiwa], a o fi oke ile Oluwa [ijọsin tootọ rẹ̀ ti a gbé ga] kalẹ . . . gbogbo orilẹ-ede ni yoo sì wọ́ si nu rẹ̀. Ọpọlọpọ eniyan ni yoo sì lọ, wọn o sì wi pe, Ẹ wá, ẹ jẹ ki a lọ si oke Oluwa, . . . oun ó sì kọ́ wa ni ọna rẹ̀, awa ó sì maa rin ni ipa rẹ̀.”—Aisaya 2:2, 3.

14. Bawo ni a ṣe lè dá awọn eniyan Ọlọrun mọ̀ lonii?

14 Fun idi yii, iṣẹ jijẹrii nipa Ijọba Ọlọrun yika ayé jẹ́ ẹ̀rí lilagbara pe a ti sunmọ opin eto igbekalẹ buburu yii ati pe ominira tootọ kù sí dẹ̀dẹ̀. Ẹni naa ti ń késí awọn eniyan pẹlu ihin-iṣẹ ti ó kun fun ireti nipa ayé titun ti Ọlọrun ni a ṣapejuwe ni Iṣe 15:14 gẹgẹ bi ‘eniyan fun orukọ Ọlọrun.’ Awọn wo ni wọn ń jẹ́ orukọ Jehofa ti wọn sì ń funni ni ẹ̀rí yika ayé nipa Jehofa ati Ijọba rẹ̀? Akọsilẹ ìtàn ti ọrundun 20 dahun pe: kìkì Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni. Lonii wọn pọ̀ ju million mẹrin ninu ohun ti o ju 66,000 ijọ ni gbogbo ayé.—Aisaya 43:10-12; Iṣe 2:21.

15. Niti awọn àlámọ̀rí oṣelu, bawo ni a ṣe lè dá awọn iranṣẹ Ọlọrun tootọ mọ?

15 Ẹ̀rí miiran pe Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń mú awọn asọtẹlẹ nipa iṣẹ iwaasu Ijọba naa ṣẹ ni a kọsilẹ ni Aisaya 2:4: “Wọn o fi idà wọn rọ ohun-eelo ìtúlẹ̀, wọn ó sì fi ọ̀kọ̀ wọn rọ doje; orilẹ-ede ki yoo gbe idà soke si orilẹ-ede; bẹẹni wọn ki yoo kọ́ ogun jija mọ́.” Nitori naa awọn wọnni ti wọn ń ṣe iṣẹ iwaasu kari ayé nipa iṣakoso Ijọba Ọlọrun ‘ko gbọdọ kọ́ ogun jíjà mọ́.’ Jesu sọ pe wọn kò gbọdọ ‘jẹ́ apakan ayé.’ (Johanu 17:16) Eyi tumọsi pe wọn gbọdọ wà láìdásí tọ̀túntòsì ninu awọn àlámọ̀rí oṣelu, ní ṣíṣàì gbè sí ìhà kankan lẹhin ninu awọn ariyanjiyan ati ogun awọn orilẹ-ede. Awọn wo ni wọn ki i ṣe apakan ayé ti wọn kò sì kọ́ ogun jíjà mọ? Lẹẹkan sii, akọsilẹ ìtàn ti ọrundun 20 jẹrii sí i pe: kìkì Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni.

16. Bawo ni iṣẹ ìmọ̀-ẹ̀kọ́ kari aye ti Ọlọrun yoo ti jẹ́ kúnnákúnná tó?

16 Iṣẹ ìmọ̀-ẹ̀kọ́ kari aye ti Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa yoo maa baa lọ ani lẹhin ti Ọlọrun bá ti mú ayé buburu isinsinyi wá si opin rẹ̀ paapaa. Aisaya 54:13 sọ pe: “A o sì kọ́ gbogbo awọn ọmọ rẹ lati ọdọ Oluwa [“Jehofa,” NW] wá.” Kúnnákúnná gan-an ni ìkọ́ni yii yoo jẹ́ debi pe Aisaya 11:9 sọtẹlẹ pe: “Ayé yoo kún fun ìmọ̀ Oluwa [“Jehofa,” NW] gẹgẹ bi omi ti bo okun.” Ìkọ́ni ti ń ba a lọ ni a o nilo kì í ṣe fun awọn olùla opin ayé ogbologbo yii já ati fun awọn ọmọ ti a lè bí ninu ayé titun nikan ni, ṣugbọn fun ẹgbẹẹrun ọkẹ ti wọn pada wá si ìyè ninu ajinde pẹlu. Asẹhinwa-asẹhinbọ, olukuluku eniyan ti ń gbé lori ilẹ̀-ayé ni a ó kọ́ lati lo ominira ifẹ-inu rẹ̀ lọna bibojumu ninu ààlà awọn ofin Ọlọrun. Ki ni abajade rẹ̀? “Awọn ọlọ́kàn-tútù ni yoo jogun ayé; wọn yoo sì maa ṣe inu didun ninu ọpọlọpọ alaafia.”—Saamu 37:11.

Ominira Ńláǹlà Nisinsinyi Paapaa

17. Ki ni Mose sọ fun awọn eniyan Ọlọrun igbaani lati ṣe?

17 Nigba ti awọn ọmọ Isirẹli igbaani wà ni bèbè Ilẹ Ileri, Mose bá wọn sọrọ pe: “Emi ti kọ́ yin ni ilana ati idajọ, bi Oluwa [“Jehofa,” NW] Ọlọrun mi ti paṣẹ fun mi, pe ki ẹyin ki o lè maa ṣe bẹẹ ni ilẹ naa nibi ti ẹyin ń lọ lati gbà á. Nitori naa ẹ pa wọn mọ́, ki ẹ sì maa ṣe wọn; nitori pe eyi ni ọgbọn yin ati oye yin ni oju awọn orilẹ-ede, ti yoo gbọ gbogbo ilana wọnyi, ti yoo si wi pe, Ọlọgbọn ati amoye eniyan nitootọ ni orilẹ-ede ńlá yii. Nitori orilẹ-ede ńlá wo ni o wà, ti o ní Ọlọrun sunmọ wọn tó, bi Oluwa [“Jehofa,” NW] Ọlọrun wa ti rí ninu ohun gbogbo ti awa ké pè é si?”—Deutaronomi 4:5-7.

18. Awọn ominira ńlá wo ni wọn ń wá nisinsinyi paapaa fun awọn wọnni ti ń ṣiṣẹsin Ọlọrun?

18 Lonii araadọta-ọkẹ tí ń jọsin Jehofa pẹlu wà ni bèbè ilẹ ileri kan—ayé titun. Nitori pe wọn ṣegbọran si awọn ofin Ọlọrun, wọn ní Ọlọrun pẹkipẹki lẹgbẹẹ ọdọ wọn wọ́n sì tayọ laaarin gbogbo awọn eniyan yooku. Ṣaaju akoko yii Ọlọrun ti sọ wọn dominira kuro ninu awọn èrò isin èké, ẹ̀yà temi lọ̀gá, lilo oogun ti kò bá ofin mu, ifẹ orilẹ-ede ẹni, ogun, ati itankalẹ awọn àrùn ti ibalopọ takọtabo ń ta látaré. Siwaju sii, ó ti so wọn pọ̀ ṣọ̀kan ninu ifẹ ẹgbẹ́ ará ti kò ṣee fàjá jakejado awọn orilẹ-ede. (Johanu 13:35) A kò kó ipaya bá wọn nipa ọjọ-ọla ṣugbon wọn “kọrin fun inu didun.” (Aisaya 65:14) Iru ominira ńlá wo ni wọn ń gbadun nisinsinyi paapaa nipa ṣiṣiṣẹsin Ọlọrun gẹgẹ bi Oluṣakoso!—Iṣe 5:29, 32; 2 Kọrinti 4:7; 1 Johanu 5:3.

Sísọ Awọn Ẹlomiran Dominira Kuro Ninu Awọn Igbagbọ Èké

19, 20. Bawo ni a ṣe sọ awọn eniyan dominira nipa ẹkọ Bibeli nipa ipo awọn oku?

19 Ọpọlọpọ ti Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń waasu fun tún ń wá lati rí awọn ominira wọnyi. Fun apẹẹrẹ, ni awọn ilẹ nibi ti wọn ti ń ba a niṣo ninu ijọsin awọn babanla, Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ń sọ ọ́ di mímọ̀ fun awọn ẹlomiran pe awọn oku kò walaaye nibi kankan wọn kò sì lè pa alààyè lara. Awọn Ẹlẹ́rìí ń tọka si Oniwaasu 9:5, eyi ti ó sọ pe “alààyè mọ̀ pe awọn yoo kú; ṣugbọn awọn oku kò mọ ohun kan.” Wọn tun ń tọka si Saamu 146:4, eyi ti ó wi pe nigba ti ẹnikan bá kú “ó pada si erupẹ rẹ̀; ni ọjọ naa gan-an, iro inu rẹ̀ run.” Nitori naa Bibeli fihan pe kò si ẹmi bí iwin tabi aileku ọkàn lati ṣe iwosan tabi dáyàfo awọn alààyè. Nitori naa, kò sí idi, lati fi owó ti a fi òógùn ojú wá ṣòfò ni sísanwó fun awọn baba-alawo tabi awọn alufaa.

20 Iru ìmọ̀ pipeye Bibeli bẹẹ ń sọ awọn eniyan dominira kuro ninu awọn ẹkọ èké ti ọrun apaadi ati pọgatori. Nigba ti awọn eniyan bá kẹkọọ otitọ Bibeli pe awọn oku kò mọ ohun kan, gẹgẹ bi ẹni pe wọn wà ninu orun àsùnwọra, wọn kii daamu mọ́ nipa ohun ti o ti ṣẹlẹ si awọn ololufẹ wọn ti o ti kú. Kaka bẹẹ, wọn ń wo iwaju fun akoko agbayanu naa ti apọsiteli Pọọlu sọrọ nipa rẹ̀ nigba ti ó wi pe: “Ajinde oku ń bọ̀, ati ti oloootọ, ati ti alaiṣootọ.”—Iṣe 24:15.

21. Awọn wo laiṣiyemeji ni yoo wà ninu awọn wọnni ti a o jí dide, ki ni o sì ṣeeṣe ki o jẹ́ iṣarasihuwa wọn?

21 Nigba ajinde awọn oku yoo pada wá sí ìyè lori ilẹ̀-ayé ti a ti sọ dominira titilae kuro lọwọ iku Adamu ti a ti jogun. Kò sí iyemeji pe awọn ti a o jí dide yoo ni awọn ọmọ ti a fi rubọ si awọn ọlọrun Kenani, iru bii Moleki ninu, awọn ọdọmọkunrin ti a fi rubọ si awọn ọlọrun Aztec, ati ọkẹ aimọye ti a fi rubọ si ọlọrun ogun. Bawo ni iyalẹnu ati idunnu naa yoo ti pọ̀ tó fun awọn ojiya ipalara igbagbọ èké tẹlẹri wọnni! Iru awọn ti a jí dide bẹẹ lè fi tayọtayọ polongo nigba naa pe: ‘Iku, oró rẹ dà? Isa-oku iparun rẹ dà?’—Hosea 13:14.

Ṣàfẹ́rí Jehofa

22. Bi a bá fẹ́ wà ninu ayé titun ti Ọlọrun, ki ni a nilati pamọ si ọkàn?

22 Iwọ ha fẹ́ lati gbé ninu ayé titun ododo Ọlọrun, nibi ti ominira tootọ yoo gbé wà bi? Bi o bá ri bẹẹ, nigba naa fi awọn ọrọ 2 Kironika 15:2 sọkan pe: “Oluwa [“Jehofa,” NW] pẹlu yin, nitori ti ẹyin ti wà pẹlu rẹ̀; bi ẹyin bá sì ṣàfẹ́rí rẹ̀, ẹyin yoo sì rí i; ṣugbọn bi ẹyin bá kọ̀ ọ́, oun yoo sì kọ̀ yin.” Ki o sì fi sọkan pe awọn isapa oloootọ-inu rẹ lati kẹkọọ nipa Ọlọrun ati lati wù ú ni a kò ni ṣaifiyesi. Heberu 11:6 sọ pe Ọlọrun ni “oluṣẹsan fun awọn ti o fi ara balẹ wá a.” Roomu 10:11 si sọ pe: “Ẹnikẹni ti ó bá gbà á gbọ́ oju kì yoo tì í.”

23. Eeṣe ti a fi gbọdọ kókìkí ayé titun ominira ti Ọlọrun?

23 Eyi ti ó wọle dé tan gan-an ni ayé titun olominira tootọ ti Ọlọrun. Nibẹ ni “a o sọ ẹ̀dá tikalaarẹ di ominira kuro ninu ẹrú idibajẹ, si ominira ogo awọn ọmọ Ọlọrun.” “[Ọlọrun] yoo sì nu omije gbogbo nù kuro ni oju wọn; iku ki yoo sì sí mọ́, bẹẹ ni ọ̀fọ̀, tabi igbe tabi irora kì yoo sí mọ́.” (Roomu 8:21; Iṣipaya 21:4, NW) Nigba naa ni gbogbo awọn iranṣẹ Jehofa yoo gbé ori wọn soke wọn yoo sì fi tayọtayọ kókìkí ayé titun olominira ti Ọlọrun nipa kíké sáàfúlà pe, ‘O ṣeun Jehofa, fun ominira tootọ nigbẹhingbẹhin!’

Bawo ni Iwọ Yoo Ṣe Dahun?

◻ Bawo ni Jehofa ṣe ṣaṣefihan agbara rẹ̀ lati sọ awọn eniyan rẹ̀ dominira?

◻ Awọn ominira agbayanu wo ni yoo wà nibẹ ninu ayé titun ti Ọlọrun?

◻ Bawo ni Jehofa ṣe ń kọ́ awọn eniyan rẹ̀ lẹkọọ fun ìyè?

◻ Awọn ominira diẹ wo ni awọn eniyan Ọlọrun ń gbadun nisinsinyi paapaa nipa ṣiṣiṣẹsin Jehofa?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Jehofa fi ipo ajulọ rẹ̀ lori awọn ọlọrun èké Ijibiti han, ni sisọ awọn olujọsin Rẹ̀ dominira

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12, 13]

Lonii, awọn iranṣẹ Ọlọrun tootọ ni a dámọ̀ nipa ṣiṣe iṣẹ ìmọ̀-ẹ̀kọ́ kari ayé ati jíjẹ́ orukọ rẹ̀

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́