ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 4/15 ojú ìwé 26-30
  • Jehofa Bojuto Wa Labẹ Ifofinde Apa 1

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jehofa Bojuto Wa Labẹ Ifofinde Apa 1
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ibẹrẹ Wàhálà
  • Wọn Fofinde Iṣẹ Wa
  • Ṣiṣe Awọn Ipade Labẹ Ifofinde
  • Iṣẹ Ayanfunni Mi Pataki Akọkọ
  • Ni Igbẹkẹle Ninu Jehofa
  • Ìtọ́jú Lati Ọdọ Jehofa Fúnraarẹ̀
  • Jehofa Bojuto Wa Labẹ Ifofinde—Apa 2
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Jehofa Bojuto Wa Labẹ Ifofinde—Apa 3
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Bí Ìdílé Mi Ṣe Dúró Ṣinṣin ti Ọlọ́run Sún Mi Ṣiṣẹ́
    Jí!—1998
  • Jehofa Wà Pẹ̀lú Mi
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 4/15 ojú ìwé 26-30

Jehofa Bojuto Wa Labẹ Ifofinde Apa 1

Fun ọ̀pọ̀ ẹwadun Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ti ṣe kayefi nipa awọn arakunrin wọn ni awọn ilẹ nibi ti a ti ká awọn igbokegbodo Kristẹni wọn lọwọko. A layọ lati gbé akọkọ ninu awọn ọrọ-ẹkọ mẹta ti ó ṣipaya diẹ ninu awọn ohun ti ó ṣẹlẹ jade. Iwọnyi jẹ́ akọsilẹ ara-ẹni ti awọn Kristẹni oluṣotitọ ni ibi ti a mọ nigba naa si Ila-oorun Germany.

NI 1944, mo jẹ́ ará German ti a mú loju ogun, tí ń ṣiṣẹ gẹgẹ bi ọmọ-ọdọ ni ile iwosan ni Ibùdó Cumnock, nitosi Ayr, Scotland. A yọnda fun mi lati jade sita ibùdó naa, bi o tilẹ jẹ́ pe bíbá awọn eniyan adugbo dọ́rẹ̀ẹ́ ni a káwọ́ rẹ̀ kò. Ni rínrìn gbẹ̀rẹ̀ ni ọjọ Sunday kan, mo pade ọkunrin kan tí ó ṣe awọn isapa onifọkansi lati ṣalaye awọn nǹkan fun mi lati inu Bibeli. Lẹhin iyẹn niye ìgbà a maa ń rìn gbẹ̀rẹ̀ kiri papọ.

Laipẹ lajinna ó ké sí mi wá sibi ikorajọpọ kan ninu ile. Eyi léwu niha ọdọ tirẹ̀, niwọnbi mo ti jẹ́ mẹmba orilẹ-ede ọ̀tá kan. Ni akoko naa emi kò mọ pe oun jẹ́ ọ̀kan lara Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa—ipade naa ni kedere jẹ́ ọ̀kan lara awujọ ikẹkọọ Bibeli wọn. Bi o tilẹ jẹ pe emi kò loye ohun pupọ, mo ranti ni kedere aworan ọmọ kan ti a wọ̀ ni ẹ̀wù funfun gigun kan, papọ pẹlu kinniun ati ọdọ agutan. Aworan ayé titun yii, gẹgẹ bi a ti ṣapejuwe rẹ̀ ninu iwe Bibeli ti Aisaya, wọ̀ mí lọ́kàn ṣinṣin.

Ni December 1947, a dá mi silẹ kuro ninu ibùdó ẹ̀wọ̀n. Ni pipada si ile ni Germany, mo gbé Margit, ẹni ti mo ti mọ̀ ṣaaju ogun niyawo. A fi Zittau, ti ó sunmọ ẹnu ibode pẹlu Poland ati Czechoslovakia ṣe ile wa. Laaarin iwọnba ọjọ diẹ, ọ̀kan lara Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa kan ilẹkun wa. “Bi eyi bá jẹ́ awujọ kan naa ti mo pade ni Scotland,” ni mo sọ fun aya mi, “nigba naa a nilati darapọ mọ wọn.” Ni ọ̀sẹ̀ yẹn kan naa, a lọ si ipade wa akọkọ pẹlu Awọn Ẹlẹ́rìí naa.

Lati inu Bibeli, kò pẹ́ ti a fi mọ̀ nipa aini naa lati lọ si awọn ipade Kristẹni deedee ati lati ṣajọpin ninu iṣẹ wiwaasu. Niti tootọ, ohun ti Awọn Ẹlẹ́rìí fi kọni lati inu Bibeli di ohun pataki julọ ninu igbesi-aye wa laipẹ. Laipẹ laijinna mo bẹrẹ sii dari awujọ ikẹkọọ Bibeli kan. Nigba ti ó yá, ni February 1950, awọn Kristẹni alaboojuto arinrin-ajo meji beere pe: “Ṣe ẹyin kò fẹ́ lati ṣe iribọmi rárá ni?” Ni ọ̀sán ọjọ yẹn gan-an emi ati Margit fi ami iṣapẹẹrẹ iyasimimọ wa han si Ọlọrun nipasẹ iribọmi.

Ibẹrẹ Wàhálà

Zittau wà ninu ipinlẹ Soviet ti Germany, awọn isapa lati bá Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa fa wàhálà sì ti bẹrẹ ni 1949. Kìkì lẹhin ọpọ julọ iṣoro ni a tó rí ohun eelo fun apejọ kekere ni Bautzen gbà. Lẹhin naa, ni ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn, awọn ọkọ̀ oju-irin akanṣe fun apejọpọ agbegbe titobi ju ni Berlin ni a wọ́gi lé lojiji. Sibẹ ẹgbẹẹgbẹrun pésẹ̀.

Awọn ipade ìjọ ni a tún dí lọwọ. Awọn olùṣèdíwọ́ yoo wá kìkì lati pariwo ki wọn sì súfèé. Ni akoko kan a fẹrẹẹ fi dandan mú wa lati dá ọrọ asọye alaboojuto arinrin-ajo kan duro. Awọn onirohin pè wá ni wolii iparun. Awọn ọrọ-ẹkọ iwe irohin tilẹ sọ pe a ti korajọ sori awọn òkè nigba ti a ń duro de ìgbà ti awọsanma yoo gbá wa lọ. Awọn iwe irohin tun ṣayọlo ọrọ awọn ọdọmọbinrin kan pé wọn sọ pe Awọn Ẹlẹ́rìí gbiyanju lati bá wọn ṣe iṣekuṣe. Alaye naa pe ‘awọn wọnni ti wọn ń ṣe iyasimimọ si Jehofa yoo gba ìyè ainipẹkun’ ni wọn lọ́po lati sọ pe awọn wọnni ti wọn ni ibalopọ takọtabo pẹlu Awọn Ẹlẹ́rìí yoo jèrè ìyè ainipẹkun.

Lẹhin naa wọn tún fi ẹ̀sùn jíjẹ́ adá-ogun sílẹ̀ kàn wá. Ohun ti a sọ nipa ogun Ọlọrun ti Amagẹdọni ni wọn ṣì tumọ si pe a ń fun idije ohun ìjà ogun ati ogun niṣiiri. Ó ti jẹ́ èké tó! Sibẹ, ni August 1950, nigba ti mo dé fun iyipo iṣẹ alẹ́ ni ile-iṣẹ iwe irohin adugbo kan nibi ti mo ti ń ṣiṣẹ gẹgẹ bi ontẹwe kan, a dá mi duro ni ẹnu ibode. “A ti lé ọ kuro lẹnu iṣẹ́,” ni olùṣọ́ naa, ti ọlọpaa kan duro tì sọ. “Ẹyin eniyan wọnyi wà ninu awọn ti o fọwọsi ogun.”

Ni ile, Margit ni a tù lára. “Kò si iṣẹ àṣedòru mọ́,” ni ó sọ. A kò ṣaniyan. Mo ri iṣẹ́ miiran laipẹ. A nigbẹkẹle ninu Ọlọrun lati pese, ó sì ṣe bẹẹ.

Wọn Fofinde Iṣẹ Wa

Ni August 31, 1950, igbokegbodo Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni German Democratic Republic ni wọn fofinde. Ọpọ jantirẹrẹ ifaṣẹ ọba muni ni ó tẹle e. Awọn Ẹlẹ́rìí ni a fi sabẹ iyẹwo ẹjọ, ti awọn kan sì gba ijiya ẹ̀wọ̀n gbére. Awọn meji lati Zittau, ti wọn ti jiya ninu awọn ibùdó ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ labẹ awọn oṣelu Nazi, ni awọn Kọmunisti tì mọnu ẹ̀wọ̀n.

Ẹni ti ó ń bojuto ìjọ wa ni a faṣẹ ọba mú pẹlu aya rẹ̀. Awọn wọnni ti wọn faṣẹ ọba mú wọn fi awọn ọmọ wọn kekere meji silẹ ni awọn nikanṣoṣo ninu ile lati bojuto araawọn. Awọn obi iyawo kó awọn ọmọ naa tira, ati lonii awọn ọmọbinrin mejeeji jẹ́ onitara ninu sisọ fun awọn ẹlomiran nipa Ijọba Ọlọrun.

Awọn olùkówèé irohin lati inu awọn ìjọ ni Ila-oorun Germany rin irin-ajo ni àlọbọ̀ si Berlin lati ko iwe ikẹkọọ ni ọgangan ibi ti a ń já wọn sí ni apá ipin iwọ-oorun ti ó lominira. Ọpọlọpọ ninu awọn olùkówèé irohin onigboya wọnyi ni a faṣẹ ọba mú, ti a sì wọ́ lọ si ile-ẹjọ, ti a sì fun wọn ni idajọ ẹ̀wọ̀n.

Awọn alaṣẹ dé ni kutukutu owurọ ọjọ kan lati wá inu ile wa. A ti fojusọna fun wíwá wọn, nitori naa mo ti kó gbogbo awọn akọsilẹ ìjọ, ti mo ń tọju, ninu àká wa, lọ si ẹ̀bá ile agbọ́n kan. Awọn kokoro naa kò yọ mi lẹnu, ṣugbọn nigba ti awọn ọkunrin naa bẹrẹ sii fòfintótó ṣe iwakiri, lojiji ni ọgọọrọ awọn agbọ́n ṣùùrù bò wọn. Gbogbo ohun ti awọn ọkunrin naa lè ṣe ni lati sá fun aabo!

Jehofa ti mura wa silẹ fun ifofinde naa nipasẹ awọn apejọpọ ti a ṣe ni 1949. Itolẹsẹẹsẹ naa ti rọ̀ wa lati mú ikẹkọọ ara-ẹni, lilọ si awọn ipade, ati igbokegbodo iwaasu wa pọ sii, ati bakan naa lati gbarale ẹnikinni keji fun itilẹhin ati iṣiri. Eyi ran wa lọwọ lati wà ni aduroṣinṣin niti gidi. Nipa bayii, ani bi o tilẹ jẹ pe awọn eniyan niye ìgbà maa ń le mọ́ wa ti wọn sì ń bú wa, a kò kà á sí.

Ṣiṣe Awọn Ipade Labẹ Ifofinde

Tẹle ikede nipa ifofinde naa, mo lọ sọdọ Awọn Ẹlẹ́rìí ẹlẹgbẹ mi meji lati jiroro bi a o ṣe maa bá awọn ipade ìjọ wa lọ. Pipesẹ sibẹ léwu, niwọn bi ifaṣẹ ọba muni nigba ti a bá wà nibẹ ti lè tumọsi idajọ ẹ̀wọ̀n. A ké si Awọn Ẹlẹ́rìí ni agbegbe wa. Ara awọn kan kò balẹ, ṣugbọn ó funni niṣiiri pe ẹnikọọkan mọ aini naa lati lọ si awọn ipade lẹkun-un-rẹrẹ.

Ọkunrin olùfìfẹ́hàn kan ti ó ni àká pese rẹ̀ fun lilo gẹgẹ bi ibi ipade. Bi o tilẹ jẹ pe ó wà ni ori pápá, ti gbogbo eniyan lè rí i, àká naa ni ilẹkun ẹhin ile ti ó ṣí si ipa ọna kan ti ó farasin nipasẹ igbo. Nitori naa wíwá ati lilọ wa ni a kò ṣakiyesi. Fun gbogbo ìgbà òtútù àká ogbologboo yẹn jẹ́ ohun eelo fun awọn ipade wa ti a ṣe labẹ ìmọ́lẹ̀ àbẹ́là, pẹlu nǹkan bii 20 eniyan ni ijokoo. A ń pade lọsọọsẹ fun ikẹkọọ iwe irohin Ilé-Ìṣọ́nà wa ati fun Ipade Iṣẹ-Isin. Itolẹsẹẹsẹ naa ni a mú bá ipo wa mu, ni titẹnumọ ọn pe awa nilati maa baa lọ ni jíjẹ́ ọ̀jáfáfá nipa tẹmi. Ó dun mọ wa lati tẹwọgba ọkunrin olùfìfẹ́hàn kan naa gẹgẹ bi arakunrin wa ninu otitọ.

Ni aarin awọn ọdun 1950, awọn idajọ ile-ẹjọ tubọ dẹrùn, awọn arakunrin kan ni a sì tú silẹ kuro ninu ẹ̀wọ̀n. Ọpọlọpọ ni a kó lọ si Iwọ-oorun Germany. Niti emi, awọn nǹkan yipada lọna airotẹlẹ tẹle ibẹwo arakunrin kan lati Iwọ-oorun Germany.

Iṣẹ Ayanfunni Mi Pataki Akọkọ

Arakunrin naa pe araarẹ̀ ni Hans. Tẹle ijumọsọrọpọ wa, a sọ fun mi lati wá si adirẹsi kan ni Berlin. Ní rírí orukọ ẹnà naa lara aago ara ilẹkun, a ké sí mi wọle. Awọn ẹni meji darapọ mọ mi wọn sì bá mi ni ijiroro gbigbadun mọni ṣugbọn ti ó jẹ́ ti gbogbogboo gan-an. Lẹhin naa ni wọn dé ibi ti wọn ń lọ gan-an: “Bi a bá fun ọ ni iṣẹ ayanfunni akanṣe kan, iwọ yoo ha tẹwọgba a bi?”

“Dajudaju,” ni idahun mi.

Wọn sọ pe, “o dara, gbogbo ohun ti a fẹ́ lati mọ̀ niyẹn. Wàá délé layọ o.”

Ní ọ̀sẹ̀ mẹta lẹhin naa a sọ fun mi lati pada si Berlin mo sì bá araami ninu iyàrá yẹn lẹẹkan sii. Bi wọn ti nawọ́ aworan ilẹ ẹkùn ti o yi Zittau ka si mi, awọn arakunrin naa la ọrọ mọlẹ. “Awa kò ni ifarakanra pẹlu Awọn Ẹlẹ́rìí ni agbegbe yii. Iwọ ha lè mú ifarakanra pẹlu wọn padabọsipo fun wa bi?”

“Dajudaju emi yoo ṣe bẹẹ,” ni esi ti mo fọ̀ loju ẹsẹ. Agbegbe naa tobi, ohun ti o ju 60 ibusọ lọ ni gigun, lati Riesa si Zittau, ati ohun ti ó tó ibusọ 30 ni fífẹ̀. Gbogbo ohun ti mo sì ní ni kẹ̀kẹ́ kan. Nigba ti a fidii ifarakanra pẹlu Awọn Ẹlẹ́rìí kọọkan mulẹ, ẹnikọọkan ni a mú darapọ pẹlu ìjọ tirẹ̀, eyi ti ó maa ń rán aṣoju si Berlin deedee lati kó iwe ikẹkọọ ati awọn itọni. Ọ̀nà ti a gbà ń gbéṣẹ́ṣe yii dí fifi awọn ìjọ miiran sinu ewu lọwọ nigba ti awọn alaṣẹ bá ń ṣenunibini si ìjọ eyikeyii kan.

Ni Igbẹkẹle Ninu Jehofa

Laika inunibini sí, ni iṣegbọran si awọn itọni Bibeli, a kò dawọ lilọ lati ile de ile pẹlu ihin-iṣẹ wa nipa Ijọba Ọlọrun duro. (Matiu 24:14; 28:19, 20; Iṣe 20:20) A ṣebẹwo si awọn ibugbe oninọmba lara lori ipilẹ awọn idamọran lati ọdọ awọn ẹni ti a ti mọ̀ tẹlẹ, a sì gbadun awọn iriri agbayanu melookan. Nigba miiran awọn aṣiṣe wa paapaa ni a yipada si awọn ibukun, gẹgẹ bi eyi ti ó tẹle e yii ti ṣakawe.

Emi ati aya mi ni a fun ni adirẹsi kan lati bẹwo, ṣugbọn a lọ si ile ọ̀tọ̀. Nigba ti ilẹkun ṣí, a ṣakiyesi aṣọ ọlọpaa lori ìkọ́. Oju Margit rẹwẹsi; ọkan-aya mi lùkìkì. Eyi lè tumọsi ẹ̀wọ̀n. Kìkì adura àyáragbà ni akoko wà fun.

“Ta ni yin?” ni ọkunrin naa beere ni kukuru. A farabalẹ.

“Ó dá mi loju pe mo mọ̀ ọ́ nibikan,” ni Margit sọ, “ṣugbọn emi kò wulẹ lè ranti ibo ni mọ́. Bẹẹni, ọlọpaa ni iwọ. Mo ti nilati ri ọ lẹnu iṣẹ.”

Eyi mú ọ̀ràn naa fúyẹ́, ó sì beere pẹlu ohùn bi ọ̀rẹ́. “Ẹlẹrii Jehofa ni yin bi?”

“Bẹẹni,” ni mo lóhùn sii, “Ẹlẹrii ni wa, iwọ sì gbọdọ gbà pe ó gba igboya fun wa lati kan ilẹkun rẹ. A nifẹẹ si ọ gẹgẹ bi ẹnikan.”

Ó ké sí wa wọnu ile rẹ̀. A ṣebẹwo sọdọ rẹ̀ ni ọpọlọpọ ìgbà a sì bẹrẹ ikẹkọọ Bibeli. Laipẹ laijinna ọkunrin yii di Kristẹni arakunrin wa. Ẹ wo bi iriri yẹn ṣe fun igbẹkẹle wa ninu Jehofa lokun tó!

Awọn arabinrin niye ìgbà ń ṣe bii awọn olùkówèé, eyi ti ó beere pe ki wọn fi igbẹkẹle wọn patapata sinu Jehofa. Bẹẹ ni ọ̀ràn rí lẹẹkan ri nigba ti Margit rinrin-ajo lọ si Berlin lati lọ kó iwe ikẹkọọ. Ohun ti ó wà pọ̀ ju ohun ti ó reti lọ. Ó lo okùn ìsáṣọsí lati di apoti aṣọ wiwuwo, ti ó kún àkúnwọ́sílẹ̀. Gbogbo nǹkan lọ daradara titi di ìgbà ti Margit wà ninu ọkọ̀ oju-irin. Lẹhin naa ni oṣiṣẹ ẹnu ibode kan ṣàdéédé yọju.

“Ta ni lẹrù, ki ni ó sì wà ninu rẹ̀?” ni ó beere, ni nínàka si apoti aṣọ naa.

“Ẹrù aṣọ fífọ̀ mi ni,” Margit dahun pada.

Bí ara ti fu ú, ó paṣẹ fun un lati tú u. Ní diẹdiẹ ati ní mímọ̀ọ́mọ̀, ó ń tú kókó kọọkan nigba kan, Margit bẹrẹ sii tú awọn okùn ìsáṣọsí ti ó yi apoti naa ká. Niwọn bi iṣẹ oṣiṣẹ ẹnu bode naa ti beere fun pe ki o rin irin-ajo pẹlu ọkọ̀ oju-irin naa kìkì fun gigun ọ̀nà kan ki ó sì sọkalẹ ki ó wọ ọkọ̀ oju-irin miiran pada, kò lè mú suuru mọ́. Nikẹhin, nigba ti ó ku kìkì kókó mẹta, ó juwọsilẹ. “Bá araarẹ dànù, ki o sì maa gbé ẹrù aṣọ fífọ̀ rẹ lọ!” ni ó pariwo.

Ìtọ́jú Lati Ọdọ Jehofa Fúnraarẹ̀

Niye ìgbà mo jàjà ń sun orun ti kò ju wakati mẹrin lọ ni alẹ, niwọn bi mo ti sábà maa ń bojuto awọn ọ̀ràn ìjọ loru. Ó jẹ́ lẹhin iru alẹ́ bẹẹ ni awọn ijoye oṣiṣẹ gbá ilẹkun wa ni owurọ ọjọ kan. Wọn ti wá lati ṣe iwadii kan. Ó ti pẹ́ jù lati fi ohunkohun pamọ.

Awọn ijoye oṣiṣẹ naa lo gbogbo owurọ ni títú gbogbo ilé síta, ani ni ṣiṣayẹwo iyàrá ìtura paapaa boya a fi ohunkohun pamọ sibẹ. Kò si ẹni ti ó ronu lati ṣayẹwo jakẹẹti ti mo fi kọ́ sara ìkọ́. Mo ti fi ikanju tọjú awọn iwe akọsilẹ pamọ sinu awọn àpò rẹ̀. Awọn àpò naa wú fun awọn nǹkan ti awọn ijoye oṣiṣẹ ń wá kiri gan-an, ṣugbọn wọn lọ lọ́wọ́ òfo.

Ni akoko miiran, ni August 1961, mo wà ni Berlin. Ó já sí kíkó iwe irohin mi ti ó kẹhin ṣaaju ki a tó mọ Ogiri Berlin. Ibùdókọ̀ oju-irin Berlin kún fun ìrọ́gìrọ́gìrọ́ awọn eniyan ti wọn ti mura lati pada si Zittau. Ọkọ oju-irin dé, olukuluku sì sáré gun ori pepele lati wọle. Bi mo ti ń lọ pẹlu ọpọlọpọ èrò, mo ṣàdéédé bá araami ni apá ibi kan ti ó ṣofo ninu ọkọ̀ oju-irin naa. Kò pẹ ti mo wọle ni oluṣọ ti awọn ilẹkun lode. Mo danikan duro si apa kan naa, ti a sì dari awọn èrò ọkọ yooku wọ inu apá ti o kù ninu ọkọ̀ oju-irin naa.

A gbéra lọ si Zittau. Fun akoko kan mo danikan wà ninu ọkọ̀ naa. Lẹhin naa ọkọ oju-irin naa duro, wọn sì ṣí awọn ilẹkun ti ó wà ni apa ibi ti mo wà. Ọpọlọpọ awọn ọmọ-ogun Soviet wọle. Kìkì nigba naa ni mo tó mọ pe mo ti ń rinrin-ajo ninu apa ti wọn yà sọ́tọ̀ fun awọn ọmọ-ogun Soviet. Ó dabi ki ilẹ la ẹnu ki ó gbémi mì. Sibẹ, awọn ọmọ-ogun naa ko jọbi pe wọn rí ohunkohun ti kò ṣaitọ.

A ń ba irin-ajo lọ si Zittau, nibi ti wọn ti ṣí ilẹkun apa ọdọ wa silẹ gbayawu, ti awọn ọmọ-ogun naa sì bẹ́ pì-pì-pì jade. Wọn bẹrẹ sii tú gbogbo ẹrù awọn èrò inu ọkọ̀ wò ni ibùdókọ̀. Emi nikanṣoṣo ni wọn fi silẹ laidalaamu. Pupọ ninu awọn ọmọ-ogun naa tilẹ bẹ́rí fun mi, ni rironu pe oṣiṣẹ olóyè giga kan ni mi.

Kìkì lẹhin iyẹn ni a tó mọyì bi iwe ikẹkọọ yẹn ti niyelori tó, nitori ìkọ́gbéro Ogiri Berlin bẹgidi ipa-ọna ti a ń gbà rí awọn ipese fun ìgbà kukuru. Sibẹ, iwe ikẹkọọ yẹn tó lati kúnjú awọn aini wa fun awọn oṣu melookan. Laaarin akoko yii ná, awọn iṣeto lati kàn wá lara ni a lè ṣe.

Ifarahan Ogiri Berlin ni 1961 mú awọn iyipada wá fun wa ni Ila-oorun Germany. Ṣugbọn Jehofa, gẹgẹ bi o ti maa ń ṣe nigba gbogbo, ti duro de awọn iṣẹlẹ naa niwaju. Ó ń baa lọ lati bojuto wa labẹ ifofinde.—Gẹgẹ bi Hermann Laube ti sọ ọ́.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

A gbadun apejọ kekere kan ni Bautzen

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́