ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w92 5/15 ojú ìwé 28-31
  • Jehofa Bojuto Wa Labẹ Ifofinde—Apa 3

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Jehofa Bojuto Wa Labẹ Ifofinde—Apa 3
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Pipese Ounjẹ Tẹmi
  • Ìyọ́bọ́ Pọ́rọ́ Kan
  • Ninu Ẹ̀wọ̀n Ṣugbọn Lominira
  • Awọn Ọmọ Wa Ni A Danwo
  • Mímú Awọn Igbokegbodo Itagbangba Wa Pọ Sii
  • Awọn Itunṣebọsipo Bi Ominira Ti Sunmọle
  • Jehofa Bojuto Wa Labẹ Ifofinde—Apa 2
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Jehofa Bojuto Wa Labẹ Ifofinde Apa 1
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
  • Bí Ìdílé Mi Ṣe Dúró Ṣinṣin ti Ọlọ́run Sún Mi Ṣiṣẹ́
    Jí!—1998
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
w92 5/15 ojú ìwé 28-31

Jehofa Bojuto Wa Labẹ Ifofinde—Apa 3

Ó JẸ́ March 14, 1990. Ní ọjọ manigbagbe yẹn, mo wà lara awọn wọnni ti wọn wà nibẹ nigba ti ijoye oṣiṣẹ ijọba onipo giga kan ni Ẹka-Iṣẹ Ijọba ti ń bojuto Awọn Àlámọ̀rí Isin ni Ila-oorun Berlin fi iwe aṣẹ ti ń fun Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni ipo ìdámọ̀ labẹ òfin funni ni ohun ti a ń pè ni German Democratic Republic, tabi Ila-oorun Germany nigba naa. Lakooko awọn ìgbésẹ̀ ẹjọ naa ni ọjọ yẹn, mo ronu pada lọ si ìgbà ti mo di Ẹlẹ́rìí mo sì ronu lori awọn akoko iṣoro ti a niriiri rẹ̀.

Lagbedemeji awọn ọdun 1950, nigba ti Margarete, alajọṣiṣẹpọ kan ti ó jẹ́ Ẹlẹ́rìí, kọ́kọ́ bá mi sọrọ nipa awọn igbagbọ rẹ̀ ti a gbekari Bibeli, inunibini Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ni Ila-oorun Germany gbóná janjan. Laipẹ lẹhin iyẹn ó lọ kuro lati lọ ṣiṣẹ nibomiran, mo sì bẹrẹ sii kẹkọọ Bibeli pẹlu Ẹlẹ́rìí miiran. Mo ṣe iribọmi ni 1956, emi ati Margarete sì fẹ́ra ni ọdun yẹn kan naa. A darapọ mọ́ Ijọ Lichtenberg ni Berlin. Ó ni nǹkan bii 60 awọn akede Ijọba ti ń ṣajọpin ninu iṣẹ iwaasu.

Ọdun meji lẹhin iribọmi, awọn ijoye oṣiṣẹ ijọba lọ sí ile ẹni naa tí ń mú ipo iwaju ninu ìjọ wa. Wọn ní in lọ́kàn lati faṣẹ ọba mú un, ṣugbọn ó wà lẹnu iṣẹ ni Iwọ-oorun Berlin. Ó ṣeeṣe fun idile rẹ̀ lati fi tó o leti lati duro sibẹ, ati ni oṣu diẹ lẹhin naa wọn darapọ mọ́ ọn ni Iwọ-oorun. Bi o tilẹ jẹ pe mo wulẹ jẹ́ kìkì ẹni ọdun 24, a fun mi ni awọn ẹru-iṣẹ wiwuwo ninu ìjọ. Mo ń kún fun ọpẹ́ pe Jehofa pese ọgbọn ati okun ti mo nilo lati bojuto iru awọn iṣẹ bẹẹ.—2 Kọrinti 4:7.

Pipese Ounjẹ Tẹmi

Nigba ti wọn mọ Ogiri Berlin ni August 1961, Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa ní Ila-oorun di ẹni ti a mú dádó lojiji kuro lọdọ awọn arakunrin wọn ni Iwọ-oorun. Bayii ni sáà akoko kan nigba ti a ń ṣẹ̀dà iwe ikẹkọọ wa, lakọọkọ nipasẹ ẹ̀rọ ìtẹ̀wé, ati lẹhin naa nipasẹ ọ̀wọ́ awọn ẹ̀rọ aṣẹ̀dà iwe ṣe bẹrẹ. Bẹrẹ ni 1963, mo lo ọdun meji ni ṣiṣe ibi ìkọ̀kọ̀ ninu ile wa lati ṣe ìtẹ̀wé yii. Lẹhin ṣiṣiṣẹ ṣúlẹ̀ ọjọ gẹgẹ bi arọrin-iṣẹ́, mo ń lo gbogbo òru fun ṣiṣe ẹ̀dà Ilé-Ìṣọ́nà pẹlu iranlọwọ awọn arakunrin melookan miiran. Awọn alaṣẹ ni wọn pinnu lati rí fìn-ín ìdi kókò eto-ajọ ìtẹ̀wé wa, ṣugbọn Jehofa ràn wá lọwọ debi pe ounjẹ wa, gẹgẹ bi a ti ń pè é jade lakooko.

Mímú awọn ẹ̀dà iwe irohin wa ti ó pọ̀ tó jade beere fun ìwọ̀n bébà pupọ jaburata, rírí ìwọ̀n iye yii rà ni kò sì rọrun. Bi a bá ti ra bébà ní ọpọ kìtí, eyi yoo ti fa afiyesi awọn alaṣẹ. Nitori naa a jẹ́ ki ẹnikọọkan ra bébà ni ìwọ̀n kekere ki o sì mú un wá si awujọ ikẹkọọ Bibeli wa. Lati ibẹ ni a ti ń kó o lọ si ibi ti a ti ń tẹ iwe irohin naa jade. Awọn Ẹlẹ́rìí miiran a pín awọn iwe irohin ti a ti pari wọnyi kiri lẹhin naa.

Niwọnbi awọn ijoye oṣiṣẹ ti fura pe mo ń lọwọ ninu titẹ iwe ikẹkọọ, wọn bẹrẹ sii ṣọ́ mi lọ́wọ́lẹ́sẹ̀. Ni apa ipari 1965, mo ṣakiyesi wọn ti wọn ń tẹle mi ju bi o ti sábà maa ń rí tẹlẹ lọ mo sì foye mọ pe wọn ń gbèrò ohun kan. Lojiji, wọn ṣe ìkọlù ni kùtùkùtù owurọ ọjọ kan.

Ìyọ́bọ́ Pọ́rọ́ Kan

Mo ń lọ sẹnu iṣẹ ni owurọ ìgbà otutu yẹn. Kí ilẹ̀ tó mọ́ ni, mo sì figboya dojukọ otutu rinrin naa. Nigba ti mo ń rìn lọ, mo rí orí mẹrin lókè ọgbà. Awọn ọkunrin naa ṣẹ́kọ́nà wọn sì ń tọ̀ mi bọ̀ taarata. Sí ìfòyà mi mo da wọn mọ sí olóyè oṣiṣẹ ijọba. Ki ni emi yoo ṣe o?

Ojo dídì jijinlẹ ni a ti wọ́ tì sẹgbẹẹkan lati fààyè silẹ fun ọ̀nà gbóóró kan. Mo ń rìn lọ. Ni gbígbé ori mi walẹ, mo tẹsiwaju pẹlu oju mi ti ń wolẹ̀ roro. Mo yára gbadura wúyẹ́wúyẹ́ kiakia kan. Awọn ọkunrin naa tubọ ń sunmọ tosi sii. Wọn ha ti dá mi mọ̀ bi? Bi a ṣe kọja araawa bayii loju ọ̀nà ẹlẹ́sẹ̀ ti o há gádígádí naa, mo fẹrẹẹ má lè gba ohun ti ń ṣẹlẹ gbọ́. Mo ń yára rìn kémọ́kémọ́. “Éè,” ọ̀kan ninu wọn kébòòsí, “oun niyẹn. Duro níbẹ̀!”

Mo sá gbogbo eré ti ó wà lẹsẹ mi. Ni sísáré gba kọ̀rọ̀, mo fo kọja ọgbà aladuugbo kan ati sinu ẹ̀hìnkùnlé temi. Ní sísá wọnu ile, mo ti ilẹkun mo gbé igi dá a. “Gbogbo yin ẹ dide!” Ni mo ké tantan. “Wọn ti wà nihin-in lati mú mi.”

Margarete ti dé isalẹ ile ni kiakia ó sì duro lẹhin ilẹkun. Kí á tó paju pẹ́ẹ́ mo ti wà ninu yàrá ìkó-nǹkan sí nisalẹ ile ni dídáná sinu àdògán. Mo yára kó gbogbo awọn akọsilẹ ìjọ ti ó wà níkàáwọ́ mi sinu ina tí ń jó.

“Ṣílẹ̀kùn!” ni awọn ọkunrin naa kígbe. “Ṣílẹ̀kùn! Agbèfọ́ba ilu nìyí.”

Margarete kò mira bi mo ti ń jó ohun gbogbo kọja ìdámọ̀. Lẹhin naa mo darapọ mọ Margarete mo sì mi orí pe ki ó ṣí ilẹkun. Awọn ọkunrin naa já wọle.

“Eeṣe ti o fi sálọ?” ni wọn beere.

Laipẹ ọpọ awọn olóyè oṣiṣẹ dé, gbogbo inu ile ni wọn sì tú. Idaniyan mi pataki ni ibi ìpamọ́ nibi ti a kó ẹ̀rọ itẹwe wa ati 40,000 abala tákàdá sí. Ṣugbọn àbáwọlé sinu ibi ti o farasin naa ni wọn kò rí. Bi o tilẹ jẹ pe ifibeere wadii ọrọ lọ fun ọpọ wakati, Jehofa ràn mi lọwọ lati wà ni ìparọ́rọ́. Iriri yẹn tubọ fà wá sunmọra pẹkipẹki mọ Baba wa ọ̀run onifẹẹ ó sì fun wa lokun lati farada.

Ninu Ẹ̀wọ̀n Ṣugbọn Lominira

Ni apá ipari awọn ọdun 1960, a fi tó mi leti lati farahan fun iṣẹ ologun. Niwọnbi emi ko ti lè ṣiṣẹsin pẹlu ẹ̀rí-ọkàn rere, a fi ipá mú mi lati lo oṣu meje ninu ìhámọ́ ati ninu ibùdó òpò ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́. Awọn Ẹlẹ́rìí 15 ni wọn wà ninu ibùdó naa ni Cottbus, guusu ila-oorun Berlin. Gbogbo wa wà nibẹ nitori àìdásí tọ̀túntòsì Kristẹni wa. (Aisaya 2:2-4; Johanu 17:16) Ọjọ ti a fi ń ṣiṣẹ gùn, iṣẹ́-òpò naa sì le. A maa ń jí ni 4:15 owurọ wọn a sì kó wa lọ sẹhin ibùdó lati ṣiṣẹ loju òpó ọ̀nà ọkọ oju-irin. Bi o ti wu ki o ri, nigba ti a wà ninu ẹ̀wọ̀n, a ní awọn anfaani lati sọ fun awọn ẹlomiran nipa Ijọba Jehofa.

Fun apẹẹrẹ, awọn woṣẹ́woṣẹ́ meji wà pẹlu wa ni Cottbus. Ni ọjọ kan mo gbọ pe eyi ti ó kere ju fi ìgbékútà fẹ́ lati bá mi sọrọ. Ki ni ó lè fẹ́ yi o? Ó sọ gbogbo ohun ti ó wà ninu ọkàn rẹ̀ fun mi. Ìyá rẹ̀ àgbà ti jẹ́ woṣẹ́woṣẹ́, ó sì ti mu iru awọn agbara kan naa dagba lẹhin kíka awọn iwe rẹ̀. Bi o tilẹ jẹ pe ọkunrin yii fẹ́ gidigidi lati bọ́ dominira kuro lọwọ awọn agbara ti wọn jẹ gàba lé e lori, ẹ̀rù ìforóyaró ń bà á. Ó sọkún titi. Ṣugbọn ki ni ó kàn mi ninu gbogbo eyi?

Nigba ti ijumọsọrọpọ wa ń  baa lọ, ó ṣalaye pe agbara òye oun lati sọtẹlẹ nipa ọjọ-ọla bàjẹ́ nigba ti oun wà ninu ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹlu Awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa. Mo ṣalaye pe awọn ẹmi buburu tabi awọn ẹmi eṣu, ati awọn ẹmi daradara, tabi awọn angẹli ododo wà. Ni lilo apẹẹrẹ awọn wọnni ti wọn di Kristẹni ni Efesu igbaani, mo tẹnumọ aini naa lati kó gbogbo awọn ohun ti o tan mọ wíwo iṣẹ́ tabi àṣà bíbá ẹmi lò eyikeyii miiran dànù. (Iṣe 19:17-20) “Ki o sì wá Awọn Ẹlẹ́rìí kàn,” ni mo sọ fun un. “Awọn Ẹlẹ́rìí ń gbé nibi gbogbo.”

Ọdọmọkunrin naa fi ibùdó naa silẹ niwọnba awọn ọjọ diẹ lẹhin naa, emi kò sì gbọ́ ohunkohun nipa rẹ̀ mọ́. Ṣugbọn iriri ti mo ni pẹlu ọkunrin ti ẹ̀rù bà gidigidi ti kò sì ni ìtùnú yẹn ti ó yánhànhàn fun ominira mu ifẹ mi fun Jehofa jinlẹ. Awa Ẹlẹ́rìí 15 wà ninu ibùdó nitori igbagbọ wa, ṣugbọn a wà lominira ni ọ̀nà ti ẹmi. Ọdọmọkunrin yẹn ni a ti dá silẹ lominira kuro ninu ẹ̀wọ̀n, ṣugbọn ó ṣì wà ninu ìsìnrú fun “ọlọrun” kan ti ó dáyàfò ó. (2 Kọrinti 4:4) Ẹ wo bi awa Ẹlẹ́rìí ti gbọdọ ṣikẹ ominira tẹmi wa tó!

Awọn Ọmọ Wa Ni A Danwo

Kì í ṣe kìkì pe awọn agbalagba nilati duro gbọnyingbọnyin fun awọn idaniloju igbagbọ wọn ti a gbekari Bibeli nikan ni ṣugbọn bẹẹ gẹgẹ ni awọn ọ̀dọ́ ṣe pẹlu. A mu wọn ni ọ̀ranyàn lati juwọsilẹ ni ile-ẹkọ ati lẹnu iṣẹ. Gbogbo awọn ọmọ wa mẹrẹẹrin nilati mú iduro fun igbagbọ wọn.

Ayẹyẹ àsìá kíkí ni a maa ń ṣe ni gbogbo ọjọ Monday ni ile-ẹkọ. Awọn ọmọ yoo tò wọnu agbala, kọ orin kan, ti wọn yoo sì sọ ọrọ ikini Thälmann ti a fẹnu lasan pe bẹẹ bi a bá ti ń ta àsìá soke. Ernst Thälmann jẹ́ Kọmunisti ara Germany kan ti awọn ṣọja Nazi SS pa ni 1944. Lẹhin ogun agbaye keji, Thälmann di akọni kan ni Ila-oorun Germany. Nitori idaniloju igbagbọ wa ti a gbekari Bibeli pe iṣẹ-isin mímọ́ ni a gbọdọ dari si Jehofa Ọlọrun nikanṣoṣo, aya mi ati emi fun awọn ọmọ wa ni itọni lati duro tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ lakooko iru awọn ayẹyẹ bẹẹ láìkópa.

Awọn ọmọ ile-ẹkọ ni a tun kọ́ ni awọn orin Kọmunisti. Margarete ati emi lọ si ile-ẹkọ awọn ọmọ wa a sì ṣalaye idi ti wọn ki yoo fi kọ iru awọn orin oṣelu bẹẹ. Bi o ti wu ki o ri, a sọ pe, wọn yoo muratan lati kọ́ iru awọn orin miiran. Nipa bayii, ni ọjọ ori ti o kéré, awọn ọmọ wa kẹkọọ lati duro gbọnyingbọnyin ki wọn sì yatọ si awọn ẹlẹgbẹ wọn.

Ni ìhà opin awọn ọdun 1970, ọmọbinrin wa ti o dagba julọ fẹ lati jẹ́ ọmọ-ẹ̀kọ́ṣẹ́ ni ọfiisi kan. Bi o ti wu ki o ri, ọmọ-ẹ̀kọ́ṣẹ́ kọọkan ni a kọ́kọ́ beere pe ki o gba idanilẹkọọ ọlọjọ 14 ṣaaju didi ologun. Niwọn bi ẹ̀rí-ọkàn Renate ki yoo ti fààyè gbà á lati kópa ninu eyi, ó mú iduro onigboya a sì tú u silẹ kuro ninu ẹru-iṣẹ lati gba iru idanilẹkọọ bẹẹ.

Ni akoko ti o fi jẹ́ ọmọ-ẹ̀kọ́ṣẹ́, Renate lọ si kilaasi ikọnilẹkọọ kan nibi ti a ti ké sí i lati wà nibi ifidanrawo ìbọn yíyìn. “Renate, iwọ pẹlu ń bọ̀ wá sibi ifidanrawo ìbọn yíyìn,” ni olukọ naa sọ. Ó dagunla si kíkọ̀ rẹ̀. “Iwọ kò nilati yìnbọn,” ni o ṣeleri. “Iwọ lè bojuto awọn ipapanu.”

Ni irọlẹ ọjọ yẹn, a jiroro awọn nǹkan papọ gẹgẹ bi idile. A nimọlara pe wíwà nibẹ Renate ni ibi ifidanrawo ìbọn yíyìn kò tọna, ani bi kò bá tilẹ kópa ni taarata. Bi a ti fun un lokun nipa ijiroro naa pẹlu wa ati nipasẹ adura, ko jẹ́ ki jìnnìjìnnì dà bo oun. Iru iṣiri wo ni o jẹ́ fun wa lati ri ọmọbinrin wa ọdọ ti o mú iduro fun awọn ilana ododo!

Mímú Awọn Igbokegbodo Itagbangba Wa Pọ Sii

Nigba ti atako lati ṣiṣẹ rọlẹ ni apá ipari awọn ọdun 1970, ipese jaburata awọn itẹjade Kristẹni wa ni a bẹrẹ sii kó wá lati Iwọ-oorun. Bi o tilẹ jẹ pe eyi jẹ́ iṣẹ ti o lewu, awọn arakunrin onigboya yọnda lati ṣe é. A mọriri awọn ipese iwe ikẹkọọ pupọ sii wọnyi ati awọn isapa awọn wọnni ti wọn mu wọn ṣeeṣe. Nigba ti inunibini gbóná janjan ni awọn ọdun ibẹrẹ ifofinde naa, igbokegbodo iwaasu ile-de-ile jẹ́ ipenija gidi kan. Nitootọ, ẹ̀rù ijiya lati ọdọ awọn alaṣẹ sún awọn kan lati fà sẹhin kuro ninu rẹ̀. Ṣugbọn bi akoko ti ń lọ iṣẹ iwaasu itagbangba wa pọ sii lọna amunijigiri. Ni awọn ọdun 1960, kìkì nǹkan bii ipin 25 ninu ọgọrun-un awọn akede Ijọba ni wọn ń kópa ninu iṣẹ-isin ile-de-ile deedee. Bi o ti wu ki o ri, iye ti ń nípìn-ín ninu apá iṣẹ-ojiṣẹ yẹn ti goke dé ipin 66 ninu ọgọrun-un nigba ti o fi maa di apa ipari awọn ọdun 1980! Ni akoko naa awọn alaṣẹ kò fi iyè ti o pọ̀ si igbokegbodo iwaasu itagbangba wa.

Ni akoko kan arakunrin kan ti mo ń bá ṣiṣẹ ninu iṣẹ-ojiṣẹ mu ọmọbinrin rẹ̀ ọdọ dani. Bi a ti mú un lara yá gágá nipa wíwà nibẹ ọmọdebinrin naa, obinrin agbalagba kan ti a bá sọrọ ké si wa wọ ile rẹ̀. Ó mọriri igbekalẹ ọrọ wa ti o bá Iwe Mimọ mu ó sì gbà pe ki a pada wá. Lẹhin eyi ni mo fi ikesini naa lé iyawo mi lọwọ, ẹni ti ó bẹrẹ ikẹkọọ Bibeli inu ile pẹlu obinrin naa lọgan. Laika gigun ọjọ-ori ati kẹ́gẹkẹ̀gẹ ara si, obinrin yii di arabinrin wa ó sì ń baa lọ ni ṣiṣe deedee ninu iṣẹ-isin Jehofa.

Awọn Itunṣebọsipo Bi Ominira Ti Sunmọle

Jehofa mura wa silẹ fun akoko ìgbà ti awa yoo gbadun ominira giga ju. Lati ṣakawe: Kété ṣaaju ki a tó gbé ifofinde kuro, a sọ fun wa lati lati yi ọ̀nà ti a gbà ń sọrọ pẹlu araawa ẹnikinni keji pada ni awọn ipade. Nitori aabo, a ti pe araawa ẹnikinni keji ni kìkì orukọ akọkọ wa. Ọpọlọpọ ti wọn ti mọ araawọn ẹnikinni keji fun ọpọ ọdun kò mọ orukọ idile ti onigbagbọ ẹlẹgbẹ wọn. Ni imurasilẹ fun kíkí pupọ sii awọn olùfìfẹ́hàn kaabọ si awọn ipade, bi o ti wu ki o ri, a fun wa niṣiiri lati pe araawa ẹnikinni keji pẹlu awọn orukọ idile. Fun awọn kan eyi dabi ṣiṣai tọka si ẹnikan pato, ṣugbọn awọn wọnni ti wọn tẹle amọran naa fi ìrọ̀rùn yipada nigba ti a gba ominira wa.

A tun fun wa niṣiiri lati bẹrẹ awọn ipade wa pẹlu orin. Ni ọ̀nà yii a dagba dojulumọ ọ̀nà igbaṣe tí awọn ìjọ nibomiran ń tẹle. Itunṣebọsipo miiran jẹ́ niti ìtóbi awujọ ikẹkọọ wa. Wọn pọ sii ni kẹrẹkẹrẹ lati ori ẹni mẹrin ni awọn ọdun 1950 dé ori mẹjọ. Lẹhin naa a mú wọn tobi sii dori 10 ati nikẹhin 12. Ni afikun, iwadiiwo kan ni a ṣe lati ri i daju pe ibi ipade fun ìjọ kọọkan ni a mú ki o wà ni aarin gbungbun fun ọpọ julọ Awọn Ẹlẹ́rìí.

Nigba miiran ó maa ń ṣeeṣe fun wa lati ri ọgbọn itunṣebọsipo kan ti a damọran kìkì lẹhin ìgbà ti a bá ti ṣe é tan. Jehofa ti fi araarẹ̀ han gẹgẹ bi Baba ọlọgbọn ati agbatẹniro lọpọ ìgbà tó! Ni kẹrẹkẹrẹ, ó mú wa wá sinu ìlà pẹlu iyooku eto-ajọ rẹ̀ ti ori ilẹ̀-ayé, a sì nimọlara jíjẹ́ apakan ẹgbẹ ara kari ayé ti awọn eniyan rẹ̀ siwaju ati siwaju sii. Dajudaju, Jehofa Ọlọrun ti fi tifẹtifẹ daabobo awọn eniyan rẹ̀ jalẹ ohun ti o sunmọ 40 ọdun ti wọn fi ṣiṣẹ labẹ ifofinde ni Ila-oorun Germany. A ti yọ̀ tó nisinsinyi lati ni ipo ti a tẹwọgba labẹ ofin!

Lonii, 22,000 Awọn Ẹlẹ́rìí ti Jehofa tabi ju bẹẹ lọ ni wọn wà ni ibi ti a ń pe ni Ila-oorun Germany tẹlẹri. Wọn duro gẹgẹ bi ẹ̀rí fun itọsọna ati abojuto onifẹẹ Jehofa Ọlọrun. Itilẹhin rẹ̀ ni awọn ọdun ti a wà labẹ ifofinde fihan pe oun lè jà lodisi ipo eyikeyii. Laika ohun ìjà ti a lè rọ lodisi awọn eniyan rẹ̀ si, kò ni ṣaṣeyọri. Jehofa sábà maa ń bojuto awọn wọnni ti wọn ni igbẹkẹle ninu rẹ̀ daradara. (Aisaya 54:17; Jeremaya 17:7, 8) Gẹgẹ bi Horst Schleussner ti sọ ọ́.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Horst ati Margarete Schleussner ni ayika ọgbà Society ni Ila-oorun Berlin

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́